Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kíróníkà Kìíní

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kíróníkà Kìíní

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kíróníkà Kìíní

NǸKAN bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77] ti kọjá lẹ́yìn táwọn Júù padà dé sílùú wọn láti ìgbèkùn ní Bábílónì. Ó sì ti pé ọdún márùndínlọ́gọ́ta tí tẹ́ńpìlì tí Serubábélì tó jẹ́ gómìnà kọ́ ti wà níbẹ̀. Ìdí pàtàkì táwọn Júù fi padà wálé ni láti mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ àwọn èèyàn náà ò nítara fún ìjọsìn Jèhófà. Wọ́n nílò ìṣírí lójú méjèèjì, èyí sì lohun tí ìwé Kíróníkà Kìíní fún wọn.

Yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ ìrandíran wọn tó wà nínú Kíróníkà Kìíní, ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún nǹkan bí ogójì ọdún tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ìyẹn láti àkókò tí Sọ́ọ̀lù Ọba kú títí dìgbà tí Dáfídì Ọba kú. Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà làwọn èèyàn gbà pé ó kọ ìwé yìí lọ́dún 460 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Kíróníkà Kìíní ṣe pàtàkì fún wa gan-an nítorí pé ó jẹ́ ká mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì, ó sì tún jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìlà ìran Mèsáyà. Nítorí pé ó wà lára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí, àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, ó sì túbọ̀ jẹ́ ká lóye Bíbélì sí i.—Hébérù 4:12.

ÀWỌN ORÚKỌ TÍ WỌ́N KỌ SÍLẸ̀ WÚLÒ GAN-AN

(1 Kíróníkà 1:1–9:44)

Àkọsílẹ̀ àwọn orúkọ ìdílé tí Ẹ́sírà tó lẹ́sẹẹsẹ ṣe pàtàkì gan-an nítorí ìdí mẹ́ta. Èkíní, láti mọ̀ dájú pé kìkì àwọn ọkùnrin tí ipò àlùfáà tọ́ sí ló ń ṣiṣẹ́ àlùfáà. Èkejì, ó ṣèrànwọ́ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ogún tó jẹ́ ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀kẹta, láti tọ́jú àkọsílẹ̀ nípa ìran tó nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ Mèsáyà. Àkọsílẹ̀ náà sọ ìtàn àwọn Júù padà sẹ́yìn títí dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá. Ìran mẹ́wàá ló wà látọ̀dọ̀ Ádámù títí dé ọ̀dọ̀ Nóà, ìran mẹ́wàá mìíràn sì nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ Ábúráhámù. Lẹ́yìn tí àkọsílẹ̀ náà dárúkọ gbogbo àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, ó wá dárúkọ àwọn ọmọ Kétúrà tó jẹ́ wáhàrì Ábúráhámù, ó tún dárúkọ àwọn ọmọ Ísọ̀, kó tó wá dẹ́nu lé ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjèèjìlá.—1 Kíróníkà 2:1.

Àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ni àkọsílẹ̀ náà mẹ́nu kàn ní kínníkínní jù lọ nítorí pé ìdílé ọlọ́ba ni, ibẹ̀ sì ni Dáfídì Ọba ti wá. Ìran mẹ́rìnlá ló wà látọ̀dọ̀ Ábúráhámù títí dé ọ̀dọ̀ Dáfídì, mẹ́rìnlá mìíràn sì wà látìgbà yẹn títí dìgbà tí wọ́n fi lọ sígbèkùn ní Bábílónì. (1 Kíróníkà 1:27, 34; 2:1-15; 3:1-17; Mátíù 1:17) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Ẹ́sírà wá to orúkọ àwọn àtọmọdọ́mọ àwọn ẹ̀yà tó wà ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì lẹ́sẹẹsẹ, tí ìtàn ìdílé àwọn ọmọ Léfì sì tẹ̀ lé e. (1 Kíróníkà 5:1-24; 6:1) Ẹ́sírà tún wá ṣe àkópọ̀ orúkọ díẹ̀ lára àwọn ẹ̀yà mìíràn tó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Odò Jọ́dánì, ó sì tún to orúkọ ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (1 Kíróníkà 8:1) Orúkọ àwọn tó dé sí Jerúsálẹ́mù láti ìgbèkùn ní Bábílónì tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú.—1 Kíróníkà 9:1-16.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ

1:18Ta ni bàbá Ṣélà, ṣé Káínánì ni àbí Ápákíṣádì? (Lúùkù 3:35, 36) Ápákíṣádì ni bàbá Ṣélà. (Jẹ́nẹ́sísì 10:24; 11:12) Ọ̀rọ̀ náà “Káínánì” tó wà nínú Lúùkù 3:36 lè jẹ́ àṣìpè ọ̀rọ̀ náà “àwọn Kalidíà.” Tí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, ẹsẹ yẹn ì bá ti kà pé, “ọmọkùnrin Ápákíṣádì tó jẹ́ Kalidíà.” Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹni tó ń jẹ́ Káínánì ló tún ń jẹ́ Ápákíṣádì. Ohun pàtàkì kan tá ò tún ní gbojú fò dá ni pé gbólóhùn náà “ọmọkùnrin Káínánì” kò sí nínú àwọn Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n fọwọ́ dà kọ.—Lúùkù 3:36, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

2:15Ṣé Dáfídì ni ọmọkùnrin keje tí Jésè bí? Rárá o. Ọmọkùnrin mẹ́jọ ni Jésè bí, Dáfídì ló sì kéré jù nínú gbogbo wọn. (1 Sámúẹ́lì 16:10, 11; 17:12) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọkàn lára àwọn ọmọkùnrin Jésè ti kú láìní ọmọ kankan. Ẹ́sírà ò dárúkọ rẹ̀ rárá, nítorí pé kò sí ipa kankan tí ọmọ náà kó nínú ìtàn ìran náà.

3:17Kí nìdí tí ìwé Lúùkù 3:27 fi pe Ṣéálítíẹ́lì, ọmọkùnrin Jekonáyà ní ọmọkùnrin Nẹ́rì? Jekonáyà ni bàbá Ṣéálítíẹ́lì. Àmọ́, ó dájú pé Nẹ́rì ló bí ọmọbìnrin tí Ṣéálítíẹ́lì fi ṣaya. Lúùkù wá pe ọkọ ọmọ Nẹ́rì ní ọmọkùnrin Nẹ́rì bó ṣe pe Jósẹ́fù ní ọmọkùnrin Hélì tó jẹ́ bàbá Màríà.—Lúùkù 3:23.

3:17-19Ọ̀nà wo ni Serubábélì, Pedáyà, àti Ṣéálítíẹ́lì gbà bára wọn tan? Serubábélì jẹ́ ọmọ Pedáyà tí í ṣe arákùnrin Ṣéálítíẹ́lì. Àmọ́ nígbà míì, Bíbélì máa ń pe Serubábélì ní ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì. (Mátíù 1:12; Lúùkù 3:27) Ó lè jẹ́ pé Ṣéálítíẹ́lì ló tọ́ Serubábélì dàgbà nígbà tí Pedáyà kú. Tàbí kẹ̀, bóyá ńṣe ni Ṣéálítíẹ́lì kú láìní ọmọ kankan, tí Pedáyà wá ṣú ìyàwó rẹ̀ lópó tí Serubábélì sì jẹ́ àkọ́bí wọn.—Diutarónómì 25:5-10.

