Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà Ń fún Wa Níṣìírí Láti Bá Ọlọ́run Rìn
Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà Ń fún Wa Níṣìírí Láti Bá Ọlọ́run Rìn
“Wọn yóò máa tẹ̀ lé Jèhófà.”—HÓSÉÀ 11:10.
1. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ wo ló wà nínú ìwé Hóséà?
ǸJẸ́ o máa ń gbádùn àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí ìran àwọn èèyàn inú rẹ̀ dùn-ún wò? Àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ wà nínú ìwé Hóséà. a Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé wòlíì Ọlọ́run tó ń jẹ́ Hóséà, ó sì tún dúró fún ìgbéyàwó tí Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tó fún wọn ní Òfin Mósè tó fi bá wọn dá májẹ̀mú.
2. Kí ni Bíbélì sọ nípa Hóséà?
2 Inú ìwé Hóséà orí kìíní la ti máa rí àlàyé ṣókí nípa àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ó jọ pé ilẹ̀ ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá ni Hóséà ń gbé. A tún máa ń pe ìjọba yìí ní Éfúráímù torí pé ẹ̀yà Éfúráímù ni akíkanjú wọn. Hóséà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà ìṣàkóso àwọn ọba méje tó jẹ kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì àti nígbà ìṣàkóso Ùsáyà, Jótámù, Áhásì àti Hesekáyà tí wọ́n jẹ́ ọba Júdà. (Hóséà 1:1) Èyí fi hàn pé ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ni Hóséà fi sọ tẹ́lẹ̀, ó kéré tán. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yìn ọdún 745 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló kọ ìwé Hóséà parí, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣì wúlò láyé òde òní tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ohun tó bá ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú ìwé rẹ̀ mu, ọ̀rọ̀ náà ni: “Wọn yóò máa tẹ̀ lé Jèhófà.”—Hóséà 11:10.
Kókó Inú Ìwé Hóséà Orí Kìíní sí Ìkarùn-ún
3, 4. Ní ṣókí, sọ ohun tó wà nínú Hóséà orí kìíní sí ìkarùn-ún.
3 Tá a bá gbé kókó inú ìwé Hóséà orí kìíní sí ìkarùn-ún yẹ̀ wò, yóò jẹ́ ká túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa pé a óò máa bá Ọlọ́run rìn. Bá a sì ṣe lè bá Ọlọ́run rìn ni pé ká ní ìgbàgbọ́, ká sì máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba Ísírẹ́lì ṣe panṣágà nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ Ọlọ́run yóò dárí jì wọ́n bí wọ́n bá ronú pìwà dà. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ọ̀nà tí Hóséà gbà bá Gómérì aya rẹ̀ lò. Ẹ̀rí fi hàn pé lẹ́yìn tó bímọ kan fún Hóséà, ó tún lọ bímọ méjì míì síta. Síbẹ̀, Hóséà gbà á padà gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe múra tán láti ṣàánú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà.—Hóséà 1:1-3:5.
4 Jèhófà yóò dá Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ torí pé kò sí òtítọ́, inú rere onífẹ̀ẹ́ àti ìmọ̀ Ọlọ́run nílẹ̀ náà. Yóò mú kí Ísírẹ́lì abọ̀rìṣà àti ìjọba Júdà oníwàkiwà jíhìn. Àmọ́, nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run bá wà “nínú hílàhílo,” wọn yóò wá Jèhófà.—Hóséà 4:1-5:15.
Bí Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Náà Ṣe Lọ
5, 6. (a) Báwo ni ìwà àgbèrè ṣe gbilẹ̀ tó nínú ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́?
