Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ o Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Dáadáa?

Ǹjẹ́ o Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Dáadáa?

Ǹjẹ́ o Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Dáadáa?

ǸJẸ́ o ti sọ gbólóhùn yìí rí pé, “Mo mọ̀ lọ́kàn mi pé kò tọ̀nà,” tàbí “Mi ò lè ṣe ohun tó o ní kí n ṣe yẹn, ọkàn mi ń sọ fún mi pé kò tọ̀nà”? Ẹ̀rí ọkàn rẹ ló ń bá ọ sọ̀rọ̀ yẹn, ìyẹn ni ohun kan nínú wa tó ń jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, tó sì máa ń dáni láre tàbí dáni lẹ́bi. Dájúdájú, wọ́n bí ẹ̀rí ọkàn mọ́ wa ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá èèyàn ti bára wọn nípò tó sọ wọn dàjèjì sí Ọlọ́run, ó ṣì ṣeé ṣe fún wọn láti mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ìdí ni pé àwòrán Ọlọ́run la dá ènìyàn, ó sì ṣeé ṣe fún wọn láti fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bí ọgbọ́n àti òdodo hàn dé àyè kan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí, Ọlọ́run mí sí i láti kọ̀wé pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.” aRóòmù 2:14, 15.

Àtọ̀dọ̀ Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ la ti jogún ànímọ́ tó ń jẹ́ ká mọ ìwà tó dára àtèyí tí kò dára yìí. Ànímọ́ yìí máa ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “òfin” tàbí ìlànà tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ìwà tó yẹ kí wọ́n hù láìka ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. Òun ló ń jẹ́ ká lè yẹ ara wa wò ká sì fúnra wa sọ pé irú ẹni báyìí la jẹ́. (Róòmù 9:1) Ádámù àti Éfà fi ànímọ́ yìí hàn gbàrà tí wọ́n rú òfin Ọlọ́run, nítorí pé ńṣe ni wọ́n lọ fara pa mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:7, 8) Àpẹẹrẹ mìíràn nípa bí ẹ̀rí ọkàn ṣe ń ṣiṣẹ́ lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba nígbà tó rí i pé kíkà tóun ka àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti mú òun dẹ́ṣẹ̀. Bíbélì sọ pé ‘Ọkàn-àyà Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí nà án.’—2 Sámúẹ́lì 24:1-10.

Àwa èèyàn lè ronú padà sẹ́yìn ká sì fúnra wa mọ̀ pé ìwà kan tá a hù kò dára. Èyí sì lè sún wa ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn ni pé ká ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Dáfídì kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀. Mo wí pé: ‘Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.’ Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” (Sáàmù 32:3, 5) Èyí fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa lè dá ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, èyí yóò sì jẹ́ kó rí i pé rírí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti títẹ̀lé àwọn ọ̀nà Rẹ̀ ṣe pàtàkì.—Sáàmù 51:1-4, 9, 13-15.

Ẹ̀rí ọkàn tún máa ń fúnni ní ìkìlọ̀ tàbí ìtọ́sọ́nà nígbà tá a bá fẹ́ hu ìwà kan tàbí tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà tí ẹ̀rí ọkàn tún máa ń gbà ṣiṣẹ́ yìí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti tètè mọ̀ pé panṣágà kò dára, ó burú jáì, pé ẹ̀ṣẹ̀ ló jẹ́ sí Ọlọ́run. Nígbà tó yá, Ọlọ́run wá fi òfin tó ka panṣágà léèwọ̀ sára Òfin mẹ́wàá tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Jẹ́nẹ́sísì 39:1-9; Ẹ́kísódù 20:14) Kò sí àní-àní pé àǹfààní tá a máa rí á túbọ̀ pọ̀ sí i tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa láti máa tọ́ wa sọ́nà dípò kó kàn máa dá wa lẹ́bi. Ǹjẹ́ ẹ̀rí ọ̀kan tìrẹ máa ń tọ́ ẹ sọ́nà?