5:1, 2Kí ni gbígba ẹ̀tọ́ àkọ́bí túmọ̀ sí fún Jósẹ́fù? Ó túmọ̀ sí pé Jósẹ́fù gba ìlọ́po méjì lára ogún náà. (Diutarónómì 21:17) Ó tipa bẹ́ẹ̀ di bàbá ẹ̀yà méjì, ìyẹn ẹ̀yà Éfúráímù àti ẹ̀yà Mánásè. Nígbà tí àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù yòókù sì jẹ́ bàbá ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

Ẹ̀kọ́ tó kọ́ wa:

1:1-9:44. Ìtàn ìran àwọn èèyàn tá a dárúkọ yìí fi hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ni gbogbo ètò tó wà fún ìjọsìn tòótọ́, kì í ṣe ìtàn àròsọ.

4:9, 10. Jèhófà dáhùn àdúrà àtọkànwá tí Jábésì gbà pé kí Jèhófà jẹ́ kí ìpínlẹ̀ òun túbọ̀ gbòòrò sí i láìsí pé òun jagun káwọn èèyàn tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè pọ̀ sí i níbẹ̀. Àwa náà ní láti máa gba àdúrà àtọkànwá pé káwọn olùjọsìn Ọlọ́run túbọ̀ pọ̀ sí i bá a ṣe ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.

5:10, 18-22. Nígbà ayé Sọ́ọ̀lù Ọba, àwọn ẹ̀yà tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì ṣẹ́gun àwọn Hágíríìtì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Hágíríìtì pọ̀ ju àwọn ẹ̀yà náà lọ ní ìlọ́po méjì. Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé àwọn akíkanjú ọkùnrin tó wà nínú àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá bá a ṣe ń bá àwọn ọ̀tá tó pọ̀ jù wa lọ fíìfíì jagun tẹ̀mí.—Éfésù 6:10-17.

9:26, 27. Ipò pàtàkì làwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ aṣọ́bodè wà. Ọwọ́ wọn ni kọ́kọ́rọ́ ilẹ̀kùn àbáwọlé sínú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì náà wà. Bí wọ́n ṣe ń ṣí àwọn géètì náà lójoojúmọ́ fi hàn pé wọ́n ṣeé gbára lé. Àwa náà ní iṣẹ́ kan tá a gbé lé wa lọ́wọ́, iṣẹ́ náà ni pé ká lọ wàásù fáwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá jọ́sìn Jèhófà. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé àti ẹni tó ṣeé fọkàn tán bíi táwọn ọmọ Léfì wọ̀nyẹn tí wọ́n jẹ́ aṣọ́bodè?

DÁFÍDÌ JỌBA

(1 Kíróníkà 10:1–29:30)

Ìtàn Sọ́ọ̀lù Ọba àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó kú sógun tí wọ́n bá àwọn Filísínì jà ní Òkè Ńlá Gíbóà ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ náà. Wọ́n fi Dáfídì, ọmọkùnrin Jésè jọba lórí ẹ̀yà Júdà. Àwọn ọkùnrin látinú gbogbo ẹ̀yà wá sí Hébúrónì, wọ́n sì fi Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. (1 Kíróníkà 11:1-3) Kété lẹ́yìn náà ló ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Jerúsálẹ́mù “pẹ̀lú igbe ìdùnnú àti pẹ̀lú ìró ìwo . . . tí wọ́n ń fi àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù kọrin sókè.”—1 Kíróníkà 15:28.