5 Ọlọ́run pàṣẹ fún Hóséà pé: “Lọ, mú àgbèrè aya àti àwọn ọmọ àgbèrè fún ara rẹ, nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè, ilẹ̀ yìí ti yí padà dájúdájú kúrò ní títọ Jèhófà lẹ́yìn.” (Hóséà 1:2) Báwo ni àgbèrè ṣe gbilẹ̀ tó nílẹ̀ Ísírẹ́lì? Hóséà kọ̀wé pé: “Ẹ̀mí àgbèrè gan-an ti mú kí [àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá] rìn gbéregbère lọ, àti nípasẹ̀ àgbèrè, wọ́n jáde kúrò lábẹ́ Ọlọ́run wọn. . . . Àwọn ọmọbìnrin yín . . . ń ṣe àgbèrè, tí aya àwọn ọmọ yín sì ń ṣe panṣágà. . . . Ní ti àwọn ọkùnrin wọnnì, àwọn aṣẹ́wó ni wọ́n ya ara wọn sápá kan fún, wọ́n sì ń bá àwọn kárùwà obìnrin inú tẹ́ńpìlì rúbọ.”—Hóséà 4:12-14.
6 Ìwà àgbèrè nípa tara àti nípa tẹ̀mí gbilẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé òun yóò béèrè “ìjíhìn” lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Hóséà 1:4; 4:9) Ó yẹ ká fiyè sí ìkìlọ̀ yìí o torí pé Jèhófà máa dá àwọn tó bá ń hùwà pálapàla àtàwọn tó bá ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn tí kò mọ́ lónìí lẹ́jọ́. Àmọ́ o, àwọn tó ń bá Ọlọ́run rìn kúnjú ìwọ̀n ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́, wọ́n sì mọ̀ pé “kò sí àgbèrè kankan . . . tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.”—Éfésù 5:5; Jákọ́bù 1:27.
7. Kí ni ìgbéyàwó tí Hóséà bá Gómérì ṣe dúró fún?
7 Nígbà tí Hóséà fẹ́ Gómérì, kò sí àní-àní pé wúńdíá ni, kì í sì í ṣe oníṣekúṣe nígbà tó “bí ọmọkùnrin kan fún un.” (Hóséà 1:3) Lọ́nà kan náà, kò pẹ́ tí Ọlọ́run dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nídè lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ó bá Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú tó dà bí àdéhùn ìgbéyàwó mímọ́ irú èyí tí Hóséà bá Gómérì ṣe. Májẹ̀mú yìí fi hàn pé Ísírẹ́lì ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, “ọkọ olówó orí” rẹ̀. (Aísáyà 54:5) Ìgbéyàwó mímọ́ tí Hóséà bá Gómérì ṣe yìí dúró fún ìgbéyàwó ìṣàpẹẹrẹ tí Ọlọ́run ṣe pẹ̀lú Ísírẹ́lì. Àmọ́ o, nǹkan yí padà nígbà tó yá!
8. Báwo ni ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá ṣe wáyé, irú ìjọsìn wo ni wọ́n sì ń ṣe?
8 Aya Hóséà tún “lóyún ní ìgbà mìíràn, ó sì bí ọmọbìnrin kan.” Ó ní láti jẹ́ pé ìgbà tí Gómérì ṣe panṣágà ló bí ọmọbìnrin náà àti ọmọ tó tún bí lẹ́yìn ìyẹn. (Hóséà 1:6, 8) Níwọ̀n bí Gómérì ti dúró fún Ísírẹ́lì, o lè máa ronú pé, ‘Ọ̀nà wo ni Ísírẹ́lì gbà ṣe ìṣekúṣe?’ Lọ́dún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ya ara wọn kúrò lára ẹ̀yà Júdà àti Bẹ́ńjámínì tó wà ní gúúsù. Láìpẹ́, ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ọmọ màlúù kí wọ́n má bàa máa lọ sí Jerúsálẹ́mù láti jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ìjọsìn òrìṣà Báálì, tí ìṣekúṣe jẹ́ ara ààtò ẹ̀sìn rẹ̀, wá di ohun tó gbilẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Hóséà 1:6 ṣe sọ tẹ́lẹ̀?
9 Nígbà tí Gómérì bí ọmọ rẹ̀ kejì tó jọ pé ó jẹ́ ọmọ àlè, Ọlọ́run sọ fún Hóséà pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà [èyí tó túmọ̀ sí “A Kò Fi Àánú Hàn Sí I”], nítorí èmi kì yóò tún fi àánú hàn sí ilé Ísírẹ́lì mọ́, nítorí pé kíkó ni èmi yóò kó wọn lọ.” (Hóséà 1:6) Jèhófà ‘kó wọn lọ’ nígbà tó jẹ́ kí àwọn ará Asíríà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbèkùn lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, Ọlọ́run fi àánú hàn sí àwọn ẹ̀yà méjì tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọba Júdà, ó sì gbà wọ́n là, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípasẹ̀ ọrun, idà, ogun, àwọn ẹṣin tàbí àwọn ẹlẹ́ṣin. (Hóséà 1:7) Lọ́dún 732 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lálẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo, ẹyọ áńgẹ́lì Jèhófà kan ṣoṣo pa àwọn ọmọ ogun Ásíríà tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] tí wọ́n fẹ́ gbógun wọ Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Júdà.—2 Àwọn Ọba 19:35.
Jèhófà Dá Ísírẹ́lì Lẹ́jọ́
10. Kí ni ìwà panṣágà tí Gómérì hù ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?
10 Gómérì kúrò lọ́dọ̀ Hóséà, ó sì di “àgbèrè aya” nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí bá ọkùnrin mìíràn gbé. Èyí ṣàpẹẹrẹ bí ìjọba Ísírẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà lẹ̀dí àpò pọ̀, tó ń bá wọn ṣe òṣèlú, tó wá bẹ̀rẹ̀ sí gbára lé wọn. Dípò kí Ísírẹ́lì máa fògo fún Jèhófà nítorí aásìkí rẹ̀, àwọn òrìṣà tàwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn ń bọ ló ń fògo fún, ó sì tipa ṣíṣe ìjọsìn èké fagi lé májẹ̀mú ìgbéyàwó tó bá Ọlọ́run dá. Abájọ tí Jèhófà fi dá orílẹ̀-èdè tó ti ya panṣágà nípa tẹ̀mí yìí lẹ́jọ́.—Hóséà 1:2; 2:2, 12, 13.
11. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí májẹ̀mú Òfin nígbà tí Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n kó Ísírẹ́lì àti Júdà lọ sígbèkùn?
11 Ìyà wo ni Ọlọ́run fi jẹ Ísírẹ́lì nítorí pé ó kúrò lọ́dọ̀ òun tó jẹ́ Ọkọ Olówó Orí rẹ̀? Ọlọ́run mú kó “lọ sí aginjù” Bábílónì, ìyẹn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́gun Ásíríà tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbèkùn lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Hóséà 2:14) Nígbà tí Jèhófà wá ṣe èyí láti fòpin sí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà, kò fagi lé májẹ̀mú ìgbéyàwó tó ti bá ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì dá nígbà tí wọ́n ṣì para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo. Kódà, nígbà tí Ọlọ́run gba àwọn ará Bábílónì láyè láti pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tó sì jẹ́ kí wọ́n kó àwọn èèyàn Júdà nígbèkùn, kò wọ́gi lé májẹ̀mú Òfin Mósè tó fi bá ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá dá májẹ̀mú ìgbéyàwó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ìgbà táwọn olórí ẹ̀sìn Júù kọ Jésù Kristi tí wọ́n sì pa á lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni ni àjọṣe yẹn tó bà jẹ́.—Kólósè 2:14.
Jèhófà Gba Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Níyànjú
12, 13. Kí ni kókó inú Hóséà 2:6-8, báwo sì ni ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì mu?
