Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo Yìí

Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo Yìí

Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo Yìí

“Énọ́kù sì ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́. Lẹ́yìn náà, òun kò sì sí mọ́, nítorí tí Ọlọ́run mú un lọ.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 5:24.

1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó mú kí àkókò wa yìí jẹ́ àkókò ìyọnu?

 ÌGBÀ hílàhílo! Ọ̀nà tó ṣe kedere gan-an ni gbólóhùn yìí gbà ṣàpèjúwe àwọn ọdún oníwàhálà àti oníwà ipá táráyé ti kó sí látìgbà tí Ìjọba Mèsáyà ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Àtìgbà yẹn laráyé ti wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Àwọn ìyọnu bí ìyàn, àrùn, ìsẹ̀lẹ̀ àti ogun sì ti han aráyé léèmọ̀ ju tìgbàkigbà rí lọ. (2 Tímótì 3:1; Ìṣípayá 6:1-8) Èyí ò sì yọ àwọn olùjọsìn Jèhófà sílẹ̀. Gbogbo wa là ń kojú ìṣòro àtàwọn ipò àìdánilójú tí ayé wà lónìí. Wàhálà ìṣúnná owó, rògbòdìyàn àwọn olóṣèlú, ìwà ọ̀daràn, àti àìsàn wà lára àwọn nǹkan tó mú kí ìgbésí ayé nira fáwọn èèyàn.

2. Kí ni nǹkan táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń fojú winá rẹ̀?

2 Ohun mìíràn tún wà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń fojú winá rẹ̀ lásìkò yìí, ìyẹn ni inúnibíni. Ńṣe ni inúnibíni ń gorí inúnibíni fáwọn Kristẹni bí Sátánì ṣe ń gbógun ti ‘àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ìjẹ́rìí Jésù.’ (Ìṣípayá 12:17) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nínú wa ò tíì fojú winá inúnibíni tó le koko rí. Síbẹ̀, gbogbo Kristẹni ló ní láti gbéjà ko Sátánì Èṣù àti ẹ̀mí tí Sátánì ń mú kó tàn kálẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. (Éfésù 2:2; 6:12) A gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà kí ẹ̀mí ayé yìí má bàa ràn wá, nítorí pé kò síbi tí ẹ̀mí yìí ò sí, ó wà níbi iṣẹ́, nílé ìwé, àti níbikíbi tí nǹkan bá ti da àwa àtàwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn mímọ́ pọ̀.

Ọlọ́run Ni Kó O Bá Rìn, Má Ṣe Bá Àwọn Orílẹ̀-Èdè Rìn

3, 4. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni gbà yàtọ̀ sí ayé?

3 Láti ọ̀rúndún kìíní làwọn Kristẹni ti ń sa gbogbo ipá wọn kí ayé yìí má báa kó èèràn rẹ̀ ràn wọ́n, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí kò sí nínú ìjọ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn yìí nígbà tó kọ̀wé pé: “Nítorí náà, èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí sí nínú Olúwa, pé kí ẹ má ṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn, bí wọ́n ti wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, nítorí àìmọ̀kan tí ń bẹ nínú wọn, nítorí yíyigbì ọkàn-àyà wọn. Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.”—Éfésù 4:17-19.

4 Ẹ ò rí i pé kedere làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣàlàyé inú òkùnkùn biribiri tí ayé yìí wà nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere! Ó rí bẹ́ẹ̀ nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, ó sì tún rí bẹ́ẹ̀ lónìí. Bíi ti ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni òde òní náà kì í ‘rìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ń rìn.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n láǹfààní tó ga láti máa bá Ọlọ́run rìn. Lóòótọ́, àwọn kan lè máa béèrè bóyá ó mọ́gbọ́n dání láti sọ pé èèyàn aláìpé lásánlàsàn ń bá Jèhófà rìn. Àmọ́, Bíbélì sọ pé wọ́n lè bá a rìn. Kódà, ohun tí Jèhófà ń retí pé kí wọ́n ṣe nìyẹn. Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Míkà kọ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí pé: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”Míkà 6:8.

Báwo La Ṣe Lè Bá Ọlọ́run Rìn, Kí sì Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Ṣe Bẹ́ẹ̀?

