Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ní Ìfaradà Bí Ọmọ Ogun Kristi

Mo Ní Ìfaradà Bí Ọmọ Ogun Kristi

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Ní Ìfaradà Bí Ọmọ Ogun Kristi

GẸ́GẸ́ BÍ YURII KAPTOLA ṢE SỌ Ọ́

“Ó ti wá dá mi lójú báyìí pé lóòótọ́ lo nígbàgbọ́!” Ẹnu ẹnì kan tí n kò retí pé ó lè sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ni gbólóhùn yìí ti jáde. Ẹni náà jẹ́ aláṣẹ kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ìjọba Soviet, gbólóhùn náà sì bọ́ sásìkò gan-an nítorí pé ó fún mi níṣìírí lọ́pọ̀lọpọ̀. Wọ́n ti dá ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún mi mo sì ti fi gbogbo ọkàn gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ìṣòro ọlọ́jọ́ gbọọrọ ni mo dojú kọ, èyí tó ń béèrè ìfaradà àti ìpinnu tó lágbára.

ỌJỌ́ kọkàndínlógún oṣù October ọdún 1962 ni wọ́n bí mi, apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Ukraine ni mo sì dàgbà sí. Ọdún tí wọ́n bí mi yìí gan-an ni bàbá mi, tórúkọ òun náà ń jẹ́ Yurii bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Kò pẹ́ sí àkókò náà ló di Ẹlẹ́rìí, òun sì lẹni tó kọ́kọ́ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà lábúlé wa. Àwọn aláṣẹ ta ko iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí fojú sí i lára.

Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn aládùúgbò wa ló fẹ́ràn àwọn òbí mi, nítorí ìwà dáadáa wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àti bí wọ́n ṣe máa ń bìkítà fáwọn èèyàn. Gbogbo àǹfààní táwọn òbí mi ní ni wọ́n lò láti gbin ìfẹ́ Ọlọ́run sínú ọkàn èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àtàwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì, èyí sì jẹ́ kí n lè kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro tí mo ní níléèwé. Ọ̀kan lára irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ yọjú nígbà tí wọ́n ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan fi báàjì kan sáyà tó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ èwe tí wọ́n ń pè ní Lenin’s October Children. Àmọ́ mi ò fi báàjì náà sáyà nítorí pé Kristẹni ni mí, mi ò sì ń dá sí ọ̀ràn òṣèlú, ìyẹn sì mú kí n yàtọ̀ láàárín gbogbo àwọn yòókù.—Jòhánù 6:15; 17:16.

Lẹ́yìn náà, nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, wọ́n ní gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Ìjọba Kọ́múníìsì tí wọ́n ń pè ní Ọ̀jẹ̀ Wẹ́wẹ́. Bí wọ́n ṣe ní kí kíláàsì wa jáde sínú ọgbà iléèwé wa lọ́jọ́ kan nìyẹn fún ètò ìforúkọsílẹ̀ náà. Ẹ̀rù bà mí gidi gan-an, mo sì retí pé wọ́n á fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ gan-an wọ́n á sì kàn mí lábùkù. Gbogbo àwọn ọmọ tó kù pátá ló mú síkáàfù aláwọ̀ pupa tuntun tó jẹ́ ti ẹgbẹ́ náà wá látilé àyàfi èmi nìkan, gbogbo àwa akẹ́kọ̀ọ́ sì tò lórí ìlà gígùn níwájú ọ̀gá iléèwé wa, àwọn olùkọ́ wa, àtàwọn ọmọléèwé tí wọ́n ti wà ní kíláàsì gíga. Nígbà tí wọ́n sọ pé káwọn tó wà ní kíláàsì gíga yìí ta síkáàfù náà mọ́ ọrùn wa, mo dorí kodò mo sì ń wolẹ̀, pẹ̀lú ìrètí pé kò sẹ́ni tó máa wo ọ̀dọ̀ mi rárá.

Mo Lọ Ṣẹ̀wọ̀n Láwọn Ìlú Tó Jìnnà Gan-An

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta nítorí pé mi ò lọ́wọ́ sí ogun níwọ̀n bí mo ti jẹ́ Kristẹni. (Aísáyà 2:4) Ìlú Trudovoye, ní Ìpínlẹ̀ Vinnitskaya, lórílẹ̀-èdè Ukraine ni mo ti ṣe ọdún àkọ́kọ́. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń lọ sí nǹkan bí ọgbọ̀n pàdé. Àwọn aláṣẹ pín wa ní méjì méjì síbi iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ká má bàa lè bára wa kẹ́gbẹ́.

