Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí “Àsọjáde” Jèhófà Máa Ṣọ́ Ọ

Jẹ́ Kí “Àsọjáde” Jèhófà Máa Ṣọ́ Ọ

Jẹ́ Kí “Àsọjáde” Jèhófà Máa Ṣọ́ Ọ

ÌJÀ mánigbàgbé kan wáyé nílùú Marathon lọ́dún 490 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Níbi ìjà náà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún àwọn ará Áténì dojú kọ ògìdìgbó awọn ọmọ ogun Páṣíà. Ọgbọ́n kan táwọn ọmọ ogun Gíríìkì tó kéré níye yìí dá ni pé gbogbo wọn ń yan pa pọ̀ wọ́n sì sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Wọ́n gbé apata wọn sún mọ́ra, èyí tó mú kí wọ́n dà bí ògiri tí nǹkan kan kò lè wọ̀, wọ́n sì ń ju ọ̀kọ̀ wọn jáde fòròfòrò. Báwọn ọmọ ogun Áténì wọ̀nyí ṣe sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí ló jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Páṣíà tó pọ̀ jù wọ́n lọ fíìfíì, mánigbàgbé sì ni ìṣẹ́gun náà.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń jagun tẹ̀mí. Àwọn ọ̀tá tó lágbára ni wọ́n ń bá jà, ìyẹn àwọn alákòóso tí kò ṣeé fojú rí tí wọ́n ń darí ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Àwọn ni Bíbélì pè ní “olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, . . . àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12; 1 Jòhánù 5:19) Àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣẹ́gun nìṣó, àmọ́ kì í ṣe ní agbára wọn. Jèhófà ni gbogbo ògo tọ́ sí torí pé òun ló ń ṣọ́ wọn tó sì ń fún wọn ní ìtọ́ni, bí Sáàmù 18:30 ṣe sọ pé: “Àsọjáde Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́. Apata ni ó jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ń sá di í.”

Ká sòótọ́, Jèhófà ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ewu tẹ̀mí nípasẹ̀ “àsọjáde” rẹ̀ tá a yọ́ mọ́, tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Sáàmù 19:7-11; 119:93) Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ nípa ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sọ pé: “Má fi í sílẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́. Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” (Òwe 4:6; Oníwàásù 7:12) Báwo lọgbọ́n àtọ̀runwá ṣe ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu? Gbé àpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ọjọ́un yẹ̀ wò.

Àwọn Èèyàn tí Ọgbọ́n Ọlọ́run Dáàbò Bò

Gbogbo ìgbésí ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lòfin Jèhófà ti dàábò bò wọ́n tó sì tọ́ wọn sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní òfin nípa oúnjẹ, ìmọ́tótó, àti mímú alárùn kúrò láàárín wọn. Òfin náà jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àrùn tó ń pa èèyàn nípakúpa láwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Ẹ̀yìn táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàwárí kòkòrò àrùn ní ọ̀rúndún Kọkàndínlógún ni wọ́n tó lóye ohun tí Òfin Ọlọ́run ti sọ tipẹ́tipẹ́. Òfin tó dá lórí ẹ̀tọ́ onílẹ̀, àtúnrà, dídárí gbèsè jini, àti yíyáni lówó èlé ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní torí pé ó jẹ́ kí àwùjọ wọn wà létòlétò kí ètò ọ̀rọ̀ ajé wọn sì dára. (Diutarónómì 7:12, 15; 15:4, 5) Kódà, Òfin Jèhófà tún jẹ́ kí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dára! (Ẹ́kísódù 23:10, 11) Òfin tí Ọlọ́run ṣe pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké dáàbò bò wọ́n nípa tẹ̀mí. Ó jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìnira àwọn ẹ̀mí èṣù, fífọmọ rúbọ àtàwọn ìwàkiwà mìíràn, àti ìwà tó ń bu ẹ̀dá èèyàn kù, ìyẹn fíforí balẹ̀ fáwọn ère tí kò lẹ́mìí.—Ẹ́kísódù 20:3-5; Sáàmù 115:4-8.