5. Báwo ni ẹ̀dá aláìpé ṣe lè bá Ọlọ́run rìn?

5 Báwo la ṣe lè bá Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára gbogbo, tá ò sì lè fojú rí rìn? Ó dájú pé a ò lè bá Jèhófà rìn lọ́nà tá a máa gbà bá èèyàn bíi tiwa rìn. Ọ̀rọ̀ náà “rìn” nínú Bíbélì lè túmọ̀ sí “bíbá a lọ láti máa ṣe ohun kan pàtó.” a Ohun tá a túmọ̀ rẹ̀ sí yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń bá Ọlọ́run rìn máa ń gbé ìgbé ayé tó bá ọ̀nà tí Ọlọ́run là sílẹ̀ tí inú rẹ̀ sì dùn sí mu. Bíbá Ọlọ́run rìn lọ́nà yìí ló jẹ́ ká yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó yí wa ká. Bẹ́ẹ̀ ohun kan ṣoṣo tó tọ́ fún àwa Kristẹni láti ṣe nìyẹn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ pọ̀ gan-an.

6, 7. Kí nìdí tí bíbá Ọlọ́run rìn fi jẹ́ ohun tó dára jù lọ láti máa ṣe?

6 Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ni Orísun ìwàláàyè wa àti Olùpèsè gbogbo ohun tá a nílò láti gbé ẹ̀mí wa ró. (Ìṣípayá 4:11) Nítorí ìdí èyí, òun nìkan ṣoṣo ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún wa bó ṣe yẹ ká máa rìn. Yàtọ̀ síyẹn, bíbá Ọlọ́run rìn ni ọ̀nà tó ṣeni láǹfààní jù lọ. Jèhófà ti ṣètò ọ̀nà táwọn tó ń bá a rìn máa gbà rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n ní ìrètí tó dájú pé àwọn máa wà láàyè títí láé. Bàbá wa ọ̀run tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ tún ti pèsè ìtọ́ni ọlọgbọ́n tó ń ran àwọn tó ń bá a rìn lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé rere nísinsìnyí, láìka bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìpé sí, tí wọ́n sì ń gbé nínú ayé tó wà lábẹ́ agbára Sátánì. (Jòhánù 3:16; 2 Tímótì 3:15, 16; 1 Jòhánù 1:8; 2:25; 5:19) Ìdí mìíràn tá a fi ń bá Ọlọ́run rìn ni pé fífi gbogbo ọkàn wa bá a rìn ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan túbọ̀ wà nínú ìjọ.—Kólósè 3:15, 16.

7 Lékè gbogbo rẹ̀, ìdí pàtàkì jù lọ tó fi yẹ ká bá Ọlọ́run rìn ni pé, tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi ìhà tá a wà hàn nínú ọ̀ràn ńlá tí Sátánì dá sílẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn ọ̀ràn nípa ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) A ń tipasẹ̀ ọ̀nà tá a ń gbà gbé ìgbésí ayé wa fi hàn pé ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà digbí, a sì ń polongo láìbẹ̀rù pé òun nìkan ṣoṣo ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. (Sáàmù 83:18) A ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tó bá àdúrà tá à ń gbà mu pé kí orúkọ Ọlọ́run di sísọ di mímọ́, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di ṣíṣe. (Mátíù 6:9, 10) Àwọn tó yàn láti bá Ọlọ́run rìn mà kúkú gbọ́n o! Ó dá wọn lójú pé ọ̀nà tó tọ́ làwọ́n ń tọ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.” Kì í ṣàṣìṣe.—Róòmù 16:27.

8. Báwo ni ìgbà ayé Énọ́kù àti ti Nóà ṣe jọ àkókò tiwa?

8 Àmọ́ ṣá o, báwo lèèyàn ṣe lè gbé ìgbésí ayé lọ́nà tó yẹ kí Kristẹni máa gbé e lákòókò hílàhílo yìí, tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ò fẹ́ sin Jèhófà? A óò rí ìdáhùn sí èyí nígbà tá a bá gbé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìgbàanì yẹ̀ wò, ìyẹn àwọn tó pa ìwà títọ́ wọn mọ́ láwọn àkókò ìṣòro. Méjì lára àwọn wọ̀nyí ni Énọ́kù àti Nóà. Àkókò tó dà bíi tiwa yìí làwọn méjèèjì gbé ayé. Ìwà ibi gbòde kan lákòókò náà. Ìwà ipá àti ìṣekúṣe kúnnú ayé ní ọjọ́ Nóà. Síbẹ̀, Énọ́kù àti Nóà kọ ẹ̀mí ayé sílẹ̀ pátápátá, wọ́n sì bá Jèhófà rìn. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà ṣe é? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, a óò jíròrò àpẹẹrẹ Énọ́kù nínú àpilẹ̀kọ yìí. A óò sì jíròrò ti Nóà nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo

9. Kí làwọn ohun tá a rí kà nípa Énọ́kù?

9 Énọ́kù lẹni tí Ìwé Mímọ́ kọ́kọ́ mẹ́nu kàn pé ó bá Ọlọ́run rìn. Àkọsílẹ̀ Bíbélì náà sọ pé: “Lẹ́yìn tí ó sì bí Mètúsélà, Énọ́kù ń bá a lọ ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:22) Àmọ́, lẹ́yìn tí àkọsílẹ̀ náà sọ iye ọdún tí Énọ́kù lò láyé, èyí tó gùn gan-an tá a bá fi wé ọjọ́ ayé tiwa, àmọ́ tó kúrú gan-an láyé ìgbà yẹn lọ́hùn-ún, ó wá sọ pé: “Énọ́kù sì ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́. Lẹ́yìn náà, òun kò sì sí mọ́, nítorí tí Ọlọ́run mú un lọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:24) Ó dájú pé ńṣe ni Jèhófà ṣí Énọ́kù nípò padà tó sì mú kó sùn nínú ikú kí ọwọ́ ọ̀tá tó tẹ̀ ẹ́. (Hébérù 11:5, 13) Yàtọ̀ sáwọn ẹsẹ bíi mélòó kan yìí, àwọn ẹsẹ díẹ̀ mìíràn tún sọ̀rọ̀ nípa Énọ́kù nínú Bíbélì. Látinú àwọn ohun tá a rí kà yìí àtàwọn ẹ̀rí mìíràn, a lè sọ ọ́ ní kedere pé ìgbà hílàhílo ni Énọ́kù gbé ayé lóòótọ́.

10, 11. (a) Báwo ni ìwà ìbàjẹ́ ṣe tàn kálẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Énọ́kù wàásù rẹ̀, kí sì ni ìṣesí àwọn tó gbọ́ ọ?

10 Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀nà tí ìwà ìbàjẹ́ fi tàn kálẹ̀ kíákíá láàárín ìràn ènìyàn lẹ́yìn tí Ádámù ṣẹ̀ yẹ̀ wò. Bíbélì sọ fún wa pé Kéènì, àkọ́bí Ádámù lẹni tó kọ́kọ́ pànìyàn láyé, nígbà tó pa Ébẹ́lì, àbúrò rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:8-10) Lẹ́yìn tí Ébẹ́lì kú ikú oró yìí, Ádámù àti Éfà tún bí ọmọkùnrin mìíràn, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì. Òun la kà nípa rẹ̀ pé: “A sì bí ọmọkùnrin kan fún Sẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́ṣì. Àkókò yẹn ni a bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:25, 26) Ó ṣeni láàánú pé bí wọ́n tilẹ̀ ń “pe orúkọ Jèhófà” wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà rẹ̀. b Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Énọ́ṣì, àtọmọdọ́mọ Kéènì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lámékì kọ orin kan fún àwọn ìyàwó rẹ̀ méjèèjì tó sọ pé òun ti pa ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó dọ́gbẹ́ sí òun lára. Ó tún là á mọ́lẹ̀ pé: “Bí a óò bá gbẹ̀san Kéènì ní ìgbà méje. Nígbà náà, ti Lámékì yóò jẹ́ ní ìgbà àádọ́rin àti méje.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:10, 19, 23, 24.

11 Àwọn kókó díẹ̀ tá a mẹ́nu kàn lókè yìí fi hàn pé kò pẹ́ rárá tí ìwà ìbàjẹ́ tí Sátánì dá sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì fi mú kí ìwà ibi tàn kálẹ̀ láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù. Inú irú ayé bẹ́ẹ̀ ni Énọ́kù ti jẹ́ wòlíì Jèhófà, kódà ọ̀rọ̀ rẹ̀ alágbára tó ní ìmísí ṣì wúlò gan-an lọ́jọ́ òní. Júdà ròyìn pé Énọ́kù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn yóò ní ìmúṣẹ ìkẹyìn ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé nígbà ayé Énọ́kù pàápàá, ọ̀pọ̀ “àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” ló gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù tí wọ́n sì bínú gidigidi. Ẹ ò rí i pé mímú tí Jèhófà mú wòlíì náà lọ káwọn èèyàn yẹn má bàa ṣe é léṣe fìfẹ́ hàn gan-an ni!

Kí Ló fún Énọ́kù Lókun Láti Bá Ọlọ́run Rìn?

