Àpẹẹrẹ Àwọn Òbí Mi fún Mi Lókun
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Àpẹẹrẹ Àwọn Òbí Mi fún Mi Lókun
GẸ́GẸ́ BÍ JANEZ REKELJ ṢE SỌ Ọ́
Ọdún 1958 lohun tí mo fẹ́ sọ yìí ṣẹlẹ̀. Èmi àti Stanka ìyàwó mi ń gbìyànjú láti sá lọ sórílẹ̀-èdè Ọ́síríà, a sì ti dé ibi tó ga jù lọ lórí àwọn òkè ńláńlá tó wà lágbègbè Karawanken, níbi tí ilẹ̀ Yugoslavia àti ilẹ̀ Ọ́síríà ti pààlà. Ohun tá a fẹ́ ṣe yìí léwu, nítorí pé àwọn sójà ilẹ̀ Yugoslavia tó ń ṣọ́ ààlà ilẹ̀ náà kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá rárá sí orílẹ̀-èdè mìíràn, ńṣe ni wọ́n sì ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́. Bá a ti ń rìn lọ, a wá dé téńté orí òkè kan. Èmi àti Stanka kò tíì rí orílẹ̀-èdè Ọ́síríà rí látorí àwọn òkè yẹn. La bá kọrí sápá ìlà oòrùn, a sì ń rìn lọ títí tá a fi dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kan tó rí gbágungbàgun tó sì ní àwọn òkúta wẹ́wẹ́. Bẹ́ẹ̀ la so tapólì tá a gbé dání mọ́ ara wa, a sì yí gbirigbiri lọ sísàlẹ̀, láìmọ bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí.
JẸ́ KÍ n sọ ohun tó mú ká bára wa nírú ipò yìí fún ọ àti bí jíjẹ́ táwọn òbí mi jẹ́ olóòótọ́ ṣe ran èmi náà lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lákòókò ìṣòro.
Ilẹ̀ Slovenia tó ti di orílẹ̀-èdè kékeré kan nísinsìnyí ní Àárín Gbùngbùn Ilẹ̀ Yúróòpù ni mo dàgbà sí. Àárín àwọn orílẹ̀-èdè tó ní òkè ńláńlá nílẹ̀ Yúróòpù ló wà. Orílẹ̀-èdè Ọ́síríà wà lápá àríwá rẹ̀, ilẹ̀ Ítálì sì wà lápá ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ Croatia wà lápá gúúsù rẹ̀, ilẹ̀ Hungary sì wà lápá ìlà oòrùn. Àmọ́ apá kan Ilẹ̀ Ọba Ọ́síríà òun Hungary ni Slovenia jẹ́ lákòókò tí wọ́n bí bàbá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Franc àti màmá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rozalija. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí, Slovenia wá di ara ìjọba tuntun kan tí wọ́n ń pè ní Ìjọba ẹ̀yà Serbia, Croatia àti Slovenia. Lọ́dún 1929, wọ́n yí orúkọ orílẹ̀-èdè yìí padà sí Yugoslavia tó túmọ̀ sí “Gúúsù Slavia.” Ọjọ́ kẹsàn-án oṣù January ọdún
yẹn gan-an ni wọ́n bí mi, nítòsí abúlé Podhom, lẹ́bàá Adágún Odò Bled tó lẹ́wà gan-an.Inú ìdílé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì paraku ni ìyá mi ti dàgbà. Àlùfáà ni ọ̀kan lára àwọn àbúrò bàbá rẹ̀, ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé sì ni mẹ́ta lára àwọn ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ obìnrin. Ó wu màmá mi gan-an pé kóun náà ní Bíbélì, kóun máa kà á, kóun sì lóye ohun tó wà nínú rẹ̀. Àmọ́ bàbá mi ní tiẹ̀ kò ka ẹ̀sìn sí ohun tó ṣe pàtàkì. Ipa táwọn ìsìn kó nínú Ogun Ńlá tó jà lọ́dún 1914 sí ọdún 1918 máa ń kó o nírìíra.
Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí ogun yẹn parí ni mọ̀lẹ́bí màmá mi kan tó ń jẹ́ Janez Brajec àti ìyàwó rẹ̀ tóun ń jẹ́ Ančka di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Orílẹ̀-èdè Ọ́síríà ni wọ́n ń gbé lákòókò náà. Ančka bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ màmá mi láti ọdún 1936. Ó fún màmá mi ní Bíbélì àtàwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ pẹ̀lú àwọn ìwé mìíràn tó dá lórí Bíbélì lédè Slovenia, kíákíá ni màmá mi sì kà wọ́n. Níkẹyìn, Janez àti Ančka padà sórílẹ̀ èdè Slovenia, nígbà tí Hitler gba orílẹ̀-èdè Ọ́síríà lọ́dún 1938. Mo rántí pé tọkọtaya tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti olóye ni wọ́n, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Wọ́n sábà máa ń bá màmá mi sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, èyí sì mú kí màmá mi ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọdún 1938 ló ṣèrìbọmi.
Nígbà tí màmá mi jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, irú bí ayẹyẹ Kérésìmesì, tí kò sì jẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ ẹran sè mọ́, àgàgà nígbà tó kó gbogbo ère tá a ní nílé jọ tó sì dáná sun wọ́n, ni wàhálà bá dé. Kíákíá ló ti bẹ̀rẹ̀ sí rí àtakò. Àwọn mọ̀lẹ́bí màmá mi tí wọ́n jẹ́ obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kọ lẹ́tà sí màmá mi láti yí i lọ́kàn padà pé kó padà sọ́dọ̀ Màríà mímọ́ àti sínú ẹ̀sìn Kátólíìkì. Àmọ́ nígbà tí màmá mi kọ lẹ́tà sí wọn padà pé kí wọ́n dáhùn àwọn ìbéèrè kan fún òun látinú Bíbélì, kò rí èsì gbà. Bàbá màmá mi pàápàá ṣàtakò sí i gan-an. Bàbá náà kì í ṣe èèyànkéèyàn, àmọ́ àwọn ẹbí wa àtàwọn èèyàn àdúgbò wa ló fúngun mọ́ ọn tó fi ń hùwà bẹ́ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fa àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì tí màmá mi máa ń kà ya nígbà bíi mélòó kan, àmọ́ kò fọwọ́ kan Bíbélì rẹ̀ rárá. Kódà ó kúnlẹ̀ bẹ màmá mi pé kó jọ̀ọ́ kó padà sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ó tiẹ̀ ṣeé débi pé ó fọ̀bẹ halẹ̀ mọ́ ọn. Àmọ́ bàbá mi jẹ́ kó yé e pé òun ò ní gba irú ìwà bẹ́ẹ̀ láyè.
Bàbá mi kò fì màmá mi sílẹ̀, ó ní ó lẹ́tọ̀ọ́ láti ka Bíbélì ó sì lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn èyíkéyìí tó bá wù ú. Ọdún 1946 lòun náà ṣèrìbọmi. Bí mo ṣe ń rí i tí Jèhófà ń fún màmá mi lókun láti ṣe ìsìn tòótọ́ láìbẹ̀rù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣàtakò sí i àti bí Jèhófà ṣe bù kún un nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ló jẹ́ kó wu èmi náà láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí
màmá mi sì ṣe máa ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì sí mi létí nígbà gbogbo tún ràn mí lọ́wọ́ gan-an.Màmá mi tún máa ń bá àbúrò rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Marija Repe sọ̀rọ̀ gan-an, ọjọ́ kan náà lèmi àti àǹtí Marija sì ṣèrìbọmi nínú oṣù July ọdún 1942. Arákùnrin kan ló wá sọ̀ àsọyé ṣókí lórí ìrìbọmi náà, inú ọpọ́n onígi ńlá kan nílé wa ni wọ́n sì ti ṣèrìbọmi fún wa.
Iṣẹ́ Bóofẹ́bóokọ̀ Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì
Lọ́dún 1942, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́, ilẹ̀ Jámánì àti ilẹ̀ Ítálì gbógun wá bá Slovenia, àwọn orílẹ̀-èdè méjì yìí àti ilẹ̀ Hungary sì jọ pín ilẹ̀ Slovenia láàárín ara wọn. Àwọn òbí mi kọ̀ láti dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tó ń jẹ́ Volksbund, ìyẹn ẹgbẹ́ táwọn tó jẹ́ alátìlẹyìn ìjọba Násì dá sílẹ̀. Nílé ìwé, èmi náà kọ̀ láti bá wọn sọ gbólóhùn náà: “Ẹ Kókìkí Hitler.” Kò sì sí àní-àní pé olùkọ́ mi ló lọ sọ ọ̀rọ̀ yìí fáwọn aláṣẹ.
