Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Dúró Ṣánṣán”

“Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Dúró Ṣánṣán”

“Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Dúró Ṣánṣán”

“Àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán, àwọn olódodo sì ni yóò máa rìn nínú wọn.”—HÓSÉÀ 14:9.

1, 2. Ipa ọ̀nà wo ni Jèhófà fi ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lé, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tó yá?

 JÈHÓFÀ fi ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lé ipa ọ̀nà òdodo nígbà ayé wòlíì Mósè. Àmọ́, nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ipò wọn ti burú débi tí Ọlọ́run fi sọ pé ìwà ibi wọn pàpọ̀jù. Hóséà orí kẹwàá sí ìkẹrìnlá jẹ́ ká rí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ gan-an.

2 Ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti di alágàbàgebè. Ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì “túlẹ̀ ìwà burúkú,” wọ́n sì ká àìṣòdodo. (Hóséà 10:1, 13) Jèhófà sọ pé: “Nígbà tí Ísírẹ́lì jẹ́ ọmọdékùnrin, nígbà náà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, láti Íjíbítì ni mo sì ti pe ọmọkùnrin mi.” (Hóséà 11:1) Ọlọ́run gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó mú wọn nígbèkùn, àmọ́ irọ́ pípa àti ẹ̀tàn ni wọ́n fi san án padà fún un. (Hóséà 11:12) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi rọ̀ wọ́n pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ ni kí o padà sí, ní pípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mọ́.”—Hóséà 12:6.

3. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Samáríà nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, àmọ́ kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n bàa lè rí ìdáríjì?

3 Samáríà àti ọba rẹ̀ máa tó kàgbákò nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ wọn. (Hóséà 13:11, 16) Ṣùgbọ́n orí tó gbẹ̀yìn àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àrọwà yìí pé: “Padà wá, ìwọ Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Bí Ísírẹ́lì bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì tọrọ ìdáríjì, Ọlọ́run yóò ṣàánú wọn. Àmọ́ ṣá o, wọ́n ní láti gbà pé “àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán,” kí wọ́n sì máa rìn nínú wọn.—Hóséà 14:1-6, 9.

4. Àwọn ìlànà wo ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà?

4 Ọ̀pọ̀ ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn ló wà nínú apá tá a dé yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà. A óò gbé àwọn ìlànà wọ̀nyí yẹ̀ wò: (1) Jèhófà ò fẹ́ ká ṣe àgàbàgebè nínú ìjọsìn wa, (2) ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin ni Ọlọ́run ní sáwọn èèyàn rẹ̀, (3) a ní láti máa ní ìrètí nínú Jèhófà nígbà gbogbo, (4) àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán ní gbogbo ìgbà, àti (5) àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà.

Jèhófà Ò Fẹ́ Ká Ṣe Àgàbàgebè Nínú Ìjọsìn Wa

5. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa jọ́sìn òun?

5 Jèhófà fẹ́ ká máa sin òun lọ́nà tó mọ́, láìsí àgàbàgebè. Àmọ́, Ísírẹ́lì di “àjàrà jíjẹrà bàjẹ́” tí kò lè so èso kankan. Àwọn tó ń gbé ní Ísírẹ́lì ‘sọ àwọn pẹpẹ di púpọ̀’ kí wọ́n bàa lè máa bọ̀rìṣà níbẹ̀. Àwọn apẹ̀yìndà wọ̀nyí tiẹ̀ ṣe onírúurú ọwọ̀n, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ òpó aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tí wọ́n dìídì ṣe fún lílò nínú ìjọsìn àìmọ́. Nígbà tó yá, Jèhófà wó gbogbo pẹpẹ àtàwọn òpó wọ̀nyí palẹ̀.—Hóséà 10:1, 2.

6. Ká lè máa bá Ọlọ́run rìn, irú ìwà wo la gbọ́dọ̀ fà tu kúrò nínú ọkàn wa?

6 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ alágàbàgebè. Àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? ‘Ọkàn wọn di alágàbàgebè’! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti bá Jèhófà dá májẹ̀mú ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n sì ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un, síbẹ̀ wọ́n ṣe àgàbàgebè nínú ìjọsìn wọn. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú èyí? Òun ni pé tá a bá ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kò yẹ ká máa ṣe àgàbàgebè. Òwe 3:32 kìlọ̀ pé: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” Ká bàa lè máa bá Ọlọ́run rìn, a ní láti máa fi ìfẹ́ hàn “láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.”—1 Tímótì 1:5.

Ìfẹ́ Tó Dúró Ṣinṣin Ni Ọlọ́run Ní Sáwọn Èèyàn Rẹ̀

7, 8. (a) Kí ló lè mú ká jàǹfààní ìfẹ́ Ọlọ́run tó dúró ṣinṣin? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá?

7 Tá a bá ń fi òótọ́ ọkàn sin Jèhófà láìsí àgàbàgebè, a ó jàǹfààní inú rere onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ rẹ̀ tó dúró ṣinṣin. Wòlíì Hóséà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì oníwàkiwà náà pé: “Ẹ fún irúgbìn fún ara yín ní òdodo; ẹ kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Ẹ ro ilẹ̀ adárafọ́gbìn fún ara yín nígbà tí àkókò wà fún wíwá Jèhófà, títí yóò fi dé, tí yóò sì fún yín ní ìtọ́ni ní òdodo.”—Hóséà 10:12.

8 Ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá mà dára gan-an o ká ní pé wọ́n ronú pìwà dà tí wọ́n sì wá Jèhófà! Tìdùnnú-tìdùnnú ni ì bá sì ‘fún wọn ní ìtọ́ni ní òdodo.’ Bí àwa náà bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan, ẹ jẹ́ ká wá Jèhófà, ká gbàdúrà pé kó dárí jì wá ká sì lọ bá àwọn alàgbà ìjọ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (Jákọ́bù 5:13-16) Ó sì yẹ ká bẹ Ọlọ́run pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, torí pé “ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.” (Gálátíà 6:8) Tá a bá “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn,” a óò máa jàǹfààní ìfẹ́ Ọlọ́run tó dúró ṣinṣin nìṣó.

9, 10. Báwo ni ohun tí Hóséà 11:1-4 sọ ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu?

9 Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé kò sígbà kan tí Jèhófà kì í fi ìfẹ́ bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò. Ẹ̀rí èyí wà nínú Hóséà 11:1-4, ibẹ̀ kà pé: “Nígbà tí Ísírẹ́lì jẹ́ ọmọdékùnrin, nígbà náà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, láti Íjíbítì ni mo sì ti pe ọmọkùnrin mi. . . . Àwọn ère Báálì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí, àwọn ère fífín sì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú èéfín ẹbọ sí. Ṣùgbọ́n ní tèmi, mo kọ́ Éfúráímù [ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] ní ìrìn, ní gbígbé wọn sí apá mi; wọn kò sì mọ̀ pé mo ti mú wọn lára dá. Mo ń bá a nìṣó láti fi àwọn ìjàrá ará ayé fà wọ́n, pẹ̀lú àwọn okùn ìfẹ́, tí ó fi jẹ́ pé, sí wọn, mo dà bí àwọn tí ó gbé àjàgà kúrò ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sì ni mo gbé oúnjẹ wá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”

10 Jèhófà fi Ísírẹ́lì wé ọmọ kékeré nínú ẹsẹ yẹn. Ó fi ìfẹ́ kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìrìn, ó di apá wọn mú. Ó sì fi “okùn ìfẹ́” fà wọ́n. Ìfẹ́ yìí mà pọ̀ o! Ká sọ pé òbí ni ọ́, o wá ń fa ọmọ rẹ kékeré ní tẹ̀ẹ̀tẹ́ láti ṣíṣẹ̀ rìn fún ìgbà àkọ́kọ́. O lè na apá rẹ sí i. O tiẹ̀ lè na okùn kan sí i tó máa dì mú kó má bàa ṣubú. Bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ gan-an nìyẹn. Ó jẹ́ ayọ̀ rẹ̀ láti fi “okùn ìfẹ́” darí rẹ.

11. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà ‘dà bí ẹni tí ó gbé àjàgà kúrò’?

11 Bí Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò dà bí ìgbà tá a bá sọ pé ‘ó gbé àjàgà kúrò ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, lẹ́sọ̀lẹsọ̀ ló sì gbé oúnjẹ wá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.’ Ọlọ́run dà bí ẹnì kan tí ó gbé àjàgà kúrò lọ́rùn ẹranko kan tàbí tí ó sún àjàgà náà sẹ́yìn dáadáa kó lè rọrùn fún ẹran náà láti jẹ oúnjẹ rẹ̀. Kíkúrò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lábẹ́ Jèhófà ló mú kí wọ́n bọ́ sábẹ́ àjàgà àwọn ọ̀tá wọn tó wá ń fojú wọn gbolẹ̀. (Diutarónómì 28:45, 48; Jeremáyà 28:14) Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra ká má bàa bọ́ sọ́wọ́ Sátánì olórí ọ̀tá wa, torí pé tá a bá lọ bọ́ sábẹ́ àjàgà rẹ̀ yóò fojú wa rí màbo. Dípò ìyẹn, ẹ jẹ́ ká máa fi ìṣòtítọ́ bá Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ rìn nìṣó.