Lóṣù August ọdún 1982, wọ́n fi ọkọ̀ ojú irin gbé èmi àti Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eduard àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lọ sí apá àríwá àgbègbè kan tó ń jẹ́ Ural Mountains. Inú ibi tí wọ́n máa ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n sí ni wọ́n kó wa sí nínú ọkọ̀ ojú irin náà. Odindi ọjọ́ mẹ́jọ la fi wà nínú ooru burúkú tí inú ọkọ̀ náà sì há gádígádí ká tó wá gúnlẹ̀ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n ti Ìlú Solikamsk ní Ìpínlẹ̀ Permskaya. Yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n fi èmi àti Eduard sí. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tá a débẹ̀, wọ́n tún gbé mi lọ síbì kan tó jìnnà gan-an lápá àríwá, lábúlé kan tó ń jẹ́ Vels, ní ìpínlẹ̀ Krasnovishersky.

Ọ̀gànjọ́ òru lọkọ̀ wa débẹ̀, òkùnkùn sì ṣú biribiri. Inú òkùnkùn biribiri yìí ni ọ̀gágun kan ti pàṣẹ pé kí gbogbo wa kó sínú ọkọ̀ ojú omi kan ká sì sọdá odò náà. A ò ríran rí odò ọ̀hún débi tá a máa rí ọkọ̀ ojú omi! La bá bẹ̀rẹ̀ sí táràrà, tá à ń fọwọ́ wá gbogbo àgbègbè náà ká tó wá lọ já lu ọkọ̀ ojú omi kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà wá gan-an, ó ṣeé ṣe fún wa láti sọdá odò náà sódì kejì. Bá a ṣe ń dé etí odò náà lódìkejì la kọrí síbì kan tá a ti ń wo iná lórí òkè kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí wa, a sì rí àwọn àgọ́ díẹ̀ níbẹ̀. Ibi tí a ó máa gbé nìyẹn. Inú àgọ́ kan tó tóbi díẹ̀ lèmi àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn tó ń lọ sí nǹkan bí ọgbọ̀n ń gbé. Lákòókò òtútù, a fara da òtútù tó mú gan-an débi pé omi ń di yìnyín, àgọ́ náà kò sì fi bẹ́ẹ̀ dáàbò bò wá lọ́wọ́ òtútù. Iṣẹ́ táwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ń ṣe jù ni gígé igi lulẹ̀, àmọ́ kíkọ́ ahéré fáwọn ẹlẹ́wọ̀n niṣẹ́ tèmi.

Oúnjẹ Tẹ̀mí Dénú Àdádó Tá A Wà

Èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí tó wà ní ibùdó yẹn; síbẹ̀ Jèhófà kò fi mí sílẹ̀. Lọ́jọ́ kan, mo rí ẹrù kékeré kan gbà látọ̀dọ̀ màmá mi tó ṣì ń gbé lápá ìwọ̀ oòrùn Ukraine nígbà yẹn. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ kan ṣí ẹrù náà wò, ohun tó kọ́kọ́ rí ni Bíbélì kékeré kan. Ó mú un ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí i wò. Mo gbìyànjú láti ronú ohun tí mo lè sọ tí wọn ò fi ní gbẹ́sẹ̀ lé ìṣúra tẹ̀mí yìí. Lójijì ni ẹ̀ṣọ́ náà béèrè pé: “Kí leléèyí?” Kí n tó ronú èsì tí màá fún un tán, ọ̀gá kan tó dúró nítòsí ti dá a lóhùn, ó ní: “À, ìwé atúmọ̀ èdè nìyẹn!” Mi ò ya fọhùn. (Oníwàásù 3:7) Ọ̀gá náà tú ìyókù ẹrù náà ó sì gbé e fún mi pẹ̀lú Bíbélì tó ṣeyebíye yẹn. Inú mi dùn débi pé mo bu díẹ̀ fún un lára ẹ̀pà tó wà nínú ẹrù náà. Nígbà tí mo gba ẹrù yìí, mo mọ̀ pé Jèhófà kò gbàgbé mi. Ó fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn sí mi nípa pípèsè àwọn ohun tí mo nílò nípa tẹ̀mí fún mi.—Hébérù 13:5.

