Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run fún Mi Ní ‘Ohun Tí Ọkàn Mi Ń Fẹ́’

Ọlọ́run fún Mi Ní ‘Ohun Tí Ọkàn Mi Ń Fẹ́’

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ọlọ́run fún Mi Ní ‘Ohun Tí Ọkàn Mi Ń Fẹ́’

GẸ́GẸ́ BÍ DOMINIQUE MORGOU ṢE SỌ Ọ́

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo gúnlẹ̀ sílẹ̀ Áfíríkà ní oṣù December ọdún 1998! Ohun tó sì ti ń wù mí láti kékeré lọwọ́ mi tẹ̀ yìí. Ó ti pẹ́ táwọn ilẹ̀ tó fẹ̀ lọ salalu nílẹ̀ Áfíríkà àtàwọn ẹranko ìgbẹ́ ibẹ̀ tó fani mọ́ra ti máa ń wù mí gan-an. Mo sì ti wá wà níbẹ̀ báyìí! Yàtọ̀ síyẹn, ohun mìíràn tó ti ń wù mí tipẹ́tipẹ́ tún tẹ̀ mí lọ́wọ́. Ajíhìnrere alákòókò-kíkún tó ń sìn nílẹ̀ òkèèrè ni mí. Èyí lè dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Ìdí ni pé ojú mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́ tán, ajá tó sì ń fi afọ́jú mọ̀nà tó jẹ́ pé àwọn òpópónà ìlú ńlá ilẹ̀ Yúróòpù ni wọ́n dá a lẹ́kọ̀ọ́ láti máa rìn ló ń mú mi rìn láwọn òpópónà oníyanrìn ilẹ̀ Áfíríkà. Jẹ́ kí n sọ bí sísìn nílẹ̀ Áfíríkà ṣe wá di ohun tó ṣeé ṣe fún mi àti bí Jèhófà ṣe fún mi ní ‘àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́.’—Sáàmù 37:4.

ỌJỌ́ kẹsàn-án oṣù June, ọdún 1966 ni wọ́n bí mi, lápá gúúsù ilẹ̀ Faransé. Èmi làbíkẹ́yìn nínú ọmọ méje táwọn òbí mi bí, ìyẹn ọmọkùnrin méjì àti ọmọbìnrin márùn-ún, gbogbo wa sì làwọn òbí wa tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ tọ́ dáadáa. Àmọ́ ohun kan wà tó jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Mo ní àìsàn kan tí ìyá ìyá mi, ìyá mi, àti ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ní. Àìsàn tí mo jogún yìí ló wá sọ mi di afọ́jú pátápátá nígbà tó yá.

Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, àwọn nǹkan tójú mi rí mú mi ya aláìgbọràn ọmọ láwùjọ. Àwọn nǹkan náà ni ìwà bíi ẹ̀yà tèmi lọ̀gá, ẹ̀tanú àti ìwà àgàbàgebè táwọn èèyàn máa ń hù. Àárín àkókò tí nǹkan ò rọgbọ fún mi yìí la kó lọ sí àdúgbò kan tó ń jẹ́ Hérault. Ibẹ̀ ni nǹkan àgbàyanu kan ti ṣẹlẹ̀.

Láàárọ̀ ọjọ́ Sunday kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sílé wa. Màmá mi ti mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀ ó sì ní kí wọ́n wọlé. Ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà béèrè lọ́wọ́ màmá mi bóyá ó rántí pé òun ti ṣèlérí nígbà kan pé òun máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó bá yá. Màmá mi rántí, ló bá bi obìnrin náà pé, “Ìgbà wo ni ká bẹ̀rẹ̀?” Wọ́n jọ gbà láti máa ṣe é láràárọ̀ ọjọ́ Sunday, bí màmá mi sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ “òtítọ́ ìhìn rere” nìyẹn.—Gálátíà 2:14.

Bí Mo Ṣe Dẹni Tó Ní Ìjìnlẹ̀ Òye

Màmá mi sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun lóye ohun tóun ń kọ́, òun ò sì gbàgbé wọn. Nítorí pé kò ríran, ó ní láti há gbogbo ohun tó ń kọ́ sórí. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ní sùúrù fún un gan-an. Àmọ́ ńṣe lèmi máa ń sá pa mọ́ sínú yàrá táwọn Ẹlẹ́rìí yẹn bá ti dé, ìgbà tí wọ́n bá sì lọ ni màá tó jáde síta. Àmọ́ lọ́sàn-án ọjọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà tó ń jẹ́ Eugénie ká mi mọ́, ó sì bá mi sọ̀rọ̀. Ó sọ fún mi pé Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo àgàbàgebè, ìkórìíra àti ẹ̀tanú tó wà láyé. Ó ní: “Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè yanjú àwọn ìṣòro náà.” Ó sì bi mí pé ṣe màá fẹ́ láti mọ̀ sí i? Ọjọ́ kejì ni mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Gbogbo nǹkan tí mò ń kọ́ pátápátá ló ṣàjèjì sí mi. Mo wá lóye pé tìtorí àwọn ìdí pàtàkì kan ni Ọlọ́run ṣe fàyè gba àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, àti pé fúngbà díẹ̀ ni. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Jòhánù 3:16; Róòmù 9:17) Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà kò fi wá sílẹ̀ láìní ìrètí. Ó ti ṣe ìlérí ohun kan tó jẹ́ àgbàyanu fún wa, ìyẹn ni ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; 96:11, 12; Aísáyà 35:1, 2; 45:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́ tán nígbà yẹn, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé màá padà ríran kedere nínú Párádísè yẹn.—Aísáyà 35:5.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò-Kíkún

Lọ́jọ́ kejìlá oṣù December ọdún 1985, mo ṣèrìbọmi láti fi ẹ̀rí hàn pé mo ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà bíi ti ẹ̀gbọ́n mi Marie-Claire tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣáájú mi. Kò sí pẹ́ tí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, Jean-Pierre, àti màmá mi ọ̀wọ́n náà ṣèrìbọmi.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tá a tún mọ̀ sáwọn ajíhìnrere alákòókò-kíkún pọ̀ gan-an nínú ìjọ tí mo wà. Ayọ̀ wọn àti ìtara tí wọ́n ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà wú mi lórí. Kódà, ẹ̀gbọ́n mi Marie-Claire tí ojú ń yọ lẹ́nu, tí irin tó ń gbé eegun dúró sì tún wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Títí dòní ni àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣì ń fún mi níṣìírí nínú iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà. Báwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe yí mi ká nínú ìjọ àti nínú ìdílé mi jẹ́ kó wu èmi náà gan-an láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Nítorí náà, lóṣù November ọdún 1990, mo bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà nílùú Béziers—Sáàmù 94:17-19.

Bí Mo Ṣe Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì

Nígbà tí mo bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwọn aṣáájú-ọ̀nà yòókù máa ń ràn mí lọ́wọ́, wọn kì í fi mí sílẹ̀. Síbẹ̀, mo máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni mo lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, ó sì máa ń wù mí pé kí n túbọ̀ lè ṣe sí i. Àmọ́, Jèhófà mẹ́sẹ̀ mi dúró ní gbogbo àkókò tí mo ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì yìí. Mo yẹ ìwé atọ́ka tá a mọ̀ sí Watch Tower Publications Index wò láti wá ìtàn ìgbésí ayé àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọn kò ríran dáadáa bíi tèmi. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ! Àwọn ìtàn tó ń gbéni ró tó sì ń ranni lọ́wọ́ yìí kọ́ mi láti mọyì ìwọ̀nba ohun tí mo lè ṣe, kí n sì fara mọ́ ipò mi.

Kí n lè máa rí owó láti ra àwọn ohun tí mo nílò, mo ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn láwọn ibi tí ṣọ́ọ̀bù ìtajà pọ̀ sí. Lọ́jọ́ kan, mo ṣàkíyèsí pé àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tún ń padà lọ ṣàtúnṣe àwọn ibi tí mo ti ṣe. Kò sí àní-àní pé ojú mi ń fo ọ̀pọ̀ ìdọ̀tí. Ni mo bá lọ bá Valérie, ìyẹn aṣáájú-ọ̀nà tó ń ṣàbójútó àwa tá a ń ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó náà, mo sì ní kó má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ o, kó jẹ́ kí n mọ̀ tí n bá ń mú nǹkan nira fáwọn tó kù. Ó fìfẹ́ sọ fún mi pé kí n fúnra mi pinnu tí n bá rí i pé mi ò lè ṣiṣẹ́ náà mọ́. Oṣù March ọdún 1994 ni mo fi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀.

Bí ìbànújẹ́ tún ṣe dorí mi kodò nìyẹn, tí èrò pé mi ò wúlò rárá sì gba gbogbo ọkàn mi. Mo fi gbogbo ọkàn mi gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì mọ̀ pé ó gbọ́ àdúrà ẹ̀bẹ̀ mi. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé Kristẹni tún ràn mí lọ́wọ́ gan-an lákòókò yìí. Àmọ́ o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú tó ń yọ mí lẹ́nu túbọ̀ ń burú sí i, síbẹ̀ ńṣe ni ìfẹ́ ọkàn mi láti sin Jèhófà ń lágbára sí i. Kí wá ni mo lè ṣe?

Mo Kọ́kọ́ Ní Láti Dúró Díẹ̀, Lẹ́yìn Náà Mo Ṣèpinnu Pàjáwìrì

Mo kọ̀wé sí Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèrànwọ́ Fáwọn Afọ́jú Àtàwọn Tí Kò Ríran Dáadáa ní ìlú Nîmes pé mo fẹ́ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́, nígbà tó yá wọ́n gbà mí síbẹ̀ fún oṣù mẹ́ta. Àkókò tí mo lò níbẹ̀ ṣàǹfààní gan-an. Mo wá lóye bí ìṣòro mi ṣe tóbi tó mo sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí mo ṣe lè máa bá ipò náà yí. Wíwà láàárín àwọn èèyàn tó ní oríṣiríṣi àléébù ara jẹ́ kí n túbọ̀ wá rí i bí ìrètí tí mo ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ṣe ṣeyebíye tó. Ó kéré tán, mo ní ohun gúnmọ́ tí mò ń lé mo sì lè fayé mi ṣe ohun tó nítumọ̀. Bákan náà ni mo tún kọ́ bí wọ́n ṣe ń ka ìwé àwọn afọ́jú lédè Faransé.

Nígbà tí mo padà sílé, àwọn èèyàn mi ṣàkíyèsí pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Àmọ́ ohun kan tínú mi ò dùn sí rárá ni ti igi funfun kékeré kan tí wọ́n ní kí n máa lò. Ó ṣòro fún mi gan-an láti gbà láti lo ọ̀pá yẹn. Ká ní mo lè rí nǹkan mìíràn ni, inú mi ì bá dùn. Bó bá ṣeé ṣe, kí n rí ajá tó ń fi àwọn afọ́jú mọ̀nà.

Bí mo ṣe lọ forúkọ sílẹ̀ nìyẹn pé mo fẹ́ ajá kan, wọ́n sì sọ fún mi pé àwọn tó ti forúkọ sílẹ̀ ti pọ̀ gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, àjọ tó ń fúnni lájá yìí yóò ṣèwádìí nípa ẹni tó ń fẹ́ ajá náà. Wọn kì í kàn fún ẹnikẹ́ni lájá afinimọ̀nà. Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan tó ń darí ẹgbẹ́ kan tó wà fáwọn afọ́jú sọ fún mi pé ẹgbẹ́ àwọn tó ń gbá bọ́ọ̀lù orí tábìlì ní ajá kan tí wọ́n fẹ́ fi tọrẹ fún afọ́jú kan tàbí ẹnì kan tí ojú ẹ̀ kò ríran dáadáa lágbègbè wa. Ó sọ pé ọ̀dọ̀ mi lọkàn òun lọ. Ó sì bi mí pé ṣé mo fẹ́? Mo rí i pé Jèhófà lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ mo sì sọ fún un pé mo fẹ́. Àmọ́ màá ṣì ní láti dúró díẹ̀ kí n tó lè rí ajá náà gbà.

