Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn Ń Di Olùjọsìn Jèhófà

Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn Ń Di Olùjọsìn Jèhófà

“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”

Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn Ń Di Olùjọsìn Jèhófà

BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò wa yìí, àwọn èèyàn látinú orílẹ̀-èdè gbogbo yóò máa wọ́ tìrítìrí lọ síbi ìjọsìn Jèhófà tó ga ju gbogbo ìjọsìn yòókù lọ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà Ọlọ́run gbẹnu wòlíì Hágáì sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.” (Hágáì 2:7) Bẹ́ẹ̀ náà ni wòlíì Aísáyà àti Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò wa yìí, ìyẹn “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn àtàwọn orílẹ̀-èdè yóò máa sin Jèhófà bó ṣe fẹ́.—Aísáyà 2:2-4; Míkà 4:1-4.

Ǹjẹ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ lóde òní lóòótọ́? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ná. Láti ọdún mẹ́wàá báyìí, ó ju mílíọ̀nù mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [3,110,000] àwọn ẹni tuntun tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ní orílẹ̀-èdè tó lé ní igba ó lé ọgbọ̀n [230]. Tá a bá rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́wàá lóde òní, mẹ́fà nínú wọn máa jẹ́ àwọn tó ṣèrìbọmi láti ọdún mẹ́wàá síbí. Tá a bá pín iye àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣèrìbọmi lọ́dún 2004 sórí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọdún náà, a ó rí i pé ìṣẹ́jú méjì-méjì ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà jálẹ̀ ọdún náà! a

‘Iye púpọ̀ ló ń di onígbàgbọ́ tí wọ́n sì ń yí padà sọ́dọ̀ Olúwa’ lóde òní gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní. Lóòótọ́ o, iye àwọn tó ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan kọ́ ló ń fi hàn pé Ọlọ́run ń bù kún wa àmọ́ ó ń jẹ́ ká mọ̀ pé “ọwọ́ Jèhófà” wà lára àwa èèyàn rẹ̀. (Ìṣe 11:21) Kí ló ń mú kí ogunlọ́gọ̀ èèyàn wọ̀nyí wá sínú ìjọsìn Jèhófà? Báwo ni wíwá tí wọ́n ń wá yìí sì ṣe kàn ọ́?

Ohun To Ń Mú Kí Àwọn Ẹni Yíyẹ Wá Sínú Ìsìn Tòótọ́

Jésù sọ ọ́ gbangba gbàǹgbà pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Nítorí náà, Jèhófà gan-an lẹni tó ń fa àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” sínú ìsìn tòótọ́. (Ìṣe 13:48) Ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú káwọn èèyàn jí gìrì sí nǹkan tẹ̀mí tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. (Mátíù 5:3) Ó lè jẹ́ ẹ̀rí ọkàn tó ń gún àwọn kan ní kẹ́ṣẹ́ ló mú kí wọ́n fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run tàbí káwọn míì máa wá bí ọjọ́ ọ̀la wọn á ṣe dára, ó sì lè jẹ́ ìṣòro làwọn kan ní, tí wọ́n ṣe fẹ́ mọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáráyé.—Máàkù 7:26-30; Lúùkù 19:2-10.

Ohun tó mú káwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn Jèhófà ni pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ń ṣe jẹ́ kí wọ́n rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ń rú wọn lójú.

Ìbéèrè tí Davide tó ń ta oògùn olóró ní ilẹ̀ Ítálì ti ń ronú lé lórí tipẹ́ ni pé: “Bí Ọlọ́run bá wà, èé ṣe tí ìwà ìrẹ́jẹ fi ń bá a lọ láìdáwọ́dúró láyé yìí?” Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kọ́ ló jẹ ọ̀gbẹ́ni yìí lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ tó fi béèrè ìbéèrè yìí o, ó kàn fẹ́ fi dá àríyànjiyàn sílẹ̀ ni. Ó ní: “Mi ò mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí tó ń bá mi sọ̀rọ̀ á lè rí ìdáhùn kan pàtàkì fún mi. Ṣùgbọ́n, ńṣe ló fi sùúrù bá mi sọ̀rọ̀, ó sì fi ẹsẹ Bíbélì ti gbogbo ohun tó ń sọ lẹ́yìn. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn ló yí mi lọ́kàn padà.” Ní báyìí, Davide ti yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà, ó sì ti ń sin Jèhófà.

