Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Jésù Kristi?

Ta Ni Jésù Kristi?

Ta Ni Jésù Kristi?

WO BÍ inú ọmọkùnrin Júù kan tó ń jẹ́ Áńdérù ṣe dùn tó nígbà àkọ́kọ́ tó gbọ́rọ̀ Jésù ará Násárétì! Bíbélì sọ pé kíá ló lọ bá ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà [tàbí, Kristi].” (Jòhánù 1:41) Ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì táwọn èèyàn sábà máa ń tú sí “Mèsáyà” tàbí “Kristi” túmọ̀ sí ni “Ẹni Àmì Òróró.” Jésù ni Ẹni Àmì Òróró tàbí Àyànfẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn Aṣáájú tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó ń bọ̀. (Aísáyà 55:4) Ìwé Mímọ́ ti sọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé ó ń bọ̀, àwọn Júù ayé ìgbà náà sì ń retí rẹ̀ lóòótọ́.—Lúùkù 3:15.

Báwo la ṣe mọ̀ pé Àyànfẹ́ Ọlọ́run ni Jésù lóòótọ́? Ìwọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jésù pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún. Ó lọ sọ́dọ̀ Jòhánù Olùbatisí pé kó ri òun bọmi nínú Odò Jọ́dánì. Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’” (Mátíù 3:16, 17) Bí Jòhánù ṣe gbóhùn Ọlọ́run pé ó tẹ́wọ́ gba Jésù, ǹjẹ́ ó tún lè máa ṣiyèméjì pé Jésù ni Àyànfẹ́ Ọlọ́run? Ẹ̀mí mímọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run tú sórí Jésù fi hàn pé ó fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀. Bí Jésù sì ṣe di Kristi, ìyẹn Ẹni Àmì Òróró nìyẹn. Àmọ́ ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run? Ìgbà wo ni Jésù ti wà?

Ó Ti Wà Láti “Àwọn Àkókò Ìjímìjí”

A lè pín ìgbésí ayé Jésù sí ìpele mẹ́ta. Ìpele àkọ́kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó bí i sí ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ èèyàn. Míkà 5:2 sọ pé “láti àwọn àkókò ìjímìjí, láti àwọn ọjọ́ tí ó jẹ́ àkókò tí ó lọ kánrin” ló ti wà. Jésù pàápàá sọ pé: “Èmi wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso òkè,” ìyẹn láti ọ̀run. (Jòhánù 8:23) Ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ńlá ni nígbà tó wà lọ́run.

Gbogbo ìṣẹ̀dá pátá ló ní ìbẹ̀rẹ̀, tó fi hàn pé ìgbà kan wà tí kò sí ẹ̀dá kankan àfi Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Àmọ́ ní ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn nǹkan. Ta ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ná? Ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì sọ pé Jésù ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 3:14) Jésù ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” Ìdí ni pé “nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí.” (Kólósè 1:15, 16) Ó fi hàn pé Jésù nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run fúnra rẹ̀ dá. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo.” (Jòhánù 3:16) Bíbélì tún pe àkọ́bí Ọlọ́run yìí ní “Ọ̀rọ̀.” (Jòhánù 1:14) Kí nìdí tó fi pè é bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó máa ń ṣe agbẹnusọ fún Ọlọ́run nígbà tó wà lọ́run kó tó di pé wọ́n bí i sí ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn.

“Ọ̀rọ̀” yìí wà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run “ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” nígbà tí Ọlọ́run dá “ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Òun ni Ọlọ́run sọ fún pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa.” (Jòhánù 1:1; Jẹ́nẹ́sísì 1:1, 26) Àkọ́bí ọmọ Jèhófà yìí wà lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ nígbà yẹn, tí wọ́n jọ ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu. Ìwé Òwe 8:22-31 fi hàn pé ọmọ yìí sọ pé: “Mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Ẹlẹ́dàá] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.”

Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo á mọwọ́ ara wọn gan-an ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yẹn! Àjọṣe tímọ́tímọ́ tí Jésù àti Jèhófà jọ ní láti ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún ní ipa tó pọ̀ lórí Jésù, Ọmọ Ọlọ́run. Onígbọràn Ọmọ yìí sì wá dà bí Jèhófà Bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́. Kódà “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí” ni Kólósè 1:15 pe Jésù. Ìdí nìyí tó fi ṣe pàtàkì ká mọ Jésù dáadáa nítorí ìyẹn ló máa jẹ́ ká lè pòùngbẹ tó bá ń gbẹ wá nípa tẹ̀mí ká sì lè mọ Ọlọ́run dáadáa. Gbogbo ohun tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe gẹ́lẹ́. Nítorí náà, tá a bá ti lè mọ Jésù, ìmọ̀ wa nípa Jèhófà á pọ̀ sí i. (Jòhánù 8:28; 14:8-10) Àmọ́, báwo ni Jésù ṣe délé ayé?

Ó Di Èèyàn Tó Ń Gbé Lórí Ilẹ̀ Ayé

Ìpele kejì ìgbésí ayé Jésù Ọmọ Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run rán an wá sáyé. Ohun tí Jèhófà ṣe ni pé ó fi ẹ̀mí Jésù sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, wúńdíá Júù kan tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, ó sì ṣe èyí lọ́nà ìyanu. Jésù kò jogún àìpé kankan torí pé èèyàn ẹlẹ́ran ara kọ́ ni bàbá rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà bà lé Màríà, agbára Ọlọ́run sì “ṣíji bò ó,” èyí sì mú kó lóyún lọ́nà ìyanu. (Lúùkù 1:34, 35) Ìdí nìyẹn tí Màríà fi bí ọmọ tó jẹ́ ẹni pípé. Jósẹ́fù tó jẹ́ káfíńtà ni alágbàtọ́ ọmọ náà, èyí tó fi hàn pé inú agboolé tálákà ló dàgbà sí. Jésù sì ni àkọ́bí nínú àwọn ọmọ bíi mélòó kan tí Màríà bí.—Aísáyà 7:14; Mátíù 1:22, 23; Máàkù 6:3.

Bíbélì ò sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé, àmọ́ ó sọ ohun pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, àwọn òbí rẹ̀ mú un dání lọ sí àjọ̀dún Ìrékọjá tí wọ́n máa ń lọ ṣe lọ́dọọdún ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n wà lọ́hùn-ún Jésù kò kúrò ní tẹ́ńpìlì, “ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó sì ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.” Síwájú sí i, “gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” Yàtọ̀ sí pé Jésù ń bi wọ́n láwọn ìbéèrè ọlọgbọ́n, tó dá lórí nǹkan tẹ̀mí, ó tún ń fún wọn ní ìdáhùn olóye tó ń ṣe àwọn èèyàn ní kàyéfì. (Lúùkù 2:41-50) Bó ṣe ń dàgbà ní ìlú Násárétì, ó kọ́ iṣẹ́ káfíńtà, ó sì dájú pé ọwọ́ Jósẹ́fù alágbàtọ́ rẹ̀ ló ti kọ́ ọ.—Mátíù 13:55.

Ìlú Násárétì yìí ni Jésù wà títí tó fi di ọmọ ọgbọ̀n ọdún. Ó wá lọ sọ́dọ̀ Jòhánù láti lọ ṣèrìbọmi. Bí Jésù ṣe ṣèrìbọmi tán, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní pẹrẹu. Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ló fi rìn jákèjádò àgbègbè tí wọ́n bí i sí, tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó ṣe ohun tó fi hàn pé Ọlọ́run ló rán an wá sáyé. Kí lohun náà? Ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tó ju agbára èèyàn ẹlẹ́ran ara lọ.—Mátíù 4:17; Lúùkù 19:37, 38.

Bákan náà, Jésù jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ àti ẹni tó ń gba tèèyàn rò. Ìṣe rẹ̀ láàárín àwọn èèyàn jẹ́ ká rí ìwà pẹ̀lẹ́ tó ní. Jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ àti onínúure mú káwọn èèyàn fẹ́ràn rẹ̀. Kódà ọkàn àwọn ọmọdé máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀. (Máàkù 10:13-16) Jésù bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn kan nígbà ayé rẹ̀. (Jòhánù 4:9, 27) Ó mú kí àwọn tálákà àtàwọn tí àwọn èèyàn ń ní lára ‘rí ìtura fún ọkàn’ wọn. (Mátíù 11:28-30) Ó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó yéni, tó rọrùn, tó sì ṣeé múlò. Ohun tó sì fi kọ́ni jẹ́ kó hàn pé tinútinú ló fi fẹ́ káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́.—Jòhánù 17:6-8.

