Bá Ọlọ́run Rìn Kó O Lè Kórè Ohun Tó Dára
Bá Ọlọ́run Rìn Kó O Lè Kórè Ohun Tó Dára
“Ẹ̀fúùfù ni wọ́n ń bá a nìṣó ní fífúnrúgbìn, ẹ̀fúùfù oníjì sì ni wọn yóò ká.”—HÓSÉÀ 8:7.
1. Báwo la ṣe lè bá Jèhófà rìn?
BÓ O bá fẹ́ gba àgbègbè eléwu kan kọjá, ọkàn rẹ á túbọ̀ balẹ̀ tó bá jẹ́ pé ẹni tó mọ ibẹ̀ dáadáa ló ṣáájú re. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ rìn dípò kó o kàn máa dá rìn lọ. Àpẹẹrẹ yìí bá ipò tá a wà mu láwọn ọ̀nà kan. Jèhófà ń sọ fún wa pé òun á tọ́ wa sọ́nà bá a ṣe ń rìn nínú ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí tó dà bí aṣálẹ̀ ńlá kan. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká bá a rìn dípò ká máa gbìyànjú láti darí ìṣísẹ̀ ara wa. Báwo la ṣe lè bá Ọlọ́run rìn? Bá a ṣe lè bá a rìn ni pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Hóséà orí kìíní sí ìkarùn-ún. A ti rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti bá Ọlọ́run rìn wà nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ yẹn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Hós orí kẹfà sí ìkẹsàn-án. Ó máa dára ká kọ́kọ́ ṣe àkópọ̀ àwọn ohun tó wà nínú orí mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.
Àkópọ̀ Ohun Tó Wà Nínú Orí Mẹ́rẹ̀ẹ̀rin
3. Ní ṣókí, ṣe àkópọ̀ ohun tó wà nínú Hóséà orí kẹfà sí ìkẹsàn-án.
3 Ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá ni Jèhófà dìídì rán Hóséà láti lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún. Orílẹ̀-èdè náà tó tún ń jẹ́ Éfúráímù, ìyẹn orúkọ ẹ̀yà tó jẹ́ akíkanjú níbẹ̀, ti kọ Ọlọ́run sílẹ̀. Hós Hóséà orí kẹfà sí ìkẹsàn-án jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn náà hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà nítorí pé wọ́n ń tẹ májẹ̀mú rẹ̀ lójú, wọ́n sì ń hùwà búburú. (Hóséà 6:7) Ńṣe ni wọ́n lọ lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn dípò kí wọ́n padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Nítorí pé ohun búburú ni wọ́n ń fúnrúgbìn, ohun búburú náà ni wọ́n máa ká, tó túmọ̀ sí pé ìdájọ́ Ọlọ́run á dé sórí wọn. Àmọ́ o, Hóséà tún sọ ohun tó lè múnú àwọn èèyàn náà dùn. Ó mú kó dá wọn lójú pé wọ́n lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà àti pé Jèhófà yóò ṣojú àánú sí wọn bí wọ́n bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.
4. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà?
4 A lè rí ìtọ́sọ́nà síwájú sí i tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti bá Ọlọ́run rìn látinú orí mẹ́rin yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́rin tá a lè rí kọ́: (1) Ìwà ẹni ló máa fi hàn pé èèyàn ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán; (2) ẹbọ rírú nìkan ò lè múnú Ọlọ́run dùn; (3) ó máa ń dun Jèhófà báwọn olùjọsìn rẹ̀ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀; àti (4) ká tó lè kórè ohun tó dára, a gbọ́dọ̀ fúnrúgbìn ohun tó dára.
Ohun Tó Máa Fi Hàn Pé Èèyàn Ronú Pìwà Dà Tọkàntọkàn
5. Sọ kókó inú Hóséà orí kẹfà ẹsẹ kìíní sí ìkẹta.
5 Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà àti àánú. Hóséà orí kẹfà ẹsẹ kìíní sí ìkẹta sọ pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ènìyàn, ẹ sì jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Jèhófà, nítorí òun fúnra rẹ̀ ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ṣùgbọ́n òun yóò mú wa lára dá. Ó ń bá a nìṣó ní kíkọlù, ṣùgbọ́n òun yóò di ọgbẹ́ wa. Òun yóò sọ wá di ààyè lẹ́yìn ọjọ́ méjì. Ní ọjọ́ kẹta, òun yóò mú kí a dìde, àwa yóò sì wà láàyè níwájú rẹ̀. Àwa yóò sì mọ̀, a óò lépa láti mọ Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀yẹ̀, ìjáde lọ rẹ̀ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Òun yóò sì wọlé sọ́dọ̀ wa bí ọ̀yamùúmùú òjò; bí òjò ìgbà ìrúwé tí ń mú ilẹ̀ rin gbingbin.”