Dájúdájú, “àsọjáde” Jèhófà “kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí” fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì; kàkà bẹ́ẹ̀ ó dá ẹ̀mí àwọn tó mú un lò sí, ó sì jẹ́ kí ọjọ́ ayé wọn gùn. (Diutarónómì 32:47) Bó ṣe rí fáwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ Jèhófà tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n sílò lónìí náà nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin mọ́. (Gálátíà 3:24, 25; Hébérù 8:8) Dípò òfin rẹpẹtẹ, onírúurú ìlànà Bíbélì ló ń tọ́ wọn sọ́nà tó sì ń dáàbò bò wọ́n.

Àwọn Èèyàn Tí Ìlànà Ọlọ́run Ń Dáàbò Bò

Òfin lè dá lórí ohun kan, ó sì lè má pẹ́ yí padà. Àmọ́ ní tàwọn ìlànà Bíbélì, tó jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé, ó sábà máa ń ṣe é fi sílò nínú onírúurú ipò kì í sì í yí padà. Bí àpẹẹrẹ, gbé ìlànà tó wà nínú Jákọ́bù 3:17 yẹ̀ wò, tó kà lápá kan pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà.” Báwo ni òtítọ́ pọ́ńbélé yìí ṣe lè jẹ́ ààbò fáwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí?

Kéèyàn mọ́ níwà túmọ̀ sí pé kéèyàn máa hùwà tó dára. Nítorí náà, kì í ṣe ìṣekúṣe nìkan làwọn tó mọyì ìwà mímọ́ máa ń sapá láti yàgò fún, wọ́n tún ń yẹra fáwọn nǹkan tó ń múni lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe, irú bíi fífọkàn yàwòrán ìṣekúṣe àti wíwo àwòrán ìṣekúṣe. (Mátíù 5:28) Bákan náà, àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà tí wọ́n sì fi ìlànà inú Jákọ́bù 3:17 sọ́kàn máa ń yàgò fún ìfararora tó lè mú wọn dẹni tí kò ní ìkóra-ẹni-níjàánu mọ́. Nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà, wọn ò jẹ́ kí ohunkóhun tàn wọ́n kúrò nínú ìwà mímọ́, bóyá kí wọ́n máa rò pé táwọn ò bá ṣáà ti rú òfin táwọn rí kà nínú Bíbélì, Jèhófà fara mọ́ ìwà àwọn nìyẹn. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà “ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́,” ìyẹn ló sì fi ń báni lò. (1 Sámúẹ́lì 16:7; 2 Kíróníkà 16:9) Irú àwọn ọlọ́gbọ́n bẹ́ẹ̀ máa ń dáàbò bo ara wọn kúrò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àrùn tó ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, èyí tó gbòde kan lónìí, wọn ò sì kó ìrònú àti ìbànújẹ́ bá ara wọn.

Jákọ́bù 3:17 tún sọ pé ọgbọ́n Ọlọ́run “lẹ́mìí àlàáfíà.” Bá a ṣe mọ̀, Sátánì ń sapá láti sọ wá di ọ̀tá Jèhófà nípa gbíngbin èrò ìwà ipá sí wa lọ́kàn. Ó máa ń lo àwọn ìwé burúkú, fíìmù tí kò bójú mu, orinkórin, àtàwọn eré orí kọ̀ǹpútà tó jẹ́ pé díẹ̀ lára wọn máa ń dà bíi pé ẹni tó ń lò ó ló ń hùwà ìkà àti ìwà ìpakúpa bíburú jáì tó wà nínú rẹ̀! (Sáàmù 11:5) Bí ìwà ipá ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i fi hàn pé Sátánì ń ṣàṣeyọrí. Nígbà tí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà tó ń jẹ́ The Sydney Morning Herald ń sọ nípa irú àwọn ìwà ipá bẹ́ẹ̀ lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, ó fa ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Robert Ressler yọ, ẹni tó kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà, “àpaàbojúwẹ̀yìn.” Ó sọ pé àwòrán ìṣekúṣe táwọn apààyàn tóun fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò láwọn ọdún 1970 máa ń wò ló kó sí wọn lórí, “ìyẹn ò sì jẹ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn tó wà lóde báyìí.” Èyí ló mú Ressler sọ pé “nǹkan ṣì máa burú sí i lọ́jọ́ iwájú, ọ̀rúndún tó ń bọ̀ yóò sì jẹ́ èyí táwọn tó ń pààyàn bó ṣe wù wọ́n yóò pọ̀ bí eéṣú.”