12. Kí ló mú kí Énọ́kù yàtọ̀ sí gbogbo àwọn tí wọ́n jọ gbé ayé lákòókò kan náà?

12 Nínú ọgbà Édẹ́nì lọ́hùn-ún, Ádámù àti Éfà fetí sí Sátánì, Ádámù sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Àmọ́, Ébẹ́lì ọmọ wọn tọ ipa ọ̀nà tó yàtọ̀ sí tiwọn pátápátá, Jèhófà sì fojú rere wò ó. (Jẹ́nẹ́sísì 4:3, 4) Ó dunni pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ni kò fìwà jọ Ébẹ́lì. Àmọ́ Énọ́kù tí wọ́n bí ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìyẹn wá fìwà jọ ọ́. Kí ni Énọ́kù fi yàtọ̀ sáwọn mìíràn tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yẹn nígbà tó kọ̀wé pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú, a kò sì rí i níbi kankan nítorí tí Ọlọ́run ti ṣí i nípò padà; nítorí ṣáájú ìṣínípòpadà rẹ̀, ó ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.” (Hébérù 11:5) Énọ́kù wà lára ọ̀pọ̀ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí [tí wọ́n wà ṣáájú ìsìn Kristẹni],” tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títayọ. (Hébérù 12:1) Ìgbàgbọ́ ló mú kó ṣeé ṣe fún Énọ́kù láti hùwà tó dáa tó sì fi ìfaradà lo gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún, èyí tó ju ìlọ́po mẹ́ta ọjọ́ ayé ọ̀pọ̀ jù lọ wa lónìí!

13. Irú ìgbàgbọ́ wo ni Énọ́kù ní?

13 Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ìgbàgbọ́ Énọ́kù àti ti àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn nígbà tó kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tó dáni lójú pé ọwọ́ wa yóò tẹ àwọn ohun tí à ń retí. Ohun tá à ń retí yẹn lágbára lọ́kàn wà débi pé ó nípa lórí ohun tá a fẹ́ fi ayé wa ṣe. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ló mú kó ṣeé ṣe fún Énọ́kù láti bá Ọlọ́run rìn bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó yí i ká kò ṣe bẹ́ẹ̀.

14. Irú ìmọ̀ pípéye wo ló ní láti mú kí Énọ́kù ní ìgbàgbọ́?

14 Ìmọ̀ pípéye ló máa jẹ́ ká ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Irú ìmọ̀ wo ni Énọ́kù ní? (Róòmù 10:14, 17; 1 Tímótì 2:4) Ó dájú pé Énọ́kù ti ní láti mọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì dáadáa. Bóyá ó tún gbọ́ nípa bí nǹkan ṣe dára gan-an nínú ọgbà Édẹ́nì, tó ṣeé ṣe kó ṣì wà lákòókò yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn kankan ò lè wọbẹ̀ mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:23, 24) Ó tún mọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run pé àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù yóò kún ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì sọ gbogbo ayé di Párádísè bíi ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó sì dájú pé Énọ́kù fojú pàtàkì wo ìlérí tí Jèhófà ṣe nígbà náà lọ́hùn-ún pé òun yóò mú Irú Ọmọ kan wá tí yóò pa Sátánì run tí yóò sì mú gbogbo ìyọnu tí ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì dá sílẹ̀ kúrò. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Láìsí àní-àní, àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí tí Énọ́kù fúnra rẹ̀ sọ, èyí tó wà nínú ìwé Júdà, sọ nípa ìparun irú ọmọ Sátánì. Níwọ̀n bí Énọ́kù ti ní ìgbàgbọ́, a mọ̀ pé ó jọ́sìn Jèhófà, ó sì gbà pé “òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Énọ́kù kò ní gbogbo ìmọ̀ tá a ní lónìí, síbẹ̀ ó ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó láti ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Ìgbàgbọ́ yìí ló mú kí Énọ́kù lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ ní gbogbo àkókò hílàhílo yẹn.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Énọ́kù

15, 16. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Énọ́kù?

15 Níwọ̀n bá a ti fẹ́ múnú Jèhófà dùn bíi ti Énọ́kù láwọn àkókò hílàhílo tá à ń gbé lónìí, a ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Énọ́kù. A ní láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe, ká má sì jẹ́ kí ìmọ̀ yìí bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, kò mọ síbẹ̀ o. A ní láti jẹ́ kí ìmọ̀ pípéye náà máa tọ́ wa sọ́nà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe nígbèésí ayé wa. (Sáàmù 119:101; 2 Pétérù 1:19) A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà, ká máa sapá ní gbogbo ìgbà láti rí i pé gbogbo èrò àti ìṣe wa jẹ́ èyí tí yóò múnú rẹ̀ dùn.