12 Ọlọ́run gba Ísírẹ́lì níyànjú pé kó “mú àgbèrè rẹ̀ kúrò,” àmọ́ ńṣe ni Ísírẹ́lì fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn tó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i. (Hóséà 2:2, 5) Jèhófà wá sọ pé: “Nítorí náà, kíyè sí i èmi yóò fi ẹ̀gún ṣe ọgbà ààbò yí ọ̀nà rẹ ká; dájúdájú, èmi yóò sì gbé ògiri òkúta nà ró lòdì sí i, tó bẹ́ẹ̀ tí òun kì yóò fi rí òpópónà ara rẹ̀. Òun yóò sì lépa àwọn olùfẹ́ rẹ̀ onígbòónára ní ti tòótọ́, ṣùgbọ́n kì yóò bá wọn; òun yóò sì wá wọn dájúdájú, ṣùgbọ́n kì yóò rí wọn. Yóò sì wá sọ pé, ‘Mo fẹ́ padà lọ sọ́dọ̀ ọkọ mi, ti àkọ́kọ́, nítorí ó sàn fún mi ní àkókò yẹn ju ìsinsìnyí lọ.’ Ṣùgbọ́n òun alára kò mọ̀ pé èmi ni ó fún òun ní ọkà àti wáìnì dídùn àti òróró, àti pé èmi ni ó ti mú kí fàdákà pọ̀ gidigidi fún un, àti wúrà, èyí tí wọ́n lò fún Báálì [tàbí tí wọ́n fi yá ère Báálì, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW].”—Hóséà 2:6-8.
13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ísírẹ́lì wá ìrànwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n jẹ́ “àwọn olùfẹ́ rẹ̀ onígbòónára,” kò sí ìkankan lára wọn tó lè ràn án lọ́wọ́. Ńṣe làwọn ọ̀tá há a gádígádí gẹ́gẹ́ bí igbó tó dí, débi pé kò sí orílẹ̀-èdè tó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan fún un. Lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun Samáríà olú ìlú Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n ti sàga tì í fọ́dún mẹ́ta, bí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà ò sì ṣe gbérí mọ́ nìyẹn. Kìkì àwọn kọ̀ọ̀kan láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn ló mọ bí nǹkan ṣe dáa tó nígbà táwọn baba ńlá wọn ń sin Jèhófà. Àwọn èèyàn kéréje wọ̀nyí ò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn Báálì rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n wá bí Jèhófà á ṣe padà bá wọn dá májẹ̀mú.
Ohun Mìíràn Tó Wà Nínú Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Náà
14. Kí nìdí tí Hóséà tún fi gba Gómérì padà?
14 Ká bàa lè túbọ̀ lóye bí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé Hóséà ṣe bá àjọṣe tó wà láàárín Ísírẹ́lì àti Jèhófà mu, ẹ jẹ́ ká ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Hóséà sọ pé: “Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: ‘Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí alábàákẹ́gbẹ́ kan nífẹ̀ẹ́, tí ó sì ń ṣe panṣágà.’” (Hóséà 3:1) Hóséà lọ ra Gómérì padà lọ́wọ́ ọkùnrin tó ń bá gbé kó lè tẹ̀ lé àṣẹ yìí. Lẹ́yìn èyí, ó tẹ̀ ẹ́ mọ́ ìyàwó rẹ̀ létí pé: “Ìwọ yóò máa gbé ní jíjẹ́ tèmi fún ọjọ́ púpọ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ wá jẹ́ ti ọkùnrin mìíràn.” (Hóséà 3:2, 3) Gómérì gba ìbáwí yìí, òun àti Hóséà sì jọ ń gbé gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya. Báwo ni èyí ṣe kan àjọṣe Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà?
15, 16. (a) Kí ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run bá wí yìí gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kó ṣàánú àwọn? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà 2:18 ṣe ṣẹ?
15 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà wà lóko ẹrú ní Bábílónì, Ọlọ́run lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ‘bá ọkàn wọn sọ̀rọ̀.’ Tí wọ́n bá fẹ́ kí Ọlọ́run ṣàánú àwọn, wọ́n gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà kí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Ọkọ Olówó Orí wọn, gẹ́gẹ́ bí Gómérì ṣe padà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀. Ìgbà yẹn ni Jèhófà máa mú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó ti bá wí, èyí tó dà bí ìyàwó rẹ̀, kúrò ní “aginjù” Bábílónì, tí yóò sì dá a padà sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù. (Hóséà 2:14, 15) Ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló mú ìlérí yẹn ṣẹ.
16 Ìlérí míì tí Ọlọ́run tún mú ṣẹ nìyí: “Dájúdájú, èmi yóò sì dá májẹ̀mú fún wọn ní ọjọ́ yẹn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti ohun tí ń rákò lórí ilẹ̀, ọrun àti idà àti ogun ni èmi yóò sì ṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ náà, èmi yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ ní ààbò.” (Hóséà 2:18) Ìbàlẹ̀ ọkàn wà fún àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Júù tó wà nígbèkùn tí wọ́n padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, kò sì sí pé àwọn ẹranko ń halẹ̀ mọ́ wọn. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún ṣẹ lọ́dún 1919 nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì tẹ̀mí nídè kúrò lóko ẹrú “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Ní báyìí, ìbàlẹ̀ ọkàn wà fún àwọn àtàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yòókù tí wọ́n ń wọ̀nà láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, inú párádísè tẹ̀mí ni wọ́n sì wà. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn Kristẹni tòótọ́ wọ̀nyí tó ń hu ìwà ẹranko.—Ìṣípayá 14:8; Aísáyà 11:6-9; Gálátíà 6:16.
Máa Fi Ẹ̀kọ́ Inú Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà Sọ́kàn
17-19. (a) Àwọn ànímọ́ wo ni ìpínrọ̀ wọ̀nyí rọ̀ wá pé ká fara wé lára Ọlọ́run? (b) Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ aláàánú àti oníyọ̀ọ́nú bíi ti Jèhófà?
17 Aláàánú àti oníyọ̀ọ́nú ni Ọlọ́run, ó sì yẹ káwa náà fìwà jọ ọ́. Ẹ̀kọ́ kan tá a rí kọ́ nínú àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Hóséà nìyẹn. (Hóséà 1:6, 7; 2:23) Ọlọ́run múra tán láti fojú àánú hàn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá ronú pìwà dà. Èyí sì bá òwe Bíbélì kan mu, òwe náà ni pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13) Síwájú sí i, ọ̀rọ̀ onísáàmù tún lè tu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà nínú. Ó sọ pé: “Àwọn ẹbọ sí Ọlọ́run ni ẹ̀mí tí ó ní ìròbìnújẹ́; ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.”—Sáàmù 51:17.
18 Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà jẹ́ kó ṣe kedere pé oníyọ̀ọ́nú àti aláàánú ni Ọlọ́run tá à ń sìn. Kódà báwọn kan bá yapa kúrò ní ọ̀nà òdodo Ọlọ́run, wọ́n ṣì lè ronú pìwà dà, kí wọ́n sì tún ìwà wọn ṣe. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ó ṣàánú àwọn tó ronú pìwà dà lára àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó ti bá ṣe ìgbéyàwó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà tí wọ́n sì ‘ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, ó jẹ́ aláàánú ó sì ń bá a nìṣó ní rírántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n.’ (Sáàmù 78:38-41) Ó yẹ kí irú àánú tí Ọlọ́run fi hàn yìí mú ká máa bá Jèhófà, Ọlọ́run ìyọ́nú, rìn nìṣó.
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bí ìpànìyàn, olè jíjà àti panṣágà gbilẹ̀ ní Ísírẹ́lì, Jèhófà ‘bá ọkàn Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.’ (Hóséà 2:14; 4:2) Bí àwa náà ṣe ń ronú lórí àánú àti ìyọ́nú Jèhófà, ó yẹ kí èyí gún ọkàn wa ní kẹ́ṣẹ́, kó sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ìyẹn ló fi yẹ ká bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ fara wé àánú àti ìyọ́nú Jèhófà nínú bí mo ṣe ń ṣe sáwọn ẹlòmíì? Bí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni bá ṣẹ̀ mí tó sì tọrọ àforíjì, ṣé èmi náà ṣe tán láti dárí jì í bíi ti Ọlọ́run?’—Sáàmù 86:5.
20. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé ó yẹ ká gbára lé ìrètí tí Ọlọ́run fún wa.