Lóòótọ́, oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí ìròyìn yìí jáde lọkùnrin kan lọ fi ìbọn pa àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ mẹ́rìndínlógún àti olùkọ́ wọn níléèwé jẹ́-lé-o-sinmi kan nílùú Dunblane nílẹ̀ Scotland, tó sì tún para rẹ̀ lẹ́yìn náà. Oṣù tó tẹ̀ lé e lọkùnrin mìíràn tí orí rẹ̀ dà rú lọ fìbọn pa èèyàn méjìlélọ́gbọ̀n nílùú Port Arthur pípa rọ́rọ́ ní erékùṣù Tasmania nílẹ̀ Ọsirélíà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, pípààyàn nípakúpa níléèwé ti kó jìnnìjìnnì bá ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tó mú káwọn ará Amẹ́ríkà máa béèrè pé, kí ló dé? Lóṣù June, ọdún 2001, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nílẹ̀ Japan gbayé kan nípa bí ọkùnrin kan tí orí rẹ̀ dà rú ṣe wọ iléèwé kan tó sì gún àwọn ọmọ mẹ́jọ tí wọ́n wà ní kíláàsì kìíní àti èkejì nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ pa tó sì tún fọ̀bẹ ya àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún mìíràn yánnayànna. Lóòótọ́, kò sẹ́ni tó mọ ohun tó ń fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àmọ́ ìwà ipá tí wọ́n ń gbé jáde nínú àwọn fíìmú lọ̀pọ̀ èèyàn ń tọ́ka sí pé ó túbọ̀ ń fa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Phillip Adams, ọmọ ilẹ̀ Ọsirélíà kan tó máa ń kọ ìròyìn sọ pé, “bí ìpolówó ọjà ìṣẹ́jú kan péré bá lè mú kí ọjà tà wìtìwìtì, ẹ má ṣe sọ fún mi pé fíìmù tí wọ́n fi wákàtí méjì ṣe, tọ́pọ̀ èèyàn sì nífẹ̀ẹ́ sí gan-an kì í yí ìwà àwọn èèyàn padà.” Bí ọkùnrin yìí ṣe sọ lóòótọ́, ẹgbẹ̀rún méjì fídíò ìṣekúṣe àti fídíò ìwà ipá làwọn ọlọ́pàá kó jáde nílé ọkùnrin tó fìbọn pa àwọn èèyàn rẹpẹtẹ nílùú Port Arthur yẹn.

Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì máa ń dáàbò bo èrò inú àti ọkàn wọn lọ́wọ́ onírúurú nǹkan tó lè mú kí ìfẹ́ láti hùwà ipá máa dàgbà díẹ̀díẹ̀ lọ́kàn wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò jẹ́ kí “ẹ̀mí ayé” nípa lórí ìrònú àti ọkàn wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń kọ́ wọn,’ wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti ní èso rẹ̀ nígbèésí ayé wọn, èyí tí àlàáfíà jẹ́ apá kan rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 2:12, 13; Gálátíà 5:22, 23) Wọ́n ń ṣe èyí nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, gbígbàdúrà, àti ṣíṣe àṣàrò tí ń gbéni ró. Wọ́n tún ń yàgò fún ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tó máa ń ní èrò ìwà ipá lọ́kàn. Àmọ́, àwọn èèyàn bíi tiwọn, tó fẹ́ gbénú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí níbi tí àlàáfíà yóò wà, ni wọ́n ń bá rìn. (Sáàmù 1:1-3; Òwe 16:29) Dájúdájú, ọgbọ́n tó tọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń dáàbò boni gan-an!