Máa Ní Ìrètí Nínú Jèhófà Nígbà Gbogbo

12. Gẹ́gẹ́ bí Hóséà 12:6 ṣe sọ, kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó?

12 Tá a bá fẹ́ máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa ní ìrètí nínú rẹ̀ nígbà gbogbo. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ní ti ìwọ, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ ni kí o padà sí, ní pípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mọ́; kí o sì máa ní ìrètí nínú Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.” (Hóséà 12:6) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà, pé àwọn ti padà sọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n ní láti máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìdájọ́ òdodo hàn kí wọ́n sì máa ‘ní ìrètí nínú Ọlọ́run nígbà gbogbo.’ Bó ti wù kí iye ọdún tá a ti fi ń bá Ọlọ́run rìn bọ́ pọ̀ tó, a ṣì gbọ́dọ̀ máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìdájọ́ òdodo hàn, ká sì tún máa ní ìrètí nínú Ọlọ́run nígbà gbogbo.—Sáàmù 27:14.

13, 14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé Hóséà 13:14, báwo sì ni èyí ṣe jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká ní ìrètí nínú Jèhófà?

13 Ohun tí Hóséà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní ìrètí nínú Ọlọ́run. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò tún wọn rà padà láti ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù; èmi yóò mú wọn padà láti inú ikú. Ìwọ Ikú, ìtani rẹ dà? Ìwọ Ṣìọ́ọ̀lù, ìpanirun rẹ dà?” (Hóséà 13:14) Kì í ṣe pé Jèhófà fẹ́ gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ikú lásìkò yẹn o, àmọ́ yóò gbé ikú mì títí láé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, kò sì ní jẹ́ kí ikú máa pa èèyàn mọ́.

14 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bíi tirẹ̀, ó fa àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà yọ, ó ní: “Nígbà tí èyí tí ó lè díbàjẹ́ yìí bá gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, tí èyí tí ó jẹ́ kíkú yìí sì gbé àìkú wọ̀, nígbà náà ni àsọjáde náà yóò ṣẹ, èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘A ti gbé ikú mì títí láé.’ ‘Ikú, ìjagunmólú rẹ dà? Ikú, ìtani rẹ dà?’ Ìtani tí ń mú ikú jáde ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n agbára fún ẹ̀ṣẹ̀ ni Òfin. Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, nítorí ó ń fún wa ní ìjagunmólú nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi!” (1 Kọ́ríńtì 15:54-57) Jèhófà jí Jésù dìde, èyí sì jẹ́ ká ní ìfọkànbalẹ̀ àti ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò jí àwọn kan dìde. (Jòhánù 5:28, 29) Ẹ ò rí i pé ìdí tó dára gan-an nìyí láti ní ìrètí nínú Jèhófà! Àmọ́, yàtọ̀ sí ìrètí àjíǹde, nǹkan míì ṣì tún wà tó ń mú ká fẹ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn.

Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Dúró Ṣánṣán Ní Gbogbo Ìgbà

15, 16. Kí ni Hóséà sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Samáríà, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ?

15 Ìdánilójú tá a ní pé “àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán” ń jẹ́ ká lè máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó. Àwọn tó ń gbé ní Samáríà ò rìn ní àwọn ọ̀nà òdodo Ọlọ́run. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti bí wọn kò ṣe nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Hóséà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó ka Samáríà sí ẹlẹ́bi, nítorí pé ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ní ti tòótọ́ sí Ọlọ́run rẹ̀. Wọn yóò tipa idà ṣubú. Àwọn ọmọ wọn ni a óò fọ́ túútúú, àwọn aboyún wọn pàápàá ni a ó sì la inú wọn.” (Hóséà 13:16) Ìtàn fi hàn pé àwọn ará Ásíríà tí wọ́n ṣẹ́gun Samáríà lè hu irú ìwà ìkà bíburú jáì bẹ́ẹ̀.

