Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Bí ẹnì kan bá ń ṣe eré kọ̀ǹpútà oníwà ipá, ǹjẹ́ èyí lè ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?
Dáfídì tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìkórìíra” lè túmọ̀ sí “ọ̀tá.” Nítorí náà, ńṣe lẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run. Ìbéèrè tó wá yẹ ká bi ara wa ni pé: Ǹjẹ́ ṣíṣe àwọn eré kọ̀ǹpútà kan lè gbin ẹ̀mí ìwà ipá sí wa lọ́kàn?
Àwọn eré kọ̀ǹpútà oníwà ipá máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rò pé lílo ohun ìjà kò burú. Wọ́n máa ń kọ́ ẹni tó ń ṣe irú eré bẹ́ẹ̀ ní ogun jíjà. Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Àwọn eré kọ̀ǹpútà làwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà fi ń kọ́ṣẹ́ ogun jù báyìí. Lára àwọn eré bẹ́ẹ̀ sì ti wà lọ́jà báyìí fún àwọn aráàlú láti rà.”
Òótọ́ ni pé kì í ṣe àwọn èèyàn ẹlẹ́mìí làwọn tó ń ṣe eré kọ̀ǹpútà oníwà ipá ń ṣe lọ́ṣẹ́. Àmọ́ o, kí ni irú eré yìí fi hàn nípa ohun tó wà lọ́kàn wọn? (Mátíù 5:21, 22; Lúùkù 6:45) Kí ni wàá sọ nípa ẹnì kan tó fẹ́ràn láti máa gún àwọn ọmọlangidi inú eré náà tó dà bí èèyàn lọ́bẹ, kó máa yìnbọn lù wọ́n, kó máa ṣe wọ́n léṣe, kó sì máa pa wọ́n? Bí onítọ̀hún bá ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nídìí eré yìí láti máa fi ìwà ipá dára yá ńkọ́, àní tí irú eré yìí ti wá fẹ́ di bárakú fún un? Bí o kò bá tiẹ̀ pe onítọ̀hún ní apààyàn, wàá gbà pé ohun tó máa jẹ́ kí ìfẹ́ ìwà ipá túbọ̀ gbilẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀ ló ń ṣe, àní gẹ́gẹ́ bí ẹni tó bá ń wo àwòrán tó ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè ṣe ń gbin ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sọ́kàn.—Mátíù 5:27-29.
Báwo ni Jèhófà ṣe kórìíra ẹni tó fẹ́ràn ìwà ipá tó? Dáfídì sọ pé ‘dájúdájú Jèhófà kórìíra’ onítọ̀hún. Nígbà ayé Nóà, Jèhófà fi bí òun ṣe kórìíra àwọn tó fẹ́ràn ìwà ipá tó hàn. Ó sọ fún Nóà pé: “Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi, nítorí tí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nítorí wọn; sì kíyè sí i, èmi yóò run wọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:13) Ọlọ́run tòótọ́ pa gbogbo èèyàn ayé ìgbà yẹn run torí pé wọ́n jẹ́ oníwà ipá. Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ni Jèhófà dá sí. Ìdí sì ni pé àwọn èèyàn mẹ́jọ wọ̀nyí nìkan ni kò fẹ́ràn ìwà ipá.—2 Pétérù 2:5.
Àwọn tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, [kí] wọ́n . . . sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.” Dípò kí wọ́n máa wo ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n fẹ́ràn ìwà ipá, wọn kì í “kọ́ṣẹ́ ogun” rárá. (Aísáyà 2:4) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run ṣì jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tá ò fẹ́ di ọ̀tá rẹ̀, a gbọ́dọ̀ “yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí [a] sì máa ṣe ohun rere.” A ní láti máa “wá àlàáfíà, kí [a] sì máa lépa rẹ̀.”—1 Pétérù 3:11.
Ká ní a ti máa ń ṣe eré kọ̀ǹpútà oníwà ipá ńkọ́? A gbọ́dọ̀ pinnu látọkànwá pé ìfẹ́ Jèhófà la óò máa ṣe, èyí á sì jẹ́ ká jáwọ́ nínú ohunkóhun tí kò bá fẹ́. Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè jáwọ́ nínú àṣà burúkú tó lè ṣàkóbá fún wa nípa tẹ̀mí yìí. A lè jáwọ́ nínú àṣà yìí bá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí àlàáfíà, ìwà rere àti ìkóra-ẹni-níjàánu máa darí wa kí ìgbésí ayé wa lè túbọ̀ bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu.—Lúùkù 11:13; Gálátíà 5:22, 23.