Mò Ń Wàásù Nìṣó Láìjuwọ́sílẹ̀

Ní nǹkan bí oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ẹnu yà mí nígbà tí mo gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ arákùnrin kan tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní nǹkan bí irínwó [400] kìlómítà sí ibi tí mo wà. Ó ní kí n wá ọkùnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ kàn, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà lòun náà wà báyìí. Kò bọ́gbọ́n mu láti kọ irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀, nítorí pé wọ́n máa ń já lẹ́tà wa wọ́n sì máa ń kà á. Kò sì yà mí lẹ́nu nígbà tí ọ̀gá sójà kan pè mí sí ọ́fíìsì rẹ̀ tó sì kìlọ̀ fún mi gan-an pé mi ò gbọ́dọ̀ wàásù. Lẹ́yìn náà ló wá pàṣẹ fún mi pé kí n fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù kan pé mi ò ní wàásù nípa ìgbàgbọ́ mi fáwọn èèyàn mọ́. Mo dá a lóhùn pé mi ò mọ ìdí tí màá fi fọwọ́ sírú fọ́ọ̀mù bẹ́ẹ̀ níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló ti mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Mo sọ fún un pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n fi jù mí sẹ́wọ̀n. Kí wá ni kí n sọ fún wọn? (Ìṣe 4:20) Ọ̀gá sójà náà rí i pé òun ò lè kó mi láyà jẹ ó sì pinnu láti gbé mi kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n ṣe gbé mi lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n mìíràn nìyẹn.

Abúlé kan tó ń jẹ́ Vaya, tó wà ní nǹkan bí igba [200] kìlómítà síbi tí mo wà tẹ́lẹ̀ ni wọ́n gbé mi lọ. Àwọn ọ̀gá tó ń bójú tó ibẹ̀ kò fojú yẹpẹrẹ wo jíjẹ́ tí mo jẹ́ Kristẹni, wọ́n sì fún mi níṣẹ́ tí kò jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun. Wọ́n kọ́kọ́ fún mi níṣẹ́ káfíńtà, lẹ́yìn náà ni mo tún wá ṣe iṣẹ́ atúnnáṣe. Àmọ́ àwọn iṣẹ́ yìí kò ṣàì níṣòro tiwọn. Nígbà kan, wọ́n ní kí n kó irinṣẹ́ mi kí n lọ sílé ìgbafàájì abúlé náà. Nígbà tí mo débẹ̀, inú àwọn sójà tó wà níbẹ̀ dùn gan-an láti rí mi. Àwọn iná tí wọ́n tàn yíká oríṣiríṣi àwọn nǹkan tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan ogun kò ṣiṣẹ́ dáadáa, wọn ò sì rójútùú ẹ̀. Wọ́n fẹ́ kí n bá wọn tún àwọn iná náà ṣe nítorí pé wọ́n ń múra sílẹ̀ fún àyájọ́ àwọn ológun tí wọ́n ń pè ní Red Army Day tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Lẹ́yìn tí mo ronú nípa rẹ̀ tí mo sì gbàdúrà, mo sọ fún wọn pé mi ò ní lè ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Ni mo bá kó irinṣẹ́ mi fún wọn mo sì kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n ṣe lọ fẹjọ́ mi sun igbákejì ọ̀gá àgbà nìyẹn, ó sì yà mí lẹ́nu pé lẹ́yìn tó tẹ́tí sí gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí tán, èsì tó fún wọn ni pé: “Mo gba tiẹ̀ fúnyẹn. Ó mọ ohun tó tọ́.”

