Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èrò Táwọn Èèyàn Ní Nípa Wa Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Kà Á Sí?

Èrò Táwọn Èèyàn Ní Nípa Wa Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Kà Á Sí?

Èrò Táwọn Èèyàn Ní Nípa Wa Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Kà Á Sí?

ṢÀṢÀ lẹni tí kì í fẹ́ káwọn èèyàn yin òun. Báwọn èèyàn bá yìn wá, orí wa máa ń wú, inú wa sì máa ń dùn pé a ṣe dáadáa. Wọ́n ní yinni-yinni kẹ́ni ṣèmíì. Àmọ́, táwọn kan ò bá gba tiwa, inú wa ò ní dùn. Bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa tàbí tó ń fimú dá wa lóhùn, èyí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. A lè bẹ̀rẹ̀ sí fi irú ojú táwọn ẹlòmíràn fi ń wò wá wo ara wa.

Àṣìṣe gbáà ló máa jẹ́ tá ò bá ka èrò táwọn èèyàn ní nípa wa sí. Ká sòótọ́, bí àwọn èèyàn bá ń kíyè sí ìwà wa, tí wọ́n ń sọ ibi tó kù sí fún wa, èyí lè ṣe wá láǹfààní. Tó bá jẹ́ pé orí òdodo làwọn èèyàn gbé ohun tí wọ́n ń sọ nípa wa kà, èyí lè jẹ́ ká máa hùwà tó tọ́ nìṣó. (1 Kọ́ríńtì 10:31-33) Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa nǹkan lè má tọ̀nà. Ronú nípa èrò òdì táwọn olórí àlùfáà àtàwọn mìíràn ní nípa Jésù Kristi, èyí tó mú kí “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ké rara, pé: ‘Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!’” (Lúùkù 23:13, 21-25) Bó bá jẹ́ pé ìròyìn èké làwọn èèyàn gbọ́ tàbí tó jẹ́ pé ìlara tàbí ẹ̀tanú ló ń mú kí wọ́n gbin èrò kan sọ́kàn, kò yẹ ká bá wọn ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ ká máa lo làákàyè wa ká sì máa fi ọgbọ́n gbé èrò àwọn ẹlòmíràn yẹ̀ wò dáadáa ká tó tẹ̀ lé e.

Èrò Ta Ló Ṣe Pàtàkì?

A máa ń fẹ́ káwọn tá a jọ ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Lára wọn sì ni àwọn tó wà nínú ìdílé wa tá a jọ ń sin Jèhófà àtàwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin. (Róòmù 15:2; Kólósè 3:18-21) A mọyì ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ táwọn ará wa ní sí wa gan-an àti bá a ṣe jọ máa ń ṣe “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12) Nítorí pé a ní ‘ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, a kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ (Fílípì 2:2-4) Síwájú sí i, a máa ń fẹ́ kí inú “àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín” wa dùn sí wa kí wọ́n sì máa fojú tó dára wò wá, a sì mọyì èyí gan-an.—Hébérù 13:17.

A tún máa ń fẹ́ “gbólóhùn ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lóde.” (1 Tímótì 3:7) Á mà dára o káwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn aládùúgbò wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí fojú tó dára wò wá! Bákan náà, ó yẹ ká gbìyànjú láti máa hùwà tó máa wú àwọn tá à ń wàásù fún lórí kí wọ́n lè fetí sí ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀. Báwọn tó wà lágbègbè wa bá rí i pé a jẹ́ oníwà mímọ́, adúróṣinṣin àti olóòótọ́ èèyàn, èyí á gbé orúkọ Ọlọ́run ga. (1 Pétérù 2:12) Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká tẹ àwọn ìlànà Bíbélì lójú torí ká bàa lè rí ojú rere àwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ ká di alágàbàgebè torí ká lè fa ojú wọn mọra. A gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a ò lè tẹ́ gbogbo èèyàn lọ́rùn. Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.” (Jòhánù 15:19) Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe tó lè jẹ́ káwọn tó ń ṣàtakò sí wa máa fojú rere wò wá?

