Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Fàyè Gba Èrò Òdì!

Má Ṣe Fàyè Gba Èrò Òdì!

Má Ṣe Fàyè Gba Èrò Òdì!

NÍGBÀ tí Jóòbù baba ńlá wà nínú ìṣòro tó gadabú, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta tórúkọ wọn ń jẹ́ Élífásì, Bílídádì àti Sófárì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá a kẹ́dùn àti láti tù ú nínú. (Jóòbù 2:11) Ẹni tí ẹnu rẹ̀ tólẹ̀ jù nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó sì jọ pé òun ló dàgbà jù ni Élífásì. Òun ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, òun ló sì sọ̀rọ̀ jù. Irú èrò wo ló hàn pé ó wà lọ́kàn rẹ̀ nígbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó sọ̀rọ̀?

Nígbà tí Élífásì ń sọ̀rọ̀ nípa ìran àràmàǹdà tó rí nígbà kan, ó ní: “Ẹ̀mí kan sì ń kọjá lójú mi; irun ara mi bẹ̀rẹ̀ sí dìde gàn-ùn gàn-ùn. Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò dá ìrísí rẹ̀ mọ̀; nǹkan kan wà ní iwájú mi; ìparọ́rọ́ ń bẹ, mo sì wá gbọ́ ohùn kan.” (Jóòbù 4:15, 16) Ẹ̀mí wo ló mú kí Élífásì máa ronú bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tó sọ lẹ́yìn èyí fi hàn dájú pé kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run tó jẹ́ olódodo ni ẹ̀mí tó ń sọ. (Jóòbù 4:17, 18) Ẹ̀mí búburú kan ni. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí nìdí tí Jèhófà fi bá Élífásì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì wí pé wọ́n parọ́? (Jóòbù 42:7) Kò sí àní-àní pé ẹ̀mí èṣù ló lo Élífásì. Ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé èrò rẹ̀ ò bá ti Ọlọ́run mu.

Kí ni kókó inú ọ̀rọ̀ Élífásì? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká má fàyè gba èrò òdì? Àwọn nǹkan wo la sì lè ṣe láti gbógun ti èrò òdì?

“Kò Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀”

Nígbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Élífásì sọ̀rọ̀, kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé Ọlọ́run ya òǹrorò débi pé kò sóhun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe tó dára lójú rẹ̀. Ó sọ fún Jóòbù pé: “Kiyesi i, on kò gbẹkẹle awọn iranṣẹ rẹ̀, ninu awọn angeli rẹ̀ ni o si ri ẹ̀ṣẹ.” (Jóòbù 4:18, Bíbélì Mímọ́) Lẹ́yìn èyí, Élífásì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run pé: “Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ti gidi ní ojú rẹ̀.” (Jóòbù 15:15) Ó tún béèrè pé: “Olódùmarè ha ní inú dídùn rárá sí jíjẹ́ tí o jẹ́ olódodo?” (Jóòbù 22:3) Bílídádì gbà pẹ̀lú Élífásì, torí ohun tó sọ ni pé: “Òṣùpá pàápàá wà, kò sì mọ́lẹ̀; àwọn ìràwọ̀ pàápàá kò sì mọ́ lójú [Ọlọ́run].”—Jóòbù 25:5.

A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa ní irú èrò òdì bẹ́ẹ̀. Ó lè mú ká máa ronú pé ohun tí agbára wa ò gbé ni Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe. Irú èrò yìí sì lè ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, bá a bá lọ gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè, kí la máa ṣe nígbà tí wọ́n bá bá wa wí? Dípò ká fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tó yẹ, ọkàn wa lè “di èyí tí ó kún fún ìhónú sí Jèhófà” pàápàá, a sì lè bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí Jèhófà. (Òwe 19:3) Kò sí àní-àní pé èyí lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́!

“Abarapá Ọkùnrin Ha Lè Wúlò fún Ọlọ́run?”

Bí Élífásì ṣe ń dọ́gbọ́n sọ pé ohun tí agbára wa ò gbé ni Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe náà ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún fi hàn pé àwa èèyàn ò wúlò rárá lójú Ọlọ́run. Élífásì béèrè ìbéèrè kan nígbà kẹta tó sọ̀rọ̀, ó ní: “Abarapá ọkùnrin ha lè wúlò fún Ọlọ́run, pé ẹni tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò wúlò fún un?” (Jóòbù 22:2) Ohun tí Élífásì ń sọ ni pé èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Irú ohun tó wà lọ́kàn Bílídádì náà nìyẹn, torí òun náà sọ pé: “Báwo ni ẹni kíkú ṣe lè jàre níwájú Ọlọ́run, tàbí báwo ni ẹni tí obìnrin bí ṣe lè mọ́?” (Jóòbù 25:4) Lójú àwọn méjèèjì, Jóòbù tó jẹ́ ẹ̀dá aláìpé ò lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run.