Bá A Ṣe Lè kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Wa Ká Lè Máa Ṣe Ìpinnu Tó Dára

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n bí ẹ̀rí ọkàn mọ́ wa, ó dunni pé ẹ̀bùn yìí ti lábùkù. Lóòótọ́, pípé ni Ọlọ́run dá èèyàn níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti ṣàkóbá fún wa, ẹ̀rí ọkàn wa lè dìdàkudà kó má sì ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ lọ́nà tí Jèhófà ṣètò pé kó máa gbà ṣiṣẹ́ níbẹ̀rẹ̀. (Róòmù 7:18-23) Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lè nípa lórí ẹ̀rí ọkàn wa. Bákan náà, bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà, àwọn àṣà agbègbè wa, àwọn ohun tá a gbà gbọ́, àtohun táwọn èèyàn tó yí wa ká ń ṣe tún lè nípa lórí ẹ̀rí ọkàn wa. Èyí jẹ́ ká rí i dájú pé, ìwàkiwà táráyé ń hù àtàwọn ìlànà yẹpẹrẹ tí wọ́n ń tẹ̀ lé kọ́ la máa fi mọ̀ bóyá ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan dára tàbí kò dára.

Nítorí ìdí yìí, àwọn Kristẹni nílò àfikún ìrànwọ́, ìyẹn àwọn ìlànà tó jẹ́ òdodo tí kì í sì í yí padà tó wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ lè tọ́ ẹ̀rí ọkàn wa sọ́nà láti lè gbé ohun tá a fẹ́ ṣe yẹ̀ wò dáadáa ká sì wá ṣe ohun tó tọ́. (2 Tímótì 3:16) Bá a bá ń fi àwọn ìlànà Ọlọ́run tọ́ ẹ̀rí ọkàn wa sọ́nà, yóò lè túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fáwọn ìwà tó lè ṣàkóbá fún wa, a óò sì lè máa “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Tí a kò bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rí ọkàn wa má kìlọ̀ fún wa nígbà tá a bá ń dáwọ́ lé ohun kan tó lè ṣàkóbá fún wa. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”—Òwe 16:25; 17:20.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dìídì pèsè ìlànà àti ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere nípa àwọn ohun kan, tá a bá sì tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà náà, yóò ṣe wá láǹfààní. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan ló jẹ́ pé kò sí ìtọ́ni kan pàtó nípa wọn nínú Bíbélì. Àwọn nǹkan wọ̀nyí lè dá lórí ṣíṣe ìpinnu nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ọ̀rọ̀ ìlera, ohun ìnàjú, aṣọ wíwọ̀ àti ìmúra, àtàwọn nǹkan mìíràn. Kì í rọrùn láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe nínú àwọn ipò wọ̀nyí ká sì wá ṣe ìpinnu tó tọ́. Fún ìdí yìí, irú èrò tí Dáfídì ní lọ́kàn ló yẹ ká máa ní. Ó gbàdúrà pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; Kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Sáàmù 25:4, 5) Bá a bá ṣe túbọ̀ ń lóye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan àtàwọn ọ̀nà rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ la ṣe máa lè gbé àwọn ipò wa yẹ̀ wò dáadáa tó, tí a óò sì máa ṣe àwọn ìpinnu tí kò ní da ẹ̀rí ọkàn wa láàmú.

Nítorí náà, bí ọ̀rọ̀ kan bá rú wa lójú tàbí tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan, ó yẹ ká kọ́kọ́ ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ọ̀ràn náà mu. Díẹ̀ lára àwọn ìlànà náà lè jẹ́: bíbọ̀wọ̀ fún ipò orí (Kólósè 3:18, 20); jíjẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo (Hébérù 13:18); kíkórìíra ohun tó burú (Sáàmù 97:10); wíwá àlàáfíà (Róòmù 14:19) ṣíṣègbọràn sáwọn aláṣẹ (Mátíù 22:21; Róòmù 13:1-7); ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run nìkan (Mátíù 4:10); ṣíṣàì jẹ́ apá kan ayé (Jòhánù 17:14); yíyẹra fún ẹgbẹ́ búburú (1 Kọ́ríńtì 15:33); ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú aṣọ wíwọ̀ àti ìmúra (1 Tímótì 2:9, 10); àti ṣíṣàì mú àwọn mìíràn kọsẹ̀ (Fílípì 1:10). Mímọ ìlànà Bíbélì tó bá ipò kọ̀ọ̀kan mu lè fún ẹ̀rí ọkàn wa lókun èyí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe ìpinnu tó dára.

Máa Tẹ́tí sí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

Kí ẹ̀rí ọkàn wa tó lè máa ràn wá lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa tẹ́tí sí i. Àyàfi tá a bá ń yára ṣègbọràn nígbà tí ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ bá ń bá wa sọ̀rọ̀ ló tó lè ṣe wá láǹfààní. A lè fi ẹ̀rí ọkàn tá a ti kọ́ wé oríṣiríṣi iná inú ọkọ̀ tó máa ń ta awakọ̀ lólobó. Ká sọ pé iná kan tàn sílẹ̀, èyí tó ń sọ fún wa pé epò ọkọ̀ náà ti ń lọ sílẹ̀. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá ò bá tètè ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ tá a kàn ń wa ọkọ̀ náà lọ? A lè ṣàkóbá ńlá fún ọkọ̀ náà. Lọ́nà kan náà, ẹ̀rí ọkàn wa, tá a lè pè ní ohùn tó ń bá wa sọ̀rọ̀, lè máa kìlọ̀ fún wa pé ohun kan tá a fẹ́ ṣe kò bójú mu. Yóò máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tá a mọ̀ wéra pẹ̀lú ìgbésẹ̀ tí à ń gbé tàbí tá a fẹ́ gbé náà, yóò sì máa kìlọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí iná inú ọkọ̀ yẹn. Tá a bá ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ náà, kì í ṣe pé èyí á jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ àwọn àbájáde tí kò dára tó lè tinú ìwà tí kò bójú mu náà wá nìkan ni, àmọ́ á tún jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa nìṣó.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ náà? Díẹ̀díẹ̀, ẹ̀rí ọkàn wa lè di èyí tí kò ṣiṣẹ́ mọ́. A lè fi ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá ń kọ̀ láti tẹ́tí sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ní gbogbo ìgbà wé fífi irin gbígbóná sàmì sí ara. Ibi tó lápàá náà á kú tipiri, bí nǹkan kan bá sì kan ibẹ̀, èèyàn ò ní mọ̀ ọ́n lára. (1 Tímótì 4:2) Irú ẹ̀rí ọkàn bẹ́ẹ̀ kò ní dáni lẹ́bi mọ́ nígbà téèyàn bá ṣẹ̀, kò sì ní kìlọ̀ fún wa mọ́ pé kéèyàn má tún ẹ̀ṣẹ̀ náà dá. Ẹ̀rí ọkàn tó ti yigbì kì í ka àwọn ìlànà Bíbélì nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ sí, nípa bẹ́ẹ̀ ó ti di ẹ̀rí ọkàn burúkú. Ẹ̀rí ọkàn náà ti di ẹlẹ́gbin, ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá sì ti dà bẹ́ẹ̀ ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere” ó sì ti dàjèjì sí Ọlọ́run. (Éfésù 4:17-19; Títù 1:15) Ẹ ò rí i pé ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í dára béèyàn bá ń kọ̀ láti fetí sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀!

“Di Ẹ̀rí-Ọkàn Rere Mú”

Ó gba ìsapá gidigidi kí ẹ̀rí ọkàn èèyàn tó lè jẹ́ èyí tó dára nígbà gbogbo. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ń lo ara mi nígbà gbogbo láti ní ìmọ̀lára àìṣe ohun ìmúnibínú kankan sí Ọlọ́run àti ènìyàn.” (Ìṣe 24:16) Nítorí pé Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù, ó máa ń ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ nígbà gbogbo ó sì máa ń ṣàtúnṣe sí ìwà rẹ̀ láti rí i dájú pé òun ò ṣe ohunkóhun tí yóò múnú bí Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé lópin gbogbo rẹ̀, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pinnu bóyá ohun tá à ń ṣe dára tàbí ó burú. (Róòmù 14:10-12;1 Kọ́ríńtì 4:4) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.”—Hébérù 4:13.

Pọ́ọ̀lù tún sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣàì ṣe ohunkóhun tí yóò mú àwọn èèyàn bínú. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ìmọ̀ràn tó fún àwọn Kristẹni ìlú Kọ́ríńtì nípa “jíjẹ àwọn oúnjẹ tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà.” Kókó tó ń fà yọ ni pé bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò bá tiẹ̀ ta ko ohun kan tá a fẹ́ ṣe, ó ṣe pàtàkì ká ronú lórí àkóbá tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣe fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn. Tá a bá kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, èyí lè ṣe ‘àwọn arákùnrin wa tí Kristi kú fún lọ́ṣẹ́.’ Kódà a tún lè ba àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 8:4, 11-13; 10:23, 24.

Fún ìdí yìí, máa bá a lọ láti máa kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ kó o lè máa ní ẹ̀rí ọkàn rere nígbà gbogbo. Bó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu, wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:5) Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì jẹ́ káwọn ìlànà inú rẹ̀ máa darí ìrònú rẹ àti ọkàn rẹ. (Òwe 2:3-5) Táwọn ọ̀ràn tó le gan-an bá dojú kọ ọ́, fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú kó bàa lè dá ọ lójú pé o lóye àwọn ìlànà Bíbélì tó rọ̀ mọ́ ọ̀ràn náà gẹ́gẹ́ bó ti yẹ. (Òwe 12:15; Róòmù 14:1; Gálátíà 6:5) Ronú lórí bí ìpinnu rẹ yóò ṣe nípa lórí ẹ̀rí ọkàn rẹ àti lórí ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn, àti ní pàtàkì jù lọ, bí yóò ṣe nípa lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà.—1 Tímótì 1:5, 18, 19.

Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye gan-an ni ẹ̀rí ọkàn wa jẹ́ látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, Jèhófà Ọlọ́run. Bá a bá ń lò ó lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ẹni tó fún wa mu, a óò túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa gan-an. Bá a ti ń sapá láti “di ẹ̀rí-ọkàn rere mú” nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, a túbọ̀ ń fi hàn dáadáa pé àwòrán Ọlọ́run ni a dá wa.—1 Pétérù 3:16; Kólósè 3:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè tó ń jẹ́ The Analytical Greek Lexicon Revised látọwọ́ Harold K. Moulton ṣe sọ ọ́, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún ẹ̀rí ọkàn níbí yìí túmọ̀ sí “ọgbọ́n inú téèyàn fi ń mọ irú ìwà tó yẹ kóun hù.” Ìwé atúmọ̀ èdè tó ń jẹ́ Greek-English Lexicon látọwọ́ J. H. Thayer náà sì tún sọ pé ó túmọ̀ sí “fífi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ǹjẹ́ o kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ láti máa tọ́ ọ sọ́nà dípò kó kàn máa dá ọ lẹ́bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Mímọ àwọn ìlànà Bíbélì àti fífi wọ́n sílò ló máa jẹ́ ká lè ní ẹ̀rí ọkàn tó dára gan-an

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Má ṣe kọ etí dídi sí ẹ̀rí ọkàn rẹ nígbà tó bá ń kìlọ̀ fún ọ