6-8. Kí nìdí tí ìrònúpìwàdà Ísírẹ́lì kì í fi í ṣe àtọkànwá?
6 Ta ló sọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ẹsẹ yìí? Àwọn kan sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ló sọ ọ́. Wọ́n ní ńṣe làwọn aláìgbọràn ọ̀hún ń ṣe bíi pé àwọn ti ronú pìwà dà, àmọ́ wọ́n ṣì ń dẹ́ṣẹ̀ nítorí wọ́n ti gbà pé aláàánú ni Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn mìíràn sọ pé wòlíì Hóséà ló sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ní ńṣe ló ń bẹ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ẹni yòówù kó sọ̀rọ̀ yìí, ìbéèrè pàtàkì tó yẹ ká wá ìdáhùn sí ni pé, Ǹjẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló padà sọ́dọ̀ Jèhófà, tí wọ́n sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Rárá o. Jèhófà gbẹnu Hóséà sọ pé: “Kí ni èmi yóò ṣe sí ọ, ìwọ Éfúráímù? Kí ni èmi yóò ṣe sí ọ, ìwọ Júdà, nígbà tí inú-rere yín onífẹ̀ẹ́ dà bí àwọsánmà òwúrọ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ìrì tí ń tètè lọ?” (Hóséà 6:4) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ipò táwọn èèyàn Ọlọ́run wà nípa tẹ̀mí burú gan-an ni! Inú rere onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin tí wọ́n ní ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá gẹ́gẹ́ bí kùrukùru tí kì í pẹ́ pòórá nígbà tí oòrùn bá yọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà ń ṣe bíi pé àwọn ti ronú pìwà dà, Jèhófà kò rídìí tó fi máa ṣàánú wọn. Kí nìdí?
7 Ìrònúpìwàdà Ísírẹ́lì kì í ṣe àtọkànwá. Hóséà 7:14 sọ̀rọ̀ kan nípa ìbínú Jèhófà sáwọn èèyàn Rẹ̀, ó ní: “Wọn kò . . . fi ọkàn-àyà wọn ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń hu ṣáá lórí ibùsùn wọn.” Hós Ẹsẹ kẹrìndínlógún fi kún un pé: “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí padà, kì í ṣe sí ohunkóhun tí ó ga sí i,” ìyẹn ni pé “kì í ṣe sí ìjọsìn tó dára ju ìyẹn lọ.” (Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Wọn kò ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú rẹ̀ bàa lè tún dán mọ́rán torí pé kò wù wọ́n láti padà sínú ìjọsìn Jèhófà tó lékè gbogbo ìjọsìn mìíràn. Àní, àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ò fẹ́ bá Ọlọ́run rìn rárá àti rárá ni.
8 Ìdí mìíràn tún wà tí ìrònúpìwàdà Ísírẹ́lì kì í fi í ṣe àtọkànwá. Àwọn èèyàn náà ṣì ń dẹ́ṣẹ̀. Kódà, oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n ń dá, wọ́n ń lu jìbìtì, wọ́n ń pààyàn, wọ́n ń jalè, wọ́n ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, èyí tí kò bọ́gbọ́n mu. Ní Hóséà 7:4, Ọlọ́run fi àwọn èèyàn náà wé “ìléru” tàbí ibi tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì, nítorí pé ìfẹ́ àtiṣe ohun búburú ń jó fòfò lọ́kàn wọn. Níwọ̀n bí ipò wọn nípa tẹ̀mí ti burú tó báyìí, ǹjẹ́ àánú tọ́ sí wọn? Rárá o! Hóséà sọ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹ̀dá náà pé Jèhófà yóò “rántí ìṣìnà wọn,” yóò sì “fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní àfiyèsí.” (Hóséà 9:9) Jèhófà kò ní ṣàánú wọn rárá!
9. Ẹ̀kọ́ wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà kọ́ wa nípa ìrònúpìwàdà àti àánú?
9 Ẹ̀kọ́ wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà kọ́ wa nípa ìrònúpìwàdà àti àánú? Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ni pé ká tó lè jàǹfààní àánú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Kí ló máa fi hàn pé ẹnì kan ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Ẹ̀dá èèyàn ò lè fi omijé tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu lásán tan Jèhófà jẹ. Ìwà ẹni ló máa fi hàn bóyá èèyàn ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Kí Ọlọ́run tó lè ṣàánú ẹlẹ́ṣẹ̀ kan, ó gbọ́dọ̀ kọ gbogbo ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ lákọ̀tán, kó sì jẹ́ kí àwọn ìlànà pàtàkì tó wà nínú ìjọsìn Jèhófà tó lékè gbogbo ìjọsìn mìíràn máa darí gbogbo ohun tó bá ń ṣe.
Ẹbọ Rírú Nìkan Ò Lè Múnú Jèhófà Dùn
10, 11. Bá a ṣe rí i nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí nìdí tí ẹbọ lásán ò fi lè múnú Jèhófà dùn?
