Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tá a fi sọ pé Jésù ni àwọn gbólóhùn bí “ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú” àti “ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i” ń tọ́ka sí, pé kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfarahàn yìí ni aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà yóò fi hàn ní àwọn àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀, òun Ọba àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa, ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú, ẹni tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́, ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.”—1 Tímótì 6:15, 16.

Ohun táwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni pé, Olódùmarè nìkan làwọn gbólóhùn bí “ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú,” “Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà” àti “ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i,” lè máa tọ́ka sí. Lóòótọ́, a lè lo irú àwọn gbólóhùn wọ̀nyí fún Jèhófà. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ká fi hàn pé Jésù gan-an ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú 1 Tímótì 6:15, 16.

Níparí ẹsẹ kẹrìnlá, Pọ́ọ̀lù sọ nípa “ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kristi.” (1 Tímótì 6:14) Nítorí náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ ohun tó wà 1Tí 6 lẹ́sẹ̀ kẹẹ̀ẹ́dógún pé, “ìfarahàn yìí ni aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà yóò fi hàn ní àwọn àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀,” ìfarahàn Jésù ló ń sọ nípa rẹ̀, kì í ṣe ti Jèhófà Ọlọ́run. Nígbà náà, ta wá ni “Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà”? Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé Jésù ni Ọba Alágbára Gíga tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí. Kí nìdí? Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ yìí ká mú kó hàn kedere pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń fi Jésù wé àwọn ọba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, “Ọba àwọn [ẹ̀dá èèyàn] tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn [ẹ̀dá èèyàn] tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa” ni Jésù lóòótọ́. a Dájúdájú, tá a bá fi Jésù wé àwọn ọba èèyàn, òun ni “Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo.” Ọlọ́run ti fún Jésù ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dáníẹ́lì 7:14) Kò sí ọba èèyàn kankan tó lè sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa ara rẹ̀!

Ta wá ni gbólóhùn náà, “ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú” ń tọ́ka sí? Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù tún ń fi Jésù àtàwọn ọba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn wéra níbi yìí pẹ̀lú. Kò sí ọba ayé kankan tó lè sọ pé Ọlọ́run fún òun ní àìkú, àmọ́ Jésù lè sọ bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A mọ̀ pé Kristi, nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú, kò tún kú mọ́; ikú kò tún jẹ́ ọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.” (Róòmù 6:9, 10) Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù lẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé a fún ní ẹ̀bùn àìleèkú. Àní sẹ́, lákòókò tí Pọ́ọ̀lù ń kọ ọ̀rọ̀ yìí, Jésù nìkan ṣoṣo lẹ́ni tí ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ ìwàláàyè tí kò ṣeé pa run.

A tún ní láti fi sọ́kàn pé yóò jẹ́ ohun tí kò tọ̀nà fún Pọ́ọ̀lù láti sọ pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló ní àìleèkú, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù náà kò lè kú mọ́ lákòókò tí Pọ́ọ̀lù ń kọ ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù lè sọ pé Jésù nìkan lẹ́ni tí kò lè kú tá a bá fi Jésù wé àwọn alákòóso ilẹ̀ ayé.

Síwájú sí i, ó dájú pé lẹ́yìn tí Jésù ti jíǹde tó sì ti gòkè re ọ̀run, a lè pè é ní “ẹni tí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.” Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tá a fàmì òróró yàn yóò rí i lẹ́yìn táwọn náà bá ti kú tí wọ́n sì ti jí dìde sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (Jòhánù 17:24) Àmọ́ kò sí èèyàn kankan lórí ilẹ̀ ayé tí yóò rí Jésù nínú ipò ológo tó wà. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ lóòótọ́ pé látìgbà tí Jésù ti jíǹde tó sì ti gòkè re ọ̀run, “kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn” tó rí Jésù sójú.

Lóòótọ́, téèyàn bá kọ́kọ́ wo ẹsẹ yìí gààràgà, ó lè dà bíi pé Ọlọ́run làwọn àpèjúwe tó wà ní 1 Tímótì 6:15, 16 ń tọ́ka sí. Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ ká, àti ẹ̀rí tá a rí nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn fi hàn pé Jésù ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tún sọ irú àwọn gbólóhùn yìí nípa Jésù ní 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6; Ìṣípayá 17:12, 14; 19:16.