Àwọn kan lónìí máa ń ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí wọ́n máa ronú bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà, tàbí àwọn ohun tí ojú wọn ti rí nígbèésí ayé, tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ti fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n tàbí kẹ̀ káwọn kan ti fi ìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́. Àmọ́ o, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ náà máa ń fẹ́ káwọn èèyàn rò pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Bí wọ́n bá lè mú kí ẹnì kan ronú pé kò sóhun tí òun lè ṣe tó máa dára níwájú Ọlọ́run Olódùmarè, ìrẹ̀wẹ̀sì lè bo onítọ̀hún. Tó bá yá, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sú lọ, àní kó má tiẹ̀ sin Ọlọ́run alààyè mọ́.—Hébérù 2:1; 3:12.

Bí àgbà bá ti ń dé tàbí tí àìsàn ń ṣe wá, ìwọ̀nba nǹkan la máa lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ohun tá à ń ṣe lè kéré jọjọ tá a bá fi wé ìgbà tí a ṣì kéré, tí ara wa le tá a sì lókun. Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé ohun tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń fẹ́ ni pé ká máa rò pé ohun tá à ń ṣe kò dára rárá lójú Ọlọ́run! Kò yẹ ká gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè rárá.

Ohun Tá A Lè Ṣe Tá Ò Fi Ní Fàyè Gba Èrò Òdì

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì Èṣù fìyà jẹ Jóòbù, Jóòbù sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” (Jóòbù 27:5) Jóòbù nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an, ìdí nìyẹn tó fi pinnu pé òun á jẹ́ adúróṣinṣin láìka ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀ sí, kò sì jẹ́ kí ohunkóhun yí ìpinnu ọ̀hún padà. Ohun pàtàkì tó lè ran àwa náà lọ́wọ́ láti gbógun ti èrò òdì nìyẹn. Ó yẹ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó ká sì mọrírì ìfẹ́ rẹ̀ látọkànwá. Ó tún yẹ ká jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run jinlẹ̀ lọ́kàn wa. Ohun tó máa jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ ká sì tún máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́.

Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù 3:16 kà pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.” Jèhófà nífẹ̀ẹ́ aráyé gidigidi, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwa èèyàn látọdúnmọdún sì fi èyí hàn. Tí a bá ronú jinlẹ̀ lórí bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn lò láyé àtijọ́, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì rẹ̀ ká sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Èyí ló sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbógun ti èrò òdì.

Ronú nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá Ábúráhámù lò nígbà tí ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà. Ìgbà mẹ́jọ ni Ábúráhámù béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ Jèhófà nípa ìdájọ́ rẹ̀. Síbẹ̀, kò sígbà kan tí Jèhófà kanra mọ́ ọn tàbí tó bínú sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdáhùn rẹ̀ fi Ábúráhámù lọ́kàn balẹ̀, ó sì tù ú nínú. (Jẹ́nẹ́sísì 18:22-33) Nígbà tí Ọlọ́run ṣètò ọ̀nà àbáyọ fún Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ nígbà tó fẹ́ pa ìlú Sódómù run, Lọ́ọ̀tì sọ pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí òun sá lọ sí ìlú kan tí kò jìnnà dípò kí òun lọ sórí òkè ńlá. Jèhófà dá a lóhùn pé: “Kíyè sí i, mo fi ìgbatẹnirò hàn sí ọ dé ìwọ̀n yìí pẹ̀lú, ní ti pé èmi kò ní bi ìlú ńlá náà tí ìwọ ti sọ ṣubú.” (Jẹ́nẹ́sísì 19:18-22) Nígbà tá a ka ìtàn yìí, ǹjẹ́ a lè sọ pé alákòóso bóofẹ́-bóokọ̀ tí ń fagbára múni tí kò sì nífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà? Rárá o. Ìtàn yìí fi irú ẹni tó jẹ́ gan-an hàn, ìyẹn ni pé Jèhófà jẹ́ alákòóso onífẹ̀ẹ́, onínúure, aláàánú àti agbatẹnirò.

