Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O ‘Ní Ọrọ̀ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run’?

Ǹjẹ́ O ‘Ní Ọrọ̀ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run’?

Ǹjẹ́ O ‘Ní Ọrọ̀ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run’?

LÁRA ọ̀pọ̀ àkàwé tó gbàrònú gan-an tí Jésù Kristi sọ ni ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ní ilẹ̀ ńlá. Ọkùnrin náà ń wá bóun yóò ṣe ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lọ́jọ́ alẹ́ òun, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò láti kọ́ àwọn ilé ìkó-nǹkan-pa-mọ́-sí tó tóbi ju àwọn tó ní tẹ́lẹ̀ lọ. Àmọ́, nínú àpèjúwe Jésù yìí, “aláìlọ́gbọ́n-nínú” ni Ọlọ́run pe ọkùnrin náà. (Lúùkù 12:16-21) Kódà, “òmùgọ̀” ni ọ̀rọ̀ táwọn Bíbélì kan lò. Kí nìdí tí wọ́n fi pè é nírú èèyàn bẹ́ẹ̀?

Ó hàn gbangba pé ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yìí kò rántí Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tó ń gbèrò àtiṣe, bẹ́ẹ̀ ni kò fún Ọlọ́run ní ìyìn kankan pé òun ló jẹ́ kí ilẹ̀ mú àwọn irè oko rẹpẹtẹ náà jáde. (Mátíù 5:45) Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń fọ́nnu pé: “Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.” Dájúdájú, ohun tó ń rò nínú ọkàn rẹ̀ ni pé èrè gbogbo akitiyan òun yóò jẹ́ “ògiri adáàbòboni” fún òun.—Òwe 18:11.

Nígbà tí ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù, ń kìlọ̀ pé irú ẹ̀mí ìgbéraga bẹ́ẹ̀ kò dára, ó kọ̀wé pé: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé: ‘Lónìí tàbí lọ́la a ó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú ńlá yìí, a ó sì lo ọdún kan níbẹ̀, a ó sì kó wọnú iṣẹ́ òwò, a ó sì jèrè,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì.”—Jákọ́bù 4:13, 14.

Ohun tí Jákọ́bù sọ gẹ́lẹ́ ló ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àkàwé Jésù yẹn, wọ́n sọ fún un pé: “Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?” Bí ìkùukùu tí ń pòórá ni ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà yóò ṣe kọjá lọ kí gbogbo ohun tó ní lọ́kàn tó ṣẹ. Ǹjẹ́ a rí ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ ká kọ́ nínú àkàwé yìí? Jésù sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Ǹjẹ́ o ‘ní ọrọ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run’?