10 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ kejì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti bá Jèhófà rìn. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ẹbọ rírú nìkan ò lè múnú Ọlọ́run dùn. Hóséà 6:6 sọ pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni mo [Jèhófà] ní inú dídùn sí, kì í sì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun.” Kíyè sí i pé ohun tó ń múnú Jèhófà dùn ni pé ká ní inú rere onífẹ̀ẹ́, èyí tó ń tinú ọkàn wá, ká sì ní ìmọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kó o máa wò ó pé: ‘Kí nìdí tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi sọ pé Jèhófà kò ní inú dídùn sí “ẹbọ” àti “odindi ọrẹ ẹbọ sísun”? Òfin Mósè kọ́ ló béèrè nǹkan wọ̀nyẹn ni?’
11 Òótọ́ ni pé ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ pọn dandan lábẹ́ Òfin Mósè àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n gbé ayé lásìkò Hóséà ní ìṣòro ńlá kan. Ó hàn gbangba pé àwọn kan wà tí wọ́n ń rúbọ bí òfin ṣe pa á láṣẹ ṣùgbọ́n ojú ayé lásán ni wọ́n ń ṣe. Ìdí ni pé bí wọ́n ṣe ń rúbọ náà ni wọ́n tún ń dẹ́ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń dá yìí fi hàn pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run kò jinlẹ̀. Ó tún fi hàn pé wọ́n ti kọ ìmọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ nítorí pé ìwà wọn lòdì sí ohun tí Ọlọ́run sọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọkàn wọn ò mọ́, tí wọn ò sì hùwà tí Ọlọ́run fẹ́, kí wá ni gbogbo ẹbọ wọn já mọ́? Kò sí àní-àní pé ìríra gbáà ni ẹbọ wọn jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run.
12. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo làwọn èèyàn òde òní lè rí kọ́ nínú Hóséà orí kẹfà ẹsẹ ìkẹfà?
12 Ìkìlọ̀ ni ọ̀rọ̀ Hóséà jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lónìí. Àwọn ààtò ìsìn tí wọ́n ń ṣe ni ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Ọlọ́run. Àmọ́, ìjọsìn wọn ò ní ipa gidi kan lórí ìwà wọn. Ǹjẹ́ inú Ọlọ́run á dùn sáwọn èèyàn wọ̀nyí lóòótọ́ bí ọkàn wọn ò bá sún wọn láti gba ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa fi ohun tí wọ́n ń kọ́ náà sílò nípa yíyàgò pátápátá fún ẹ̀ṣẹ̀? Kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé ṣíṣe àwọn ààtò ìsìn nìkan ti tó láti múnú Ọlọ́run dùn o. Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sáwọn tó ń gbìyànjú láti wá ojúure rẹ̀ nípa ṣíṣe ìjọsìn ojú ayé dípò kí wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣèwà hù.—2 Tímótì 3:5.
13. Irú àwọn ẹbọ wo là ń rú, àmọ́ kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nípa ohun tó máa jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n?
13 Àwa Kristẹni tòótọ́ ní láti máa rántí pé ẹbọ rírú nìkan ò lè múnú Ọlọ́run dùn. Òótọ́ ni pé a kì í fi ẹran rúbọ sí Jèhófà. Síbẹ̀, à ń “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run . . . èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) A kò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n gbé lásìkò Hóséà, kí àwa náà máa rò pé a lè rú irú àwọn ẹbọ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ sí Ọlọ́run láti fi dí ẹ̀ṣẹ̀ tá a bá dá. Ẹ wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́ kan tó lọ ṣèṣekúṣe lábẹ́lẹ̀. Ó sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí jáde òde ẹ̀rí lemọ́lemọ́ torí mo rò pé èyí á bo ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀.” Èyí ò yàtọ̀ si ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì oníwàkiwà gbìyànjú láti ṣe láyé ọjọ́un. Àmọ́ ṣá o, ìgbà tí ọkàn wa bá mọ́ tá a sì ń hùwà tí Ọlọ́run fẹ́ nìkan ni Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìyìn wa.
Ó Máa Ń Dun Jèhófà Bí Àwọn Olùjọsìn Rẹ̀ Bá Kọ̀ Ọ́ Sílẹ̀
14. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà jẹ́ ká mọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run?