Bí a bá ka ìtàn Áárónì, Dáfídì àti Mánásè, a óò gbà pé irọ́ làwọn kan ń pa pé Ọlọ́run máa ń ṣe àríwísí àti pé kò sí ohun téèyàn lè ṣe tó máa dára lójú rẹ̀. Áárónì dá ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó burú gan-an. Ó ṣe ère ọmọ màlúù, òun àti Míríámù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin fẹ̀sùn kaṇ Mósè, kò sì ya Ọlọ́run sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò bọlá fún un ní Mẹ́ríbà. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà kò gbàgbé àwọn ìwà dáadáa tó ti hù sẹ́yìn, ó sì gbà á láyè kó máa ṣe àlùfáà àgbà lọ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.—Ẹ́kísódù 32:3, 4; Númérì 12:1, 2; 20:9-13.

Dáfídì Ọba dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an nígbà tó ń ṣèjọba. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe panṣágà, ó pète bí wọ́n ṣe pa ọkùnrin aláìṣẹ̀ kan, ó sì ṣètò ìkànìyàn tínú Ọlọ́run ò dùn sí. Àmọ́, Jèhófà rí i pé àtọkànwá ni ìrònúpìwàdà Dáfídì, ó sì fi í sílẹ̀ sí ipò ọba títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ kó lè mú ìlérí májẹ̀mú Ìjọba tó bá Dáfídì dá ṣẹ.—2 Sámúẹ́lì 12:9; 1 Kíróníkà 21:1-7.

Mánásè ọba Júdà kọ́ pẹpẹ Báálì, ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ nínú iná, ó gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ, ó sì kọ́ àwọn pẹpẹ ìbọ̀rìṣà sínú àgbàlá tẹ́ńpìlì. Àmọ́, nígbà tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà dárí jì í, ó tú u sílẹ̀ ní ìgbèkùn tó wà, ó sì jẹ́ kó di ọba padà. (2 Kíróníkà 33:1-13) Ṣé Ọlọ́run téèyàn ò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀ lè ṣe irú nǹkan báyìí? Rárá o!

Ẹni Tí Ń Ṣe Àríwísí Gan-an Ló Jẹ̀bi

Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Sátánì gan-an lẹni tó ń hu gbogbo ìwà tó ní Jèhófà ń hù. Òǹrorò ni Sátánì, ó sì máa ń fipá múni ṣe nǹkan. A lè rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí tá a bá wo àṣà burúkú kan táwọn abọ̀rìṣà máa ń dá láyé àtijọ́, ìyẹn ni àṣà fífi ọmọ rúbọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ apẹ̀yìndà máa ń sun àwọn ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin nínú iná, èyí kò sì sí lọ́kàn Jèhófà rárá.—Jeremáyà 7:31.

Sátánì ni alárìíwísí, kì í ṣe Jèhófà. Ìṣípayá 12:10 pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa . . . , ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa!” Àmọ́ nígbà tí onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, ó kọ ọ́ lórin pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.”—Sáàmù 130:3, 4.

Ìgbà Tí Ẹnikẹ́ni Ò Ní Ro Èrò Òdì Mọ́

Láìsí àní-àní, ara á tu àwọn áńgẹ́lì gan-an nígbà tí wọ́n lé Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run! (Ìṣípayá 12:7-9) Látìgbà yẹn làwọn ẹ̀mí burúkú wọ̀nyí ò ti lè ṣèdíwọ́ kankan mọ́ fáwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ń sin Jèhófà lọ́run.—Dáníẹ́lì 10:13.

Àkókò tí àwọn tó ń gbé ayé yóò máa yọ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. Láìpẹ́ láìjìnnà, áńgẹ́lì kan tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan dání, yóò de Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, yóò sì fi wọ́n sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí pé wọn ò ní lè ṣe ohunkóhun mọ́. (Ìṣípayá 20:1-3) Ó dájú pé ara á tù wá gan-an nígbà tíyẹn bá ṣẹlẹ̀!

Ní báyìí ná, a gbọ́dọ̀ rí i pé a ò fàyè gba èrò òdì rárá. Nígbàkigbà tá a bá rí i tí èrò òdì fẹ́ máa wá sí wa lọ́kàn, ó yẹ ká máa ronú nípa ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ká bàa lè gbógun ti èròkerò náà. Nígbà náà, ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa.’—Fílípì 4:6, 7.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Jóòbù ò fàyè gba èrò òdì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Lọ́ọ̀tì mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ Alákòóso tí ń gba tẹni rò