Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ Kristẹni kan lè ní ẹ̀rí ọkàn rere bó bá ń ṣe iṣẹ́ tó gba pé kó máa gbé ìbọn?

Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kò fọwọ́ kékeré mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ pé kí wọ́n pèsè àwọn nǹkan tara fún ìdílé wọn. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́ ṣá o, àwọn iṣẹ́ kan wà tó hàn gbangba pé ó ta ko ìlànà Bíbélì tó sì yẹ káwọn Kristẹni yàgò fún. Lára wọn ni iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú tẹ́tẹ́ títa, iṣẹ́ tó jẹ mọ́ lílo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tàbí iṣẹ́ tó ń fún àwọn èèyàn níṣìírí láti máa lo àwọn ohun tí wọ́n ń mú jáde láti ara tábà, irú bíi sìgá. (Aísáyà 65:11; Ìṣe 15:29; 2 Kọ́ríńtì 7:1; Kólósè 3:5) Àmọ́ àwọn iṣẹ́ kan wà tó jẹ́ pé bí Bíbélì ò tiẹ̀ sọ ní tààràtà pé wọ́n burú, wọ́n lè ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ náà tàbí ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn.

Fúnra èèyàn ni yóò pinnu bóyá kóun ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó gba kóun máa gbé ìbọn tàbí nǹkan ìjà mìíràn tàbí kóun má ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ tó gba kéèyàn máa gbé nǹkan ìjà lè múni jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bí wọ́n bá ké sí olúwarẹ̀ láti wá lo ohun ìjà náà. Nítorí náà, ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ ronú dáadáa kó sì gbàdúrà nípa kókó yìí, láti mọ̀ bóyá òun ṣe tán láti gba iṣẹ́ tó lè mú kóun ṣe ìpinnu pàjáwìrì tí ọ̀ràn náà bá ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí èèyàn. Gbígbé nǹkan ìjà dání tún lè mú kéèyàn fara pa tàbí kéèyàn tiẹ̀ kú pàápàá báwọn kan bá dojú ìjà kọni tàbí táwọn kan bá fẹ́ gbẹ̀san.

Bákan náà, ìpinnu téèyàn ṣe tún lè nípa lórí àwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, olórí iṣẹ́ tá a gbé lé àwọn Kristẹni lọ́wọ́ ni iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Ṣé èèyàn á lè kọ́ àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn” bí èèyàn fúnra rẹ̀ bá ń ṣe iṣẹ́ tó gba pé kó máa gbé nǹkan ìjà? (Róòmù 12:18) Àwọn ọmọ tàbí àwọn mìíràn nínú ìdílé ńkọ́? Ṣé níní ìbọn nínú ilé kò lè fi ẹ̀mí wọn sínú ewu? Yàtọ̀ síyẹn, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ọwọ́ téèyàn fi mú ọ̀ràn yìí mú àwọn mìíràn kọsẹ̀?—Fílípì 1:10.

Lákòókò òpin yìí, ńṣe làwọn èèyàn tó jẹ́ “òǹrorò” àti “aláìní ìfẹ́ ohun rere” túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (2 Tímótì 3:1, 3) Níwọ̀n ìgbà tí ẹnì kan bá sì ti mọ èyí, ǹjẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ aláìní “ẹ̀sùn lọ́rùn” bó bá lọ ń ṣe iṣẹ́ tó gba pé kó máa gbé ohun ìjà, èyí tó lè mú kóun àtàwọn èèyànkéèyàn yẹn dojú ìjà kọra wọn? (1 Tímótì 3:10) Rárá o. Fún ìdí yìí, ìjọ Kristẹni kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí “aláìlẹ́gàn” bó bá ṣì ń gbé ohun ìjà lẹ́yìn tí wọ́n ti fún un nímọ̀ràn tìfẹ́tìfẹ́ látinú Bíbélì. (1 Tímótì 3:2; Títù 1:5, 6) Nípa bẹ́ẹ̀, irú ọkùnrin tàbí obìnrin bẹ́ẹ̀ kò lè ní àwọn àkànṣe àǹfààní nínú ìjọ.

Jésù mú un dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé bí wọ́n bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn, kò sídìí fún wọn láti bẹ̀rù nípa bí wọ́n ṣe máa rí àwọn ohun kòṣeémánìí tí wọ́n nílò nígbèésí ayé wọn. (Mátíù 6:25, 33) Ó dájú pé, bí a bá gbọ́kàn wa lé Jèhófà pátápátá, ‘òun fúnra rẹ̀ yóò gbé wa ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.’—Sáàmù 55:22.