Dáfídì sọ pé ó wu òun láti kọ́ ilé kan fún Ọlọ́run tòótọ́. Jèhófà sọ pé Sólómọ́nì lóun máa fún láǹfààní yẹn, àmọ́ ó bá Dáfídì dá májẹ̀mú Ìjọba kan. Bí Dáfídì ṣe ń bá àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì jagun ni Jèhófà ń fún un ní ọ̀pọ̀ ìṣẹ́gun. Ìkànìyàn kan tó lòdì sófin Ọlọ́run yọrí sí ikú ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin [70,000] èèyàn. Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì kan sọ fún Dáfídì pé kó kọ́ pẹpẹ kan fún Jèhófà, Dáfídì lọ ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ Ónánì ará Jébúsì. Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí “ṣe ìpèsèsílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ” láti kọ́ ilé kan tó jẹ́ “ọlọ́lá ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá” fún Jèhófà lórí ilẹ̀ náà. (1 Kíróníkà 22:5) Dáfídì ṣètò iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì, inú ìwé Kíróníkà Kìíní ni wọ́n sì ti ṣàlàyé iṣẹ́ náà lẹ́kún-ún rẹ́rẹ́ ju ibikíbi mìíràn nínú Ìwé Mímọ́. Ọba àtàwọn èèyàn náà fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ mú ọrẹ púpọ̀ wá fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. Lẹ́yìn ogójì ọdún tí Dáfídì fi jọba, ó kú “ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an, ó kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́, ọrọ̀ àti ògo; Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.”—1 Kíróníkà 29:28.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ

11:11Kí nìdí tí iye àwọn tó pa fi jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún [300] tí kì í ṣe ẹgbẹ̀rin [800] gẹ́gẹ́ bí ìtàn yẹn kan náà ṣe sọ nínú 2 Sámúẹ́lì 23:8? Jáṣóbéámù tàbí Joṣebi-báṣébétì ni olórí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó jẹ́ akíkanjú jù lọ fún Dáfídì. Àwọn méjì yòókù ni Élíásárì àti Ṣámáhì. (2 Sámúẹ́lì 23:8-11) Ìdí tí ìyàtọ̀ fi wà nínú ìtàn méjèèjì náà lè jẹ́ nítorí pé àwọn tó ń sọ ìtàn náà sọ nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì tí ẹnì kan náà ṣe.

11:20, 21—Ipò wo ni Ábíṣáì wà sí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó jẹ́ akíkanjú jù lọ lára àwọn ọkùnrin Dáfídì? Ábíṣáì kò sí lára àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó jẹ́ akíkanjú jù lọ lára àwọn ọkùnrin tó ń jagun fún Dáfídì. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé 2 Sámúẹ́lì 23:18, 19 sọ, ó jẹ́ olórí àwọn ọgbọ̀n jagunjagun, ó sì ta gbogbo wọn yọ. Ipò iyì tí Ábíṣáì wà yìí bá ti àwọn mẹ́ta tó jẹ́ akíkanjú náà dọ́gba nítorí pé ó ṣe ohun ńlá kan tó jọ ohun tí Jáṣóbéámù ṣe.

12:8Ọ̀nà wo ni ojú àwọn jagunjagun ọmọ Gáàdì fi dà bí “ojú kìnnìún”? Àwọn akíkanjú wọ̀nyí wà lọ́dọ̀ Dáfídì nínú aginjù. Irun wọn ti gùn gan-an. Irun tó gùn tó sì rí yàùyau yìí ló mú kí ìrísí wọn dà bíi ti kìnnìún.

13:5Kí ni “odò Íjíbítì”? Apá kan lára Odò Náílì làwọn kan rò pé gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé “àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì” ni gbólóhùn náà ń tọ́ka sí, ìyẹn àfonífojì gígùn tó jẹ́ ààlà Ilẹ̀ Ìlérí ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn.—Númérì 34:2, 5; Jẹ́nẹ́sísì 15:18.

16:30Kí ni gbólóhùn náà “ìrora mímúná” nítorí Jèhófà túmọ̀ sí? Ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ ni wọ́n gbà lo gbólóhùn náà “ìrora” níhìn-ín, ó sì túmọ̀ sí ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà.

16:1, 37-40; 21:29, 30; 22:19—Irú ètò ìjọsìn wo ni wọ́n ń tẹ̀ lé ní Ísírẹ́lì látìgbà tí wọ́n ti gbé Àpótí ẹ̀rí wá sí Jerúsálẹ́mù títí dìgbà tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì? Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni Àpótí ẹ̀rí náà kò fi sí nínú àgọ́ ìjọsìn kó tó di pé Dáfídì gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù tó sì gbé e sínú àgọ́ tó ṣe sílẹ̀ dè é. Lẹ́yìn tó gbé Àpótí ẹ̀rí náà dé, inú àgọ́ yẹn ló fi sílẹ̀ sí ní Jerúsálẹ́mù. Àgọ́ ìjọsìn náà sì wà ní Gíbéónì, níbi tí Sádókù, Àlùfáà Àgbà àtàwọn arákùnrin rẹ̀ ti máa ń rú ẹbọ tí Òfin là sílẹ̀. Ètò yìí ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí tí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù tán. Nígbà tí wọ́n sì kọ́ tẹ́ńpìlì náà tán, wọ́n gbé àgọ́ ìjọsìn láti Gíbéónì wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì gbé Àpótí ẹ̀rí náà sínú ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì náà.—1 Àwọn Ọba 8:4, 6.

Ẹ̀kọ́ tó kọ́ wa:

13:11. Dípò ká máa bínú ká sì máa dá Jèhófà lẹ́bi nígbà tí ohun kan tá a dáwọ́ lé bá kùnà, a gbọ́dọ̀ gbé nǹkan náà yẹ̀ wò dáadáa ká sì gbìyànjú láti mọ ohun tó fa ìkùnà náà. Ó dájú pé ohun tí Dáfídì ṣe nìyẹn. Ó kọ́gbọ́n látinú àṣìṣe rẹ̀, ó sì gbé Àpótí ẹ̀rí náà wá sí Jerúsálẹ́mù bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ níkẹyìn. a

14:10, 13-16; 22:17-19. A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì máa béèrè ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ká tó dáwọ́ lé ohunkóhun tó máa nípa lórí ipò tẹ̀mí wa.

16:23-29. Ìjọsìn Jèhófà ló gbọ́dọ̀ ká wa lára jù lọ nígbèésí ayé wa.

18:3. Jèhófà jẹ́ Olùmú àwọn ìlérí ṣẹ. Nípasẹ̀ Dáfídì, ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á fún irú ọmọ Ábúráhámù ní gbogbo ilẹ̀ Kénáánì “láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, odò Yúfírétì.”—Jẹ́nẹ́sísì 15:18; 1 Kíróníkà 13:5.

21:13-15. Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì náà láti dáwọ́ ìyọnu náà dúró nítorí pé ara rẹ̀ kì í gbà á nígbà táwọn èèyàn Rẹ̀ bá ń jìyà. Dájúdájú, “àánú rẹ̀ pọ̀ púpọ̀.” b

22:5, 9; 29:3-5, 14-16. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Dáfídì la sọ pe kó kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, síbẹ̀ ó fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí ó gbà pé inú rere Jèhófà ló jẹ́ kóun ní gbogbo nǹkan tóun ní. Ó yẹ kí irú ẹ̀mí ìmoore bẹ́ẹ̀ máa mú káwa náà lawọ́.

24:7-18. Ètò pípín àwọn àlùfáà sí ọ̀nà mẹ́rìnlélógún, èyí tí Dáfídì fi lọ́lẹ̀ ṣì ń bá a lọ nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà fara han Sekaráyà, bàbá Jòhánù Olùbatisí, tó sì sọ fún un nípa bí wọn yóò ṣe bí Jòhánù. Nítorí pé Sekaráyà jẹ́ ara “ìpín Ábíjà,” inú tẹ́ńpìlì ló wà lákòókò náà níbi tó ti ń ṣe iṣẹ́ tó yí kàn án. (Lúùkù 1:5, 8, 9) Àwọn èèyàn tó gbé ayé rí la mẹ́nu kàn nínú ìjọsìn tòótọ́, kì í ṣe àwọn èèyàn tó jẹ́ àròsọ. Ìbùkún rẹpẹtẹ la máa rí tá a bá fi gbogbo ọkàn wa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” nínú ìjọsìn Jèhófà tá a ṣètò rẹ̀ dáradára lóde òní.—Mátíù 24:45.