Ìṣírí Wá Látẹnu Ẹnì Kan Tí Mi Ò Retí

Wọ́n dá mi sílẹ̀ lọ́jọ́ kẹjọ oṣù June, ọdún 1984, lẹ́yìn tó pé ọdún mẹ́ta gééré tí wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn tí mo padà sí orílẹ̀-èdè Ukraine, mo ní láti lọ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ológun pé mo ti ṣẹ̀wọ̀n rí. Àwọn òṣìṣẹ́ tó wà níbẹ̀ wá sọ fún mi pé lẹ́yìn oṣù mẹ́fà wọ́n á tún bá mi ṣẹjọ́ o, àti pé yóò dára kí n fi àgbègbè náà sílẹ̀ pátápátá. Bí mo ṣe fi orílẹ̀-èdè Ukraine sílẹ̀ nìyẹn mo sì ríṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Latvia nígbà tó yá. Ó ṣeé ṣe fún mi láti wàásù fúngbà díẹ̀ mo sì bá àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ tí wọ́n ń gbé nílùú Riga tó jẹ́ olú-ìlú Latvia àti àgbègbè rẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀. Àmọ́, kò ju ọdún kan péré lẹ́yìn náà tí wọ́n tún pè mí kí n wá lọ ṣiṣẹ́ ológun. Nígbà tí mo débi tí wọ́n ti ń forúkọ àwọn èèyàn sílẹ̀, mo sọ fún ọ̀gá tó wà níbẹ̀ pé wọ́n ti pè mí fún iṣẹ́ ológun nígbà kan àmọ́ mi ò ṣe é. Ló bá kígbe mọ́ mi pé: “Ǹjẹ́ orí ẹ pé báyìí? Màá wo ohun tí wàá sọ fún ọ̀gá!”

Bó ṣe mú mi lọ sínú yàrá kan ní àjà kejì ilé náà nìyẹn níbi tí ọ̀gá ológun náà jókòó sí tí tábìlì gígùn kan sì wà níwájú rẹ̀. Ọ̀gá náà fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí mo ti ń ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi lè ṣiṣẹ́ ológun, lẹ́yìn náà ló wá sọ fún mi pé àkókò ṣì wà fún mi láti túnnú rò kó tó di pé màá lọ síwájú ìgbìmọ̀ tó ń fi àwọn èèyàn sẹ́nu iṣẹ́ ológun. Bá a ti ń jáde kúrò nínú ọ́fíìsì ọ̀gá náà ni sójà tó ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ sí mi yẹn wá sọ pé: “Ó ti wá dá mi lójú báyìí pé lóòótọ́ lo nígbàgbọ́!” Nígbà tí mo déwájú ìgbìmọ̀ ológun, mo tún àlàyé mi ṣe pé mi ò lè lọ́wọ́ síṣẹ́ ológun, wọ́n sì sọ pé kí n ṣì máa lọ ná.

Lákòókò yẹn, ilé elérò púpọ̀ tó jẹ́ tìjọba ni mò ń gbé. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo gbọ́ tẹ́nì kan rọra kan ilẹ̀kùn mi. Bí mo ṣe ṣí i ni mo rí ọkùnrin kan tó wọ kóòtù tó sì gbé báàgì kan dání. Ó sọ ẹni tí òun jẹ́ fún mi ó sì sọ pé: “Láti iléeṣẹ́ Àjọ Aláàbò ni mo ti wá. Mo mọ̀ pé nǹkan ò rọgbọ fún ẹ, wọ́n sì fẹ́ bá ẹ ṣẹjọ́ ní kóòtù.” Mo dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, òótọ́ lo sọ.” Ni ọkùnrin náà bá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “A lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá gbà láti máa bá wa ṣiṣẹ́ pọ̀.” Mo dá a lóhùn pé: “Rárá o, ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Mi ò ní yà kúrò nínú ìgbàgbọ́ mi.” Kò tiẹ̀ gbìyànjú láti rọ̀ mí mọ́, ló bá jáde.

Mo Tún Bára Mi Lẹ́wọ̀n, Mo Sì Tún Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù Padà

Lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù August ọdún 1986, Kóòtù Ìjọba ti Ìlú Riga dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára fún mi, wọ́n sì sọ mí sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ìjọba Àpapọ̀ ti ìlú Riga. Yàrá ẹ̀wọ̀n ńlá kan tí ogójì ẹlẹ́wọ̀n mìíràn wà nínú rẹ̀ ni wọ́n fi mí sí, mo sì gbìyànjú láti wàásù fún gbogbo àwọn tá a jọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nínú yàrá náà. Àwọn kan nínú wọn sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, àmọ́ yẹ̀yẹ́ làwọn mìíràn ń ṣe. Mo ṣàkíyèsí pé wọ́n máa ń pín àwọn ọkùnrin náà sí ẹgbẹẹgbẹ́. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, àwọn olórí ẹgbẹ́ wọ̀nyí sọ fún mi pé àwọn ò gbà mí láyè láti máa wàásù níwọ̀n ìgbà tí mi ò ti tẹ̀ lé àwọn òfin wọn, èyí tí kò sí lákọsílẹ̀. Ni mo bá ṣàlàyé fún wọn pé ohun tí wọ́n torí ẹ̀ fi mí sẹ́wọ̀n gan-an nìyẹn àti pé òfin mìíràn ni mò ń tẹ̀ lé.

Mò ń dọ́gbọ́n wàásù nìṣó, nígbà tí mo sì rí àwọn kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí, ó ṣeé ṣe fún mi láti kọ́ mẹ́rin lára wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tá a bá ń jíròrò, wọ́n máa ń kọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ṣe kókó sínú ìwé kan. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé mi lọ sí àgọ́ kan nílùú Valmiera táwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣọ́ lójú méjèèjì, níbi tí mo ti ṣiṣẹ́ atúnnáṣe. Níbẹ̀, mo kọ́ ẹnì kan tóun náà jẹ́ atúnnáṣe lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún mẹ́rin lẹ́yìn náà.

Lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù March ọdún 1988, wọ́n gbé mi láti àgọ́ náà lọ sí àdádó kan tí kò jìnnà síbẹ̀. Ìbùkún ńlá lèyí jẹ́, nítorí ó jẹ́ kí n lómìnira sí i. Wọ́n ní kí n lọ máa ṣiṣẹ́ láwọn ibi tí wọ́n bá ti ń kọ́lé, gbogbo ìgbà ni mo sì máa ń wá àǹfààní láti wàásù. Mi ò kì í sí nínú àgọ́ náà lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ni mo máa ń wàásù títí dalẹ́, àmọ́ kò sígbà kan tí mo padà dé ibùdó náà tí mo níṣòro rí.

Jèhófà bù kún ìsapá mi. Àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan ń gbé lágbègbè náà, àmọ́ Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo péré ló wà nínú ìlú náà fúnra rẹ̀. Àgbàlagbà ni arábìnrin náà, Vilma Krūmin̗a sì lorúkọ rẹ̀. Èmi àti arábìnrin Krūmin̗a bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin máa ń wá láti ìlú Riga tí í ṣe olú ìlú náà láti wá kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, kódà àwọn aṣáájú ọ̀nà díẹ̀ máa ń wá láti Leningrad (tó ti di St. Petersburg báyìí). Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn èèyàn kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo forúkọ sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, tí mò ń lo àádọ́rùn-ún wákàtí nínú iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù.

Lọ́jọ́ keje oṣù April ọdún 1990, wọ́n tún ẹjọ́ mi gbé yẹ̀ wò ní Kóòtù Gbogbo gbòò ìlú Valmiera. Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀, mo rí i pé mo mọ olùpẹ̀jọ́ náà rí. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí mo ti bá sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì rí ni! Òun náà dá mi mọ̀ ó sì rẹ́rìn-ín músẹ́ àmọ́ kò sọ nǹkan kan. Mo ṣì máa ń rántí ohun tí adájọ́ náà sọ fún mi níbi ìgbẹ́jọ́ náà lọ́jọ́ yẹn, ó ní: “Yurii, ẹjọ́ tí wọ́n dá lọ́dún mẹ́rin sẹ́yìn tí wọ́n fi fi ọ́ sẹ́wọ̀n kò bófin mu. Kò yẹ kí wọ́n sọ ẹ́ sẹ́wọ̀n rárá.” Bí mo ṣe dòmìnira láìròtẹ́lẹ̀ nìyẹn!

