Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí A Lè Ṣe Tí Nǹkan Kan Ò Bá Múnú Wa Dùn

Ohun Tí A Lè Ṣe Tí Nǹkan Kan Ò Bá Múnú Wa Dùn

Ohun Tí A Lè Ṣe Tí Nǹkan Kan Ò Bá Múnú Wa Dùn

ǸJẸ́ ìbànújẹ́ máa ń dorí rẹ kodò nígbà míì? Ǹjẹ́ inú máa ń tètè bí ọ, ǹjẹ́ o máa ń tètè rẹ̀wẹ̀sì, ǹjẹ́ nǹkan sì máa ń tètè dà ọ́ lọ́kàn rú? Ǹjẹ́ àwọn àníyàn ayé máa ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́?

Bí inú wa ṣe máa ń dùn náà ni inú wa máa ń bà jẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bá ò bá yọ àyọ̀jù tá ò sì jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí wa kodò, a óò túbọ̀ gbádùn ayé wa. Àmọ́ Bíbélì sọ pé “ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Nínú ayé tá à ń gbé yìí tó jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni ìwà ipá àti jàǹbá ń ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ a rẹ́ni tí nǹkan wọ̀nyí kì í bà nínú jẹ́? Àmọ́, Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé: “Kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ènìyàn máa yọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Oníwàásù 3:22) Torí náà, ká lè túbọ̀ gbádùn ayé wa, ó yẹ ká máa múnú ara wa dùn nípa ríro ohun tó dáa sí ara wa. Kí la lè ṣe láti máa múnú ara wa dùn, tá ò sì ní jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí wa kodò?

Tí a bá ṣe àwọn ohun tá a rí i pé ó yẹ, èyí lè jẹ́ kí ìbànújẹ́ wa dín kù. Bí àpẹẹrẹ, táwọn ohun kan tá ò lè fúnra wa yanjú bá ń mú ká ṣàníyàn, ǹjẹ́ kò ní dára ká yíwọ́ padà tàbí ká kúrò níbi tá a wà dípò ká kàn máa ronú nípa wọn ṣáá? Lára àwọn ohun tá a lè ṣe ni pé ká rin ìrìn gbẹ̀fẹ́, ká tẹ́tí sí orin atunilára, ká ṣe eré ìdárayá tó máa jẹ́ ká làágùn tàbí ká ṣoore fún ẹnì kan tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́, èyí lè jẹ́ kí ara tù wá díẹ̀, ká sì túbọ̀ láyọ̀.—Ìṣe 20:35.

Àmọ́, ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà gbógun ti ìbànújẹ́ ni pé ká gbára lé Ẹlẹ́dàá wa. Bí ìbànújẹ́ bá kọ̀ tí kò lọ, ńṣe ló yẹ ká ‘kó gbogbo àníyàn wa lé Ọlọ́run,’ ká máa gbàdúrà sí i. (1 Pétérù 5:6, 7) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà . . . Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.” (Sáàmù 34:18, 19) Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò jẹ́ ‘ìrànwọ́ wa àti Olùpèsè àsálà fún wa’? (Sáàmù 40:17) Kí ìyẹn lè ṣeé ṣe, a ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ gidi tó wà nínú rẹ̀, èyí tó fi hàn bí Ọlọ́run ṣe fi ìfẹ́ bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò.