Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tó O Lè Fojú Rí!

Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tó O Lè Fojú Rí!

Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tó O Lè Fojú Rí!

“Nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí a rí.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 5:7.

1. Kí ló fi hàn pé nípa ìgbàgbọ́ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìn, pé kì í ṣe nípa ohun tó rí?

 NÍ ỌDÚN 55 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù, ọkùnrin kan tó ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù di Kristẹni, ó kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ní ìrètí ti ọ̀run. Pọ́ọ̀lù ló ń jẹ́ nígbà tó kọ̀wé yìí. Ní gbogbo àkókò yìí, kò jẹ́ kí ohunkóhun bomi paná ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run. Kò fojú ara rẹ̀ rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lọ́run rí o, síbẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀ dúró sán-ún. Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni yìí, ó ní: “Nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí a rí.”—2 Kọ́ríńtì 5:7.

2, 3. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń rìn nípa ìgbàgbọ́? (b) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan ń rìn nípa ohun tó lè fojú rí?

2 Ká tó lè máa rìn nípa ìgbàgbọ́, a ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tọkàntọkàn pé ó lè tọ́ wa sọ́nà nígbèésí ayé. Ó ní láti dá wa lójú láìsí iyèméjì kankan pé Ọlọ́run mọ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ. (Sáàmù 119:66) Bá a ṣe ń ṣe àwọn ìpinnu nígbèésí ayé wa tá a sì ń ṣiṣẹ́ lé wọn lórí, ó yẹ ká máa ronú lórí “àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Lára àwọn ohun gidi náà sì ni “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” tí Ọlọ́run ṣèlérí. (2 Pétérù 3:13) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá ń rìn nípa ohun tá a lè fojú rí, à ń jẹ́ kí ohun tá a lè fojú rí darí ìgbésí ayé wa nìyẹn. Èyí sì léwu nítorí pé ó lè mú ká dẹni tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run mọ́.—Sáàmù 81:12; Oníwàásù 11:9.

3 Yálà a jẹ́ ara “agbo kékeré” tó ní ìrètí ti ọ̀run ni o tàbí ara “àgùntàn mìíràn” tó ń retí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, olúkúlùkù wa ní láti fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn, ìyẹn ni pé ká máa rìn nípa ìgbàgbọ́, kó má ṣe jẹ́ nípa ohun tá a lè fojú rí. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Ẹ jẹ́ ká wo bí títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní kó sínú ìdẹkùn “jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fúngbà díẹ̀,” tá ò fi ní kó sínú ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tí a ò sì ní jẹ́ kó kúrò lọ́kàn wa pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí là ń gbé yìí. A óò tún sọ̀rọ̀ nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa rìn nípa ohun tó lè fojú rí.—Hébérù 11:25.

Bá A Ṣe Lè Kọ “Ìgbádùn Ẹ̀ṣẹ̀ fún Ìgbà Díẹ̀”

4. Kí ni ohun tí Mósè pinnu láti ṣe, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

4 Fojú inú wo irú ìgbé ayé tí Mósè, ọmọ Ámúrámù ì bá gbé. Òun àtàwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé ọba Íjíbítì ìgbàanì ni wọ́n jọ tọ́ dàgbà, èyí ì bá sì jẹ́ kó láǹfààní láti di alágbára, ọlọ́rọ̀ àti ẹni ńlá. Mósè lè sọ ọ́ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Ó ṣe tán, wọ́n ti kọ́ mi ní gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì tó jọ àwọn èèyàn lójú, alágbára sì ni mí nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Tí mi ò bá kúrò lágboolé ọba, mo lè lo àǹfààní yẹn láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn mi, ìyẹn àwọn Hébérù tí wọ́n ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́!’ (Ìṣe 7:22) Àmọ́ Mósè kò rò bẹ́ẹ̀, dípò ìyẹn ó gbà “kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” Kí nìdí? Kí ló mú kí Mósè kọ gbogbo àǹfààní tó ní ní Íjíbítì? Bíbélì dáhùn pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni [Mósè] fi Íjíbítì sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò bẹ̀rù ìbínú ọba, nítorí tí ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:24-27) Dídá tó dá Mósè lójú hán-ún pé Jèhófà yóò san èrè fáwọn tó bá jẹ́ olódodo ló jẹ́ kó lè kọ ẹ̀ṣẹ̀, ayé ìjẹkújẹ àti ìgbádùn onígbà kúkúrú sílẹ̀.

5. Ọ̀nà wo ni àpẹẹrẹ Mósè lè gbà ràn wá lọ́wọ́?

5 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwa náà ní láti ṣe ìpinnu tó gbàrònú gan-an lórí àwọn ọ̀ràn bí ìwọ̀nyí: ‘Ǹjẹ́ kò yẹ kí n jáwọ́ nínú àwọn nǹkan kan tí mò ń ṣe tàbí àwọn ìwà kan tí mò ń hù tó ta ko ìlànà Bíbélì? Ǹjẹ́ ó yẹ kí n ṣe iṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé àmọ́ tó máa ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú mi nípa tẹ̀mí?’ Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Mósè, a ò ní dà bí àwọn èèyàn ayé tó jẹ́ pé àǹfààní ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n ń wá, dípò ìyẹn ńṣe ló yẹ ká gbára lé ọgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run, “Ẹni tí a kò lè rí” nítorí pé ọgbọ́n rẹ̀ ń ríran jìnnà. Gẹ́gẹ́ bíi ti Mósè, ẹ jẹ́ káwa náà fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ju ohunkóhun mìíràn lọ nínú ayé.

6, 7. (a) Báwo ni Ísọ̀ ṣe fi hàn pé òun fẹ́ràn láti máa rìn nípa ohun tó rí? (b) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísọ̀ jẹ́ fún wa?

6 Fi ọ̀rọ̀ ti Mósè wé ti Ísọ̀, ọmọ Ísákì baba ńlá náà. Ísọ̀ fẹ́ràn ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ púpọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 25:30-34) Nítorí pé Ísọ̀ “kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀,” ó fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí ṣe “pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.” (Hébérù 12:16) Kò ronú lórí bí ìpinnu tó ṣe láti ta ogún ìbí rẹ̀ ṣe máa kan àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà tàbí ipa tó máa ní lórí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Ojú tẹ̀mí rẹ̀ kò ríran mọ́. Ísọ̀ fọwọ́ rọ́ àwọn ìlérí dáradára tí Ọlọ́run ṣe tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kò kà á sí rárá. Ńṣe ló ń rìn nípa ohun tó rí, kò rìn nípa ìgbàgbọ́.

7 Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísọ̀ jẹ́ fún wa lónìí. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu kan, ì báà jẹ́ kékeré tàbí ńlá, kò yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀tàn ayé Sátánì mú wa, ẹ̀tàn yẹn sì ni pé kéèyàn ní ohun tó ń fẹ́ báyìí-báyìí. Á dára ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé irú ẹ̀mí tí Ísọ̀ ní lèmi náà ní? Tí mo bá ń lépa àwọn nǹkan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí nísinsìnyí, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní mú kí n fọwọ́ rọ́ nǹkan tẹ̀mí tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan? Ǹjẹ́ àwọn ohun tí mò ń ṣe lè ṣàkóbá fún àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti èrè mi ọjọ́ iwájú? Irú àpẹẹrẹ wo ni mò ń fi lélẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn?’ Tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó fi hàn pé a mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí, Jèhófà yóò bù kún wa.—Òwe 10:22.

Bá A Ṣe Lè Yẹra fún Ìdẹkùn Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì

8. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká kọbi ara sí ìkìlọ̀ náà?

8 Nínú ìran tí Jésù Kristi tí Ọlọ́run ṣe lógo fi han àpọ́sítélì Jòhánù lápá ìparí ọ̀rúndún kìíní, Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan fún ìjọ tó wà nílùú Laodíkíà, ní Éṣíà Kékeré. Ńṣe ló fi àwọn ọ̀rọ̀ náà kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Ọlọ́rọ̀ làwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà, àmọ́ òtòṣì ni wọ́n nípa tẹ̀mí. Dípò tí wọn ì bá máa rìn nípa ìgbàgbọ́, ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí kíkó àwọn nǹkan ìní ti ara jọ fọ́ ojú wọn nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 3:14-18) Ọṣẹ́ tí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ń ṣe lónìí náà nìyẹn. Ó lè sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ, ó sì lè mú ká ṣíwọ́ fífi “ìfaradà sá eré ìje” ìyè. (Hébérù 12:1) Tá ò bá ṣọ́ra, “adùn ìgbésí ayé yìí” lè bo àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí mọ́lẹ̀ débi tó fi máa “fún wọn pa pátápátá.”—Lúùkù 8:14.

9. Báwo ni ẹ̀mí ohun-moní-tómi àti ìmọrírì fún oúnjẹ tẹ̀mí ṣe lè dáàbò bò wá?

9 Ohun pàtàkì kan tó máa mú ká ní ààbò tẹ̀mí ni pé ká lẹ́mìí ohun-moní-tómi dípò ká máa lo ayé yìí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tàbí ká máa wá bí a ó ṣe di ọlọ́rọ̀. (1 Kọ́ríńtì 7:31; 1 Tímótì 6:6-8) Tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́, tí kì í ṣe nípa ohun tá a lè fojú rí, a óò ní ayọ̀ nínú párádísè tẹ̀mí tá a wà nínú rẹ̀ yìí. Bá a ṣe ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀, ǹjẹ́ èyí kì í ṣe ìṣírí fún wa pé ká máa “fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà”? (Aísáyà 65:13, 14) Ìyẹn nìkan kọ́ o, inú wa ń dùn láti máa bá àwọn tí èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run ń hàn nínú ìgbésí ayé wọn kẹ́gbẹ́. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí àwọn nǹkan tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì jẹ́ kí wọ́n tù wá lára!

10. Àwọn ìbéèrè wo ni yóò dára ká bi ara wa?

10 Àwọn ìbéèrè kan tó yẹ ká bi ara wa rèé: ‘Báwo ni àwọn nǹkan tara ṣe ṣe pàtàkì sí mi tó? Ṣé ìgbésí ayé adùn ni mò ń fi àwọn nǹkan ìní mi gbé ni àbí mo fi ń ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ kó lè máa tẹ̀ síwájú? Kí lohun tó máa ń fún mi láyọ̀ jù lọ? Ṣé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìbákẹ́gbẹ́ láwọn ìpàdé ìjọ ni àbí ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀ tí kò la nǹkan tẹ̀mí lọ? Ǹjẹ́ mo máa ń lo ọ̀pọ̀ òpin ọ̀sẹ̀ fún eré àṣenajú dípò tí màá fi lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ láti jáde òde ẹ̀rí tàbí láti kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn tòótọ́?’ Láti fi hàn pé à ń rìn nípa ìgbàgbọ́, a ní láti máa ṣe iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lójú méjèèjì, ká sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí Jèhófà.—1 Kọ́ríńtì 15:58.

Fi Í Sọ́kàn Pé Òpin Ti Sún Mọ́lé

11. Báwo ní rírìn nípa ìgbàgbọ́ ṣe ń jẹ́ ká lè máa fi í sọ́kàn pé òpin ayé ti sún mọ́lé?

11 Tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́, a ò ní máa ronú pé ó máa pẹ́ kí òpin tó dé tàbí pé òpin ò tiẹ̀ ní dé rárá. A yàtọ̀ sáwọn oníyèmejì tí wọn ò gbà pé òótọ́ làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nítorí a lóye pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa àkókò tá a wà yìí. (2 Pétérù 3:3, 4) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn tí ń bẹ nínú ayé lónìí kò fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé yìí? (2 Tímótì 3:1-5) Ìgbàgbọ́ ló ń jẹ́ ká rí i pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé lọ́wọ́lọ́wọ́ kì í kàn án ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ lásán. Dípò ìyẹn, wọ́n jẹ́ “àmì wíwàníhìn-ín [Kristi] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 24:1-14.

12. Báwo ni ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Lúùkù 21:20, 21 ṣe ṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?

12 Wo ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni tó bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí mu. Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa ṣẹ, ọ̀gágun Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun Róòmù yí Jerúsálẹ́mù ká lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni. Ṣùgbọ́n, àwọn ọmọ ogun náà ṣàdédé padà sílùú wọn, èyí wá jẹ́ káwọn Kristẹni mọ̀ pé ó tó àkókó wàyí fún wọn láti “sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” Nígbà tó di ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà wá, wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josephus sọ pé àwọn Júù tó kú lé ní mílíọ̀nù kan, àti pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97,000] èèyàn ni wọ́n kó nígbèkùn. Ìdájọ́ Ọlọ́run dé sórí ètò àwọn nǹkan Júù yẹn. Àwọn tó rìn nípa ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Jésù ló yè bọ́ nínú àjálù náà.

13, 14. (a) Kí làwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò sí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?

