Má Ṣe Ní Ẹ̀mí Ìgbéraga
Má Ṣe Ní Ẹ̀mí Ìgbéraga
“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera.”—JÁKỌ́BÙ 4:6.
1. Sọ ohun kan téèyàn lè fi yangàn.
ǸJẸ́ ohun kan ti ṣẹlẹ̀ rí tó mú orí rẹ wú? Ṣàṣà lẹni tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ sí rí. Kì í ṣe ohun tó burú rárá téèyàn bá ń yangàn nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn òbí kan tó jẹ́ Kristẹni bá wo káàdì ọmọ wọn tí wọ́n rí i pé ó ń ṣe dáadáa ó sì fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, kò sí àní-àní pé èyí á múnú wọn dùn gan-an. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń wàásù fi ìjọ tuntun kan tí kò tíì pẹ́ tí wọ́n dá a sílẹ̀ yangàn nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ará tó wà níbẹ̀ fara da inúnibíni láìyẹsẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 1:1, 6; 2:19, 20; 2 Tẹsalóníkà 1:1, 4.
2. Kí nìdí tí kò fi dára kéèyàn máa gbéra ga?
2 Àwọn àpẹẹrẹ tá a tọ́ka sí lókè yìí jẹ́ ká rí i pé ohun kan téèyàn ṣe tàbí ohun kan téèyàn ní lè múnú ẹni dùn, kò sì burú téèyàn bá fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yangàn. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀bùn àbínibí táwọn èèyàn ní, ẹwà wọn, ọrọ̀ wọn tàbí ipò wọn láwùjọ ló ń mú kí wọ́n máa gbéra ga, kí wọ́n máa ṣe bíi pé àwọn sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fẹgẹ̀, wọ́n sì jọ ara wọn lójú gan-an. Àwa Kristẹni ò sì gbọ́dọ̀ gba irú ẹ̀mí yìí láyè rárá. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó rọrùn fún wa láti di agbéraga nítorí pé gbogbo wa la ti jogún ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan látọ̀dọ̀ Ádámù baba ńlá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Èyí sì lè mú kí ọkàn wa máa tàn wá jẹ, ká wá máa tìtorí àwọn nǹkan kan máa gbéra ga. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ káwa Kristẹni máa gbéra ga nítorí ẹ̀yà wa, àwọn ẹ̀bùn àbínibí wa, ọrọ̀ tá a ní, ìwé tá a kà tàbí nítorí pé a mọ àwọn nǹkan kan ṣe ju àwọn ẹlòmíràn lọ. Kò dára rárá ká máa gbéra ga nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, Jèhófà ò sì nífẹ̀ẹ́ sí i.—Jeremáyà 9:23; Ìṣe 10:34, 35; 1 Kọ́ríńtì 4:7; Gálátíà 5:26; 6:3, 4.
3. Kí ni ìrera, kí ni Jésù sì sọ nípa rẹ̀?
3 Ìdí mìíràn tí a kò fi gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí ìgbéraga láyè ni pé, bá a bá jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí ta gbòǹgbò lọ́kàn wa, a lè di onírera. Kí ni ìrera túmọ̀ sí? Yàtọ̀ sí pé àwọn onírera máa ń jọ ara wọn lójú, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tún máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí wọ́n bá wò pé wọn kò tó àwọn. (Lúùkù 18:9; Jòhánù 7:47-49) Jésù ka “ìrera” mọ́ àwọn ìwà búburú mìíràn tí ń wá “láti inú ọkàn-àyà” tó máa ń “sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.” (Máàkù 7:20-23) Nítorí ìdí yìí, kò yẹ káwa Kristẹni jẹ́ onírera.
