Jàǹfààní Látinú Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jù Lọ Láyé Yìí!
Jàǹfààní Látinú Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jù Lọ Láyé Yìí!
BÍBÉLÌ sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹni tó dá ohun gbogbo, títí kan àwa ọmọ èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Ìṣípayá 4:11) Torí pé òun ni Atóbilọ́lá Olùkọ́ni, ó kọ́ Ádámù àti Éfà tó jẹ́ tọkọtaya ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè gbádùn ayé wọn nínú Édẹ́nì, ọgbà ẹlẹ́wà. Ṣe ni Ọlọ́run fẹ́ máa kọ́ wọn nìṣó, kó sì máa tọ́jú wọn títí ayérayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 29; 2:15-17; Aísáyà 30:20, 21) Àǹfààní tí wọ́n ní yìí mà ga o!
Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí fọwọ́ ara wọn ṣera wọn. Àìgbọràn wọn ló fa ìwà ìbàjẹ́ tí ìran èèyàn ń hù, òun ló sì mú kí wọ́n máa ṣàìsàn kí wọ́n sì máa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Róòmù 5:12) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó gbé láyé ní ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá èèyàn, ó ní: “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5.
Ó ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [4,500] ọdún báyìí tí Jèhófà ti sọ pé kìkì ibi lèèyàn ń gbèrò lọ́jọ́ ayé wọn, ipò táráyé sì wà báyìí ti burú ju tàtijọ́ lọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń purọ́ tí ojú kì í sì í tì wọ́n, ọ̀pọ̀ sì ti ya olè àti oníjàgídíjàgan. Bí ìṣòro ṣe ń peléke sí i lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ táwọn èèyàn ní sí ọmọnìkejì wọn túbọ̀ ń dín kù. Ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti ìdílé ni àárín wọn ti dà rú, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àmọ́, Ọlọ́run kọ́ ló fa gbogbo nǹkan wọ̀nyí o, kì í sì í ṣe pé kò ṣe nǹkan kan nípa àwọn ìṣòro tó wà lóde òní. Kò sígbà tí ọ̀rọ̀ àwa ọmọ èèyàn kì í jẹ Jèhófà lọ́kàn, ó sì ṣe tán láti kọ́ àwọn tó bá ń fẹ́ kó tọ́ àwọn sọ́nà kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbé ayé aláyọ̀. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn, Jèhófà rán Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, Jèhófà sì fi hàn pé òun fẹ́ láti kọ́ àwọn tó bá fẹ́ káyé àwọn dára lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni jẹ́ ẹ̀kọ́ pípé tó yẹ ká máa tẹ̀ lé nítorí pé ọ̀dọ̀ Atóbilọ́lá Olùkọ́ni ló ti kọ́ ọ fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún.
Ojúlówó Ẹ̀kọ́ Ń Bẹ Nínú Ìsìn Kristẹni Tòótọ́
Jésù Kristi ló dá ìsìn Kristẹni tòótọ́ sílẹ̀, ìfẹ́ ló sì ń darí àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn náà. Wọ́n ní láti mú gbogbo èrò àti ìwà wọn bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu kí wọ́n bàa lè fi ọlá àti ògo fún orúkọ rẹ̀. (Mátíù 22:37-39; Hébérù 10:7) Jèhófà Bàbá Jésù ti Jésù lẹ́yìn nínú bó ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n gbé ìgbésí ayé. Jòhánù orí kẹjọ ẹsẹ ìkọkàndínlọ́gbọ̀n sọ bí Ọlọ́run ṣe ti Jésù lẹ́yìn, ó kà pé: “Ẹni tí ó rán mi sì wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì ní èmi nìkan, nítorí pé nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” Bẹ́ẹ̀ ni, jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Bàbá rẹ̀ tì í lẹ́yìn. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí náà rí ìtọ́sọ́nà tó máa jẹ́ kí wọ́n lè yanjú ìṣòro ìgbésí ayé. Jèhófà lo Ọmọ rẹ̀ láti kọ́ wọn. Àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti àpẹẹrẹ rẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé mú kí ayé wọn dára gan-an. Bó ṣe rí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí ń bẹ lónìí náà nìyẹn.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ìrànlọ́wọ́ Tí Jésù Àtàwọn Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Ṣe Fáwọn Èèyàn,” lójú ìwé 6.
Ohun kan tó ta yọ nípa ìsìn Kristẹni tòótọ́ ni pé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ máa ń wọni lọ́kàn, èyí sì ń mú káwọn èèyàn yí ìwà wọn padà. (Éfésù 4:23, 24) Bí àpẹẹrẹ, wo ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni nípa jíjẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya ẹni, ó sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:27, 28) Ẹ̀kọ́ tí Jésù ń fi ọ̀rọ̀ tó sọ yìí kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn wọn wà ní mímọ́ àti pé bí ẹnì kan bá ní èrò tí kò mọ́ lọ́kàn, bí onítọ̀hún ò kàn tíì ṣe nǹkan ọ̀hún, ó lè ṣàkóbá fún un. Ǹjẹ́ kì í ṣòótọ́ pé èrò búburú lè mú kéèyàn ṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí tó sì máa kó ìbànújẹ́ bá àwọn ẹlòmíì?
Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) O lè béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ yí èrò inú wa padà?’ Nígbà tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé kí ẹnì kan yí èrò inú rẹ̀ padà, ó túmọ̀ sí pé kí onítọ̀hún darí ọkàn rẹ̀ sí nǹkan mìíràn nípa fífi àwọn ìlànà àti ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn. Ọ̀nà tá a sì lè gbà ṣe èyí ni pé ká gba ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ wa.
Àwọn Tí Ẹ̀kọ́ Bíbélì Yí Ìgbésí Ayé Wọn Padà
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Títí di ìsinsìnyí, Bíbélì ṣì ń sa agbára lórí àwọn èèyàn, tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ò kùtà. Ó lè mú kí ẹnì kan yí ìwà rẹ̀ padà, kó di Kristẹni tòótọ́, kó sì dẹni tó wúlò. Àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí fi bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ṣe pàtàkì tó hàn.
Obìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Emilia tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ pé: “Mo rí i pé ipa témi nìkan ń sà láti mú kí ìdílé mi wà nípò tó dára kò tó. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo wá rí i pé ìrètí ń bẹ, bí mo sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí yí ìwà mi padà nìyẹn. Mi ò kì í bínú fùfù bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Nígbà tó yá, baálé mi náà bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́. Kò rọrùn fún un láti dáwọ́ ọtí àmujù dúró, àmọ́ ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Ìgbà tá a jáwọ́ nínú gbogbo ìwà yẹn la di tọkọtaya rere. Kristẹni aláyọ̀ ni wá báyìí, a sì ń fi àwọn ìlànà rere tó wà nínú Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wa.”—Diutarónómì 6:7.
Ẹ̀kọ́ táwa Kristẹni tòótọ́ ń kọ́ lè mú ká jáwọ́ nínú àwọn ìwà búburú àti ìṣekúṣe. Manuel a rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ló wà nígbà tó sá kúrò nílé, tó lọ bẹ̀rẹ̀ sí mugbó. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró tó ń jẹ́ heroin. Ó ń bá àwọn ọkùnrin àtobìnrin ṣèṣekúṣe káàkiri kó lè máa ríbi sùn kó sì rówó ná. Nígbà míì, Manuel máa ń dá àwọn èèyàn lọ́nà láti gbowó ọwọ́ wọn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló máa ń lo oògùn olóró. Àìmọye ìgbà ló sì ti ṣẹ̀wọ̀n nítorí ìwà jàgídíjàgan tó ń hù. Ìgbà kan wà tó lo ọdún mẹ́rin gbáko lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ibẹ̀ ló sì ti di ara àwọn onífàyàwọ́ tó ń ta ohun ìjà ogun. Lẹ́yìn tí Manuel fẹ́yàwó, nǹkan túbọ̀ burú fún un nítorí irú ìgbésí ayé tó ń gbé. Manuel sọ pé: “Inú ilé tí wọ́n ti ń sin adìyẹ tẹ́lẹ̀ lèmi àtìyàwó mi ń gbé. Mo ṣì rántí bí ìyàwó mi ṣe máa ń dáná oúnjẹ ní orí àwọn bíríkì kan báyìí. Nǹkan burú fún wa débi pé àwọn mọ̀lẹ́bí mi sọ fún ìyàwó mi pé kó kọ̀ mí.”
Kí ló wá yí ìgbésí ayé Manuel padà? Ó ní: “Lọ́jọ́ kan, ojúlùmọ̀ wa kan wá sílé wa láti wàásù. Mo gbà á láyè kó wá máa bá wa sọ̀rọ̀ nítorí mo fẹ́ jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run ò bìkítà nípa àwa èèyàn rárá àti rárá. Èmi alára jẹ́ àpẹẹrẹ kan. Sùúrù àti ọ̀wọ̀ tí Ẹlẹ́rìí yìí ní yà mí lẹ́nu, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tó ní kí n wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo sọ fún un pé màá wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára àwọn tó wà nípàdé náà mọ irú èèyàn tí mo jẹ́, síbẹ̀ wọ́n kí mi dáadáa. Wọ́n gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Èyí sì mára tù mí gan-an. Ó wú mi lórí débi pé mo pinnu pé màá fi òwò oògùn olóró tí mò ń ṣe sílẹ̀, màá sì wáṣẹ́ míì tó yẹ ọmọlúwàbí ṣe. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo tóótun láti máa jáde òde ẹ̀rí, nígbà tó sì di oṣù mẹ́rin lẹ́yìn ìyẹn, mo ṣe ìrìbọmi.”
Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ṣe fún Manuel àti ìdílé rẹ̀? Ó sọ pé: “Bí kì í bá ṣe ẹ̀kọ́ Bíbélì ni, ǹ bá ti kú tipẹ́. Àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa gbé ìgbésí ayé ni kò jẹ́ káwọn ọmọ àtìyàwó mi fi mí sílẹ̀. Àwọn ọmọ mi méjèèjì ò ní gbé irú ìgbé ayé tí mo gbé lọ́mọdé. Inú mi dùn, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi àti ìyàwó mi ń gbé nísinsìnyí bó ṣe yẹ kí ọkọ àtìyàwó máa gbé. Lára àwọn ojúlùmọ̀ mi tẹ́lẹ̀ bá mi yọ̀, wọ́n sì sọ fún mi pé ìgbésí ayé tí mò ń gbé nísinsìnyí ló dára jù lọ.”
Tẹ́nì kan bá jẹ́ Kristẹni gidi, yàtọ̀ sí pé kó máa hùwà mímọ́, ó tún gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó mọ́ tónítóní. Ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John tó ń gbé lágbègbè táwọn tálákà wà ní Gúúsù 1 Pétérù 1:16 tó gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ mímọ́ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́. Ní báyìí, àwa náà ń gbìyànjú láti mú kí ilé kékeré tá a ní wà nípò tó bójú mu.”
Áfíríkà rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ó ní: “Nígbà míì, ọmọ wa obìnrin kò ní wẹ̀ fún odindi ọ̀sẹ̀ kan, kò sì sí ìkankan nínú wa tó bìkítà nípa ìyẹn.” Ìyàwó rẹ̀ sọ pé ńṣe nílé àwọn máa ń rí jákujàku tó sì máa ń dọ̀tí gan-an tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ẹ̀kọ́ Bíbélì ti mú kí nǹkan yí padà báyìí. John ò bá àwọn tó ń jí mọ́tò gbé kẹ́gbẹ́ mọ́, ó sì ti ń bójú tó ìdílé rẹ̀ bó ṣe yẹ. Ó ní: “Ẹ̀kọ́ tá a kọ́ ni pé àwa tá a jẹ́ Kristẹni ní láti rí i pé ara wa àti aṣọ wa wà ní mímọ́ tónítóní. Mo fẹ́ràn ọ̀rọ̀ tó wà nínúO Lè Rí Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jú Lọ Gbà
Àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà lókè yìí nìkan kọ́ ló wà o. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ́ ti mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbé ayé tó dára. Nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ wọn, wọn kì í sì í ṣe ọ̀lẹ, àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ mọyì wọn gan-an. Wọ́n ti wá dèèyàn rere ládùúgbò àtẹni tó ṣeé bá dọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n sì ń wá ire àwọn ọmọnìkejì wọn. Wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní máa lọ́wọ́ nínú ìwàkiwà àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, nítorí náà wọ́n ń tọ́jú ara wọn bó ṣe yẹ, wọn ò gba èròkérò láyè, wọ́n sì ń ṣàkóso ara wọn bó ṣe yẹ. Dípò kí wọ́n máa fowó wọn ṣòfò lórí ìwàkiwà, ohun tó máa ṣe àwọn àti ìdílé wọn láǹfààní ni wọ́n ń lò ó fún. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11; Kólósè 3:18-23) Láìsí àní-àní, àwọn àǹfààní téèyàn máa ń rí tó bá fi àwọn ohun tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì sílò fi hàn pé fífi àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni tòótọ́ ṣèwà hù ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé, èyí tó fi hàn pé òun ni ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ. Bíbélì sọ nípa ẹni tó bá ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ pé: “Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:3.
Inú wa dùn pé Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ṣe tán láti kọ́ wa. Ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ti fọ̀nà hàn wá nípasẹ̀ àpẹẹrẹ tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ fi lélẹ̀ àtàwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ni. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó mọ̀ ọ́n nígbà tó wà láyé yí ìgbé ayé wọn padà, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn yí ìgbé ayé wọn padà lónìí. O ò ṣe wáyè láti túbọ̀ kọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ yóò dùn láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ tó ṣeyebíye yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìrànlọ́wọ́ Tí Jésù Àtàwọn Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Ṣe Fáwọn Èèyàn
Nítorí ipò tí Sákéù wà gẹ́gẹ́ bí olórí agbowó orí, ó máa ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì, ó sì máa ń rẹ́ àwọn gbáàtúù èèyàn jẹ, ìyẹn ló wá sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹ̀kọ́ Jésù tó fi sílò mú kó yí ìgbé ayé rẹ̀ padà.—Lúùkù 19:1-10.
Sọ́ọ̀lù ará Tásù dẹ́kun ṣíṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni, òun fúnra rẹ̀ sì di Kristẹni. Òun ló wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—Ìṣe 22:6-21; Fílípì 3:4-9.
Nígbà kan rí, àwọn kan lára àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì jẹ́ ‘alágbèrè, abọ̀rìṣà, panṣágà, ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, olè, oníwọra, ọ̀mùtípara, olùkẹ́gàn àti alọ́nilọ́wọ́gbà.’ Àmọ́ nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìsìn Kristẹni tòótọ́, wọ́n di ẹni tá a ‘wẹ̀ mọ́, tá a sọ di mímọ́, tá a sì polongo ní olódodo ní orúkọ Olúwa wọn Jésù Kristi.’—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe tí ayé rẹ á fi dára