Jẹ́ Kí “Àsọjáde” Jèhófà Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ

Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò láginjù, ó pa Sátánì lẹ́nu mọ́ nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Lúùkù 4:1-13) Kò bá Sátánì rojọ́ wẹ́wẹ́ láti mọ ẹni torí ẹ̀ pé jù nínú àwọn méjèèjì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi Ìwé Mímọ́ gbèjà ara rẹ̀ ó sì sọ̀rọ̀ látọkànwá, ìdí nìyẹn tí ọgbọ́n burúkú tí Èṣù ń lò, èyí tó ṣiṣẹ́ gan-an lọ́gbà Édẹ́nì, kò fi nípa lórí Jésù. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì kò ní nípa lórí àwa náà bá a bá ń fàwọn àsọjáde Jèhófà kúnnú ọkàn wa. Kò sóhun tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ, torí pé “láti inú [ọkàn] ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—Òwe 4:23.

Síwájú sí i, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa dáàbò bo ọkàn wa, kò sì gbọ́dọ̀ sú wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì kò rí Jésù mú nínú aginjù, kò jáwọ́ nínú dídán Jésù wò. (Lúùkù 4:13) Kò ní fi àwa náà sílẹ̀, gbogbo ọgbọ́n tó sì mọ̀ ní yóò máa ta láti rí i pé òun ba ìwà títọ́ wa jẹ́. (Ìṣípayá 12:17) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fára wé Jésù, ká nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gidigidi, ká sì máa gbàdúrà láìdabọ̀ pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ àti ọgbọ́n. (1 Tẹsalóníkà 5:17; Hébérù 5:7) Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún gbogbo àwọn tó bá fi Ọlọ́run ṣe ààbò wọn ni pé, wọn ò ní rí aburú tẹ̀mí.—Sáàmù 91:1-10; Òwe 1:33.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Dáàbò Bo Ìjọ

Kò sóhun tí Sátánì lè ṣe tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn kò fi ní la ìpọ́njú ńlá já. (Ìṣípayá 7:9, 14) Síbẹ̀, kò yéé sapá láti sọ ìrònú àwọn Kristẹni dìdàkudà, kí díẹ̀ lára wọn ó kéré tán lè pàdánù ojú rere Jèhófà. Ọgbọ́n tó ń dá yìí ṣíṣẹ́ láyé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tó mú kí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún lára wọn kú nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 25:1-9) Lóòótọ́, àwọn Kristẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ronú pìwà dà máa ń rí ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ gbà láti lè padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí. Àmọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà, ti wọn dà bíi Símírì ayé ọjọ́un jẹ́ ewu fún ipò tẹ̀mí àti ìwà rere àwọn mìíràn. (Númérì 25:14) Irú wọn ò yàtọ̀ sáwọn ọmọ ogun kan tó sọ apata wọn dà nù láàárín ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí nígbà tíjà ń lọ lọ́wọ́. Kì í ṣe ara wọn nìkan nirú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi sínú ewu, wọ́n tún fàwọn yòókù sínú ewu pẹ̀lú.

Ìdí nìyí tí Bíbélì fi pàṣẹ pé: “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun. . . . Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.” (1 Kọ́ríńtì 5:11, 13) Ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà pé “àsọjáde” ọlọ́gbọ́n yìí ń dáàbò bo ìwà mímọ́ àti ipò tẹ̀mí ìjọ Kristẹni?