16 Samáríà ni olú ìlú ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì. Àmọ́, Samáríà tún lè tọ́ka sí gbogbo ibi tó wà lábẹ́ ìjọba náà nílé-lóko. (1 Ọba 21:1) Ṣálímánésà Karùn-ún tí í ṣe ọba Ásíríà gbógun ti ìlú Samáríà lọ́dún 742 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí Ásíríà wá ṣẹ́gun Samáríà lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, púpọ̀ lára àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tó ń gbé níbẹ̀ ni wọ́n kó lọ sígbèkùn ní Mesopotámíà àti Mídíà. Bóyá Ṣálímánésà Karùn-ún ló ṣẹ́gun Samáríà ni tàbí ẹni tó gorí àlééfà lẹ́yìn rẹ̀, ìyẹn Ságónì Kejì, kò sẹ́ni tó lè sọ ní pàtó. (2 Ọba 17:1-6, 22, 23; 18:9-12) Àmọ́ èyí ó wù ó jẹ́, àkọsílẹ̀ nípa ìjọba Ságónì fi hàn pé ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé àádọ́rùn-ún lérúgba [27,290] àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n lé kúrò lágbègbè yẹn lọ sápá òkè Odò Yúfírétì àti ilẹ̀ Mídíà.

17. Dípò tá ò fi ní ka ìlànà Ọlọ́run sí, kí ló yẹ ká máa ṣe?

17 Ìyà tó jẹ àwọn tó ń gbé ní Samáríà kì í ṣe kékeré nítorí pé wọn kò rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà tó dúró ṣánṣán. Bákan náà, tí àwa tá a jẹ́ Kristẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́ bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà tá ò sì ka àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run sí, ìyà tó máa jẹ àwa náà ò ní kéré. Ẹ má ṣe jẹ́ ká hu irú ìwà burúkú yẹn o! Dípò ìyẹn, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù yìí: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n bí òun bá jìyà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, kí ó má ṣe tijú, ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní yíyin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí.”—1 Pétérù 4:15, 16.

18. Báwo la ṣe lè “máa bá a nìṣó ní yíyin Ọlọ́run lógo”?

18 Ọ̀nà kan tá a lè gbà “máa bá a nìṣó ní yíyin Ọlọ́run lógo” ni pé ká máa rìn ní àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀, dípò tí a ó fi máa ṣe tinú wa. Torí pé Kéènì ṣe tinú ẹ̀ tí kò sì gba ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún un pé ẹ̀ṣẹ̀ máa tó lé e bá ló mú kó pààyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1-8) Báláámù gba owó tí ọba Móábù fún un nígbà tí ìyẹn ní kó lọ bá òun ṣépè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. (Númérì 24:10) Ọlọ́run pa Kórà ọmọ Léfì àtàwọn mìíràn nítorí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì tó jẹ́ aṣáájú. (Númérì 16:1-3, 31-33) Ó dájú pé, a ò ní fẹ́ tẹ̀ lé “ipa ọ̀nà Kéènì” tó jẹ́ apànìyàn tàbí “ipa ọ̀nà ìṣìnà Báláámù,” bẹ́ẹ̀ la ò sì ní fẹ́ ṣègbé “nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ Kórà.” (Júúdà 11) Síbẹ̀, tá a bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà lè tù wá nínú.

Àwọn Tó Dẹ́ṣẹ̀ Lè Padà Sọ́dọ̀ Jèhófà

19, 20. Irú ẹbọ wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ronú pìwà dà láǹfààní láti rú?

19 Kódà àwọn tí wọ́n ti kọsẹ̀ tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ńlá pàápàá lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Hóséà 14:1, 2 pàrọwà pé: “Padà wá, ìwọ Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí ìwọ ti kọsẹ̀ nínú ìṣìnà rẹ. Ẹ mú àwọn ọ̀rọ̀ dáni pẹ̀lú yín, kí ẹ sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Gbogbo yín, ẹ sọ fún un pé, ‘Kí o dárí ìṣìnà jì; kí o sì tẹ́wọ́ gba ohun rere, àwa yóò sì fi ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa rúbọ ní ìdápadà.’”

20 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ronú pìwà dà láǹfààní láti fi ‘ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wọn’ rúbọ sí Ọlọ́run. Ìrúbọ yìí jẹ́ ìyìn tó ti ọkàn wọn wá. Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí nígbà tó gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n “máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run . . . , èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ fún wa láti máa bá Ọlọ́run rìn ká sì máa rú irú ẹbọ yìí lónìí!

21, 22. Irú ìmúpadàbọ̀sípò wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ronú pìwà dà jàǹfààní rẹ̀?

21 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ti jáwọ́ nínú ìwàkiwà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì ti padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run ‘fi ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wọn’ rúbọ sí Ọlọ́run. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ló mú kí Ọlọ́run mú wọn padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí ìlérí tó ṣe. Hóséà 14:4-7 sọ pé: “Èmi [Jèhófà] yóò wo àìṣòótọ́ wọn sàn. Èmi yóò nífẹ̀ẹ́ wọn láti inú ìfẹ́ àtinúwá tèmi, nítorí pé ìbínú mi ti yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Èmi yóò dà bí ìrì sí Ísírẹ́lì. Òun yóò yọ ìtànná bí òdòdó lílì, yóò sì ta gbòǹgbò rẹ̀ bí Lẹ́bánónì. Àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ yóò yọ jáde, iyì rẹ̀ yóò sì dà bí ti igi ólífì, ìtasánsán rẹ̀ yóò sì dà bí ti Lẹ́bánónì. Wọn yóò tún jẹ́ olùgbé lábẹ́ òjìji rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Wọn yóò gbin ọkà, wọn yóò sì rudi bí àjàrà. Ìrántí rẹ̀ yóò dà bí wáìnì Lẹ́bánónì.”

22 Ọlọ́run mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ronú pìwà dà lára dá nípa tẹ̀mí, ó sì padà fẹ́ràn wọn bó ṣe fẹ́ràn wọn tẹ́lẹ̀. Jèhófà dà bí ìrì sí wọn ní ti pé ó ń rọ̀jò ìbùkún sórí wọn. Àwọn èèyàn Ọlọ́run tá a mú padà bọ̀ sípò tún padà níyì “bí ti igi ólífì,” wọ́n sì wá ń rìn láwọn ọ̀nà rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀nà Jèhófà Ọlọ́run làwa náà pinnu pé a óò ti máa rìn, kí ló yẹ ká ṣe?

Máa Rìn ní Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Tó Dúró Ṣánṣán Nìṣó

23, 24. Ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ni Hóséà fi parí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, báwo sì ni ọ̀rọ̀ náà ṣe kàn wá?

23 Tá a bá fẹ́ máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa lo “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè,” ká sì máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tó dúró ṣánṣán. (Jákọ́bù 3:17, 18) Ẹsẹ tó gbẹ̀yìn àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà kà pé: “Ta ni ó gbọ́n, kí ó lè lóye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó lóye, kí ó lè mọ̀ wọ́n? Nítorí àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán, àwọn olódodo sì ni yóò máa rìn nínú wọn; ṣùgbọ́n àwọn olùrélànàkọjá ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.”—Hóséà 14:9.

24 Dípò tí a ó fi máa tẹ̀ lé ọgbọ́n ayé àtàwọn ìlànà rẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àwọn ọ̀nà Ọlọ́run tó dúró ṣánṣán la óò máa rìn. (Diutarónómì 32:4) Ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ni Hóséà fi ṣèyẹn. Ó jíṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán an gẹ́lẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ ọ́ nítorí ó mọ̀ pé àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n àti olóye yóò lóye rẹ̀. Àwa náà ńkọ́? Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà bá ṣì ní ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ, a ò ní dáwọ́ dúró ní wíwá àwọn tí yóò tẹ́wọ́ gba inú rere onífẹ̀ẹ́ yìí. Inú wa sì dùn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mátíù 24:45-47.

25. Kí ló yẹ kí àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà tá a gbé yẹ̀ wò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?

25 Ó yẹ kí àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà tá a gbé yẹ̀ wò yìí ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó ká sì máa fi ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí sọ́kàn. (2 Pétérù 3:13; Júúdà 20, 21) Ohun tá à ń retí yìí ti lọ wà jù! A óò dénú ayé tuntun tá à ń retí náà tá a bá ń jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa pé lóòótọ́ la gbà pé, “Àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán.”

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe bá wa lò tó bá jẹ́ pé ọkàn mímọ́ la fi ń sìn ín?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ní ìrètí nínú Jèhófà nígbà gbogbo?

• Kí ló mú kó dá ọ lójú pé àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán?

• Báwo la ṣe lè máa rìn nìṣó láwọn ọ̀nà Jèhófà tó dúró ṣánṣán?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Lọ bá àwọn alàgbà ìjọ kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká ní ìrètí nínú ìlérí Jèhófà pé òun yóò jí àwọn òkú dìde

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó kó o sì máa fi ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun sọ́kàn