4. Báwo làwọn ìtàn inú Bíbélì nípa àwọn onírera ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
4 Àwọn ìtàn Bíbélì nípa àwọn tó jẹ́ onírera lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó o lè ṣe tí o kò fi ní gba ìwà búburú yìí láyè. Àwọn ìtàn náà yóò mú kó rọrùn fún ọ láti mọ̀ bóyá ẹ̀mí ìgbéraga wà lọ́kàn rẹ tàbí bóyá ó ti fẹ́ máa gbilẹ̀ díẹ̀díẹ̀ lọ́kàn rẹ. Èyí ò sì ní jẹ́ kó o fàyè gba èrò èyíkéyìí tó máa jẹ́ kó o lẹ́mìí ìgbéraga. Nígbà tí Ọlọ́run bá fẹ́ fìyà jẹ àwọn onírera, kò ní kàn ọ́. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi yóò mú àwọn tìrẹ tí ń fi ìrera yọ ayọ̀ ńláǹlà kúrò ní àárín rẹ; ìwọ kì yóò sì tún jẹ́ onírera mọ́ ní òkè ńlá mímọ́ mi.”—Sefanáyà 3:11.
Ọlọ́run Máa Ń Jẹ Àwọn Onírera Níyà
5, 6. Kí ni Fáráò ṣe tó fi hàn pé onírera ni, kí ló sì gbẹ̀yìn rẹ̀?
5 Tó o bá wo ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọba alágbára bíi Fáráò, wàá mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìrera. Kò sí àní-àní pé onírera ni Fáráò. Ó ka ara rẹ̀ sí ọlọ́run tó yẹ káwọn èèyàn máa júbà, ìdí nìyẹn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ẹrú rẹ̀ kò fi já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Ronú nípa ohun tó sọ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé kó fún àwọn láyè káwọn lè lọ sí aginjù láti lọ “ṣe àjọyọ̀” sí Jèhófà. Nígbà tí ọba aláfojúdi yìí máa fèsì, ó ní: “Ta ni Jèhófà, tí èmi yóò fi ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀ láti rán Ísírẹ́lì lọ?”—Ẹ́kísódù 5:1, 2.
6 Lẹ́yìn tí ìyọnu mẹ́fà ti dé bá Fáráò ọba Íjíbítì, Jèhófà ní kí Mósè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ ha ṣì ń hùwà lọ́nà ìrera sí àwọn ènìyàn mi ní ṣíṣàìrán wọn lọ bí?” (Ẹ́kísódù 9:17) Mósè tún sọ fún un pé ìyọnu keje ń bọ̀, ó ní òjò yìnyín yóò rọ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. Bí Fáráò ṣe rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń lọ nígbà tó fún wọn láyè lẹ́yìn ìyọnu kẹwàá, ó pèrò dà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, omi Òkun Pupa sé Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́. Ó dájú pé oríṣiríṣi èrò ló máa wá sí wọn lọ́kàn nígbà tí wọ́n rí i pé alagbalúgbú omi fẹ́ ya bò wọ́n mọ́lẹ̀! Kí ni ìrera Fáráò yọrí sí? Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ akọni sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a sá fún níní ìfarakanra èyíkéyìí pẹ̀lú Ísírẹ́lì, nítorí pé Jèhófà ń jà fún wọn dájúdájú ní ìlòdìsí àwọn ará Íjíbítì.”—Ẹ́kísódù 14:25.
7. Kí làwọn ọba Bábílónì ṣe tó fi hàn pé onírera ni wọ́n?
7 Jèhófà tún jẹ́ káwọn ọba mìíràn tí wọ́n jẹ́ onírera kàbùkù. Ọ̀kan lára wọn ni Senakéríbù ọba Ásíríà. (Aísáyà 36:1-4, 20; 37:36-38) Nígbà tó yá, orílẹ̀-èdè Bábílónì ṣẹ́gun Ásíríà, àmọ́ àwọn ọba Bábílónì méjì tí wọ́n jẹ́ onírera náà tún kàbùkù. Ṣé o rántí àsè ńlá tí Ọba Bẹliṣásárì sè, nígbà tí òun àtàwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tó pè ń fi àwọn ohun èlò tí wọ́n kó látinú tẹ́ńpìlì Jèhófà mu wáìnì, tí wọ́n sì ń júbà àwọn òrìṣà Bábílónì? Lójijì, ìka ọwọ́ èèyàn hàn lára ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ nǹkan síbẹ̀. Nígbà tí wọ́n ní kí wòlíì Dáníẹ́lì sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ àdììtú tó wà lára ògiri náà, ó rán Bẹliṣásárì létí pé: “Ní tìrẹ, ọba, Ọlọ́run Gíga Jù Lọ fún Nebukadinésárì baba rẹ ní ìjọba . . . Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera . . . , a rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ láti orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, a sì gba iyì rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. . . . Ní tìrẹ, Bẹliṣásárì ọmọkùnrin rẹ̀, ìwọ kò rẹ ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ gbogbo èyí.” (Dáníẹ́lì 5:3, 18, 20, 22) Ní òru ọjọ́ yẹn gan-an làwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, tí wọ́n sì pa Bẹliṣásárì.—Dáníẹ́lì 5:30, 31.