Òdìkejì èyí làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe. Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, títí kan àwọn apẹ̀yìndà, ló ka àwọn apá kan nínú Bíbélì sóhun tí kò bóde mu mọ́ torí pé ó ta ko ìwà ohun-tó-wù-mí-ni-màá-ṣe tí ọ̀pọ̀ ń hù lóde òní. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ pé kò sóhun tó burú nínú onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí wọ́n ń dá, kódà èyí ò yọ àwọn àlùfáà sílẹ̀. (2 Tímótì 4:3, 4) Àmọ́ kíyè sí àṣẹ tó tẹ̀ lé gbólóhùn inú Òwe 30:5, èyí tó fi “àsọjáde” Jèhófà wé apata. Ní ẹsẹ 6, àṣẹ náà sọ pé: “Má fi nǹkan kan kún ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run], kí ó má bàa bá ọ wí, kí a má bàa sì mú ọ ní òpùrọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, òpùrọ́ pátápátá nípa tẹ̀mí làwọn tó bá ń túmọ̀ Bíbélì sódì, irọ́ tó sì burú jù lọ lèyí! (Mátíù 15:6-9) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká mọrírì bá a ṣe jẹ́ apá kan ètò tó bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

“Òórùn Dídùn” Ń Pa Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Mọ́

Nítorí pé àwọn èèyàn Ọlọ́run rọ̀ mọ́ Bíbélì wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìtùnú inú rẹ̀ fáwọn èèyàn, wọ́n ń tú “òórùn dídùn” jáde bíi tùràrí, èyí tó ń fúnni níyè tó sì ń múnú Jèhófà dùn. Àmọ́, bí Bíbélì J. B. Phillips ṣe sọ ọ́, “òórùn ikú tó ń yọrí sí ìparun” lohun táwọn oníwàásù yìí ń tú jáde jẹ́ fáwọn aláìṣòótọ́ èèyàn. Dájúdájú, ètò àwọn nǹkan Sátánì ti yí ọ̀nà ìgbóòrùn tẹ̀mí àwọn ẹni ibi padà débi pé, ara wọn kì í balẹ̀ níbi táwọn tó ń tú “òórùn dídùn Kristi” jáde bá wà, wọ́n tiẹ̀ lè máa bínú wọn pàápàá. Àmọ́, “òórùn dídùn Kristi” làwọn tó ń fìtara sọ ìhìn rere fáwọn èèyàn jẹ́ “láàárín àwọn tí a ń gbà là.” (2 Kọ́ríńtì 2:14-16) Ńṣe ni àgàbàgebè àtàwọn ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ inú ìsìn èké máa ń kó irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nírìíra. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tá a bá ṣí Bíbélì tá a sì sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú rẹ̀ fún wọn, wọ́n máa ń fẹ́ wá sọ́dọ̀ Kristi wọ́n sì máa ń fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ sí i.—Jòhánù 6:44.

Nítorí náà, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì táwọn kan ò bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa wo “òórùn dídùn Kristi” bí ààbò tẹ̀mí tó ń lé ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹni ibi kúrò láyìíká tẹ̀mí táwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbé, àmọ́ tó ń fa àwọn ọlọ́kàn rere mọ́ra.—Aísáyà 35:8, 9.

Nítorí pé àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí wọ́n sì di apata wọn mú gírígírí níbi ogun ìlú Marathon yẹn, wọ́n borí láìka àwọn ìṣòro kíkàmàmà tí wọ́n dojú kọ sí. Bẹ́ẹ̀ náà ló dájú pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó jólóòótọ́ sí Jèhófà yóò borí nínú ogun tẹ̀mí tí wọ́n ń jà, torí pé “ohun ìní àjogúnbá” wọn lèyí jẹ́. (Aísáyà 54:17) Fún ìdí yìí, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa rí i pé à ń fi Jèhófà ṣe ààbò wa nìṣó, ká máa “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.”—Fílípì 2:16.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

‘Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà’