Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ti Gbilẹ̀ Gan-an ní “Ilẹ̀ Ẹyẹ Idì”

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ti Gbilẹ̀ Gan-an ní “Ilẹ̀ Ẹyẹ Idì”

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ti Gbilẹ̀ Gan-an ní “Ilẹ̀ Ẹyẹ Idì”

“ILẸ̀ Ẹyẹ Idì” làwọn ará Alibéníà ń pe orílẹ̀-èdè wọn lédè wọn. Àgbègbè Balkan létí Òkun Adriatic ni orílẹ̀-èdè Alibéníà wà, láàárín ilẹ̀ Gíríìsì àti orílẹ̀-èdè tó ń jẹ́ Yugoslavia tẹ́lẹ̀. Onírúurú ìtàn làwọn èèyàn ti sọ nípa ibi táwọn ará Alibéníà ti pilẹ̀ ṣẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òpìtàn gbà pé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ílíríkónì ayé ìgbàanì ni àwọn àti èdè wọn ti ṣẹ̀ wá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé láti ọdún 2000 ṣáájú Sànmánì Kristẹni làwọn èèyàn Ílíríkónì ti wà.

Lára àwọn ohun tó gbàfiyèsí lórílẹ̀-èdè Alibéníà ni àwọn òkè págunpàgun tó wà lápá àríwá àti etíkun Adriatic lápá gúúsù. Etíkun náà gùn gan-an, ó sì ní iyanrìn funfun. Àmọ́ ohun tó fani mọ́ra jù làwọn èèyàn ibẹ̀. Wọ́n fẹ́ràn èèyàn, wọ́n máa ń ṣàlejò gan-an, wọ́n lọ́yàyà, wọn ò dinú rárá, nǹkan máa ń tètè yé wọn, wọ́n sì máa ń fìtara sọ̀rọ̀ gan-an.

Gbajúgbajà Míṣọ́nnárì Kan Dé Ọ̀dọ̀ Wọn

Kò sí àní-àní pé ìwà dáadáa táwọn èèyàn yìí ní àti bí orílẹ̀-èdè yẹn ṣe rí fa ẹnì kan tí ìrìn àjò rẹ̀ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan mọ́ra ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn. Ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀pọ̀ ibi kọ̀wé pé: “Títí dé Ílíríkónì ni mo ti wàásù ìhìn rere nípa Kristi kúnnákúnná.” (Róòmù 15:19) Àárín orílẹ̀-èdè Alibéníà òde òní sí apá àríwá rẹ̀ ni gúúsù Ílíríkónì láyé ìgbà yẹn. Ìlú Kọ́ríńtì nílẹ̀ Gíríìsì, èyí tó wà lápá gúúsù Ílíríkónì ni Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé yìí. Bó ṣe sọ pé òun wàásù kúnnákúnná “títí dé Ílíríkónì” fi hàn pé ó ní láti jẹ́ pé ó wàásù dé ààlà Ílíríkónì tàbí pé ó wọbẹ̀ lọ wàásù pàápàá. Èyí ó wù kó jẹ́, ó ṣáà wàásù ní àgbègbè tó jẹ́ gúúsù ilẹ̀ Alibéníà òde òní. Nítorí náà Pọ́ọ̀lù la lè sọ pé ó kọ́kọ́ wàásù ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ní Alibéníà.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ti kọjá báyìí lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù wá síbẹ̀. Onírúurú ilẹ̀ ọba ló ti ṣàkóso kọjá. Onírúurú ìjọba ilẹ̀ òkèèrè ló sì ti ṣàkóso lórí apá kékeré ní ilẹ̀ Yúróòpù tó wá di orílẹ̀-èdè Alibéníà yìí kí wọ́n tó gbòmìnira lọ́dún 1912. Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí ilẹ̀ Alibéníà gbòmìnira, ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Jèhófà tún padà débẹ̀.

Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Níbẹ̀ Lóde Òní Wúni Lórí Gan-an

Láwọn ọdún 1920, àwọn ọmọ Alibéníà kan tó wà ní Amẹ́ríkà tí wọ́n di ara àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé, bí a ṣe ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, padà wá sí Alibéníà láti sọ ohun tí wọ́n kọ́ fáwọn èèyàn. Nasho Idrizi jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àwọn èèyàn kan sì kọbi ara sí ọ̀rọ̀ wọn. Lọ́dún 1924, ètò Jèhófà sọ pé kí ọ́fíìsì ẹ̀ka tó wà ní ilẹ̀ Romania máa bójú tó ètò iṣẹ́ ìwàásù ní Alibéníà káwọn olùfìfẹ́hàn tó ń pọ̀ sí i níbẹ̀ lè rí àbójútó tó yẹ.

Thanas Duli (Athan Doulis) wà lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ní Alibéníà nígbà náà lọ́hùn-ún. Ó ní: “Ìjọ mẹ́ta ló wà ní Alibéníà lọ́dún 1925, yàtọ̀ sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn olùfìfẹ́hàn tó wà ní àdádó káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Ìfẹ́ tó wà láàárín wọn jinlẹ̀ gan-an ni, ó yàtọ̀ sí . . . tàwọn èèyàn yòókù níbẹ̀!” a

Kò rọrùn rárá láti máa ti ibì kan dé ibòmíràn láyé ìgbà yẹn nítorí ọ̀nà tí kò dáa. Síbẹ̀ ìyẹn ò dá àwọn akéde onítara dúró. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 1928, Areti Pina tó ń gbé ní ìlú Vlorë tó wà létíkun ní gúúsù Alibéníà ṣèrìbọmi nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún. Bí arábìnrin yìí ṣe ń lọ ló ń bọ̀ látorí òkè págunpàgun kan dé òmíràn tó ń wàásù ìhìn rere tòun ti Bíbélì lọ́wọ́. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akéde ìjọ onítara tó wà ní ìlú Vlorë lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930.

Ní nǹkan bí ọdún 1930, ọ́fíìsì ẹ̀ka tó wà ní Áténì ní Gíríìsì ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní Alibéníà. Lọ́dún 1932, alábòójútó arìnrìn-àjò kan wá sí Alibéníà láti Gíríìsì láti wá fún àwọn ará níṣìírí àti okun. Láyé ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń retí àtilọ sí ọ̀run. Bí àwọn ará ṣe jẹ́ olóòótọ́ èèyàn àti afínjú tí kì í rìnrìn ìdọ̀tí jẹ́ káwọn èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún wọn níbi gbogbo. Àwọn èèyàn sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìwàásù àwọn ará olóòótọ́ yìí gan-an ni. Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [6,500] onírúurú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n fi sóde ní Alibéníà lọ́dún 1935, iye yìí náà ni wọ́n sì fi síta lọ́dún 1936.

Lọ́jọ́ kan láàárín ìlú Vlorë, Nasho Idrizi gbé àwo àsọyé J. F. Rutherford sínú ẹ̀rọ giramọfóònù káwọn èèyàn lè gbọ́ ọ. Àwọn èèyàn pa ọjà wọn tì láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà bí Arákùnrin Idrizi ṣe ń túmọ̀ àsọyé náà sí èdè Alibéníà. Ìtara àwọn ará tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìkáàárẹ̀ láyé ìgbà yẹn ò sì já sí asán rárá. Nígbà tó fi máa di ọdún 1940, àádọ́ta Ẹlẹ́rìí ti wà ní Alibéníà.

Orílẹ̀-Èdè Tí Kò Gbà Pé Ọlọ́run Wà

Lọ́dún 1939, Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ti ilẹ̀ Ítálì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso Alibéníà. Ni ìjọba bá gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Kò pẹ́ sígbà náà làwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì gbógun ja orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, òkìkí ọ̀gágun Enver Hoxha ẹlẹ́nu-dùn-juyọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kàn. Ẹgbẹ́ òṣèlú tirẹ̀ tó jẹ́ Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ló borí nínú ìbò ti ọdún 1946, bó ṣe di olórí ìjọba nìyẹn. Àwọn èèyàn wá ń pe àwọn ọdún ẹ̀yìn ìgbà náà ní àkókò òmìnira, àmọ́ àkókò ìtẹ̀lóríba ló jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó di pé ìjọba ò fara mọ́ ẹ̀sìn ṣíṣe mọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Alibéníà kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun, wọn kò sì lọ́wọ́ sí ìṣèlú torí pé Kristẹni tí kì í lọ́wọ́ sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n. (Aísáyà 2:2-4; Jòhánù 15:17-19) Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni wọ́n sọ sẹ́wọ̀n láìfún wọn lóúnjẹ àtàwọn ohun kòṣeémánìí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn arábìnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí kò sí lẹ́wọ̀n ló ń fọ aṣọ wọn tó sì ń fún wọn lóúnjẹ.

Inúnibíni Ò Dẹ́rù Bà Wọ́n

Abúlé kan nítòsí ìlú Përmet ni Frosina Xheka, ọmọbìnrin kan tí ò tíì pé ogún ọdún ń gbé lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940 nígbà tó gbọ́ ẹ̀kọ́ táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin ń kọ́ lọ́dọ̀ Nasho Dorí, Ẹlẹ́rìí kan tó ń ṣe bàtà. b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni táwọn aláṣẹ ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń le sí i lásìkò yẹn, síbẹ̀ ńṣe ni ìgbàgbọ́ Frosina ń lágbára sí i, ìyẹn ò sì dùn mọ́ àwọn òbí rẹ̀ nínú. Frosina ní: “Wọ́n máa ń kó bàtà mi pa mọ́, wọ́n á tún nà mí bí mo bá lọ sípàdé ìjọ. Wọ́n fẹ́ kí n fẹ́ ọkùnrin aláìgbàgbọ́ kan. Nígbà tí mi ò gbà, wọ́n lé mi jáde kúrò nílé. Ìrì dídì ń sẹ̀ lọ́jọ́ tí mò ń wí yìí. Nasho Dori ní kí Arákùnrin Gole Flloko tó wà ní ìlú Gjirokastër ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n sì ní kí n máa gbé lọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì nítorí wọn ò lọ́wọ́ sí ìṣèlú àti ogun. Nígbà tí wọ́n kúrò lẹ́wọ̀n mo wá lọ ń gbé lọ́dọ̀ wọn nílùú Vlorë.

“Àwọn ọlọ́pàá gbìyànjú láti fipá mú mi lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Ṣùgbọ́n mo kọ̀. Wọ́n wá mú mi, wọ́n sì fà mí wọ yàrá kan níbi táwọn ọlọ́pàá ti fi mí sáàárín. Ọ̀kan nínú wọn halẹ̀ mọ́ mi, ó ní: ‘Ṣé o mọ ohun tá a lè ṣe fún ẹ ṣá?’ Mo fèsì pé: ‘Ohun tí Jèhófà bá gbà kẹ́ ẹ ṣe nìkan lẹ lè ṣe.’ Ló bá pariwo mọ́ mi pé: ‘Ó jọ pé wèrè ni ẹ́! Jáde!’”

Bẹ́ẹ̀ náà làwọn ará yòókù ní Alibéníà ṣe jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ gbogbo ọdún wọ̀nyẹn. Nígbà tó fi máa di ọdún 1957, akéde Ìjọba Ọlọ́run ti di márùndínlọ́gọ́rin ní Alibéníà. Lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kí John Marks wá sí Tiranë láti wá bá wa rí sí ètò iṣẹ́ ìsìn wa. Ọmọ ilẹ̀ Alibéníà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Marks. c Àmọ́, kò pẹ́ sígbà náà tí wọ́n fi kó Luçi Xheka, Mihal Sveci, Leonidha Pope àtàwọn arákùnrin mìíràn tó ń ṣe kòkárí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

Ìṣòro Wa Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dópin

Ṣáájú ọdún 1967, ìjọba ò fojúure wo ẹ̀sìn kankan ní Alibéníà. Àmọ́ láti ọdún 1967 síwájú, wọn ò tiẹ̀ wá fàyè gba ẹ̀sìn kankan mọ́. Wọn ò gbà kí olórí ìsìn kankan, yálà ti ẹ̀sìn Kátólíìkì, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tàbí ti Mùsùlùmí, ṣe ààtò ìsìn mọ́. Wọ́n ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí kan pa, wọn sì sọ àwọn mìíràn di ibi ìṣeré ìdárayá, ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tàbí ọjà. Wọn ò gbà kí ẹnikẹ́ni ní Bíbélì. Wọ́n ní ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ fi hàn pé òun gba Ọlọ́run gbọ́.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe láti wàásù tàbí láti ṣèpàdé mọ́. Síbẹ̀ Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti sin Jèhófà bí wọ́n tiẹ̀ wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Iye àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí dín kù láti ọdún 1960 sí àwọn ọdún 1980, títí tó fi ku àwọn díẹ̀ péré. Síbẹ̀ ìgbàgbọ́ àwọn tó kù yìí dúró digbí.

Láàárín ọdún 1986 sí 1989, àyípadà bẹ̀rẹ̀ sí bá ètò ìṣèlú díẹ̀díẹ̀ ní Alibéníà. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí oúnjẹ àti aṣọ. Inú àwọn aráàlú ò sì dùn. Àyípadà tó ń bá ọ̀ràn ìṣèlú káàkiri Ìlà-Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù náà kan Alibéníà lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990. Lẹ́yìn tí ìjọba oníkùmọ̀ ti ṣàkóso fún ọdún márùndínláàádọ́ta, ìjọba tuntun bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, wọ́n sì gbà káwọn èèyàn tún padà máa ṣe ẹ̀sìn.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ pé kí ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Austria àti ti Gíríìsì wá àwọn ará tó wà ní Alibéníà kàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi falẹ̀. Àwọn ará ní Gíríìsì tó gbọ́ èdè Alibéníà kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ wá sí ìlú Tiranë àti Berat. Inú àwọn ará tó ti wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tipẹ́tipẹ́ yìí dùn gan-an nígbà tí wọ́n tún fojú kan àwọn ará láti ilẹ̀ òkèèrè lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Onítara Láti Ilẹ̀ Òkèèrè Múpò Iwájú Lẹ́nu Iṣẹ́ Náà

Lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1992, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní kí tọkọtaya kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì, ìyẹn Michael àti Linda DiGregorio wá sí Alibéníà. Ọmọ ilẹ̀ Alibéníà ni wọ́n. Wọ́n wá àwọn ará tó ṣì ń ṣe dáadáa tó wà níbẹ̀ kàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti darúgbó, wọ́n sì mú kí wọ́n tún wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wọn kárí ayé. Ní November ọdún yẹn, àwọn mẹ́rìndínlógún tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, ìyẹn ajíhìnrere alákòókò kíkún, láti ilẹ̀ Ítálì àtàwọn aṣáájú ọ̀nà mẹ́rin láti ilẹ̀ Gíríìsì wá sí Alibéníà. Àwọn ará ṣètò káwọn aṣáájú ọ̀nà yìí kọ́kọ́ kọ́ èdè Alibéníà ná.

Nǹkan ò rọrùn fáwọn aṣáájú ọ̀nà tó tilẹ̀ òkèèrè wá yìí. Iná mànàmáná máa ń ṣe ségesège. Òtútù ìgbà ọ̀gìnnìtìn kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Àwọn èèyàn máa ń tò fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó lè rí oúnjẹ àtàwọn ohun kòṣeémánìí. Àmọ́ ìṣòro tó ga jù fáwọn ará ni bí wọ́n á ṣe rí àwọn ilé tó máa gba ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́!

Àwọn aṣáájú ọ̀nà tó ń gbìyànjú láti sọ èdè Alibéníà rí i pé kí èdè yọ̀ mọ́ni lẹ́nu kọ́ ló jà jù. Arákùnrin kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù sọ fún wọn pé: “Kò dìgbà tí èdè bá yọ̀ mọ́ni lẹ́nu dáadáa kéèyàn tó lè fi ọ̀yàyà rẹ́rìn-ín sáwọn ará tàbí kó gbá wọn mọ́ra. Èdè yíyọ̀mọ́nilẹ́nu kọ́ ló máa mú káwọn ará Alibéníà fà mọ́ yín bí kò ṣe ìfẹ́ àtọkànwá tẹ́ ẹ ní sí wọn. Ẹ fọkàn balẹ̀, wọ́n á mọ̀ pé ẹ̀ ń gbìyànjú.”

Lẹ́yìn táwọn aṣáájú ọ̀nà yìí ti kọ́ èdè díẹ̀, wọ́n bẹ́rẹ̀ iṣẹ́ wọn ní ìlú Berat, Durres, Gjirokastër, Shkodër, Tiranë, àti Vlorë. Kò sì pẹ́ tí ìjọ fi gbèrú nílùú wọ̀nyẹn. Ìlú Vlorë náà ni arábìnrin Areti Pina ṣì wà nígbà náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún ara rẹ̀ ò sì fi bẹ́ẹ̀ le. Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe méjì ni wọ́n gbé lọ sí ìlú náà kí àwọn àti Areti lè jọ máa wàásù. Ó ya àwọn èèyàn lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ará láti ilẹ̀ òkèèrè ń sọ èdè Alibéníà. Wọ́n ní: “Ńṣe làwọn míṣọ́nnárì inú ẹ̀sìn yòókù máa ń sọ pé ká kọ́kọ́ kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì tàbí èdè Ítálì tá a bá mọ̀ pé a fẹ́ kẹ̀kọ̀ọ́. Ó ní láti jẹ́ pé ẹ fẹ́ràn wa gan-an, ẹ sì lóhun pàtàkì tẹ́ ẹ fẹ́ ká mọ̀ lẹ fi kọ́ èdè Alibéníà tó sì yọ̀ mọ́ ọn yín lẹ́nu tó báyìí!” Oṣù January ọdún 1994 ni Areti parí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kódà ó ṣì wàásù títí di oṣù yẹn. Ìsapá rẹ̀ àti tàwọn aṣáájú ọ̀nà tó wà níbẹ̀ ò já sí asán rárá. Lọ́dún 1995, ìjọ kan tún padà fìdí múlẹ̀ nílùú Vlorë. Lónìí, odindi ìjọ mẹ́ta ló wà nílùú tó wà létíkun yẹn tí wọ́n ń wàásù ìhín rere.

Jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ni ebi nǹkan tẹ̀mí ti ń pa àwọn èèyàn, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀tanú ẹ̀sìn. Tinútẹ̀yìn ni wọ́n ń ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n bá gbà lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí. Ọ̀pọ̀ àwọn èwe ló bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú kíákíá.

Àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ kéékèèké tó wà jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí lé ní àádọ́rùn-ún báyìí, wọ́n sì “ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (Ìṣe 16:5) Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Alibéníà, tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlá [3,513] ṣì níṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe. Ní March 2005, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ó lé mẹ́rìnlélógóje [10,144] èèyàn ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó ń wáyé nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí bá wàásù fáwọn èèyàn Alibéníà tí wọ́n jẹ́ olùfẹ́ àlejò yìí ti mú kí wọ́n ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lé ní ẹgbàáta [6,000]. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tẹ̀ jáde lédè Alibéníà láìpẹ́ yìí yóò ṣe láǹfààní. Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ Jèhófà ti gbilẹ̀ gan-an ní “Ilẹ̀ Ẹyẹ Idì,” èyí sì ń gbé orúkọ Jèhófà ga.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ ka ìtàn ìgbésí ayé Thanas Duli, wo Ile-Iṣọ Na, December 1, 1969.

b Tó o bá fẹ́ ka ìtàn ìgbésí ayé Nasho Dori, wo Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1996.

c Tó o bá fẹ́ ka ìtàn ìgbésí ayé Helen, aya John Marks, wo Ilé Ìṣọ́ January 1, 2002.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

OGUN KẸ́LẸ́YÀMẸ̀YÀ WÁBI GBÀ NÍ KỌ́SÓFÒ!

Ṣàṣà lẹni tí kò gbọ́ orúkọ ilẹ̀ Kọ́sófò lápá ìparí àwọn ọdún 1990. Nígbà náà, ìjà lórí ààlà ilẹ̀ àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà di ogun, èyí táwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé wá dá sí.

Nígbà tí wọ́n ń ja ogun tó gba gbogbo ilẹ̀ Balkan yìí, ńṣe ni ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí sá lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè ìtòsí ibẹ̀. Bí ogun yẹn ṣe rọlẹ̀, àwọn díẹ̀ lára wọn padà sí Kọ́sófò láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe láti Alibéníà àti Ítálì wá sí Kọ́sófò láti wá wàásù láàárín àwọn èèyàn ibẹ̀ tí iye wọ́n tó mílíọ̀nù méjì ó lé ẹgbàá márùndínlọ́gọ́sàn-án [2,350,000]. Ìjọ mẹ́rin àti àwùjọ onítara mẹ́fà tí àpapọ̀ akéde wọn jẹ́ àádóje [130] ló ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní ìpínlẹ̀ náà.

Wọ́n ṣe ìpàdé àkànṣe kan nílùú Priština nígbà ìrúwé ọdún 2003. Àádọ́talénígba ó lé méjì [252] èèyàn ló wá síbẹ̀. Àwọn ará Alibéníà, Jámánì, Ítálì, Serbia àtàwọn ẹ̀yà Gypsy wà lára wọn. Ní ìparí ọ̀rọ̀ ìrìbọmi, olùbánisọ̀rọ̀ béèrè ìbéèrè méjì. Àwọn mẹ́ta ló dìde dúró láti dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí àwọn ìbéèrè náà. Ọ̀kan jẹ́ ọmọ Alibéníà, ìkejì jẹ́ ẹ̀yà Gypsy, ìkẹta sì jẹ́ ọmọ Serbia.

Nígbà tí àwùjọ gbọ́ ohùn àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó fẹ́ ṣèrìbọmi, tí wọ́n dáhùn pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà pé: “Po!,” “Va!” àti “Da!,” olúkúlùkù ní èdè tirẹ̀, ńṣe làtẹ́wọ́ sọ. Àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà wá dì mọ́ra wọn. Wọ́n ti fa ẹ̀tanú ẹ̀yà táwọn èèyàn wọn ní tu lọ́kàn tiwọn tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 17]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Òkun Mẹditaréníà

ÍTÁLÌ

ALIBÉNÍÀ

GÍRÍÌSÌ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àgbà àárín wọn tí wọ́n jẹ́ onítara

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Areti Pina fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà láti ọdún 1928 títí tó fi kú lọ́dún 1994

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn aṣáájú ọ̀nà àkọ́kọ́ láti ilẹ̀ òkèèrè tó ń kọ́ èdè Alibéníà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹyẹ idì: © Brian K. Wheeler/VIREO