Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Wa

Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Wa

Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Wa

“Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.”—SÁÀMÙ 23:1.

1-3. Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì fi Jèhófà wé?

 TÍ WỌ́N bá sọ pé kó o ṣàlàyé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀, kí lo máa sọ? Àfiwé wo lo lè lò láti jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́? Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, Dáfídì Ọba ṣàpèjúwe Jèhófà lọ́nà tó dára gan-an nínú sáàmù kan, ó lo àfiwé kan tó bá iṣẹ́ tó ṣe nígbà tó wà lọ́mọdé mu.

2 Olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì nígbà tó wà lọ́mọdé. Ìdí nìyẹn tó fi mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn. Ó mọ̀ dájú pé téèyàn ó bá bójú tó àwọn àgùntàn dáadáa, wọ́n lè sọnù kí wọ́n sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà tàbí kí ẹranko búburú pa wọ́n jẹ. (1 Sámúẹ́lì 17:34-36) Tí kò bá sí olùṣọ́ àgùntàn kan tó bìkítà dáadáa lọ́dọ̀ wọn, àwọn àgùntàn náà lè máà rí pápá tí wọ́n á ti jẹun bó ṣe wù wọ́n. Nígbà tí Dáfídì darúgbó, ó dájú pé tayọ̀tayọ̀ ló fi máa ń rántí ọ̀pọ̀ wákàtí tó fi máa ń da àwọn àgùntàn, tó fi ń dáàbò bò wọ́n, tó sì fi máa ń fún wọn lóúnjẹ.

3 Abájọ tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló wá sí Dáfídì lọ́kàn nígbà tí Ọlọ́run mí sí i láti sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. Sáàmù kẹtàlélógún tí Dáfídì kọ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.” Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tí gbólóhùn yìí fi bá a mú wẹ́kú. Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sáàmù ẹtàlélógún, a óò rí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bójú tó àwọn olùjọsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀.—1 Pétérù 2:25.

Àfiwé Tó Bá A Mu Wẹ́kú

4, 5. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe irú ẹran tí àgùntàn jẹ́?

4 Ọ̀pọ̀ orúkọ oyè la fi pe Jèhófà nínú Ìwé Mímọ́, àmọ́ orúkọ náà, “Olùṣọ́ Àgùntàn” wà lára èyí tó fi ẹ̀mí jẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn jù lọ. (Sáàmù 80:1) Tá a bá fẹ́ túbọ̀ lóye ìdí tí pípè tá a pe Jèhófà ní Olùṣọ́ Àgùntàn fi bá a mú wẹ́kú, yóò dára ká mọ àwọn ohun méjì kan: ohun àkọ́kọ́, ìwà àwọn àgùntàn àti ohun kejì, iṣẹ́ àti àwọn ànímọ́ olùṣọ́ àgùntàn rere.

5 Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn àgùntàn ṣe máa ń ṣe, ó ní wọ́n máa ń sún mọ́ olùṣọ́ àgùntàn tó bá fìfẹ́ hàn sí wọn (2 Sámúẹ́lì 12:3), wọ́n máa ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ (Aísáyà 53:7), wọn ò sì lè dáàbò bo ara wọn. (Míkà 5:8) Òǹkọ̀wé kan tó sin àgùntàn fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Àwọn àgùntàn ò lè fúnra wọn bójú tó ara wọn báwọn kan ṣe rò. Nínú gbogbo ohun ọ̀sìn, àwọn ló fẹ́ àbójútó jù lọ tí wọ́n sì nílò ìtọ́jú tó jíire.” Olùṣọ́ àgùntàn kan tó bìkítà dáadáa ní láti bójú tó àwọn ẹran tí kò lè dáàbò bo ara wọn yìí kí wọ́n má bàa kú.—Ìsíkíẹ́lì 34:5.

6. Báwo ni ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì kan ṣe ṣàlàyé iṣẹ́ tí olùṣọ́ àgùntàn kan láyé ọjọ́hun máa ń ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan?