20 Ọlọ́run máa ń fúnni ní ìrètí tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣèlérí pé: ‘Èmi yóò fún un ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Ákórì gẹ́gẹ́ bí ẹnu ọ̀nà sí ìrètí.’ (Hóséà 2:15) Ètò Jèhófà láyé àtijọ́, èyí tó dà bí ìyàwó rẹ̀, ní ìrètí tó dájú pé Ọlọ́run yóò mú un padà sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, níbi tí “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Ákórì” wà. Ọlọ́run mú ìlérí rẹ̀ yìí ṣẹ lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìdí pàtàkì nìyí tó fi yẹ kí inú wa máa dùn pé ó dájú pé Jèhófà yóò ṣe àwọn ohun tó ṣèlérí fún wa.
21. Báwo ni ìmọ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn?
21 Tá a bá fẹ́ máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ ká sì máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò nígbà gbogbo. Ìmọ̀ nípa Jèhófà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá ní Ísírẹ́lì. (Hóséà 4:1, 6) Síbẹ̀, àwọn kan níbẹ̀ ṣì mọyì ìtọ́ni Ọlọ́run gidigidi, wọ́n sì ń fi í sílò, ìyẹn sì mú kí Ọlọ́rùn bù kún wọn gan-an. Hóséà jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn mìíràn tó tún ṣe bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún méje èèyàn tí kò tẹ eékún wọn ba, ìyẹn ni pé wọn ò jọ́sìn Báálì nígbà ayé Èlíjà. (1 Àwọn Ọba 19:18; Róòmù 11:1-4) Bí àwa náà bá mọrírì ìtọ́ni Ọlọ́run, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó.—Sáàmù 119:66; Isaiah 30:20, 21.
22. Èrò wo ló yẹ ká ní nípa ìpẹ̀yìndà?
22 Jèhófà ò fẹ́ káwọn tó wà ní ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ fàyè gba ìpẹ̀yìndà. Síbẹ̀, Hóséà 5:1 sọ pé: “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin àlùfáà, ẹ sì fiyè sílẹ̀, ilé Ísírẹ́lì, àti ẹ̀yin, ilé ọba, ẹ fi etí sí i, nítorí pé ẹ̀yin ni ẹ fẹ́ gba ìdájọ́; nítorí pé ẹ ti di pańpẹ́ fún Mísípà àti gẹ́gẹ́ bí àwọ̀n tí a nà bo Tábórì.” Àwọn aṣáájú tí wọ́n jẹ́ apẹ̀yìndà jẹ́ páńpẹ́ àti àwọ̀n fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé ńṣe ni wọ́n ń tàn wọ́n láti bọ̀rìṣà. Ó ṣeé ṣe kí Òkè Tábórì àti ibi tí wọ́n ń pè ní Mísípà jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn èké wọ̀nyẹn.
23. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú Hóséà orí kìíní sí ìkarùn-ún?
23 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà ti jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run aláàánú tó ń fúnni ní ìrètí ni Jèhófà, ó sì máa ń bù kún àwọn tó bá fi ìtọ́ni rẹ̀ sílò tí wọ́n sì kọ ìpẹ̀yìndà. Ẹ jẹ́ káwa náà fìwà jọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ronú pìwà dà, ká máa wá Jèhófà ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti múnú rẹ̀ dùn. (Hóséà 5:15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò ká ohun tó dára, a ó sì ní ayọ̀ àti àlàáfíà tí ò láfiwé tí gbogbo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn bá Ọlọ́run rìn máa ń ní.—Sáàmù 100:2; Fílípì 4:6, 7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ wà nínú Gálátíà 4:21-26. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa rẹ̀, wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ìwé 693 àti 694. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni ìgbéyàwó tí Hóséà bá Gómérì ṣe dúró fún?
• Kí nìdí tí Jèhófà fi dá Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ ?
• Ẹ̀kọ́ wo ló wọ̀ ọ́ lọ́kàn nínú Hóséà orí kìíní sí ìkarùn-ún?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ìyàwó Hóséà dúró fún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun àwọn ará Samáríà lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn èèyàn aláyọ̀ padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn