Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?

Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?

Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?

“TÍTÍ dòní olónìí, kàyéfì lọ̀rọ̀ Pílátù oníyèmejì tó fi Jésù ṣẹlẹ́yà jẹ́ fáwọn èèyàn. Àwọn kan kà á sí ẹni mímọ́, àwọn míì sì kà á sí ojo èèyàn, ẹni tó ṣe bíi tàwọn olóṣèlú, tó lọ pa ẹni ẹlẹ́ni nítorí pé kò fẹ́ káwọn èèyàn fa wàhálà.”—Ìwé Pontius Pilate tí Ann Wroe kọ.

Èyí tó wù kó o fara mọ́ nínú ohun táwọn èèyàn kà á sí, ohun tó dájú ni pé Pọ́ńtíù Pílátù gborúkọ nítorí ohun tó ṣe sí Jésù Kristi. Ta ni Pílátù yìí? Kí laráyé mọ̀ nípa rẹ̀? Tá a bá mọ ipò rẹ̀ dáadáa, a óò túbọ̀ lóye àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀ rí lórí ilẹ̀ ayé.

Ipò Rẹ̀, Iṣẹ́ Rẹ̀, àti Agbára Rẹ̀

Tìbéríù olú ọba Róòmù ló fi Pílátù jẹ gómìnà ẹkùn Júdíà lọ́dún 26 Sànmánì Kristẹni. Inú àwọn tí wọ́n kà sí ẹgbẹ́ àwọn bọ̀rọ̀kìnní ilẹ̀ Róòmù ni wọ́n ti sábà máa ń mú ẹni tó máa wà nírú ipò aláṣẹ tí Pílátù wà. Ipò àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí kò tó tàwọn ọ̀tọ̀kùlú tó ń di ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ipò ọ̀gá kékeré ni wọ́n fi Pílátù sí nígbà tó wọṣẹ́ ológun, tí ipò rẹ̀ wá ń ga sí i bó ṣe ń báṣẹ́ ológun lọ, tó fi wá di gómìnà kó tó pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún.

Ẹ̀wù awọ tó gùn dé orúnkún àti ìgbàyà irin ni ẹ̀wù ológun tó ṣeé ṣe kí Pílátù máa wọ̀ nígbà yẹn. Àmọ́ nígbà tí kò bá múra bí ológun, aṣọ funfun tí wọ́n fi àwọ̀ elésè àlùkò gbá létí ló ṣeé ṣe kó máa lọ́ mọ́ra bíi tàwọn ará Róòmù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irun orí rẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ kún, ó sì máa ń fá irùngbọ̀n rẹ̀. Àwọn kan gbà pé ọmọ ilẹ̀ Sípéènì ni, àmọ́ orúkọ rẹ̀ fi hàn pé ẹ̀yà Pontii, ìyẹn àwọn ọ̀tọ̀kùlú ilẹ̀ Samnium ní gúúsù orílẹ̀-èdè Ítálì ló ti wá.

Aláṣẹ tó bá wà nírú ipò Pílátù ni wọ́n sábà máa ń rán lọ bójú tó àgbègbè tí kò lajú. Irú àgbègbè bẹ́ẹ̀ làwọn ará Róòmù sì ka Jùdíà sí. Yàtọ̀ sí pé Pílátù máa ń mú kí nǹkan lọ létòlétò níbẹ̀, ó tún máa ń rí i dájú pé wọ́n gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọlọ́jà láfikún sí owó orí gbogbo gbòò. Ilé ẹjọ́ àwọn Júù ló ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ṣùgbọ́n tí ẹjọ́ kan bá máa la ikú lọ, wọ́n á fà á lé gómìnà tó jẹ́ adájọ́ àgbà lọ́wọ́.

Ìlú Kesaréà tó wà létíkun ni Pílátù àti aya rẹ̀ ń gbé, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn akọ̀wé rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àtàwọn mìíràn tí wọ́n ń bá a kẹ́gbẹ́. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] sí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ àti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta agẹṣinjagun ló wà lábẹ́ Pílátù. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sábà máa ń kan àwọn arúfin mọ́gi. Nígbà tí nǹkan bá ń lọ déédéé nílùú, wọ́n máa ń ṣe ìgbẹ́jọ́ ráńpẹ́ kí wọ́n tó pa ọ̀daràn, àmọ́ ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n ń pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ nígbà rògbòdìyàn, àpalù ni wọ́n sì ń pa wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbàáta [6,000] ẹrú làwọn ọmọ ogun Róòmù kàn mọ́gi láti lè paná ọ̀tẹ̀ kan tí Spartacus dá sílẹ̀. Bí wàhálà bá bẹ́ sílẹ̀ ní Jùdíà, gómìnà ibẹ̀ yóò wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ gómìnà àgbà ní Síríà, tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta sí mẹ́fà ọmọ ogun àti agẹṣinjagun wà lábẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àsìkò tí Pílátù fi jẹ́ gómìnà ni kò sí gómìnà àgbà ní Síríà, torí náà Pílátù ní láti fúnra rẹ̀ paná ọ̀tẹ̀ tó bá yọjú ní kíákíá.

Àwọn gómìnà máa ń fi ohun tó ń lọ lágbègbè wọn tó olú ọba létí déédéé. Wọ́n ní láti tètè jẹ́ kí olú ọba gbọ́ nípa ọ̀ràn tó bá kàn án gbọ̀ngbọ̀n tàbí èyí tó bá fẹ́ jin ìṣàkóso Róòmù lẹ́sẹ̀, olú ọba yóò wá pàṣẹ lórí ọ̀ràn náà. Àwọn gómìnà sábà máa ń fẹ́ kí ìròyìn tiwọn nípa ohun tó ń lọ tẹ olú ọba lọ́wọ́ ṣáájú káwọn ẹlòmíì tó gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ìyẹn lọkàn Pílátù kò fi balẹ̀ nígbà tó rí i pé wàhálà fẹ́ bẹ́ sílẹ̀ ní Jùdíà.

Yàtọ̀ sí ohun tí àwọn Ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Pílátù, àwọn òpìtàn bíi Flavius Josephus àti Philo tún jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa. Kódà òpìtàn ará Róòmù tó ń jẹ́ Tacitus sọ pé Pílátù pa Christus, ẹni táwọn Kristẹni ń jórúkọ mọ́.

Ó Ṣe Ohun Tó Bí Àwọn Júù Nínú

Josephus sọ pé àwọn gómìnà tó jẹ́ ará Róòmù kì í gbé ọ̀págun tí ère olú ọba wà lórí rẹ̀ wọ Jerúsálẹ́mù nítorí awuyewuye àwọn Júù lórí ọ̀ràn ó ṣère kò ṣère. Nígbà tí Pílátù gbé ọ̀págun wá síbẹ̀, àwọn Júù kan fìbínú lọ sí Kesaréà láti fẹ̀hónú hàn. Àmọ́ Pílátù ò ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ fún ọjọ́ márùn-ún. Lọ́jọ́ kẹfà, ó kó àwọn ọmọ ogun yí àwọn tó wá fẹ̀hónú hàn náà ká, ó ní tí wọn ò bá tú ká kíá, òun á pa wọ́n. Ṣùgbọ́n àwọn Júù yẹn ta kú pé ojú ẹ̀mí àwọn kọ́ lẹnì kan á máa tẹ Òfin àwọn lójú, ni Pílátù bá jáwọ́, ó sì ní kí wọ́n kó àwọn ère náà kúrò.

Pílátù máa ń lo agbára tó bá fẹ́ lò ó. Bí àpẹẹrẹ, Josephus kọ ìtàn kan pé Pílátù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀nà àtifa omi wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì lò lára owó inú ìṣúra tó wà ní tẹ́ńpìlì láti fi ṣe iṣẹ́ náà. Pílátù ò kàn dédé bẹ̀rẹ̀ sí lo owó yẹn torí ó mọ̀ pé èèwọ̀ ló jẹ́ láti já wọ tẹ́ńpìlì lọ kó nǹkan, ìyẹn sì lè mú káwọn Júù fìbínú sọ pé kí Tìbéríù gbé e kúrò. Èyí fi hàn pé àwọn aláṣẹ tẹ́ńpìlì ti ní láti fọwọ́ sí i kó tó mú owó náà. Kò sì lòdì tó bá lo owó tí wọ́n yà sí mímọ́, tí wọ́n ń pè ní “kọ́bánì” láti fi ṣe nǹkan ire fáwọn aráàlú. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Júù kóra jọ láti fẹ̀hónú hàn lórí ohun tó ṣe yìí.

Pílátù wá rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sáàárín àwọn èèyàn náà, ṣùgbọ́n ó ní kí wọ́n má fi idà bá wọn jà, pé kóńdó ni kí wọ́n fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n. Ó jọ pé ńṣe ló fẹ́ dá wọn lẹ́kun láìpa ẹnikẹ́ni. Ó dá wọn lẹ́kun lóòótọ́, àmọ́ ẹ̀mí àwọn díẹ̀ lọ sí i. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí làwọn tó wá sọ fún Jésù pé Pílátù po ẹ̀jẹ̀ àwọn ará Gálílì kan mọ́ ẹbọ wọn ń tọ́ka sí.—Lúùkù 13:1.

“Kí Ni Òtítọ́?”

Ìgbẹ́jọ́ tí Pílátù ṣe lórí ẹ̀sùn táwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà àwọn Júù fi kan Jésù pé ó pera ẹ̀ ní Ọba ló fi gborúkọ burúkú. Nígbà tí Pílátù gbọ́rọ̀ tí Jésù sọ pé òtítọ́ lòun wá jẹ́rìí sí láyé, ó rí i pé Jésù ò jin ìjọba Róòmù lẹ́sẹ̀ lọ́nàkọnà. Ó wá bi Jésù pé: “Kí ni òtítọ́?” Èrò Pílátù ni pé òtítọ́ jẹ́ àdììtú téèyàn ò lè máa fàkókò ṣòfò lé lórí pé òun fẹ́ mọ̀. Kí ló wá parí ẹjọ́ yẹn sí? Ó ní: “Èmi kò rí ìwà ọ̀daràn kankan nínú ọkùnrin yìí.”—Jòhánù 18:37, 38; Lúùkù 23:4.

Ọ̀rọ̀ yìí ni ì bá fi tú ìgbẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Jésù ká, àmọ́ àwọn Júù fàáké kọ́rí wọ́n ní Jésù fẹ́ da orílẹ̀-èdè àwọn rú sẹ́. Ẹ̀tanú lolórí ohun tó mú káwọn olórí àlùfáà fa Jésù lé àwọn aláṣẹ lọ́wọ́, Pílátù sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó sì mọ̀ pé tóun bá dá Jésù sílẹ̀ pẹ́nrẹ́n yóò di wàhálà, kò sì fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó wò ó pé wàhálà ti Bárábà àtàwọn míì tó wà lẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ sí ìjọba àti ìpànìyàn ti tó. (Máàkù 15:7, 10; Lúùkù 23:2) Yàtọ̀ síyẹn, wàhálà tó ti bá àwọn Júù fà tẹ́lẹ̀ ti sọ ọ́ lẹ́nu lọ́dọ̀ Tìbéríù, ẹni tí wọ́n sọ pé kì í gba gbẹ̀rẹ́ pẹ̀lú gómìnà tí ò bá mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Pílátù sì tún wò ó pé tóun bá ṣe ohun táwọn Júù ń fẹ́ yìí, àwọn èèyàn á sọ pé ojo lòun. Pílátù ò wá mọ èyí tí ì bá ṣe.

Bí Pílátù ṣe wá gbọ́ pé Gálílì ni Jésù ti wá, ó fẹ́ ti ẹjọ́ náà sọ́rùn Hẹ́rọ́dù Áńtípà alákòóso àgbègbè náà. Nígbà tí ìyẹn ò bọ́ sí i, ó tún fẹ́ dọ́gbọ́n lo àṣà dídá tí wọ́n máa ń dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ nígbà àjọ Ìrékọjá kí àwọn tó pé jọ síwájú ìta rẹ̀ lè sọ pé kó dá Jésù sílẹ̀. Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ta kú, wọ́n ní Bárábà làwọn ń fẹ́ kó dá sílẹ̀.—Lúùkù 23:5-19.

Pílátù lè fẹ́ ṣe ohun tó tọ́ o, àmọ́ ó ń du orí ara rẹ̀ ó sì tún fẹ́ ṣe ohun tó dùn mọ́ àwọn èèyàn náà. Níkẹyìn, torí pé kò fẹ́ kúrò nípò tó wà, ó ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ àti ìdájọ́ òdodo. Ó ní kí wọ́n bu omi wá, ó sì ṣan ọwọ́ rẹ̀, ó ní ọwọ́ òun mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ ikú Jésù, ìyẹn lẹ́yìn tó ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa á. a Pílátù mọ̀ pé Jésù ò jẹ̀bi, síbẹ̀ ó ní kí wọ́n fi bílálà oníkókó nà án, ó sì tún gbà káwọn ọmọ ogun fi í ṣẹlẹ́yà, kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì tutọ́ sí i lára.—Mátíù 27:24-31.

Pílátù tún gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan sí i láti dá Jésù sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà kígbe pé tó bá dán an wò, kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì mọ́. (Jòhánù 19:12) Bí Pílátù ṣe jáwọ́ nìyẹn o. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ńṣe ni Pílátù máa sọ pé: “Kí wọ́n pa á jàre, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣebí ẹ̀mí Júù kan lásán-làsàn ló kàn máa ṣòfò, kí lèèyàn wá fẹ́ torí ẹ̀ forí jálé agbọ́n sí.”

Kí Ló Wá Ṣẹlẹ̀ sí Pílátù?

Ohun táwọn òpìtàn kọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pílátù nígbẹ̀yìn gbẹ́yín pàápàá kò bára mu. Josephus sọ pé àwọn ará Samáríà kan tó dìhámọ́ra lọ kóra jọ sórí Òkè Gérísímù pé àwọn ń wá ìṣúra kan tí wọ́n ní Mósè rì mọ́bẹ̀. Pílátù wá dá sí ọ̀rọ̀ náà, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pa àwọn mélòó kan lára wọn. Làwọn ará Samáríà bá lọ fẹjọ́ sun ọ̀gá Pílátù, ìyẹn Lucius Vitellius tó jẹ́ gómìnà Síríà. Bóyá Vitellius gbà pé Pílátù ṣàṣejù ni o, Josephus ò sọ. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ó ní kí Pílátù lọ jẹ́jọ́ lọ́dọ̀ olú ọba. Ṣùgbọ́n kí Pílátù tó dé ọ̀hún Tìbéríù ti kú.

Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Bá ò ṣe gbúròó Pílátù mọ́ nínú ìwé ìtàn nìyẹn, tó jẹ́ pé ìtàn àtẹnudẹ́nu lèyí tó kù tá à ń gbọ́ nípa rẹ̀.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti gbìyànjú láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn ìgbà náà. Àwọn kan sọ pé Pílátù di Kristẹni. Àwọn kan tó pera wọn ní Kristẹni ní Etiópíà tiẹ̀ pè é ní “ẹni mímọ́.” Yùsíbíọ̀sì tó kọ̀wé ní ìparí ọ̀rúndún kẹta sí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrin ló kọ́kọ́ sọ pé ńṣe ni Pílátù para ẹ̀ bíi ti Júdásì Ísíkáríótù, àwọn míì náà tún sọ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Àmọ́ ṣá, kò sẹ́ni tó lè sọ ohun tó gbẹ̀yìn Pílátù ní pàtó.

Ó ṣeé ṣe kí Pílátù jẹ́ olórí kunkun, ẹni tí kì í ka nǹkan sí àti atẹnilóríba. Síbẹ̀ ọdún mẹ́wàá gbáko ló fi ṣàkóso, bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn alákòóso Jùdíà kì í pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ rárá. Ìyẹn fi hàn pé àwọn ará Róòmù gbà pé Pílátù mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́. Àwọn kan pè é ní ojo ẹ̀dá tó torí dídù tó ń du orí ara rẹ̀ sọ pé kí wọ́n fìyà jẹ Jésù láìṣẹ̀ láìrò, kí wọ́n sì pa á. Àwọn míì sì sọ pé ẹ̀bi Pílátù kọ́, wọ́n níbí ìlú á ṣe tòrò kí ohunkóhun má sì jin ìṣàkóso ilẹ̀ Róòmù lẹ́sẹ̀ ló gba iwájú nínú iṣẹ́ rẹ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo.

Lóòótọ́, ìgbà ayé Pílátù yàtọ̀ sí tiwa yìí. Síbẹ̀, kò sí adájọ́ tó lè jàre tó bá mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹni tó gbà pé kò ṣẹ̀ lẹ́bi. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé, bí kò bá jẹ́ ti ọ̀rọ̀ Jésù, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn má tiẹ̀ gbọ́ nípa Pọ́ńtíù Pílátù yìí tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Júù ló sábà máa ń ṣanwọ́ láti fi hàn pé ọwọ́ àwọn mọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ ẹni tí àwọn kan pa, kì í ṣe àṣà àwọn ará Róòmù rárá.—Diutarónómì 21:6, 7.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ìlú Kesaréà la ti rí àkọlé yìí tó fi hàn pé Pọ́ńtíù Pílátù ni alákòóso Jùdíà