Ni wọ́n bá kó wa sínú ọkọ̀ ojú ìrin kan wọ́n sì kó wa lọ sáwọn ilé kan tí wọ́n fi odi yí ká, tí wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí àgọ́ tí wọ́n ti ń kó àwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ bóofẹ́bóokọ̀ nítòsí abúlé kan tó ń jẹ́ Hüttenbach lórílẹ̀-èdè Bavaria. Bàbá mi fi mí sọ́dọ̀ ọkùnrin kan tó ń ṣe búrẹ́dì lábúlé náà pé kí n máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ kí n sì máa gbé pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Láàárín àkókò yẹn, mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe búrẹ́dì, èyí sì wá wúlò fún mi gan-an nígbà tó yá. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n kó gbogbo àwọn tó kù nínú ìdílé mi lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n ìlú Gunzenhausen, (títí kan àǹtí Marija àti ìdílé tirẹ̀ náà).
Nígbà tí ogun yẹn parí, mo fẹ́ bá àwọn kan rìn kí n lè máa lọ síbi táwọn òbí mi wà. Àmọ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí n gbéra, bàbá mi kàn ṣàdédé yọ ni. Ká ní mo ti lọ bá àwọn èèyàn náà lọ ni, mi ò mọ ohun tí ì bá ṣẹlẹ̀ sì mi, nítorí pé ọwọ́ wọn kò mọ́. Mo tún rí i pé Jèhófà fìfẹ́ hàn sí mi lákòókò yìí nítorí pé ó lo àwọn òbí mi láti dáàbò bò mí àti láti darí mi. Odindi ọjọ́ mẹ́ta lèmi àti bàbá mi fi fẹsẹ̀ rìn ká tó dé ibi tí ìdílé wa wà. Nígbà tó fi máa di oṣù June ọdún 1945, gbogbo wa ti padà délé.
Lẹ́yìn tógun yẹn parí, àwọn Kọ́múníìsì gbàjọba lórílẹ̀-èdè Yugoslavia lábẹ́ Ààrẹ Josip Broz Tito. Fún ìdí yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò bọ́ nínú wàhálà rárá.
Lọ́dún 1948, arákùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Ọ́síríà wá sílé wa ó sì jẹun lọ́dọ̀ wa. Gbogbo ibi tí arákùnrin náà ń lọ làwọn ọlọ́pàá ń tẹ̀ lé e, wọ́n sì kó àwọn arákùnrin tó lọ sọ́dọ̀ wọn. Wọ́n mú bàbá mi náà nítorí pé ó ṣe é lálejò àti pé kò fẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn aláṣẹ. Ẹ̀wọ̀n ọdún méjì ni Bàbá mi fi gbára nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Àkókò yẹn nira fún màmá mi gan-an. Kì í ṣe nítorí pé bàbá mi ò sí nílé nìkan ni, àmọ́ nítorí ó mọ̀ pé èmi àti àbúrò mi ọkùnrin náà máa tó rí àdánwò nítorí pé a ò ní lọ́wọ́ sógun.
Wọ́n Sọ Mí Sẹ́wọ̀n Nílùú Makedóníà
Lóṣù November ọdún 1949, wọ́n pè mí fún iṣẹ́ ológun. Mo lọ láti ṣàlàyé ìdí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò fi lè jẹ́ kí n ṣe é. Àwọn aláṣẹ náà kò tiẹ̀ tẹ́tí sí àlàyé mi rárá, ńṣe ni wọ́n sọ mí sínú ọkọ̀ ojú irin tó ń kó àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà síṣẹ́ ológun lọ sílùú Makedóníà, lópin ilẹ̀ Yugoslavia.
Odindi ọdún mẹ́ta ni mi ò fi gbúròó ìdílé mi àtàwọn arákùnrin mi nípa tẹ̀mí, kò sí ìwé kankan tí mo lè kà, kódà kò sí Bíbélì. Kò rọrùn fún mi rárá. Ṣíṣàṣàrò nípa Jèhófà àti àpẹẹrẹ tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ fi lélẹ̀ ló gbé mí ró. Àpẹẹrẹ àwọn òbí mi náà tún fún mi lókun. Ohun mìíràn tí kò tún jẹ́ kí n bọ́hùn ni gbígbàdúrà sí Jèhófà déédéé pé kó fún mi lókun.
