Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Èdè Jámánì Ìjímìjí Lo Orúkọ Ọlọ́run

Bíbélì Èdè Jámánì Ìjímìjí Lo Orúkọ Ọlọ́run

Bíbélì Èdè Jámánì Ìjímìjí Lo Orúkọ Ọlọ́run

ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN ìgbà ni Jèhófà, tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde lédè Jámánì lọ́dún 1971. a Àmọ́, òun kọ́ ni Bíbélì èdè Jámánì àkọ́kọ́ tó lo orúkọ Ọlọ́run. Ó jọ pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún sẹ́yìn ni wọ́n tẹ Bíbélì èdè Jámánì tó kọ́kọ́ lo orúkọ náà, Jèhófà, jáde. Johann Eck tó jẹ́ olùkọ́ nípa ẹ̀sìn Kátólíìkì tó sì gbajúmọ̀ gan-an ló ṣe é.

Ọdún 1486 ni wọ́n bí ọ̀gbẹ́ni Johann Eck lápá gúúsù Jámánì. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún, ó ti di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn ní yunifásítì ìlú Ingolstadt, ipò yìí ló sì wà títí tó fi kú lọ́dún 1543. Àkókò kan náà ni Eck àti Martin Luther gbé ayé, ọ̀rẹ́ sì làwọn méjèèjì fúngbà díẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, Luther lọ di aṣáájú Ẹgbẹ́ Tó Ń Ta Ko Àwọn Ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nígbà tí Eck ní tiẹ̀ jẹ́ olùgbèjà ìjọ Kátólíìkì.

Olórí ìlú Bavaria fún Eck láṣẹ láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè Jámánì, wọ́n sì tẹ Bíbélì náà jáde lọ́dún 1537. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó ń jẹ́ Kirchliches Handlexikon ṣe sọ, ohun tó wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ gan-an ló wà nínú Bíbélì rẹ̀ “ó sì yẹ ká ka [Bíbélì] náà sí ju báwọn èèyàn ti kà á sí látẹ̀yìnwá lọ.” Bí Ẹ́kísódù 6:3 ṣe kà nínú Bíbélì Eck nìyí, ó ní: “Èmi ni Olúwa, ẹni tó fara han Ábúráhámù, Ísákì, àti Jákọ́bù ní Ọlọ́run Olódùmarè: orúkọ mi Adonai, ni èmi kò sì tíì ṣí payá fún wọn.” Eck ṣe àlàyé etí ìwé síbi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, èyí tó kà pé: “Adonai Jehoua lorúkọ náà.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ gbà pé èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n lo orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ nínú Bíbélì èdè Jámánì.

Àmọ́, láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti mọ orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ti ń lò ó. Inú èdè Hébérù ni wọ́n ti kọ́kọ́ lo orúkọ yìí, níbi tí wọ́n ti pe Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà ní “Jèhófà.” (Diutarónómì 6:4) Ó [sì] ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún báyìí tí wọ́n ti fi èdè Gíríìkì ṣe àkọsílẹ̀ gbólóhùn tí Jésù sọ pé òun ti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀. (Jòhánù 17:6) Látìgbà náà, wọ́n ti tẹ orúkọ náà jáde nínú àwọn ìwé láìmọye èdè. Láìpẹ́, gbogbo èèyàn ni yóò mọ̀ pé ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé, èyí yóò sì mú ohun tó wà nínú Sáàmù 83:18 ṣẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, ọdún 1961 la sì kọ́kọ́ tẹ̀ ẹ́ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ní báyìí, ó ti wà ní ohun tó lé ní àádọ́ta èdè, yálà lódindi tàbí lápá kan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Bíbélì Johann Eck tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1558 tí orúkọ náà, Jèhófà, wà nínú àlàyé ètí ìwé tí wọ́n ṣe nípa Ẹ́kísódù 6:3