16 A ò mọ̀ nípa ẹlòmíràn tó sin Jèhófà nígbà ayé Énọ́kù, àmọ́ ohun tó hàn kedere ni pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun nìkan ló ń sin Jèhófà nígbà náà tàbí kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn díẹ̀ tó ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwọ̀nba díẹ̀ làwa náà nínú ayé yìí, àmọ́ ìyẹn ò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Jèhófà yóò tì wá lẹ́yìn láìfi ẹnikẹ́ni tó lè lòdì sí wa pè. (Róòmù 8:31) Énọ́kù fìgboyà kìlọ̀ nípa ìparun tó ń bọ̀ wá sórí àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Àwa náà ń lo ìgboyà bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” láìfi ìfiniṣẹ̀sín, àtakò, àti inúnibíni pè. (Mátíù 24:14) Énọ́kù ò pẹ́ láyé tó púpọ̀ lára àwọn tí wọ́n jọ wà láyé nígbà yẹn. Síbẹ̀, kò ka ayé ìgbà yẹn sí nǹkan kan. Ohun kan tó dára jùyẹn lọ gan-an ló ń retí. (Hébérù 11:10, 35) Àwa náà ń fojú sọ́nà de ìmúṣẹ àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe. Ìdí nìyẹn tá ò fi lo ayé yìí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (1 Kọ́ríńtì 7:31) Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìsìn Jèhófà là ń lo okun wa àtàwọn ohun ìní wa fún.

17. Ìmọ̀ wo làwa ní tí Énọ́kù ò ní, kí ló sì yẹ ká ṣe?

17 Énọ́kù nígbàgbọ́ pé Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò fara hàn nígbà tó bá tó àkókò lójú Jèhófà. Ó ti ń lọ sí ẹgbàá [2,000] ọdún báyìí tí Jésù Kristi tó jẹ́ Irú Ọmọ náà ti fara hàn, ó pèsè ìràpadà, ó sì ṣí ọ̀nà láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fún wa àti fún àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ ìgbàanì bí Énọ́kù. Irú Ọmọ náà ti gorí ìtẹ́ báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó ti lé Sátánì kúrò ní ọ̀run wá sórí ilẹ̀ ayé yìí, a sì ń rí ìpọ́njú tí èyí ń fà níbi gbogbo. (Ìṣípayá 12:12) Láìsí àní-àní, ìmọ̀ tá a ní lónìí pọ̀ gan-an ju èyí tí Énọ́kù ní lọ. Ẹ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa jinlẹ̀ bíi tirẹ̀. Kí ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní pé àwọn ìlérí Ọlọ́run á ṣẹ máa nípa lórí gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Ẹ jẹ́ kí àwa náà bá Ọlọ́run rìn bíi ti Énọ́kù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò hílàhílo la wà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ojú ìwé 220, ìpínrọ̀ kẹfà, nínú Ìdìpọ̀ Kìíní ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

b Jèhófà ti bá Ádámù sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó bí Énọ́ṣì. Ébẹ́lì rú ẹbọ kan tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Jèhófà. Kódà, Ọlọ́run bá Kéènì sọ̀rọ̀ kó tó di pé owú jíjẹ àti ìbínú mú kí Kéènì dẹ́ṣẹ̀ ìpànìyàn. Nítorí náà, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí i “pe orúkọ Jèhófà” yìí ní láti jẹ́ lọ́nà kan tó yàtọ̀, kì í ṣe lọ́nà ti ìjọsìn mímọ́.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni bíbá Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí?

• Kí nìdí tí bíbá Ọlọ́run rìn fi jẹ́ ohun tó dára jù lọ láti ṣe?

• Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Énọ́kù láti bá Ọlọ́run rìn láìfi ti àkókò hílàhílo pè?

• Báwo la ṣe lè fara wé Énọ́kù?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Nípa ìgbàgbọ́, ‘Énọ́kù ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ó dá wa lójú hán-únhán-ún pé àwọn ìlérí Jèhófà yóò ṣẹ

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Obìnrin tó wà lápá ọ̀tún pátápátá: Fọ́tò FAO/B. Imevbore; ilé tó ń wó: San Hong R-C Picture Company