Ọmọ Ogun Kristi

Ó tún di dandan pé kí n forúkọ sílẹ̀ lóṣù June ọdún 1990, kí n lè rí ìwé àṣẹ láti máa gbé ìlú Riga gbà, ọ́fíìsì tí wọ́n sì ti ń forúkọ àwọn èèyàn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun yẹn ni màá lọ. Mo wọnú ọ́fíìsì ọ̀hún, tábìlì gígùn náà ṣì wà níbẹ̀, níbi tí mo ti sọ fún ọ̀gá sójà yẹn lọ́dún mẹ́rin sẹ́yìn pé mi ò lè ṣiṣẹ́ ológun. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ni ọ̀gá náà dìde tó kí mi, ó bọ̀ mí lọ́wọ́, ó sì sọ fún mi pé: “Kò ṣeé gbọ́ sétí rárá pé o jẹ gbogbo ìyà tó o jẹ yẹn. Ó dùn mí gan-an pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ọ.”

Àmọ́ mo dá a lóhùn pé: “Ọmọ ogun Kristi ni mí, mo sì ní láti ṣiṣẹ́ tó gbé lé mi lọ́wọ́. Bíbélì lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti gbádùn ohun tí Kristi ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ìyẹn ìgbésí ayé aláyọ̀ àti ìwàláàyè tí kò lópin lọ́jọ́ iwájú.” (2 Tímótì 2:3, 4) Ọ̀gá sójà náà fèsì pé: “Mo ra Bíbélì kan láìpẹ́ yìí, mo sì ti ń kà á.” Mo ní ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọ́wọ́. a Ni mo bá ṣí i sí àkòrí tó jíròrò àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn mo sì fi bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe bá àkókò tí à ń gbé yìí mu hàn án. Ọ̀gá sójà náà mọrírì rẹ̀ gan-an, ló bá tún bọ̀ mí lọ́wọ́, ó sì ní iṣẹ́ mi á yọrí sí rere.

Ní gbogbo àkókò yìí, pápá ti funfun gan-an fún ìkórè lórílẹ̀-èdè Latvia. (Jòhánù 4:35) Lọ́dún 1991, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Alàgbà méjì péré ló wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn! Ní ọdún kan lẹ́yìn náà, wọ́n pín ìjọ kan ṣoṣo tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè Latvia sí méjì, ọ̀kan jẹ́ ìjọ tó ń sọ èdè Latvia, èkejì sì jẹ́ ti èdè Rọ́ṣíà. Mo láǹfààní láti wà ní ìjọ tó ń sọ èdè Rọ́ṣíà. Ìdàgbàsókè náà yára kánkán débi pé lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n pín ìjọ wa sí mẹ́ta! Bí mo ti ń wẹ̀yìn padà, ó dá mi lójú pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀ sínú ètò rẹ̀.

Lọ́dún 1998, wọ́n yàn mí láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe nílùú Jelgava, tó jẹ́ nǹkan bí ogójì kìlómítà sílùú Riga. Lọ́dún yẹn kan náà, mo wà lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tí wọ́n ṣe lédè Rọ́ṣíà nílùú Solnechnoye, nítòsí ìlú St. Petersburg, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ náà, mo wá mọrírì bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Ohun kan tó wú mi lórí ju gbogbo ohun tí wọ́n kọ́ wa nílé ẹ̀kọ́ náà ni ìfẹ́ tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn olùkọ́ wa fi hàn sí wa àti bí wọ́n ṣe bójú tó wa.

Mo gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì mìíràn nígbèésí ayé mi lọ́dún 2001 nígbà tí mo gbé arábìnrin kan tó fani mọ́ra gan-an tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Karina níyàwó. Èmi àti Karina wá jọ ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Bí mo ṣe máa ń rí aya mi tó máa ń láyọ̀ lójoojúmọ́ nígbà tó bá ń padà bọ̀ láti òde ẹ̀rí máa ń jẹ́ ìṣírí fún mi gan-an. Ká sòótọ́, jíjọ́sìn Jèhófà máa ń fúnni ní ayọ̀ ńláǹlà. Ohun tójú mi rí lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ti kọ́ mi láti túbọ̀ gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá. Kò sí ohun tó tóbi jù láti yááfì béèyàn bá fẹ́ máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà nìṣó tó sì fẹ́ máa ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lẹ́yìn. Ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà ti mú kí ìgbésí ayé mi lójú. Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ fún mi pé mò ń sin Jèhófà “gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun àtàtà ti Kristi Jésù.”—2 Tímótì 2:3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ìjọba Àpapọ̀ nílùú Riga

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Èmi àti Karina rèé lóde ẹ̀rí