13 Irú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn máa tó wáyé ní àkókò tiwa yìí. Àwọn ẹgbẹ́ tí ń bẹ nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè yóò kópa nínú mímú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ. Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé Pax Romana, ìyẹn Àlàáfíà Róòmù, làwọn ọmọ ogun Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní ń wá, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ lónìí láti mú kí àlàáfíà wà nínú ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Róòmù gbìyànjú láti mú kí àlàáfíà wà jákèjádò ayé nígbà náà lọ́hùn-ún, àwọn náà ló tún wá pa Jerúsálẹ́mù run. Bákan náà lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àwọn ológun tó wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè yóò rí ìsìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìdíwọ́, wọ́n á sì pa Jerúsálẹ́mù òde òní run, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, àti ìyókù Bábílónì Ńlá. (Ìṣípayá 17:12-17) Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ti wà ní bèbè ìparun.

14 Gbàrà tí ìparun ìsìn èké bá wáyé, ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Nígbà tí àkókò ìpọ́njú ńlá náà bá sì wá ń parí lọ, ìyókù ètò àwọn nǹkan yìí yóò ṣègbé. (Mátíù 24:29, 30; Ìṣípayá 16:14, 16) Rírìn nípa ìgbàgbọ́ ń mú ká wà lójúfò sí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. A mọ̀ dájúdájú pé kì í ṣe ètò èyíkéyìí táráyé gbé kalẹ̀, irú bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni Ọlọ́run máa lò láti mú àlàáfíà àti ààbò wá sórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa fi hàn pé ó dá wa lójú pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé”?—Sefanáyà 1:14.

Ewu Wo Ló Wà Nínú Kéèyàn Máa Rìn Nípa Ohun Tó Lè Fojú Rí?

15. Pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó, ìdẹkùn wo ni wọ́n ṣì pàpà kó sí?

15 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́ ká mọ àwọn ewu tó wà nínú kéèyàn jẹ́ kí rírìn nípa ohun tó lè fojú rí bomi paná ìgbàgbọ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fojú ara wọn rí ìyọnu mẹ́wàá tó dójú ti àwọn òrìṣà àwọn ara Íjíbítì, wọ́n sì tún rí ọ̀nà àrà tí Ọlọ́run gbà yọ wọ́n ní Òkun Pupa, síbẹ̀ wọ́n ṣàìgbọràn, wọ́n lọ ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ ọ́. Ara wọn ò balẹ̀, wọn ò sì ní sùúrù rárá láti dúró de Mósè tí “ó pẹ́ . . . kí ó tó sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà.” (Ẹ́kísódù 32:1-4) Àìnísùúrù wọn ló mú kí wọ́n máa bọ òrìṣà tí wọ́n lè fojú rí. Rírìn tí wọ́n ń rìn nípa ohun tí wọ́n rí yìí tàbùkù sí Jèhófà, ó sì ṣekú pa “nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ènìyàn.” (Ẹ́kísódù 32:25-29) Ẹ ò rí i pé ohun ìbànújẹ́ gbáà ló jẹ́ tí olùjọsìn Jèhófà kan lóde òní bá lọ ń ṣe ohun tó máa fi hàn pé kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tàbí tó lọ ń ṣe ohun tó máa fi hàn pé kò gbà gbọ́ pé Ọlọ́run lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ!

16. Báwo ni rírìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn nípa ohun tí wọ́n rí ṣe ṣàkóbá fún wọn?

16 Rírìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn nípa ohun tí wọ́n rí ṣàkóbá fún wọn láwọn ọ̀nà míì. Nítorí pé wọ́n ń rìn nípa ohun tí wọ́n rí, ìyẹn ló mú kí wọ́n máa bẹ̀rù nígbà tí wọ́n rí àwọn ọ̀tá wọn. (Númérì 13:28, 32; Diutarónómì 1:28) Òun ni kò jẹ́ kí wọ́n gbà pé Mósè ni Ọlọ́run fi ṣe aṣáájú wọn, tó sì tún mú kí wọ́n máa kùn nítorí ipò tí wọ́n wà. Àìnígbàgbọ́ wọn yìí ló mú kí wọ́n fẹ́ràn Íjíbítì tí ẹ̀mí èṣù ń darí ju Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 14:1-4; Sáàmù 106:24) Ẹ ò rí i pé ó ti ní láti dun Jèhófà gan-an bí wọn ò ṣe bọ̀wọ̀ fún un níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni Ọba wọn tí wọ́n ò lè fojú rí!