Èrò Nípa Áfíríkà Kò Kúrò Lọ́kàn Mi

Bí mo ṣe ń dúró kí ajá náà dé, mo gbọ́kàn mi sórí nǹkan mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, láti kékeré ni mo ti nífẹ̀ẹ́ sílẹ̀ Áfíríkà gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi túbọ̀ ń burú sí i, síbẹ̀ ìfẹ́ yẹn kò dín kù rárá, àgàgà nígbà tí mo ti gbọ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì nílẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n sì máa ń fẹ́ láti sin Jèhófà. Mo ti sọ létí Valérie rí pé ó wù mí láti lọ ṣèbẹ̀wò sílẹ̀ Áfíríkà. Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé á bá mi lọ? Ó gbà, a sì kọ̀wé sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi mélòó kan tó ń sọ èdè Faransé nílẹ̀ Áfíríkà.

Èsì dé láti ilẹ̀ Tógò. Inú mi dùn gan-an, mo sì ní kí Valérie ka èsì náà sí mi létí. Lẹ́tà náà fún wa níṣìírí láti wá, Valérie sì sọ pé: “Bó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ ká lọ nígbà náà.” Lẹ́yìn tá a kọ̀wé sáwọn arákùnrin ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ níbẹ̀, wọ́n ní kí n kàn sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sandra, tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà nílùú Lomé tí í ṣe olú ìlú Tógò. A fi ọjọ́ tá a máa gbéra sí ọjọ́ kìíní oṣù December ọdún 1998.

Lẹ́yìn tí ọkọ̀ òfuurufú wa balẹ̀ nílùú Lomé tá a sì sọ̀ kalẹ̀, bíìgbà téèyàn da aṣọ bora ni ooru ilẹ̀ Áfíríkà ṣe bò wá. Ibí yìí yàtọ̀ pátápátá síbi tá a ti wá, àmọ́ inú wa dùn gan-an! Sandra wá pàdé wa. A ò rí ara wa rí o, àmọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ yẹn la dà bí àwọn ọ̀rẹ́ tó ti mọra wọn tipẹ́tipẹ́. Ó kù díẹ̀ ká wá sí Tógò ni wọ́n yan Sandra àti ẹnì kejì rẹ̀ tó ń jẹ́ Christine gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sílùú Tabligbo, ìyẹn ìlú kékeré kan ní ìgbèríko. A sì wá láǹfààní láti bá wọn lọ síbi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún wọn náà láti lọ máa wàásù. Nǹkan bí oṣù méjì la lò, nígbà tá a sì kúrò, mo mọ̀ pé mo ṣì tún máa padà wá.

Inú Mi Dùn Gan-an Pé Mo Tún Padà Wá

Bí mo ṣe ń dé orílẹ̀-èdè Faransé padà ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí palẹ̀ mọ́ láti tún lọ sílẹ̀ Tógò lẹ́ẹ̀kejì. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ará ilé mi, ó ṣeé ṣe fún mi láti ṣe àwọn ètò tó máa jẹ́ kí n lè wà níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà. Nítorí náà, nígbà tó di oṣù September ọdún 1999, mo tún ti wà nínú ọkọ̀ òfuurufú tó ń lọ sílẹ̀ Tógò. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, èmi nìkan ni. Ẹ lè fojú inú wo bó ṣe rí lára àwọn èèyàn mi bí wọ́n ṣe rí i témi nìkan ń dá lọ pẹ̀lú bí mo ṣe jẹ́ aláàbọ̀ ara! Àmọ́ kò sídìí fún wọn láti bẹ̀rù rárá. Mo fi dá àwọn òbí mi lójú pé àwọn ọ̀rẹ́ mi, tí wọ́n ti dà bí ìdílé mi yóò ti máa dúró dè mí nílùú Lomé.

Inú mi dùn gan-an pé mo tún lè padà wá sí àgbègbè tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ti fẹ́ láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì yìí! Kì í ṣe nǹkan àjèjì láti rí àwọn èèyàn kí wọ́n máa ka Bíbélì ní òpópó ọ̀nà. Ní Tabligbo, ńṣe làwọn èèyàn máa ń pè wá pé ká wá báwọn jíròrò látinú Bíbélì. Àǹfààní ńláǹlà ló sì jẹ́ láti máa gbé nínú ilé kékeré kan pẹ̀lú àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe! Mo wá túbọ̀ mọ̀ nípa àṣà ìbílẹ̀ mìíràn, ìyẹn ni pé mo wá ń rí àwọn nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, mo kíyè sí i pé ipò kìíní làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nílẹ̀ Áfíríkà fi iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà sí nínú ìgbésí ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè ní láti rin ọ̀pọ̀ kìlómítà kí wọ́n tó dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn kò dí wọn lọ́wọ́ àtiwá sípàdé. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ gan-an látinú ìfẹ́ tí wọn ní àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣe aájò àlejò.

Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo ń bọ̀ láti òde ẹ̀rí, mo sọ fún Sandra pé ẹ̀rù ń bà mí láti padà sílẹ̀ Faransé. Ojú tó ń yọ mí lẹ́nu ti burú sí i gan-an. Mo ronú nípa bí àwọn òpópónà ìlú Béziers ṣe máa ń kún fún èrò àti ariwo, mo tún ronú nípa àtẹ̀gùn àwọn ilé onípẹ̀tẹ́ẹ̀sì àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn tó máa ń mú kí ìgbésí ayé ṣòro fún ẹni tí kò bá ríran dáadáa. Àmọ́ àwọn òpópónà ìlú Tabligbo kò rí bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò da ọ̀dà sí wọn, kò sí ariwo, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èrò rẹpẹtẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀. Báwo ló ṣe máa ṣeé ṣe fún mi láti gbé nílẹ̀ Faransé ní báyìí tí ìlú Tabligbo ti mọ́ mi lára?

Ọjọ́ kẹta ni màmá mi pè mí lórí fóònù láti sọ fún mi pé ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń dá àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń dúró dè mí. Ajá ńlá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Océane ti wà ní sẹpẹ́ láti máa mú mi kiri. Lọ́tẹ̀ yìí, Jèhófà tún pèsè ohun tí mo nílò fún mi, ẹ̀rù tó ń bà mí sì pòórá. Lẹ́yìn tí mo ti ṣe iṣẹ́ ìsìn tó fún mi láyọ̀ nílùú Tabligbo fún oṣù mẹ́fà, mo padà sílẹ̀ Faransé láti lọ mọ Océane.

Lẹ́yìn tí wọ́n fún mi ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ oṣù bíi mélòó kan, wọ́n fa Océane lé mi lọ́wọ́. Kò kọ́kọ́ rọrùn níbẹ̀rẹ̀. A ní láti mọ́wọ́ ara wa ná. Àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo wá rí i pé mo nílò Océane gan-an. Kí n sòótọ́, bí ìgbín bá fà karawun á tẹ̀ lé e lọ̀rọ̀ èmi àti Océane báyìí. Báwo làwọn èèyàn ìlú Béziers ṣe máa ń ṣe tí wọ́n bá rí i tí èmi àti ajá ń bọ̀ nílé wọn? Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún mi gan-an wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn sí mi. Océane wá di ohun táwọn ará àdúgbò ń pé wò. Níwọ̀n bí ara ọ̀pọ̀ èèyàn kò ti máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ aláàbọ̀ ara, níní tí mo ní ajá yìí jẹ́ kí n lè sọ̀rọ̀ nípa àléébù mi láìtijú. Àwọn èèyàn máa ń fara balẹ̀ dáadáa wọ́n sì máa ń tẹ́tí sí mi. Àní, Océane wá jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn.

Èmi àti Océane Nílẹ̀ Áfíríkà

Mi ò gbàgbé ilẹ̀ Áfíríkà, bí mo sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí múra fún ìrìn àjò mi ẹlẹ́ẹ̀kẹta nìyẹn. Lọ́tẹ̀ yìí, èmi àti Océane la jọ lọ. Anthony àti Aurore bá mi lọ, tọkọtaya ni wọ́n, kò sì tíì pẹ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó. Ọ̀rẹ́ mi tó ń jẹ́ Caroline náà bá mi lọ pẹ̀lú. Aṣáájú-ọ̀nà bíi tèmi ni gbogbo wọn. Ọjọ́ kẹwàá oṣù September ọdún 2000 la gúnlẹ̀ sí ìlú Lomé.

Ẹ̀rù Océane kọ́kọ́ ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn èèyàn tó ti rí irú ajá tó tóbi tó bẹ́ẹ̀ yẹn rí kò pọ̀ ní Lomé, nítorí pé àwọn ajá ilẹ̀ Tógò sábà máa ń kéré. Èrò àwọn kan nígbà tí wọ́n bá rí ìjánu rẹ̀ ni pé ajá kan tó roro ni àti pé èyí ló mú kí wọ́n so ìjánu mọ́ ọn lọ́rùn. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ajá kan tí kò gba gbẹ̀rẹ́ ni Océane, ó máa ń múra tán láti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ohunkohun tó bá kà sí ewu. Síbẹ̀, kò pẹ́ tí àyíká tuntun yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí mọ́ Océane lára. Tí ìjánu bá wà lọ́rùn rẹ̀, ẹnu iṣẹ́ ló wà yẹn, kì í gba gbẹ̀rẹ́, ó mọ iṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, ẹ̀gbẹ́ mi ló sì máa ń wà. Àmọ́ nígbà tí kò bá sí ìjánu lọ́rùn rẹ̀, ó máa ń ṣeré gan-an, kódà ó máa ń ṣèjàngbọ̀n nígbà míì. A jọ máa ń ṣeré gan-an ni.

Ọ̀dọ̀ Sandra àti Christine nílùú Tabligbo ni wọ́n ní kí gbogbo wa dé sí. Kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lè mojú Océane, a máa ń ní kí wọ́n wá sọ́dọ̀ wa, a sì máa ń ṣàlàyé iṣẹ́ tí ajá afinimọ̀nà máa ń ṣe, ìdí tí mo fi nílò rẹ̀, àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá wà nítòsí rẹ̀. Àwọn alàgbà gbà kí Océane máa bá mi wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nítorí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣàjèjì nílẹ̀ Tógò, wọ́n ṣe ìfilọ̀ kan nínú ìjọ láti ṣàlàyé kókó yìí fún àwọn ará. Ní ti iṣẹ́ ìwàásù, ìgbà tí mo bá ń lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí tí mo bá ń lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ni Océane máa ń bá mi lọ, nítorí pé yóò rọrùn fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ láti lóye ìdí tó fi wà pẹ̀lú mi.

Iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe ní ìpínlẹ̀ yìí ń múnú mi dùn gan-an. Ìgbà gbogbo ni ẹ̀mí ìgbatẹnirò àwọn èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tó wà níbí yìí máa ń wú mi lórí. Èyí máa ń hàn nínú ìwà wọn, irú bí wọ́n ṣe máa ń yára gbé àga fún mi láti jókòó. Lóṣù October ọdún 2001, nígbà ìrìn àjò mi kẹrin sílẹ̀ Tógò, màmá mi bá mi wá. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ló lò kó tó padà sílẹ̀ Faransé, inú rẹ̀ dùn ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pé kò séwu fún mi.

Mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ṣeé ṣe fún mi láti lọ sìn nílẹ̀ Tógò. Ó dá mi lójú pé Jèhófà yóò máa fún mi ní ‘àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́’ bí mo ṣe ń bá a lọ láti lo gbogbo ohun tí mo ní nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Arábìnrin Morgou padà sílẹ̀ Faransé ó sì ṣeé ṣe fún un láti tún wá sílẹ̀ Tógò ní ìgbà karùn-ún, láàárín ọjọ́ kẹfà oṣù October ọdún 2003 sí ọjọ́ kẹfà oṣù February ọdún 2004. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, ìrìn àjò yẹn lè jẹ́ ìgbà tó máa lọ sílẹ̀ Tógò kẹ́yìn nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí nítorí àìlera rẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó ń wù ú lọ́kàn jù ni pé kó lè máa sin Jèhófà nìṣó.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ó ti pẹ́ táwọn ilẹ̀ tó fẹ̀ lọ salalu nílẹ̀ Áfíríkà àtàwọn ẹranko ìgbẹ́ ibẹ̀ tó fani mọ́ra ti máa ń wù mí gan-an

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Océane máa ń bá mi lọ sí ìpadàbẹ̀wò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn alàgbà gbà kí n máa mú Océane wá sípàdé