Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Dá Àmì Tó Fi Hàn Pé Jésù Ti Wà Níhìn-ín Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Dá Àmì Tó Fi Hàn Pé Jésù Ti Wà Níhìn-ín Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Dá Àmì Tó Fi Hàn Pé Jésù Ti Wà Níhìn-ín Mọ̀?

KÒ SẸ́NI tó fẹ́ kóun ṣàìsàn tàbí kóun kàgbákò. Láti yẹra fún irú àjálù bẹ́ẹ̀, ọlọ́gbọ́n èèyàn á kíyè sí àmì tó fi hàn pé irú ewu bẹ́ẹ̀ ń bọ̀ á sì sá fún un. Jésù Kristi sọ nípa àmì pàtàkì kan tó yẹ ká kíyè sí. Àmì tó ń tọ́ka sí náà yóò nípa lórí gbogbo ayé, gbogbo èèyàn ló sì máa kàn. Yóò kan ìwọ àti ìdílé rẹ pẹ̀lú.

Jésù sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí yóò mú ìwà ibi kúrò tí yóò sì sọ ayé di Párádísè. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fẹ́ mọ ìgbà tí Ìjọba náà máa dé. Wọ́n béèrè pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3.

Jésù mọ̀ pé lẹ́yìn ikú àti àjíǹde òun, ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún yóò kọjá kí Jèhófà tó gbé òun gorí ìtẹ́ lókè ọ̀run gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo aráyé. Níwọ̀n bí kò ti sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó rí Jésù nígbà tó gorí ìtẹ́, ó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àmì kan tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ ìgbà “wíwàníhìn-ín” òun àti ti “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Àmì yìí ní onírúurú ẹ̀ka, tí gbogbo wọn lápapọ̀ fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín.

Ńṣe ni Mátíù, Máàkù, àti Lúùkù tí wọ́n kọ ìwé Ìhìn Rere kọ ìdáhùn Jésù sílẹ̀ ní kínníkínní. (Mátíù, orí 24 àti 25; Máàkù, orí 13; Lúùkù, orí 21) Àwọn mìíràn lára àwọn tó kọ Bíbélì tún sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àmì náà. (2 Tímótì 3:1-5; 2 Pétérù 3:3, 4; Ìṣípayá 6:1-8; 11:18) Àyè kò lè tó fún wa nínú àpilẹ̀kọ yìí láti ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ àmì náà, àmọ́ a ó gbé apá pàtàkì márùn-ún yẹ̀ wò, èyí tó para pọ̀ jẹ́ àmì tí Jésù mẹ́nu kàn. Wàá rí i pé èyí ṣe kókó, ó sì ṣe pàtàkì fún ìwọ alára.—Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 6.

“Ìyípadà Ńláǹlà Dé Bá Ayé”

“Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ń pè ní Der Spiegel nílẹ̀ Jámánì ròyìn pé, ṣáájú ọdún 1914, àwọn èèyàn “gbà pé ọjọ́ iwájú máa lárinrin, pé òmìnira á túbọ̀ wà, pé ìlọsíwájú àti aásìkí á sì wà pẹ̀lú.” Ṣùgbọ́n lójijì ni gbogbo nǹkan yí padà. Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ GEO sọ pé: “Ogun tó bẹ̀rẹ̀ lóṣù August 1914 tó sì parí lóṣù November 1918 jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì kan. Ó yí ìtàn ìran ènìyàn padà pátápátá, bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀ wá yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí nísinsìnyí.” Àwọn sójà tó kópa nínú ìjà tó gadabú náà lé ní ọgọ́ta mílíọ̀nù láti apá ibi márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sójà ló ń kú lójúmọ́. Àtìgbà yẹn làwọn òpìtàn látinú ìran kọ̀ọ̀kan àti gbogbo àwọn òpìtàn ọ̀ràn ìṣèlú ti gbà pé “ọdún 1914 sí ọdún 1918 ni ìyípadà ńláǹlà dé bá ayé.”

Ogun Àgbáyé Kìíní fa àwọn ìyípadà kan bá aráyé, kò sì sí àtúnṣe sáwọn ìyípadà ọ̀hún, àtìgbà yẹn laráyé sí ti wọ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan ìsinsìnyí. Ọ̀pọ̀ ogun, ìjà lóríṣiríṣi, àti ìpániláyà ló tún ń wáyé ní àwọn ọdún yòókù nínú ọ̀rúndún ogún. Nǹkan ò sì tíì dára sí i láti ọdún 2000 títi di ìsinsìnyí. Yàtọ̀ sí ogun, a tún ń rí àwọn apá mìíràn tí àmì náà ní.

Ìyàn, Àjàkálẹ̀ Àrùn, Àtàwọn Ìsẹ̀lẹ̀

‘Àìtó oúnjẹ yóò wà.’ (Mátíù 24:7) Ebi han ilẹ̀ Yúróòpù léèmọ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àtìgbà yẹn sì ni ìyàn tí ń ṣe ìràn èèyàn bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alan Bullock kọ̀wé pé nílẹ̀ Rọ́ṣíà àti Ukraine lọ́dún 1933, “ńṣe logunlọ́gọ̀ èèyàn tí ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lù pa ń rìn gbéregbère kiri àgbègbè àrọko . . . Àwọn èèyàn sì kó òkú jọ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ojú pópó.” Lọ́dún 1943, Ọ̀gbẹ́ni T. H. White tó máa ń kọ nǹkan sínú ìwé ìròyìn fojú ara rẹ̀ rí bí ìyàn ṣe mú nígbà tó wà nílùú Henan tó jẹ́ ìpínlẹ̀ àwọn ará Ṣáínà. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí ìyàn bá mú, ńṣe ló máa ń dà bíi pé gbogbo nǹkan ni oúnjẹ, téèyàn lè lọ̀, kó jẹ, kó sì fún ara lókun. Àmọ́ ṣá o, ìgbà tí ebi bá fẹ́ pa èèyàn kú lèèyàn máa ń ronú débi àtijẹ ohun téèyàn mọ̀ pé kì í ṣe oúnjẹ.” Ó ṣeni láàánú pé, ìyàn ti fẹ́ di ohun tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà láwọn ọ̀rúndún àìpẹ́ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ń mú oúnjẹ jáde fún gbogbo èèyàn, síbẹ̀ Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fojú díwọ̀n rẹ̀ pé mílíọ̀nù lọ́nà ẹgbẹ̀rin ó lé ogójì [840,000,000] èèyàn jákèjádò ayé ni oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ kó tó nǹkan rárá.

“Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn . . . láti ibì kan dé ibòmíràn.” (Lúùkù 21:11) Ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung sọ pé: “Ogún [20] mílíọ̀nù sí àádọ́ta mílíọ̀nù ènìyàn ni wọ́n fojú bù pé àrùn gágá pa lọ́dún 1918, iye yẹn sì pọ̀ ju àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn kan tí wọ́n ń pè ní black death tàbí Ogun Àgbáyé Kìíní pa.” Àìmọye èèyàn sì làwọn àrùn bí ibà, ìgbóná, ikọ́ ẹ̀gbẹ, àrùn rọmọlápá-rọmọlẹ́sẹ̀, àti kọ́lẹ́rà ti pa látìgbà yẹn. Ẹ̀rù tún ń bá gbogbo ayé gan-an nítorí àrùn éèdì tó ń tàn kálẹ̀ láìdáwọ́dúró. Ohun tó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu jù lọ báyìí ni pé pẹ̀lú bí ìmọ̀ ìṣègùn ṣe ń tẹ̀ síwájú tó, àrùn ò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Ńṣe ni ohun tó ń ṣeni ní kàyéfì yìí, téèyàn ò mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ títí di àkókò tá a wà yìí, fi hàn pé àkókò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an là ń gbé.

“Ìsẹ̀lẹ̀.” (Mátíù 24:7) Àwọn ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ilẹ̀ ríri ti gbẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. Ìwé kan sọ pé ilẹ̀ ríri tó lágbára láti wó ilé tó sì tún máa ń jẹ́ kí ilẹ̀ lanu ń wáyé nígbà méjìdínlógún lọ́dọọdún láti ọdún 1914. Àwọn ilẹ̀ ríri bíburú jáì, tó lágbára gan-an débi pé ó máa ń pa àwọn ilé rẹ́ ráúráú tún ń wáyé lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Bí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣe tẹ̀ síwájú tó, síbẹ̀ ńṣe ni iye àwọn tó ń kú túbọ̀ ń pọ̀ sí i nítorí pé ọ̀pọ̀ ìlú ńlá tó lérò púpọ̀ ló wà lórí ibí tí ilẹ̀ ti lè ri.

Ìròyìn Amọ́kànyọ̀!

Ọ̀pọ̀ jù lọ àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ló jẹ́ èyí tó ń bani lọ́kàn jẹ́. Àmọ́ Jésù tún sọ nípa ìròyìn tó ń fúnni láyọ̀.

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Iṣẹ́ tí Jésù fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà yóò débi gbogbo láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Èyí sì ti ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìhìn rere inú Bíbélì, wọ́n sì ń sọ fáwọn tó fọkàn rere gba ọ̀rọ̀ náà pé kí wọ́n fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò nínú ìgbésí ayé wọn. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà Ẹlẹ́rìí tó ń wàásù ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀, tí wọ́n sì ń fi èdè tó lé ní irínwó bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.

Kíyè sí i pé Jésù kò sọ pé àwọn èèyàn máa ṣíwọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe nítorí ipò tó ń bani lọ́kàn jẹ́ tí ayé wà. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sọ pé apá kan ṣoṣo lára àmì náà yóò kárí gbogbo ayé. Àmọ́, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò para pọ̀ jẹ́ àmì kan táwọn èèyàn á lè dà mọ́ níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé.

Dípò tí wàá fi máa wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan tàbí kó o máa wo ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtó, ǹjẹ́ ò ń fojú inú wò ó pé àmì kan ni wọ́n para pọ̀ jẹ́, tó sì kan gbogbo ayé? Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé kan ìwọ àti ìdílé rẹ. A lè béèrè pé, Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn èèyàn díẹ̀ ló ǹ fiyè sí àmì náà?

Ohun Tó Wù Wọ́n Ló Ká Wọn Lára Jù

“Má wẹ̀ níbì yìí,” “Wáyà iná tó lè pani wà níbẹ̀ yẹn,” “Onímọ́tò rọra sáré.” Díẹ̀ lára àwọn àmì àti ìkìlọ̀ tá a máa ń rí nìwọ̀nyí, àmọ́ ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fojú di wọ́n. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tá a bá fẹ́ràn láti máa ṣe ló máa ń gbà wá lọ́kàn jù. Bí àpẹẹrẹ, a lè fẹ́ wakọ̀ sáré ju ohun tí òfin fàyè gbà lọ, tàbí kó máa wù wá gan-an láti lúwẹ̀ẹ́ níbi tí wọ́n sọ pé kéèyàn má lúwẹ̀ẹ́. Àmọ́ kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa fojú di àwọn àmì tó jẹ́ ìkìlọ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni jàǹbá mọ́tò ń pa nílẹ̀ Nàìjíríà lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti sọ di aláàbọ̀ ara. Ìwé Òfin Ìrìnnà ilẹ̀ Nàìjíríà sọ pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn jàǹbá yẹn ló ń wáyé nítorí pé àwọn awakọ̀ fojú di àwọn àmì ìrìnnà tàbí kí wọ́n rú àwọn òfin ìrìnnà. Ó ṣeni láàánú pé ṣíṣàì kọbi ara sí ìkìlọ̀ lè fa jàǹbá ńlá.

Kí nìdí táwọn èèyàn ò fi kọbi ara sí àmì tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Ó lè jẹ́ pé ìfẹ́ ọ̀rọ̀ àlùmọ́ọ́nì ló fọ́ wọn lójú, ẹ̀mí ìdágunlá lè sọ wọ́n di ọlọ́kàn líle, àìlèṣèpinnu sì lè máà jẹ́ kí wọ́n ṣe ohunkóhun. Ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ lè gba gbogbo àkókò wọn, tàbí kó jẹ́ pé ìbẹ̀rù káwọn má dẹni tí kò níyì mọ́ ló fà á. Ǹjẹ́ èyíkéyìí lára nǹkan wọ̀nyí lè sọ ẹ́ dẹni tó ń fojú di àmì wíwàníhìn-ín Jésù? Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu fún wa láti kíyè sí ìkìlọ̀ náà ká sì ṣe ohun tó yẹ?

Ìgbésí Ayé Nínú Párádísè Orí Ilẹ̀ Ayé

Iye àwọn èèyàn tó ń kọbi ara sí àmì wíwàníhìn-ín Jésù túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ọmọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kristian, tó ti gbéyàwó tó sì ń gbé nílẹ̀ Jámánì kọ̀wé pé: “Àkókò tí kò fara rọ la wà yìí. Ó dájú pé ‘ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé.’” Òun àti ìyàwó rẹ̀ máa ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Mèsáyà. Orílẹ̀-èdè yẹn náà ni Frank ń gbé. Òun àti ìyàwó rẹ̀ náà máa ń fi ìhìn rere inú Bíbélì gba àwọn èèyàn níyànjú. Ó sọ pé: “Nítorí bí ipò nǹkan ṣe rí nínú ayé, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la. À ń sa gbogbo ipá wa láti fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé gbà wọ́n níyànjú.” Kristian àti Frank ń tipa bẹ́ẹ̀ mú apá kan lára àmì tí Jésù mẹ́nu kàn ṣẹ, ìyẹn wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà.—Mátíù 24:14.

Gbàrà tí ọjọ́ ìkẹyìn náà bá parí, Jésù yóò pa gbogbo ètò ògbólógbòó yìí àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn run yán-ányán-án. Ìjọba Mèsáyà yìí yóò wá máa darí gbogbo ohun tó ń lọ láyé, yóò sì mú ayé dé ipò Párádísè tá a ti sọ tẹ́lẹ̀. Ìran ènìyàn yóò bọ́ lọ́wọ́ àìsàn àti ikú, àwọn tó ti kú yóò sì jíǹde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ohun amọ́kànyọ̀ tó ń dúró de àwọn tó fiyè sí àmì àkókò tá a wà nìwọ̀nyí. Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mú láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àmì náà àti ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe láti la òpin ètò ìsinsìnyí já? Láìsí àní-àní, ó yẹ kí èyí jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú fún gbogbo wa.—Jòhánù 17:3.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò para pọ̀ jẹ́ àmì kan táwọn èèyàn á lè dà mọ́ níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Ǹjẹ́ ò ń rí àmì kan tó ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ nínú, tó sì ṣe pàtàkì gan-an kárí ayé?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

ÀWỌN OHUN TÁ A FI Ń DÁ ỌJỌ́ ÌKẸYÌN MỌ̀

Ogun tá ò rí irú rẹ̀ rí.—Mátíù 24:7; Ìṣípayá 6:4

Ìyàn.—Mátíù 24:7; Ìṣípayá 6:5, 6, 8

Àjàkálẹ̀ àrùn.—Lúùkù 21:11; Ìṣípayá 6:8

Ìwà ta-ni-yóò-mú-mi túbọ̀ ń pọ̀ sí i.—Mátíù 24:12

Àwọn ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ilẹ̀ ríri.—Mátíù 24:7

Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.— 2 Tímótì 3:1

Ìfẹ́ owó tó burú jáì.—2 Tímótì 3:2

Ṣíṣàìgbọràn sí òbí.—2 Tímótì 3:2

Àìsí ìfẹ́ àdámọ́ni.—2 Tímótì 3:3

Níní ìfẹ́ adùn dípò ìfẹ́ Ọlọ́run.—2 Tímótì 3:4

Àìní ìkóra-ẹni-níjàánu.—2 Tímótì 3:3

Àìní ìfẹ́ ohun rere.—2 Tímótì 3:3

Àwọn èèyàn kò fiyè sí ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀.—Mátíù 24:39

Àwọn olùyọṣùtì kò gbà pé àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn làwọn ohun tí à ń rí.—2 Pétérù 3:3, 4

Ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé.—Mátíù 24:14

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn sójà WWI: Látinú ìwé The World War—A Pictorial History, 1919; ìdílé tó tálákà: Fọ́tò AP/Aijaz Rahi; Ọmọ tó ní àrùn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀: © àjọ WHO/P. Virot