Ohun Tó Lè Jẹ́ Káwọn Alátakò Fojú Rere Wò Wá

Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 10:22) Nígbà míì, ìkórìíra yìí máa ń jẹ́ kí wọ́n fẹ̀sùn burúkú kàn wá. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́tanú lè máa pè wá ní ọlọ̀tẹ̀ tàbí adàlúrú. Àwọn alátakò tí ẹnu wọn tólẹ̀ lè máa pariwo pé ẹ̀ya ìsìn tó ń dá wàhálà sílẹ̀ tó yẹ kí ìjọba fòfin dè ni wá. (Ìṣe 28:22) A lè paná àwọn ẹ̀sùn èké wọ̀nyí nígbà míì. Báwo la ṣe lè ṣe é? A lè mú kí ẹnu wọn wọhò tí a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù pé: “Ẹ wà ní ìmúratán . . . . láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó yẹ ká máa sọ “ọ̀rọ̀ tí ó sunwọ̀n tí a kò lè dá lẹ́bi; kí ojú lè ti ẹni tí ó wà ní ìhà ìṣòdìsíni, láìní ohun búburú kankan láti sọ nípa wa.”—Títù 2:8.

Bí a ṣe ń gbìyànjú láti rí i pé a ò hùwà tó máa jẹ́ káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ wa ní búburú, kò yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tàbí ká wá kúkú kárí sọ báwọn èèyàn bá bà wá lórúkọ jẹ́. Àwọn èèyàn sọ pé Jésù Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé ń sọ̀rọ̀ òdì, wọ́n pè é ní ọlọ̀tẹ̀, kódà wọ́n ní ẹlẹ́mìí èṣù ni. (Mátíù 9:3; Máàkù 3:22; Jòhánù 19:12) Wọ́n ba àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà lórúkọ jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 4:13) Jésù àti Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú wọ̀nyí mú wọn dẹwọ́ o, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n tẹra mọ́ iṣẹ́ wọn. (Mátíù 15:14) Wọ́n mọ̀ pé kò sóhun táwọn lè ṣe tó máa mú káwọn ọ̀tá wọn fojú tó dáa wò wọ́n nítorí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Lóde òní náà, àwọn èèyàn ò yéé pẹ̀gàn wa. Kò yẹ ká jẹ́ kí àyà wa pami nígbà táwọn alátakò tí kò fẹ́ràn wa bá ń parọ́ mọ́ wa.—Mátíù 5:11.

Èrò Àwọn Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn máa ń ní nípa wa. Ohun tí wọ́n ti gbọ́ nípa wa àti ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ló sì máa ń fa èyí. Bí àwọn èèyàn kan ṣe ń yìn wá tí wọ́n ń pọ́n wa lé làwọn kan ń pẹ̀gàn wa tí wọ́n sì ń fojú tí kò dáa wò wá. Àmọ́ o, bó bá ti jẹ́ pé àwọn ìlànà Bíbélì ló ń darí wa, ńṣe ló yẹ kínú wa máa dùn kí ọkàn wa sì balẹ̀.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Tá a bá mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń jẹ́ kó tọ́ wa sọ́nà nínú ohun gbogbo, èyí á jẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ tẹ́wọ́ gbà wá. Ṣebí èrò tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ bá ní nípa wa ló ṣe pàtàkì jù. Èrò tí wọ́n bá ní nípa wa ló máa fi irú ẹni tá a jẹ́ gan-an hàn. Àyàfi bí wọ́n bá tẹ́wọ́ gbà wá nìkan la máa lè ní ìyè ayérayé.—Jòhánù 5:27; Jákọ́bù 1:12.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

“Ìyìn ń mójú tì mí, bẹ́ẹ̀ ọkàn mí fẹ́ ẹ.”—RABINDRANATH TAGORE AKÉWÌ ỌMỌ ILẸ̀ ÍŃDÍÀ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Irú ojú táwọn tá a jọ ń sin Jèhófà fi ń wò wá ṣe pàtàkì gan-an

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Culver Pictures