Mímọ Ìtumọ̀ Àmì Kì Í Ṣohun Téèyàn Ń Fọwọ́ Yẹpẹrẹ Mú!
Mímọ Ìtumọ̀ Àmì Kì Í Ṣohun Téèyàn Ń Fọwọ́ Yẹpẹrẹ Mú!
“Mo kọ́kọ́ rò pé orí lásán ló ń fọ́ Andreas ọmọ wa. Àmọ́ kò lè jẹun, ara rẹ̀ sì ń gbóná gan-an. Ẹ̀fọ́rí náà túbọ̀ ń le sí i, ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí bà mí. Nígbà tí ọkọ mi dé, a gbé Andreas lọ sọ́dọ̀ dókítà kan. Bí dókítà náà ṣe yẹ ara rẹ̀ wò báyìí, tó rí àmì ohun tó ń ṣe é, kíá ló sọ pé ká máa gbé e lọ sílé ìwòsàn. Ohun tó ń ṣe é lágbára gan-an ju orí fífọ́ lọ. Àìsàn lọ́rùnlọ́rùn ló ń ṣe Andreas. Wọ́n tọ́jú rẹ̀, kò sì pẹ́ tí ara rẹ̀ fi yá.”—Gertrud, ìyá kan láti ilẹ̀ Jámánì.
Ó ṢEÉ ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Gertrud yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ òbí. Àwọn òbí máa ń kíyè sáwọn àmì tó ń fi hàn pé àìsàn fẹ́ ṣe ọmọ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àìsàn ló máa ń lágbára, síbẹ̀ àwọn òbí ò jẹ́ fojú di àmì tó bá fi hàn pé ara ọmọ wọn ò fẹ́ yá. Tí wọ́n bá kíyè sí àmì náà, tí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ nípa rẹ̀, ó lè dènà àìsàn ọ̀hún. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ nípa àmì kì í ṣohun téèyàn ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú.
Kíkíyèsí àmì tún ṣe pàtàkì nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn yàtọ̀ sí ọ̀ràn ìlera. Àpẹẹrẹ kan ni ti jàǹbá òkun tí wọ́n pè ní sùnámì, èyí tó ṣẹlẹ̀ láwọn àgbègbè tó yí Òkun Íńdíà ká nínú oṣù December ọdún 2004. Àwọn àjọ kan tí ìjọba dá sílẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè bí Ọsirélíà àti Hawaii ti rí àmì pé ilẹ̀ fẹ́ ri ní àríwá Sumatra, wọ́n sì ti mọ jàǹbá tó ṣeé ṣe kó tẹ̀yìn rẹ̀ jáde. Síbẹ̀, kò sí bí àwọn tó wà lágbègbè eléwu náà ṣe máa gbọ́ nípa ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ yìí kí wọ́n lè sá kúrò níbẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn tó kú sí jàǹbá òkun ríru náà lé ní ọ̀kẹ́ mọ́kànlá [220,000].
Àwọn Àmì Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an Jùyẹn Lọ
Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ àwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kan nípa kíkíyèsí àmì àtohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ó sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an. Bíbélì sọ pé: “Àwọn Farisí àti àwọn Sadusí tọ̀ ọ́ wá, láti dẹ ẹ́ wò, wọ́n sì ní kí ó fi àmì kan hàn wọ́n láti ọ̀run. Ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, ó ti di àṣà yín láti máa sọ pé, “Ojú ọjọ́ yóò dára, nítorí sánmà pupa bí iná”; àti ní òwúrọ̀, “Ojú ọjọ́ olótùútù, tí ó kún fún òjò yóò wà lónìí, nítorí sánmà pupa bí iná, ṣùgbọ́n ó ṣú dùdù.” Ẹ Mátíù 16:1-3.
mọ̀ bí a ṣe ń túmọ̀ ìrísí sánmà, ṣùgbọ́n àwọn àmì àkókò ni ẹ kò lè túmọ̀.’”—Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “àwọn àmì àkókò” ni pé, ó yẹ káwọn Júù ọ̀rúndún kìíní tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹn mọ̀ pé àkókò táwọn wà yẹn kì í ṣe àkókò téèyàn gbọdọ̀ dẹra nù. Àjálù ńlá kan ò ní pẹ́ dé bá ètò àwọn Júù, ó sì máa nípa lórí gbogbo wọn. Jésù tún sọ nípa àmì mìíràn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́jọ́ bíi mélòó kan ṣáájú ọjọ́ tó kú, ìyẹn ni àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀. Ohun tó sọ níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ṣe pàtàkì gan-an fún gbogbo èèyàn lónìí.