6 Iṣẹ́ wo ni olùṣọ́ àgùntàn ayé ìgbàanì máa ń ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan? Ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì kan ṣàlàyé pé: “Ní òwúrọ̀ kùtù hàì, olùṣọ́ àgùntàn á kó àgùntàn rẹ̀ kúrò níbi tí wọ́n wà, á sì kó wọn lọ síbi tí wọ́n ti máa jẹko. Ibí yìí ló máa wà tá a máa bójú tó wọn látàárọ̀ ṣúlẹ̀, yóò rí i dájú pé kò sí èyí tó ṣáko lọ nínú wọn, tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan ṣèèṣì rìn gbéregbère kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó kù, kò síbi tí olùṣọ́ àgùntàn náà ò ní wá a dé títí tó fi máa rí i tá a sì gbé e padà wá bá àwọn yòókù. . . . Tó bá dalẹ́, á kó agbo ẹran náà padà sọ́gbà ẹran, á máa kà wọ́n bí wọ́n ṣe ń wọlé lọ́kọ̀ọ̀kan láti rí i dájú pé kò sí èyí tó sọnù lára wọn. . . . Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń fi gbogbo òru ṣọ́ ọgbà ẹran náà káwọn ẹranko búburú má bàa pa wọ́n jẹ, tàbí káwọn olè má bàa jí wọn gbé.” a

7. Kí nìdí tí olùṣọ́ àgùntàn fi nílò sùúrù tó pọ̀ kó sì tún jẹ́ oníwà tútù?

7 Àwọn ìgbà mìíràn wà táwọn àgùntàn máa ń fẹ́ àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, àgàgà àwọn tó lóyún lára wọn àtàwọn ọmọ wẹ́wẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 33:13) Ìwé kan tó ṣàlàyé nípa Bíbélì sọ pé: “Ibi tó jìnnà gan-an tó sì tún jẹ́ ẹ̀gbẹ́ òkè ni àgùntàn sábà máa ń bímọ sí. Olùṣọ́ àgùntàn máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti dáàbò bo àgùntàn tó ń bímọ yìí, yóò wá bẹ̀rẹ̀ gbé ọmọ àgùntàn náà wá sáàárín agbo. Gbígbé ni yóò máa gbé ọmọ àgùntàn náà fún ọjọ́ bíi mélòó kan kó tó di pé ọmọ àgùntàn náà lè dá rìn fúnra rẹ̀. Ó lè gbé e lé apá rẹ̀ tàbí kó gbé e sí apá ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀.” (Aísáyà 40:10, 11) Ó hàn gbangba pé olùṣọ́ àgùntàn rere gbọ́dọ̀ lágbára kó sì tún jẹ́ oníwà tútù.

8. Àwọn ìdí wo ni Dáfídì sọ pé ó jẹ́ kóun nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà?

8 “Jèhófà ni olùṣọ́ àgùntàn mi.” Ǹjẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti ṣàpèjúwe Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ kọ́ nìyẹn? Bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò Sáàmù kẹtàlélógún, a óò rí ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà bójútó wa bíi ti olùṣọ́ àgùntàn tó ń fi okun àti ẹ̀mí sùúrù bójú tó àwọn àgùntàn. Ní Sm 23 ẹsẹ kìíní, Dáfídì fi hàn pé òun ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run pé yóò pèsè gbogbo ohun táwọn àgùntàn Rẹ̀ nílò débi pé wọ́n kò ní “ṣaláìní nǹkan kan.” Nínú àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, Dáfídì mẹ́nu kan ìdí mẹ́ta tó fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé yìí, àwọn ìdí náà ni pé: Jèhófà máa ń ṣamọ̀nà àwọn àgùntàn Rẹ̀, ó máa ń dáàbò bò wọ́n, ó sì máa ń bọ́ wọn. Ẹ jẹ́ ká jíròrò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan.

“Ó Ń Ṣamọ̀nà Mi”

9. Ipò àìléwu wo ni Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, báwo sì làwọn àgùntàn ṣe lè bára wọn nínú irú ipò bẹ́ẹ̀?

9 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, Jèhófà ń ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko; ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa. Ó ń tu ọkàn mi lára. Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.” (Sáàmù 23:2, 3) Nígbà tí Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa agbo ẹran tó dùbúlẹ̀ láìséwu láàárín ọ̀pọ̀-yanturu oúnjẹ, ńṣe ló ń fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣàpèjúwe àwọn èèyàn tọ́kàn wọn balẹ̀, tí ara tù wọ́n, tí wọ́n sì wà lábẹ́ ààbò. Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “pápá ìjẹko” tún lè túmọ̀ sí “ibi tó tura.” Ó lè má rọrùn fáwọn àgùntàn yẹn láti fúnra wọn rí ibi kan tó tura tí wọ́n lè dùbúlẹ̀ sí láìséwu. Olùṣọ́ àgùntàn wọn ló máa ṣamọ̀nà wọn lọ sírú “ibi tó tura” bẹ́ẹ̀.

10. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń fi hàn pé òun fọkàn tán wa?

10 Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣamọ̀nà wa lónìí? Ọ̀nà kan tó gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ nípa àpẹẹrẹ tó ń fi lélẹ̀ fún wa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá láti “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfésù 5:1) Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ yẹn ká mẹ́nu kan ìyọ́nú, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ìfẹ́. (Éfésù 4:32; 5:2) Dájúdájú, Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ nínú fífi irú àwọn ànímọ́ tó dára bẹ́ẹ̀ hàn. Ṣé ohun tó ju agbára wa lọ ló ní ká ṣe nígbà tó sọ pé ká fara wé òun? Rárá o. Ìmọ̀ràn onímìísí yẹn jẹ́ ọ̀nà àgbàyanu tó gbà fi hàn pé òun fọkàn tán wa. Lọ́nà wo? Àwòrán Ọlọ́run ni a dá wa, tó túmọ̀ sí pé a ní àwọn ànímọ́ rere a sì ní làákàyè láti ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Nítorí náà, Jèhófà mọ̀ pé bá a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe fún wa láti ní àwọn ànímọ́ tóun fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀. Ìwọ rò ó wò ná, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ mọ̀ dájú pé a lè dà bí òun. Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, yóò darí wa lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ lọ sí “ibi ìsinmi” tó tuni lára. Nínú ayé tó kún fún ìwà ipá yìí, a ó “máa gbé nínú ààbò,” a ó sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní nígbà tó bá mọ̀ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba òun.—Sáàmù 4:8; 29:11.

11. Nígbà tí Jèhófà bá ń darí àwọn èèyàn rẹ̀, kí ló máa ń wò, báwo lèyí sì ṣe máa ń hàn nínú ohun tó fẹ́ ká ṣe?

11 Nígbàkigbà tí Jèhófà bá ń darí wa, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti pẹ̀lú sùúrù. Olùṣọ́ àgùntàn kan máa ń ronú nípa ibi tí agbára àwọn àgùntàn rẹ̀ mọ, ìdí nìyẹn tó fi máa ń darí wọn “ní ìbámu pẹ̀lú ìṣísẹ̀ àwọn ohun ọ̀sìn” náà. (Jẹ́nẹ́sísì 33:14) Bákan náà ni Jèhófà ṣe máa ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀ “ní ìbámu pẹ̀lú ìṣísẹ̀” wọn. Ó máa ń wo ibi tí agbára wa mọ àti ipò tá a wà. Lẹ́nu kan, kì í retí pé ká ṣe ohun tágbára wa ò gbé. Ohun tó ń fẹ́ ni pé ká fi gbogbo ọkàn wa sin òun. (Kólósè 3:23) Àmọ́ tó o bá ti darúgbó ńkọ́ tó ò sì lè ṣe tó bó o ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀? Tàbí kẹ̀ bí àìsàn líle kan ò bá jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Ìgbà yẹn gan-an ni fífi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà gbéṣẹ́ jù lọ. Kò sí ẹni méjì tó rí bákan náà láyé yìí. Fífi gbogbo ọkàn sin Jèhófà túmọ̀ sí pé kó o lo gbogbo okun rẹ àti gbogbo agbára rẹ débi tó o bá lè lò ó dé nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Láìfi gbogbo kùdìẹ̀-kudiẹ tó lè máà jẹ́ ká ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ pè, Jèhófà mọyì ìjọsìn tá à ń fi gbogbo ọkàn ṣe.—Máàkù 12:29, 30.

12. Àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Òfin Mósè tó ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀ “ní ìbámu pẹ̀lú ìṣísẹ̀” wọn?