Tìyọ́nú-tìyọ́nú ni Jésù fi fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ ìyanu láti fi mú àwọn aláìsàn àtàwọn tó wà nínú ìpọ́njú lára dá. (Mátíù 15:30, 31) Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan bẹ̀ ẹ́ pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Kí ni Jésù ṣe? Ó fọwọ́ kan adẹ́tẹ̀ náà, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Bí ara adẹ́tẹ̀ náà ṣe dá ṣáṣá nìyẹn!—Mátíù 8:2-4.

Bákan náà, tún wo ìgbà kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó lo ọjọ́ mẹ́ta lọ́dọ̀ Jésù kò rí oúnjẹ jẹ. Àánú àwọn èèyàn náà ṣe Jésù, ó sì pèsè oúnjẹ lọ́nà ìyanu fún “ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké.” (Mátíù 15:32-38) Lásìkò mìíràn, ó mú kí òkun tó ń ru gùdù pa rọ́rọ́ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó wà lójú agbami. (Máàkù 4:37-39) Ó jí àwọn òkú dìde. a (Lúùkù 7:22; Jòhánù 11:43, 44) Jésù tó jẹ́ èèyàn pípé tún fínnú-fíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí ìran ènìyàn aláìpé lè ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn jinlẹ̀ gan-an ni!

Ibo Ni Jésù Wà Lónìí?

Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àtààbọ̀ ni Jésù nígbà tó kú lórí òpó igi oró. b Àmọ́, ikú tó kú yìí kọ́ ni òpin ìgbésí ayé rẹ̀. Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ikú rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run jí Ọmọ rẹ̀ yìí dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ ìpele kẹta ìgbésí ayé rẹ̀. Nígbà tí Jésù jíǹde, ó fara han ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn. (1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Lẹ́yìn náà, ó “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,” ó ń retí ìgbà tí yóò gba agbára ìjọba. (Hébérù 10:12, 13) Nígbà tí àsìkò tó, Jésù di ọba. Irú ojú wo ló wá yẹ ká máa fi wo Jésù lónìí? Ṣé ó yẹ ká máa wo Jésù bí ẹni tó ń joró lórí òpó tí wọ́n kàn án mọ́ ni tàbí ká máa wò ó bí ẹni tó yẹ ká máa jọ́sìn? Ènìyàn kọ́ ni Jésù báyìí, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni, kódà Ọba tó ń ṣàkóso ni. Láìpẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ayé tí ìṣòro kún fọ́fọ́ yìí.

Ìwé Ìṣípayá 19:11-16 lo èdè àpèjúwe nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi, ó ní ó jẹ́ ọba tó gun ẹṣin funfun kan, tó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́, tó sì ń jagun òdodo lọ. Ó ní ‘idà gígùn mímú kan, kí ó lè fi í ṣá àwọn orílẹ̀-èdè.’ Èyí fi hàn pé Jésù yóò lo agbára ńlá rẹ̀ láti fi pa àwọn olubi run. Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá sa gbogbo ipá wọn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? (1 Pétérù 2:21) Òun àti Baba rẹ̀ yóò pa wọ́n mọ́ nígbà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” tó ń bọ̀, èyí tá à ń pè ní Amágẹ́dọ́nì. Nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n á lè wà láàyè títí láé nínú Ìjọba Ọlọ́run tí yóò máa ṣàkóso wọn látọ̀run wá.—Ìṣípayá 7:9, 14; 16:14, 16; 21:3, 4.

Nígbà ìjọba Jésù tí yóò jẹ́ ìjọba àlàáfíà, iṣẹ́ ìyanu tí Jésù yóò ṣe fún gbogbo ọmọ aráyé á pọ̀ gan-an! (Aísáyà 9:6, 7; 11:1-10) Yóò wo àwọn aláìsàn sàn yóò sì mú ikú kúrò pátápátá. Ọlọ́run yóò lo Jésù láti jí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti kú dìde, kí wọ́n lè láǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 5:28, 29) Ká sòótọ́, ohun téèyàn máa gbádùn nínú Ìjọba Ọlọ́run kọjá ohun tá a lè máa ròyìn. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa gba ìmọ̀ Bíbélì nìṣó, ká sì túbọ̀ mọ Jésù Kristi sí i.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gbangba gbàǹgbà làwọn èèyàn ń rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Kódà àwọn ọ̀tá Jésù gbà pé ó “ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì.”—Jòhánù 11:47, 48.

b Tó o bá ń fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa bóyá orí òpó igi oró ni Kristi ti kú tàbí orí àgbélébùú, wo ìwé Reasoning From the Scriptures ojú ìwé 89 àti 90. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe é.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

ṢÉ JÉSÙ NI ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ?

Ọ̀pọ̀ àwọn onísìn ló ń sọ pé Jésù ni Ọlọ́run. Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Ohun tí ẹ̀kọ́ yìí sì sọ ni pé, “Baba jẹ́ Ọlọ́run, Ọmọ jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ̀mí Mímọ́ náà sì jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ kì í ṣe Ọlọ́run mẹ́ta ló wà bí kò ṣe Ọlọ́run kan.” Wọ́n ní àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta “jẹ́ ẹni ayérayé, wọ́n sì bára dọ́gba.” (Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia) Ǹjẹ́ èrò yẹn tọ̀nà?

Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá. (Ìṣípayá 4:11) Kò ní ìbẹ̀rẹ̀ kò sì lópin, òun sì ni Olódùmarè. (Sáàmù 90:2) Ṣùgbọ́n Jésù ní ìbẹ̀rẹ̀ ní tirẹ̀. (Kólósè 1:15, 16) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run pé ó jẹ́ Baba òun, ó ní: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Jésù tún ṣàlàyé pé àwọn nǹkan kan wà tóun tàbí àwọn áńgẹ́lì ò mọ̀, tó jẹ́ pé Baba òun nìkan ló mọ̀ ọ́n.—Máàkù 13:32.

Síwájú sí i, Jésù gbàdúrà sí Baba rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Ta ni Jésù ì bá máa gbàdúrà sí bí kì í bá ṣe Ẹni tó jù ú lọ? Ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run ló jí Jésù dìde nígbà tó kú, Jésù kọ́ ló jí ara rẹ̀ dìde. (Ìṣe 2:32) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Baba àti Ọmọ rẹ̀ kò bára dọ́gba kí Jésù tó wá sáyé àti nígbà tó wà láyé. Ìgbà tí Jésù wá jíǹde tó lọ sọ́run ńkọ́? Ìwé 1 Kọ́ríńtì 11:3 sọ pé: “Orí Kristi ni Ọlọ́run.” Kódà títí láé ni Jésù yóò máa wà lábẹ́ Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 15:28) Nítorí náà, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jésù kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run ni.

Ohun táwọn kan pè ní ẹnì kẹta nínú Mẹ́talọ́kan, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́, kì í ṣe ẹni gidi kan. Nígbà tí onísáàmù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó ní: “Bí ìwọ bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a óò dá wọn.” (Sáàmù 104:30) Ẹ̀mí yìí kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ipá ìṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run fi máa ń ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣe ni. Òun ni Ọlọ́run fi dá ọ̀run òun ayé àti gbogbo ẹ̀dá alààyè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Sáàmù 33:6) Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yìí mí sí àwọn tó kọ Bíbélì. (2 Pétérù 1:20, 21) Èyí fi hàn pé Mẹ́talọ́kan kì í ṣe ẹ̀kọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni. c Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.”—Diutarónómì 6:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

c Tó o bá ń fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo ìwé pẹlẹbẹ Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Nígbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ó di Ẹni Àmì Òróró tí Ọlọ́run yàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un lójú méjèèjì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọba alágbára ni Jésù báyìí