17. Kí ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ ìtọ́sọ́nà Jèhófà sílẹ̀ nígbà ayé Sámúẹ́lì?

17 Nígbà tó tún dìgbà ayé Sámúẹ́lì, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run ṣojú rere sí yìí tún ń rìn nípa ohun tí wọ́n rí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé àwọn fẹ́ ọba táwọn lè fojú rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fi hàn wọ́n pé òun ni Ọba wọn, síbẹ̀ wọn kọ̀ láti máa rìn nípa ìgbàgbọ́. (1 Sámúẹ́lì 8:4-9) Àìgbọ́n mú kí wọ́n kọ ìtọ́sọ́nà Jèhófà sílẹ̀, wọ́n lọ ń fara wé àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Àkóbá ńlá sì ni ohun tí wọ́n ṣe yìí yọrí sí fún wọn.—1 Sámúẹ́lì 8:19, 20.

18. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa rìn nípa ohun tó lè fojú rí?

18 Àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní mọrírì àjọṣe dáradára tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run. A ṣe tán láti kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, a sì ṣe tán láti máa fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò. (Róòmù 15:4) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn nípa ohun tí wọ́n rí, wọ́n gbàgbé pé Ọlọ́run ló ń tipasẹ̀ Mósè darí wọn. Táwa náà ò bá ṣọ́ra, a lè gbàgbé pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, tí í ṣe Mósè Títóbi Jù, ló ń darí ìjọ Kristẹni lónìí. (Ìṣípayá 1:12-16) Ó yẹ ká ṣọ́ra gidigidi ká má lọ máa fi ojú tara wo apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, èyí lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí kùn sáwọn tó ń ṣojú fún Jèhófà ká má sì mọyì wọn àtàwọn ìpèsè tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè.—Mátíù 24:45.

Pinnu Láti Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́

19, 20. Kí lo pinnu láti máa ṣe, kí sì nìdí tó o fi ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀?

19 Bíbélì sọ pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Sátánì Èṣù ni olórí ọ̀tá wa. Ohun tó ń fẹ́ ò ju pé kó bomi paná ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà pátápátá. Kò sóhun tí kò ní gbìyànjú rẹ̀ wò tán láti mú ká jáwọ́ nínú sísin Ọlọ́run. (1 Pétérù 5:8) Kí ni yóò dáàbò bò wá káwọn nǹkan tá a lè fojú rí nínú ayé Sátánì yìí má bàa tàn wá jẹ? Kò sí nǹkan míì tá a lè ṣe ju pé ká máa rìn nípa ìgbàgbọ́, kó má ṣe jẹ́ nípa ohun tá a lè fojú rí. Tá a bá gbára lé àwọn ìlérí Jèhófà tá a sì gbà gbọ́ pé yóò ṣẹ, èyí kò ní jẹ́ kí ‘ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì.’ (1 Tímótì 1:19) Nígbà náà, ohunkóhun tí ì báà gbà, ẹ jẹ́ ká máa rìn nípa ìgbàgbọ́ nìṣó, ká sì mọ̀ dájú pé Jèhófà yóò bù kún wa. Ẹ sì jẹ́ ká máa gbàdúrà pé ká lè yè bọ́ nínú gbogbo àwọn nǹkan tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ ọjọ́.—Lúùkù 21:36.

20 Bá a ṣe ń rìn nípa ìgbàgbọ́, tí kì í ṣe nípa ohun tá a lè fojú rí, Ẹnì kan wà tó fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé. Bíbélì sọ pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣàlàyé bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí lo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Mósè àti ti Ísọ̀ lórí ọ̀rọ̀ rírìn nípa ìgbàgbọ́, dípò rírìn nípa ohun téèyàn rí?

• Kí ni ohun pàtàkì kan tí kò ní jẹ́ ká di olùfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì?

• Báwo ni rírìn nípa ìgbàgbọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa ronú pé òpin ṣì jìnnà?

• Kí nìdí tí rírìn nípa ohun tá a lè fojú rí fi léwu?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Mósè rìn nípa ìgbàgbọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ǹjẹ́ eré àṣenajú máa ń di ọ lọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà kó o má lè kópa nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Báwo ni kíkọbiara sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè dáàbò bò ọ́?