12 Láti ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀ “ní ìbámu pẹ̀lú ìṣísẹ̀” wọn, ronú lórí ohun tó sọ nípa àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tó mẹ́nu kàn nínú Òfin Mósè. Jèhófà fẹ́ ọrẹ ẹbọ tó dára, èyí tó wá látinú ọkàn tó kún fún ìmọrírì. Lọ́wọ́ kan náà, ẹni tó fẹ́ rúbọ náà kò ní ṣe ju agbára rẹ̀ lọ. Òfin náà sọ pé: “Bí agbára rẹ̀ kò bá ká àgùntàn, nígbà náà, kí ó mú oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.” Bí agbára rẹ̀ kò bá gbé ẹyẹlé méjì pàápàá ńkọ́? Ó lè bu “ìyẹ̀fun kíkúnná” díẹ̀ wá. (Léfítíkù 5:7, 11) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run kò béèrè ohun tó ju agbára ẹni tó ń ṣe ìrúbọ náà. Níwọ̀n bí Ọlọ́run kò ti yí padà, ìtùnú ńlá ló jẹ́ fún wa láti mọ̀ pé kò ní béèrè ohun tó ju agbára wa lọ, kàkà bẹ́ẹ̀, inú rẹ̀ máa ń dùn láti tẹ́wọ́ gba ohun tí agbára wa bá ká. (Málákì 3:6) Inú wa mà dùn o, pé irú Olùṣọ́ Àgùntàn tó ń gba tẹni rò bẹ́ẹ̀ ló ń darí wa!

“Èmi Kò Bẹ̀rù Ohun Búburú Kankan, Nítorí Tí Ìwọ Wà Pẹ̀lú Mi”

13. Báwo ni Dáfídì ṣe sọ̀rọ̀ nínú Sáàmù 23:4, tó fi hàn pé ó sún mọ́ Jèhófà gan-an, kí sì nìdí tí èyí kò fi yà wá lẹ́nu?

13 Dáfídì sọ ìdí kejì tó fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, ó ní: Jèhófà ń dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀. A kà á pé: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.” (Sáàmù 23:4) Dáfídì wá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó sún mọ́ Jèhófà gan-an, ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìwọ” fún Jèhófà. Èyí kò yà wá lẹ́nu nítorí pé ńṣe ni Dáfídì ń sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe ràn án lọ́wọ́ láti fara da ìpọ́njú. Dáfídì ti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu kọjá, ìyẹn ni pé àwọn àkókò kan wà tí ẹ̀mí òun fúnra rẹ̀ wà nínú ewu. Àmọ́ kò jẹ́ kí ìbẹ̀rù borí òun, nítorí ó mọ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú òun, “ọ̀pá” Rẹ̀ àti “ọ̀pá ìdaran” Rẹ̀ sì wá ní sẹpẹ́. Mímọ̀ tí Dáfídì mọ̀ nípa ààbò yìí tù ú nínú gan-an, ó sì dájú pé ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà dáadáa. b

14. Báwo ni Bíbélì ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà á dáàbò bò wá, àmọ́ kí ni èyí kò túmọ̀ sí?

14 Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀ lónìí? Bíbélì mú un dá wa lójú pé kò sí alátakò kankan, ì báà jẹ́ ẹ̀mí èṣù tàbí èèyàn, tí yóò lè pa àwọn àgùntàn Ọlọ́run rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà kò ní fàyè gba ìyẹn láé. (Aísáyà 54:17; 2 Pétérù 2:9) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé Olùṣọ́ Àgùntàn wa yóò gbà wá lọ́wọ́ gbogbo ewu o. Àwa náà máa ń kojú àdánwò tó máa ń bá gbogbo èèyàn, a sì ń dojú kọ àtakò táwọn èèyàn máa ń ṣe sí gbogbo Kristẹni tòótọ́. (2 Tímótì 3:12; Jákọ́bù 1:2) Àwọn àkókò kan wà tá a lè máa “rìn ní àfonífojì ibú òjìji.” Bí àpẹẹrẹ, ikú lè fẹjú mọ́ wa nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa tàbí nígbà tá a bá ń ṣàìsàn. Ẹnì kan tó sún mọ́ wa gan-an lè wà ní bèbè ikú tàbí kó tiẹ̀ kú pàápàá. Ní irú àkókò tí nǹkan le gan-an fún wa yẹn, Olùṣọ́ Àgùntàn wa wà pẹ̀lú wa, yóò sì dáàbò bò wá. Lọ́nà wo?

15, 16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tó lè dojú kọ wá? (b) Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ lásìkò àdánwò.

15 Jèhófà ò ṣèlérí pé òun á máa dá sí ọ̀ràn wa lọ́nà ìyanu. c Àmọ́ a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí ohunkóhun tó bá fẹ́ jẹ́ ìdènà fún wa. Ó lè fún wa ní ọgbọ́n láti fara da “onírúurú àdánwò.” (Jákọ́bù 1:2-5) Kì í ṣe pé olùṣọ́ àgùntàn máa ń fi ọ̀pá tàbí ọ̀pá ìdaran rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá sẹ́yìn nìkan ni, àmọ́ ó tún máa ń lò ó láti rọra darí àwọn àgùntàn rẹ̀ sí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà. Jèhófà lè “rọra darí” wa, bóyá nípasẹ̀ ẹnì kan tá a jọ jẹ́ olùjọsìn rẹ̀, ká lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì sílò, èyí tó lè ṣèrànwọ́ gan-an nínú ipò tá a bá wa. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà lè fún wa lókun láti ní ìfaradà. (Fílípì 4:13) Ó lè tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tí Sátánì lè mú bá wa. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà múra tán láti ràn wá lọ́wọ́?

16 Dájúdájú, bó ti wù kí àfonífojì tá a bára wa ṣókùnkùn tó, a ò ní láti dá nìkan rìn ín. Olùṣọ́ Àgùntàn wa wà pẹ̀lú wa, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà tá a lè má tètè kíyè sí. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni kan tó jẹ́ alàgbà yẹ̀ wò, àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fún un fi hàn pé kókó kan tó lè ṣekú pa á wà nínú ọpọlọ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé bóyá Jèhófà ń bínú sí mi ni tàbí bóyá kò nífẹ̀ẹ́ mi. Àmọ́ mo wá pinnu pé mi ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Dípò ìyẹn, ńṣe ni mo sọ gbogbo ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn mi fún un. Jèhófà sì ràn mí lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń tù mí nínú nípasẹ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Ọ̀pọ̀ ló sọ ohun tójú àwọn fúnra wọn ti rí fún mi, tí wọ́n sì jẹ́ kí n mọ báwọn náà ṣe borí àìsàn líle. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ jẹ́ kí n mọ̀ pé ohun tó ń ṣe mi kì í ṣe ohun tójú ò rí rí. Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún mi, títí kan inú rere tí wọ́n fi hàn sí mi túbọ̀ mú un dá mi lójú pé kì í ṣe pé Jèhófà ń bínú sí mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn náà ò tíì fi mí sílẹ̀, tí mi ò sì mọ ibi tó máa já sí, síbẹ̀ ó dá mi lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi, yóò sì máa bá a lọ láti ràn mí lọ́wọ́ jálẹ̀ àkókò àdánwò mi yìí.”

“Ìwọ Ṣètò Tábìlì Síwájú Mi”

17. Báwo ni Dáfídì ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà nínú Sáàmù 23:5, kí sì nìdí tí èyí kò ṣe tako àpèjúwe jíjẹ́ tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn?

17 Dáfídì wá mẹ́nu kan ìdí kẹta tó fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olùṣọ́ Àgùntàn rẹ̀, ó ní: Jèhófà ń bọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ náà lọ́pọ̀ yanturu. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ìwọ ṣètò tábìlì síwájú mi ní iwájú àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi. Ìwọ fi òróró pa orí mi; ife mi kún dáadáa.” (Sáàmù 23:5) Nínú ẹsẹ yìí, Dáfídì sọ pé Olùṣọ́ Àgùntàn òun dà bí olùgbàlejò tó lawọ́ gan-an, tó ń pèsè oúnjẹ àti ohun mímu lọ́pọ̀ yanturu. Àpèjúwe méjèèjì yìí, ìyẹn olùṣọ́ àgùntàn tó láájò àti olùgbàlejò tó lawọ́ gan-an kò tako ara wọn. Ó ṣe tán, olùṣọ́ àgùntàn rere gbọ́dọ̀ mọ ibi tóun ti máa rí pápá ìjẹko tó tutù yọ̀yọ̀ àti ọ̀pọ̀ omi mímu kí agbo ẹran rẹ̀ má bàa “ṣaláìní nǹkan kan.”— Sáàmù 23:1, 2.

18. Kí ló fi hàn pé olùgbàlejò tó lawọ́ gan-an ni Jèhófà?

18 Ṣé olùgbàlejò tó lawọ́ gan-an ni Olùṣọ́ Àgùntàn tiwa náà? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ìwọ kan tiẹ̀ ronú nípa bí oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń gbádùn lákòókò yìí ṣe pọ̀ tó, bó ṣe dára tó, àti bó ṣe tún wà lónírúurú tó. Jèhófà ti tipasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà pèsè àwọn ìwé tó wúlò gan-an fún wa, ó ti pèsè àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ alárinrin tá à ń gbádùn láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti ti agbègbè. Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí là ń gbà rí àwọn ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí. (Mátíù 24:45-47) Ó dájú pé oúnjẹ tẹ̀mí kò wọ́n wa rárá. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ti pèsè ọ̀kẹ́ àìmọye Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ sì ti wà báyìí ní èdè irínwó ó lé mẹ́tàlá [413]. Jèhófà ti pèsè àwọn oúnjẹ tẹ̀mí yìí lónírúurú, látorí “wàrà,” ìyẹn àwọn ohun téèyàn kọ́kọ́ ń mọ̀ nínú Bíbélì, títí dórí “oúnjẹ líle,” ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tẹ̀mí tó jinlẹ̀ gan-an nínú Bíbélì. (Hébérù 5:11-14) Nípa bẹ́ẹ̀, a lè rí ohun tá a nílò gan-an nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro tàbí tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu kan. Báwo ni ìgbésí ayé wa ì bá ṣe rí ká ní kò sáwọn oúnjẹ tẹ̀mí wọ̀nyí? Olùpèsè tó lawọ́ gidi gan-an ni Olùṣọ́ Àgùntàn wa lóòótọ́!—Aísáyà 25:6; 65:13.

‘Èmi Yóò Máa Gbé Inú Ilé Jèhófà’

19, 20. (a) Nínú Sáàmù 23:6, irú ìfọ̀kànbalẹ̀ wo ni Dáfídì sọ pé òun ní, báwo làwa náà sì ṣe lè nírú ìfọ̀kànbalẹ̀ bẹ́ẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

19 Lẹ́yìn tí Dáfídì ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Olùṣọ́ Àgùntàn àti Olùpèsè rẹ̀ gbà ń ṣe àwọn nǹkan, ó sọ pé: “Dájúdájú, ohun rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi; èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà fún gígùn ọjọ́.” (Sáàmù 23:6) Dáfídì sọ̀rọ̀ látinú ọkàn tó kún fún ìmoore àti ìgbàgbọ́. Ó fi ìmoore hàn ní ti pé ó rántí ohun tó ti kọjá, ó sì fi ìgbàgbọ́ hàn ní ti pé ó fọkàn sí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ọkàn Dáfídì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tẹ́lẹ̀ yìí balẹ̀, nítorí ó mọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tóun bá ṣì wà lọ́dọ̀ Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn òun tó wà lọ́rùn, tó dà bí ẹni pé òun ń gbé inú ilé Rẹ̀, yóò máa fi ìfẹ́ bójú tó òun.

20 A má dúpẹ́ gan-an o, fún àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Sáàmù kẹtàlélógún yìí! Ọ̀nà tó bá a mu wẹ́kú ni Dáfídì gbà ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń ṣamọ̀nà àwọn àgùntàn rẹ̀, bó ṣe ń dáàbò bò wọ́n, àti bó ṣe ń bọ́ wọn. Ọlọ́run pa àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí tí Dáfídì sọ yìí mọ́ sínú Bíbélì láti fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé kí àwa náà máa wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùntàn wa. Bẹ́ẹ̀ ni o, níwọ̀n bí a bá ti ń sún mọ́ Jèhófà, yóò bójú tó wa “fún gígùn ọjọ́,” àní títí ayérayé, nítorí ó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn onífẹ̀ẹ́. Àmọ́ ṣá o, ojúṣe wa ni pé ká máa bá Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn wa gíga rìn nítorí pé àgùntàn rẹ̀ ni wá. Ohun tó túmọ̀ sí láti bá Ọlọ́run rìn la ó jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Dáfídì kọ àwọn sáàmù bíi mélòó kan tó fi yin Jèhófà lógo nítorí pé ó yọ ọ́ nínú ewu.—Bí àpẹẹrẹ, wo àkọlé Sáàmù 18, 34, 56, 57, 59, àti 63.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú pé olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì fi Jèhófà wé?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi òye darí wa?

• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò?

• Kí ló fi hàn pé olùgbàlejò tó lawọ́ gan-an ni Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Bíi ti olùṣọ́ àgùntàn kan ní Ísírẹ́lì ni Jèhófà ṣe ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