Fi “Ọkàn-Àyà Tí Ó Kún fún Inú Dídùn” Sin Jèhófà

Kì í ṣe ìtàn ìran nìkan ni ìwé Kíróníkà Kìíní sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó tún sọ ìtàn gbígbé tí Dáfídì gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Jerúsálẹ́mù, ó mẹ́nu kan àwọn ogun tó jà tó sì ṣẹ́gun lọ́nà tó bùáyà, ìmúrasílẹ̀ tó ṣe de kíkọ́ tẹ́ńpìlì, àti bó ṣe pín àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ àlùfáà sí ibi iṣẹ́ ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń ṣe. Ó dájú pé gbogbo ohun tí Ẹ́sírà sọ nínú ìwé Kíróníkà Kìíní ti ní láti ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní tó pọ̀, ó ti ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ onítara fún ìjọsìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì.

Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dára ni Dáfídì fi lélẹ̀ bó ṣe fi ìjọsìn tòótọ́ sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀! Bí Dáfídì ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló gbájú mọ́ dípò tí ì bá fi máa wá ipò ọlá fún ara rẹ̀. A gbà wá níyànjú láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ pé ká “fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn” sin Jèhófà.—1 Kíróníkà 28:9.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti túbọ̀ rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú bí Dáfídì ṣe gbìyànjú láti gbé Àpótí ẹ̀rí náà wá sí Jerúsálẹ́mù, wo Ilé Ìṣọ́, May 15, 2005, ojú ìwé 16-19.

b Láti rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìkànìyàn tí kò bófin mu tí Dáfídì ṣe, wo Ilé Ìṣọ́, May 15, 2005, ojú ìwé 16-19.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8-11]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

4026 Ṣ.S.K. Ádámù Àwọn ìran tó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù títí

dé ọ̀dọ̀ Nóà (1,056 ọdún)

130 ọdún ⇩

 

Sẹ́ẹ̀tì

 

105 ⇩

 

Énọ́ṣì

 

90 ⇩

 

Kénánù

 

70 ⇩

 

Máhálálélì

 

65 ⇩

 

Járédì

 

162 ⇩

 

Énọ́kù

 

65 ⇩

 

Mètúsélà

 

187 ⇩

 

Lámékì

182 ⇩

 

2970 Ṣ.S.K. Nóà 2970 ṣááju Sànmánì Kristẹni

(Ṣ.S.K.), wọ́n bí NÓÀ

Àwọn ìran tó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Nóà títí

502 ọdún ⇩ dé ọ̀dọ̀ Ábúráhámù (952 ọdún)

 

Ṣémù

ÌKÚN OMI 2370 Ṣ.S.K.

100 ⇩

 

Ápákíṣádì

 

35 ⇩

 

Ṣélà

 

30 ⇩

 

Ébérì

 

34 ⇩

 

Pélégì

 

30 ⇩

 

Réù

 

32 ⇩

 

Sérúgì

 

30 ⇩

 

Náhórì

 

29 ⇩

 

Térà

 

130 ⇩

 

2018 Ṣ.S.K. Ábúráhámù 2018 Ṣ.S.K., wọ́n bí ÁBÚRÁHÁMÙ

Láti ọ̀dọ̀ Ábúráhámù dé ọ̀dọ̀ Dáfídì:

100 ọdún. ìran mẹ́rìnlá (911 ọdún)

 

Ísákì

 

60 ⇩

Jékọ́bù

nǹkan bí 88 ⇩

Júdà

 

 

Pérésì

 

 

Hésírónì

 

 

Rámù

 

 

Ámínádábù

 

 

Náṣónì

 

 

Sálímọ́nì

 

 

Bóásì

 

 

Óbédì

 

 

Jésè

 

 

1107 Ṣ.S.K., wọ́n bí DÁFÍDÌ