Nígbà tó yá, wọ́n gbé mi lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan
tó wà ní ìgbèríko kan tó ń jẹ́ Idrizovo, ní tòsí ìlú Skopje. Lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yìí, onírúurú iṣẹ́ ọwọ́ làwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ń ṣe. Nígbà tí mo kọ́kọ́ débẹ̀, mò ń ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó mo sì tún máa ń kó lẹ́tà láti ọ́fíìsì dé ọ́fíìsì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́wọ̀n kan níbẹ̀ tó ti jẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ rí fẹ́rẹ̀ẹ́ fayé sú mi, mi ò níṣòro rárá pẹ̀lú gbogbo àwọn tó kù níbẹ̀, ìyẹn àwọn ẹ̀ṣọ́, àwọn ẹlẹ́wọ̀n, títí kan ẹni tó jẹ́ alábòójútó iléeṣẹ́ tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.Nígbà tó yá, mo gbọ́ pé wọ́n nílò ẹnì kan tó lè máa bá wọn ṣe búrẹ́dì níléeṣẹ́ búrẹ́dì tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà ni alábòójútó náà wá síbi tí wọ́n ti máa ń pe orúkọ wa. Ó rìn wá síbi tá a tò sí, ó sì dúró níwájú mi, ló bá béèrè pé, “Ṣé o mọ búrẹ́dì ṣe?” Mo dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni sà.” Ló bá sọ pé: “Tó bá di àárọ̀ ọ̀la, kó o lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níléeṣẹ́ búrẹ́dì.” Ẹlẹ́wọ̀n tó kórìíra mi yẹn máa ń gba ibi iléeṣẹ́ búrẹ́dì yẹn kọjá lọ́pọ̀ ìgbà àmọ́ kò sóhun tó lè ṣe sí i. Mo ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lóṣù February sí oṣù July ọdún 1950.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé mi lọ sí bárékè àwọn ọlọ́pàá nílùú Volkoderi, lápá gúúsù ìlú Makedóníà, nítòsí Adágún Odò Prespa. Mo láǹfààní àtikọ lẹ́tà sílé láti ìlú Otešovo tí kò jìnnà síbi tá a wà. Mo máa ń bá àwùjọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń ṣe títì, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, iléeṣẹ́ búrẹ́dì ni mo ti máa ń ṣiṣẹ́, èyí sì mú kí nǹkan rọrùn fún mi díẹ̀. Nígbà tó di oṣù November ọdún 1952, wọ́n dá mi sílẹ̀.
Láàárín àkókò tí mi ò fi sí ní ìlú wa, ìyẹn Podhom, wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ lágbègbè náà. Inú òtẹ́ẹ̀lì kékeré kan nílùú Spodnje Gorje ni ìjọ náà ti kọ́kọ́ ń ṣèpàdé. Nígbà tó yá, bàbá mi fún ìjọ náà ní yàrá kan nílé wa kí wọ́n lè máa pàdé níbẹ̀. Inú mi dùn gan-an láti dara pọ̀ mọ́ wọn nígbà tí mo padà dé láti ìlú Makedóníà. Bákan náà, mo tún padà lọ bá Stanka. Kí n tó lọ sẹ́wọ̀n ni mo bá a pàdé. A sì ṣègbéyàwó lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù April ọdún 1954. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí ìtura ráńpẹ́ tí mo ni fi wá sópin.
Mo Ṣẹ̀wọ̀n Nílùú Maribor
Lóṣù September ọdún 1954, wọ́n tún pè mí pé kí n wá ṣiṣẹ́ ológun. Lọ́tẹ̀ yìí, ó lé ní ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tí wọ́n dá fún mi, èyí tí wọ́n ní kí n lọ ṣe lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan nílùú Maribor, tó wà nípẹ̀kun orílẹ̀-èdè Slovenia lápá ìlà oòrùn. Mo yáa tètè ra bébà díẹ̀ àti pẹ́ńsùlù bíi mélòó kan. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ gbogbo ohun tí mo bá ti rántí sílẹ̀, irú bí àwọn ẹsẹ Bíbélì, gbólóhùn látinú Ilé Ìṣọ́, àtàwọn àyọkà látinú àwọn ìwé mìíràn tó jẹ́ ti Kristẹni. Mo máa ń ka àwọn ohun tí mo kọ sílẹ̀ yìí, tí n bá sì tún ti rántí nǹkan kan, màá tún kọ ọ́ sínú ìwé mi yìí. Níkẹyìn, ìwé náà kún, èyí sì jẹ́ kí n lè pọkàn pọ̀ sórí òtítọ́, ó tún jẹ́ kí n máa lókun nìṣó nípa tẹ̀mí. Àwọn nǹkan mìíràn tí kò ṣeé díye lé tó tún fún mi lókun nípa tẹ̀mí ni àdúrà àti ṣíṣe àṣàrò. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló jẹ́ kí n lè túbọ̀ nígboyà láti máa wàásù òtítọ́ fáwọn èèyàn.
Láàárín àkókò yẹn, wọ́n fún mi láyè láti máa gba lẹ́tà kan ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù kí n sì máa gba àlejò kan fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́ẹ̀kan lóṣù. Stanka máa ń wọkọ̀ ojú irin tó máa ń rìn lóru tí yóò sì gúnlẹ̀ lówùúrọ̀ kó bàa lè tètè dé sọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà láti rí mi kó sì tún padà lọ́jọ́ náà. Àwọn ìbẹ̀wò yẹn fún mi níṣìírí gan-an. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí wá ọgbọ́n tí màá fi rí Bíbélì kan nìyẹn. Ńṣe lèmi àti Stanka máa ń jókòó dojú kọra wa nídìí tábìlì kan, tí ẹ̀ṣọ́ kan yóò sì máa ṣọ́ wa. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ náà gbójú síbòmíràn, mo yára fi lẹ́tà kan sínú báàgì Stanka, ohun tí mo sì kọ sínú lẹ́tà náà ni pé kó fi Bíbélì kan sínú báàgì rẹ̀ tó bá ń bọ̀ wá wò mí nígbà míì.
Àwọn òbí mi àti Stanka ronú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti léwu jù láti ṣe, ni wọ́n bá mú odindi Ìwé Mímọ́
Kristẹni Lédè Gíríìkì, wọ́n sì yọ ọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n wá fi àwọn ojú ìwé tí wọ́n yọ náà sínú àwọn búrẹ́dì roboto. Lọ́nà yìí, mo rí Bíbélì tí mo nílò. Mo tún máa ń rí àwọn ẹ̀dá Ilé Ìṣọ́ gbà lọ́nà kan náà, èyí tí Stanka máa ń fọwọ́ dà kọ. Kíákíá, màá yáa ṣàtúnkọ wọn lọ́nà ìkọ̀wé tèmi màá sì fa èyí tí Stanka mú wá ya sí wẹ́wẹ́ kí ẹnikẹ́ni má bàa lọ rí àwọn àpilẹ̀kọ náà kó sì mọ ibi tí mo ti rí wọn.Nítorí pé mi ò yéé wàásù, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ mi máa ń sọ fún mi pé kò sọ́gbọ́n tí mi ò fi ní kó sí wàhálà. Nígbà kan, mò ń bá ẹlẹ́wọ̀n kan sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì, a sì ń gbádùn ìjíròrò náà gan-an. Bá a ṣe gbọ́ tẹ́nì kan ń fi kọ́kọ́rọ́ ṣílẹ̀kùn nìyẹn, lẹ̀ṣọ́ kan bá wọlé. Ohun tó yára wá sí mi lọ́kàn ni pé ńṣe ni wọ́n máa lọ jù mí sí yàrá ẹ̀wọ̀n àdáwà. Àmọ́ kì í ṣe ìdí tí ẹ̀ṣọ́ yẹn fi wọlé nìyẹn. Ó ti ń tẹ́tí sí ìjíròrò náà ó sì fẹ́ mọ̀ sí i. Inú rẹ̀ dùn bí mo ṣe bá a dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀, ó jáde, ó sì fi kọ́kọ́rọ́ ti ilẹ̀kùn yàrá ẹ̀wọ̀n náà padà.
Lóṣù tí mo lò kẹ́yìn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, kọmíṣọ́nnà tó ń rí sí títún ayé àwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣe yìn mí fún bí mo ṣe dúró lórí ìpinnu mi, tí mi ò sì yẹsẹ̀ nínú òtítọ́. Mo ronú pé èrè ìsapá mi láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀ lèyí jẹ́. Lóṣù May ọdún 1958, wọ́n tún dá mi sílẹ̀.
A Sá Lọ Sílẹ̀ Ọ́síríà, A Tún Kọrí Sílẹ̀ Ọsirélíà
Lóṣù August ọdún 1958, màmá mi ṣaláìsí. Ó ti ń ṣàárẹ̀ fúngbà díẹ̀. Nígbà tó di oṣù September ọdún 1958 ni wọ́n bá tún pè mí fún iṣẹ́ ológun nígbà kẹta. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, èmi àti Stanka ṣe ìpinnu kan tó lágbára, èyí tó mú ká sọdá ààlà orílẹ̀-èdè wa lọ́nà tó yani lẹ́nu bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀. Láìsọ fún ẹnikẹ́ni, a di nǹkan díẹ̀ tá a nílò sínú àpò tí wọ́n ń gbé sẹ́yìn a sì tún gbé tapólì kan, la bá gbojú wíńdò fò bọ́ síta a sì kọrí sí ààlà orílẹ̀-èdè Ọ́síríà, èyí tí kò jìnnà síbi tí Òkè Stol wà. Ó jọ pé ńṣe ni Jèhófà ṣọ̀nà àbáyọ fún wa nígbà tó rí i pé a nílò ìtura díẹ̀.
Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Ọ́síríà ní ká lọ máa gbé ní àgọ́ tó wà fáwọn tó sá kúrò nílùú, nítòsí ìlú Salzburg. Láàárín oṣù mẹ́fà tá a lò níbẹ̀, ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè náà la máa ń wà nígbà gbogbo, nípa bẹ́ẹ̀, a kì í fi bẹ́ẹ̀ sí nínú àgọ́ náà. Bá a ṣe tètè lọ́rẹ̀ẹ́ níbẹ̀ máa ń ya àwọn tá a jọ wà nínú àgọ́ náà lẹ́nu. Àárín àkókò yẹn nìgbà tá a kọ́kọ́ lọ sí àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyé wa. Ìgbà yẹn náà la kọ́kọ́ wàásù láti ilé dé ilé láìsí ìbẹ̀rù pé wọ́n á mú wa. Nígbà tí àkókò tó láti fi àwọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n yìí sílẹ̀, kò rọrùn fún wa rárá.
Ìjọba ilẹ̀ Ọ́síríà fún wa láǹfààní láti ṣí lọ sílẹ̀ Ọsirélíà. A ò tiẹ̀ ronú pé a lè lọ gbé níbi tó jìnnà tó bẹ́ẹ̀. A wọkọ̀ ojú irin, ó di ìlú Genoa lórílẹ̀-èdè Ítálì, látibẹ̀ la sì ti wọ ọkọ̀ okun tó ń lọ sílẹ̀ Ọsirélíà. Ìlú Wollongong ní ìpínlẹ̀ New South Wales la wá fìdí kalẹ̀ sí níkẹyìn. Ibí yìí la ti bí ọmọkùnrin wa tá a sọ ní Philip, ní March 30, ọdún 1965.
Bá a ṣe ń gbé nílẹ̀ Ọsirélíà ti jẹ́ ká láǹfààní láti kópa nínú onírúurú iṣẹ́ ìsìn. Lára rẹ̀ ni wíwàásù fáwọn mìíràn táwọn náà ṣí wá láti àwọn àgbègbè tó ti jẹ́ ara Yugoslavia nígbà kan rí. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìbùkún rẹ̀, títí kan bó ṣe jẹ́ kí ìdílé wa lè máa jọ́sìn rẹ̀ níṣọ̀kan. Philip àti Susie ìyàwó rẹ̀ láǹfààní láti máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọsirélíà, kódà wọ́n tiẹ̀ láǹfààní láti lọ lo ọdún méjì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ti orílẹ̀-èdè Slovenia.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara tó ń dára àgbà àti àìsàn ń fa ìṣòro fún wa, síbẹ̀ èmi àti ìyàwó mi ṣì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. Mo mọrírì àpẹẹrẹ rere àwọn òbí mi gan-an! Títí dòní ló ṣì ń fún mi lókun, bẹ́ẹ̀ ló sì ń ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí. Ẹ máa ní ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú. Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.”—Róòmù 12:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn òbí mi rèé níparí àwọn ọdún 1920
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Màmá mi ló wà lápá ọ̀tún, òun àti Ančka tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Èmi àti Stanka aya mi kété lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ìjọ tó ń pàdé nílé wa lọ́dún 1955 rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Èmi àti aya mi, Philip ọmọ wa, àti Susie, ìyàwó rẹ̀