8. Kí ni Jèhófà ṣe fáwọn kan tó jẹ́ onírera?
8 Tún ronú nípa àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ onírera tí wọ́n sì fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn èèyàn Jèhófà. Irú àwọn onírera èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Gòláyátì òmìrán Filísínì, Hámánì tó jẹ́ olórí ìjọba ilẹ̀ Páṣíà, àti Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà tó jẹ́ alákòóso àgbègbè Jùdíà. Ẹ̀mí ìgbéraga táwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ló jẹ́ kí Ọlọ́run mú kí wọ́n kú ikú ẹ̀sín. (1 Sámúẹ́lì 17:42-51; Ẹ́sítérì 3:5, 6; 7:10; Ìṣe 12:1-3, 21-23) Ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọkùnrin onírera wọ̀nyẹn fi hàn pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” (Òwe 16:18) Ká má purọ́, “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera.”—Jákọ́bù 4:6.
9. Báwo làwọn ọba Tírè ṣe hùwà ọ̀dàlẹ̀?
9 Ìgbà kan wà tí ìwà ọba Tírè yàtọ̀ sí tàwọn ọba Íjíbítì, Ásíríà, àti Bábílónì tí wọ́n jẹ́ onírera. Ìdí ni pé òun máa ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ ní tirẹ̀. Nígbà tí Dáfídì Ọba àti Sólómọ́nì Ọba ń ṣàkóso, ọba Tírè sọ fáwọn oníṣẹ́ ọnà tí wọ́n mọṣẹ́ dunjú pé kí wọ́n lọ ran àwọn tó ń kọ́ ilé ọba àti tẹ́ńpìlì Ọlọ́run lọ́wọ́, ó sì tún fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ohun èlò tí wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà. (2 Sámúẹ́lì 5:11; ) Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, nígbà tó yá ìwà àwọn ọba Tírè yí padà sáwọn èèyàn Jèhófà. Kí ló fà á?— 2 Kíróníkà 2:11-16Sáàmù 83:3-7; Jóẹ́lì 3:4-6; Ámósì 1:9, 10.
“Ọkàn-Àyà Rẹ Di Onírera”
10, 11. (a) Ta ni ìwà tiẹ̀ àti tàwọn ọba Tírè jọra? (b) Kí ló fà á táwọn èèyàn Tírè fi yí ìwà tí wọ́n ń hù sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà?
10 Jèhófà mí sí wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé kó tú àṣírí àwọn ọba Tírè kó sì kégbèé lé wọn lórí. Nínú iṣẹ́ tí Jèhófà rán Ìsíkíẹ́lì sí “ọba Tírè,” àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí Jèhófà fi ṣàpèjúwe ìwà àwọn ọba Tírè àti ti Sátánì, ọ̀dàlẹ̀ àkọ́kọ́ tí kò “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” (Ìsíkíẹ́lì 28:12; Jòhánù 8:44) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Sátánì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Jèhófà olóòótọ́ lọ́rùn. Jèhófà Ọlọ́run sọ fún Ìsíkíẹ́lì láti sọ ohun tó fa àbùkù àwọn ọba Tírè àti Sátánì, ìyẹn ni Ìsíkíẹ́lì fi kọ̀wé pé:
11 “Ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run, ni ìwọ wà. Gbogbo òkúta iyebíye ni ìbora rẹ . . . Ìwọ ni kérúbù tí a fòróró yàn tí ó bò . . . Ìwọ jẹ́ aláìní-àléébù ní àwọn ọ̀nà rẹ láti ọjọ́ tí a ti dá ọ títí a fi rí àìṣòdodo nínú rẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹrù títà rẹ, wọ́n fi ìwà ipá kún àárín rẹ, ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀. . . . Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ kérúbù tí ó bò . . . Ọkàn-àyà rẹ di onírera nítorí ẹwà rẹ. Ìwọ run ọgbọ́n rẹ ní tìtorí ìdángbinrin rẹ.” (Ìsíkíẹ́lì 28:13-17) Ó ṣe kedere pé ìrera ló mú káwọn ọba Tírè bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ìkà sáwọn èèyàn Jèhófà. Ìlú tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù gan-an ni ìlú Tírè torí pé iṣẹ́ ajé búrẹ́kẹ́ gan-an níbẹ̀, àwọn èèyàn sì mọ̀ ọ́n nílé lóko nítorí àwọn ohun mèremère tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. (Aísáyà 23:8, 9) Bí àkókò ṣe ń lọ, àwọn ọba Tírè wá jọ ara wọn lójú gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára.
12. Kí ló sún Sátánì dédìí ìwà ọ̀tẹ̀, kí ló sì ti ń ṣe látìgbà yẹn wá?
12 Bákan náà, ìgbà kan wà tí áńgẹ́lì tó wá di Sátánì ní ọgbọ́n tó lè fi ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí Ọlọ́run bá fún un. Dípò kó máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó di ẹni tó “wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga,” ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso. (1 Tímótì 3:6) Ó jọ ara rẹ̀ lójú débi pé ó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa sin òun. Èrò burúkú yìí wá gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ̀, òun ló sì sún un dẹ́ṣẹ̀. (Jákọ́bù 1:14, 15) Sátánì tan Éfà jẹ èso igi kan ṣoṣo tí Ọlọ́run kà léèwọ̀. Lẹ́yìn èyí, Sátánì lo Éfà láti fún Ádámù ọkọ rẹ̀ ní èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà jẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé àwọn méjèèjì kò fẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣàkóso wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di olùjọsìn Sátánì. Àmọ́, Sátánì ò fi ẹ̀mí ìgbéraga rẹ̀ mọ síbẹ̀ o. Látìgbà yẹn ló ti ń gbìyànjú láti tan gbogbo àwọn tó wà lọ́run àti láyé kí wọ́n lè máa sìn ín, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ̀yìn sí Jèhófà tó jẹ́ ọba aláṣẹ àgbáyé. Ó tiẹ̀ gbìyànjú láti tan Jésù Kristi jẹ pàápàá.—Mátíù 4:8-10; Ìṣípayá 12:3, 4, 9.
13. Àwọn ìṣòro wo ni ẹ̀mí ìrera ti dá sílẹ̀?
13 Èyí á jẹ́ kó o rí i pé ọ̀dọ̀ Sátánì gan-an ni ẹ̀mí ìrera ti bẹ̀rẹ̀. Ìrera yìí ló sì fa ẹ̀ṣẹ̀, ìyà àti ìwà ìbàjẹ́ tó gbòde kan lónìí. Sátánì tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” kò yéé gbin ẹ̀mí ìgbéraga àti ìrera sọ́kàn àwọn èèyàn. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Nítorí ó mọ̀ pé àkókò òun kúrú ló ṣe ń gbógun tàwọn Kristẹni tòótọ́. Ó fẹ́ kí wọ́n kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, kí wọ́n sì di olùfẹ́ ara wọn, ajọra-ẹni-lójú àti onírera. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò máa hu irú àwọn ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí.—2 Tímótì 3:1, 2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé NW; Ìṣípayá 12:12, 17.
14. Ọ̀nà wo ni Jèhófà máa ń gbà bá àwọn ẹ̀dá rẹ̀ láyé àti lọ́run lò?
14 Jésù Kristi ò fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ rárá nígbà tó ń sọ àkóbá tí ẹ̀mí ìrera Sátánì ti ṣe. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ó kéré tán, ni Jésù sọ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá aráyé lò, èyí sì jẹ́ níṣojú àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú ara wọn. Ohun tí Jésù sọ ni pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óò tẹ́ lógo, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”—Lúùkù 14:11; 18:14; Mátíù 23:12.
Má Ṣe Gba Ẹ̀mí Ìrera Láyè
15, 16. Kí ló mú kí Hágárì di onírera?
15 Tó o bá kíyè sí i, wàá rí i pé àwọn èèyàn ńlá làwọn tá a mẹ́nu kàn lókè yìí pé wọ́n jẹ́ onírera. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn gbáàtúù èèyàn ò lè di onírera ni? Rárá o. Wo ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lágboolé Ábúráhámù. Baba ńlá náà kò ní ọmọkùnrin kankan tó máa jogún rẹ̀, Sárà aya rẹ̀ ò sì lè bímọ mọ́ torí pé ó ti darúgbó. Àṣà wọn lásìkò náà ni pé kí ọkùnrin bíi ti Ábúráhámù tí aya rẹ̀ kò bá rọ́mọ bí fẹ́yàwó kejì kí ìyẹn lè bímọ fun un. Ọlọ́run fàyè gba irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ torí pé kò tíì tó àkókò tí yóò sọ fáwọn olùjọsìn tòótọ́ pé kí wọ́n tún padà sí ìlànà ọkọ kan aya kan tó ti wà látìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.—Mátíù 19:3-9.
16 Ábúráhámù ṣe ohun tí Sárà aya rẹ̀ sọ fún un nígbà tí ìyẹn rọ̀ ọ́ pé kó fi Hágárì ìránṣẹ́bìnrin òun tó jẹ́ ará Íjíbítì ṣe aya kí Ábúráhámù lè ní ajogún. Nígbà tí Hágárì di ìyàwó Ábúráhámù, ó lóyún. Ńṣe ló yẹ kó máa dúpẹ́ torí pé ó ti kúrò ní ìránṣẹ́ ó sì ti di ìyàwó báyìí. Àmọ́ ó jẹ́ kí ẹ̀mí ìrera gbilẹ̀ lọ́kàn òun. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ó wá mọ̀ pé òun ti lóyún, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ obìnrin wá di ẹni ìtẹ́ńbẹ́lú ní ojú rẹ̀.” Wàhálà tí ìwà ìgbéraga rẹ̀ yìí dá sílẹ̀ nílé Ábúráhámù pọ̀ débi pé ńṣe ni Sárà lé Hágárì lọ. Àmọ́, ohun kan wà tó yanjú ìṣòro yìí. Áńgẹ́lì Ọlọ́run gba Hágárì nímọ̀ràn pé: “Padà sọ́dọ̀ olúwa rẹ obìnrin kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 16:4, 9) Ó ṣe kedere pé Hágárì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ó yí ìwà rẹ̀ padà, ó sì di ìyá ńlá fún ògìdìgbó èèyàn.
17, 18. Kí nìdí tí gbogbo wà ò fi gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí ìrera láyè?
17 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hágárì yìí jẹ́ ká rí i pé èèyàn lè di agbéraga bí nǹkan bá dáa sí i fún èèyàn. Ẹ̀kọ́ tí èyí sì kọ́ wa ni pé Kristẹni tó ti ń fi ọkàn mímọ́ sin Ọlọ́run pàápàá lè di onírera tó bá dé ipò ọlá tàbí ipò agbára. Ó tún lè di agbéraga báwọn èèyàn bá ń pọ́n ọn lé nítorí ohun tó gbé ṣe, nítorí òye àti ọgbọ́n tó ní, tàbí nítorí ẹ̀bùn tó ní. Dájúdájú, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí ẹ̀mí ìrera má bàa gbilẹ̀ lọ́kàn wa. Kókó yìí ṣe pàtàkì gan-an pàápàá tí nǹkan bá dáa fún wa tàbí a ní ìtẹ̀síwájú kan.
18 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá ò fi gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí ìrera láyè ni pé Ọlọ́run kórìíra ìwà yìí gan-an. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ojú ìrera àti ọkàn-àyà ìṣefọ́nńté, fìtílà àwọn ẹni burúkú, ẹ̀ṣẹ̀ ni.” (Òwe 21:4) Àní, Bíbélì dìídì ṣèkìlọ̀ fáwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí” pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ “ọlọ́kàn-gíga,” tàbí “onírera.” (1 Tímótì 6:17, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Diutarónómì 8:11-17) Bákan náà, àwọn Kristẹni tí kì í ṣe ọlọ́rọ̀ kò gbọ́dọ̀ ní “ojú tí ń ṣe ìlara,” wọ́n sì ní láti rántí pé àtolówó àti tálákà ló lè ní ẹ̀mí ìgbéraga.—Máàkù 7:21-23; Jákọ́bù 4:5.
19. Báwo ni Ùsáyà ṣe ba gbogbo dáadáa tó ti ń ṣe bọ̀ jẹ́?
19 Ẹ̀mí ìrera àtàwọn ìwà búburú mìíràn lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa irú ìwà tí Ùsáyà Ọba ń hù nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí oyè. Bíbélì sọ pé: “Ó . . . ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà . . . Ó sì ń bá a lọ ní títẹ̀ sí wíwá Ọlọ́run . . . ; àti pé, ní àwọn ọjọ́ tí ó wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.” (2 Kíróníkà 26:4, 5) Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé ohun kan ba gbogbo dáadáa tí Ùsáyà Ọba ti ń ṣe bọ̀ látẹ̀yìnwá jẹ́. Ohun náà sì ni pé “ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun.” Ó jọ ara rẹ̀ lójú débi pé ó wọ inú tẹ́ńpìlì lọ láti sun tùràrí. Nígbà táwọn àlùfáà kìlọ̀ fún un pé kó má ṣe hùwà ìkùgbù yìí, ńṣe ni “Ùsáyà kún fún ìhónú.” Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ ọ́ di adẹ́tẹ̀, Ọlọ́run ò sì yọ́nú sí i títí tó fi kú.—2 Kíróníkà 26:16-21.
20. (a) Kí ló fẹ́rẹ̀ẹ́ ba gbogbo dáadáa tí Hesekáyà Ọba ti ń ṣe bọ̀ jẹ́? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwà Ùsáyà àti ti Hesekáyà Ọba. Nígbà kan, díẹ̀ ló kù kí gbogbo dáadáa tí ọba rere yìí ti ń ṣe bọ̀ látẹ̀yìnwá bà jẹ́ nítorí pé “ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera.” Àmọ́, ó dára tí “Hesekáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ìrera ọkàn-àyà rẹ̀,” Ọlọ́run sì tún yọ́nú sí i. (2 Kíróníkà 32:25, 26) Wàá rí i pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni oògùn ẹ̀mí ìrera Hesekáyà. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìrẹ̀lẹ̀ ni òdìkejì ìrera. Nítorí náà, nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a óò jíròrò bí àwa Kristẹni ṣe lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.
21. Kí lohun táwọn Kristẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lè máa retí lọ́jọ́ iwájú?
21 Àmọ́ o, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé gbogbo àkóbá tí ẹ̀mí ìrera ti ṣe. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera,” ẹ má ṣe jẹ́ ká gba ẹ̀mí ìgbéraga láyè rárá. Bí a ṣe ń sapá lójú méjèèjì láti jẹ́ Kristẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ẹ jẹ́ ká nírètí pé a óò rí ìgbàlà ní ọjọ́ ńlá Ọlọ́run, lákòókò táwọn onírera àti gbogbo ohun tí wọ́n dá sílẹ̀ kò ní sí mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà yẹn, “ìrera ará ayé yóò sì tẹrí ba, ìgafíofío àwọn ènìyàn yóò sì di rírẹ̀sílẹ̀; Jèhófà nìkan ṣoṣo sì ni a óò gbé ga ní ọjọ́ yẹn.”—Aísáyà 2:17.
Àwọn Kókó Tó Yẹ Ká Ṣàṣàrò Lé Lórí
• Irú ìwà wo làwọn onírera máa ń hù?
• Ibo ni ìrera ti bẹ̀rẹ̀?
• Kí ló lè sọ ẹnì kan di onírera?
• Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ gba ìrera láyè?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìrera Fáráò ló jẹ́ kó kàbùkù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bí Hágárì ṣe kúrò ní ìránṣẹ́ tó di ìyàwó ló mú kó máa gbéra ga
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Hesekáyà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, Ọlọ́run sì yọ́nú sí i