Ní tàwọn míì, báyé wọn á ṣe dáa àti bí ọjọ́ ọ̀la wọn á ṣe nítumọ̀ ni wọ́n ń wá kiri tí wọ́n fi di ara ètò Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin oníṣègùn ọpọlọ kan ní ìlú Zagreb ní ilẹ̀ Croatia ń wá ojútùú sí ìdààmú ọkàn òun fúnra rẹ̀, ó wá lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin kan tó jẹ́ oníṣègùn bíi tirẹ̀ tó gbajúmọ̀ gan-an. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un nígbà tí oníṣègùn yìí fún un ní nọ́ńbà tẹlifóònù ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Zagreb àti orúkọ Ẹlẹ́rìí kan tí ọkùnrin náà mọ̀. Ó wá sọ fún un pé: “Wò ó, àwọn wọ̀nyí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Bí mo bá ní kó o lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ère lo kàn máa rí lọ́hùn, o ò ní rẹ́ni bá ọ sọ̀rọ̀ gidi, gbogbo nǹkan ló ṣókùnkùn sí wọn. Mi ò rò pé wàá rí ìrànlọ́wọ́ kankan gbà ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo máa ń sọ fún àwọn míì bíi tìẹ pé kí wọ́n lọ, mo sì rò pé ọ̀dọ̀ wọn lá dáa kí ìwọ náà lọ.” Nígbà tó yá, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, oníṣègùn ọpọlọ yìí sọ pé mímọ̀ tóun mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe ti jẹ́ kóun mọyì ìgbésí ayé òun gan-an.—Oníwàásù 12:13.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé nígbà àjálù, kò sóhun tó lè fúnni ní ojúlówó ìtùnú bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì. Ní ilẹ̀ Gíríìsì, ọmọ ọdún méje kan já bọ́ látorí òrùlé iléèwé wọn, ó sì kú. Ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí bá ìyá ọmọ náà pàdé wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde tó ń bọ̀ láti fi tù ú nínú. (Jòhánù 5:28, 29) Ni obìnrin yìí bá bú sẹ́kún. Àwọn arábìnrin yìí wá bi í pé: “Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì? Ìgbà wo la sì lè wá sọ́dọ̀ rẹ?” Obìnrin yìí fèsì pé: “Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ báyìí.” Bí obìnrin náà ṣe mú wọn lọ sílé rẹ̀ nìyẹn, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, gbogbo ìdílé rẹ̀ ti ń sin Jèhófà.

Ǹjẹ́ Ò Ń Kópa Nínú Rẹ̀?

Àwọn ìrírí yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé báyìí. Jèhófà ń kó ogunlọ́gọ̀ àwọn olùjọsìn tòótọ́ jọ látinú onírúurú orílẹ̀-èdè, ó sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Inú àwọn èèyàn tó wá látinú onírúurú orilẹ̀-èdè yìí sì dùn pé àwọn yóò la òpin ètò búburú yìí já sínú ayé tuntun òdodo.—2 Pétérù 3:13.

Lọ́lá ìbùkún Jèhófà, iṣẹ́ ìkórè ńlá yìí, tó ta yọ èyíkéyìí, ń parí lọ láìsọsẹ̀. (Aísáyà 55:10, 11; Mátíù 24:3, 14) Ṣé ò ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run yìí? Tó o bá ń kópa nínú rẹ̀, kí ó dá ọ lójú pé Ọlọ́run yóò tì ọ́ lẹ́yìn, ìwọ náà á sì lè sọ ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí, pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo oṣù September àti October nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2005.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.”—JÒHÁNÙ 6:44

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

TA LÓ MÚ KÁ PỌ̀ TÓ BÁYÌÍ?

“Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.”—Sáàmù 127:1.

“Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà; tí ó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tí ń gbìn ni ó jẹ́ nǹkan kan tàbí ẹni tí ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń mú kí ó dàgbà.”—1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.