14 Ẹ̀kọ́ kẹta tá a rí kọ́ látinú Hóséà orí kẹfà sí ìkẹsàn-án jẹ mọ́ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà bí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó fẹ́, èyí máa ń mú inú rẹ̀ dùn àmọ́ tí wọn kò bá ṣe ohun tó fẹ́ ó máa ń bà á nínú jẹ́. Báwọn èèyàn bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, inú rẹ̀ máa ń dùn ó sì máa ń fi ìyọ́nú hàn sí wọn. Àmọ́, kì í jẹ́ káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà bí wọ́n bá kọ̀ tí wọn kò ronú pìwà dà. Nítorí pé Ọlọ́run bìkítà fún wa, inú rẹ̀ máa ń dùn tá a bá ń fi ìṣòtítọ́ bá a rìn. Sáàmù 149:4 sọ pé: “Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àmọ́, báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run báwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá hùwà àìṣòótọ́?
15. Gẹ́gẹ́ bí Hóséà 6:7 ṣe sọ, ìwà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ń hù?
15 Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́, ó sọ pé: “Àwọn fúnra wọn, gẹ́gẹ́ bí ará ayé, ti tẹ májẹ̀mú lójú. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ṣe àdàkàdekè sí mi.” (Hóséà 6:7) Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí ‘ṣe àdàkàdekè’ tún túmọ̀ sí ‘híhùwà ẹ̀tàn, tàbí híhùwà àìṣòótọ́.’ Nínú Málákì orí kejì ẹsẹ kẹwàá sí ìkẹrìndínlógún, ọ̀rọ̀ Hébérù yìí kan náà la lò láti fi ṣàpèjúwe ìwà àìṣòótọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn tí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí aya wọn. Nígbà tí ìwé kan ń ṣàlàyé bí Hóséà orí kẹfà ẹsẹ ìkeje ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí, ó ní ìlò ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Ísírẹ́lì ti wà nínú àjọṣe tímọ́tímọ́ kan pẹ̀lú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí àjọṣe lọ́kọláya, àmọ́ wọ́n hùwà ẹ̀tàn sí i dípò ìfẹ́ tó ní sí wọn.
16, 17. (a) Kí ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe sí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá wọn dá? (b) Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nípa ìwà wa?
16 Májẹ̀mú tí Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá ló mú kó kà wọ́n sí aya rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ tẹ májẹ̀mú náà lójú, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń ṣe panṣágà. Ọlọ́run dà bí ọkọ kan tó jẹ́ olóòótọ́ sí aya rẹ̀, àmọ́ ńṣe làwọn èèyàn rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀!
17 Àwa náà ńkọ́? Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká máa bá òun rìn. Ká má ṣe gbàgbé pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìwà wa sì lè múnú rẹ̀ dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́. (1 Jòhánù 4:16) Bá a bá ń hùwà àìtọ́, ohun tó ń dun Jèhófà tó sì máa bà á nínú jẹ́ là ń ṣe yẹn. Tá a bá fi èyí sọ́kàn, yóò ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti má ṣe hùwà àìtọ́ nígbà ìdẹwò.
Bá A Ṣe Lè Kórè Ohun Tó Dára
18, 19. Ìlànà wo ló wà nínú Hóséà 8:7, báwo sì lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé òótọ́ ni ìlànà yìí?
18 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ kẹrin tá a lè rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà, ìyẹn ni bá a ṣe lè kórè ohun tó dára. Nígbà tí Hóséà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti bí ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n ń hù ṣe jẹ́ ìwà òmùgọ̀ àti asán tó, ó ní: “Ẹ̀fúùfù ni wọ́n ń bá a nìṣó ní fífúnrúgbìn, ẹ̀fúùfù oníjì sì ni wọn yóò ká.” (Hóséà 8:7) Ìlànà kan wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí tó yẹ ká máa fi sọ́kàn, ìyẹn ni pé ohun tá a bá fúnrúgbìn la óò ká. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ṣe fi hàn pé òótọ́ ni ìlànà yìí?
19 Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń dẹ́ṣẹ̀, ohun búburú ni wọ́n ń fúnrúgbìn yẹn. Ṣé wọ́n á lè máa hùwà ìbàjẹ́ lọ láìká ohun búburú? Rárá o. Ó dájú pé Ọlọ́run á fìyà tó múná jẹ wọ́n. Hóséà 8:13 sọ pé: “[Jèhófà] yóò rántí ìṣìnà wọn, yóò sì béèrè ìjíhìn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Síwájú sí i, Hóséà 9:17 kà pé: “Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n, nítorí tí wọn kò fetí sí i, wọn yóò sì di ìsáǹsá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà á mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì jíhìn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí pé ohun búburú ni wọ́n fúnrúgbìn, ohun búburú náà ni wọn yóò sì ká. Ìdájọ́ Ọlọ́run dé lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun Ísírẹ́lì tó jẹ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá, tí wọ́n sì kó àwọn èèyàn ibẹ̀ nígbèkùn.
20. Ẹ̀kọ́ wo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ wa?
20 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ohun téèyàn bá fúnrúgbìn ló máa ká. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Bá a bá fúnrúgbìn ohun búburú, ohun búburú la máa ká. Bí àpẹẹrẹ, ó ti dájú pé àwọn oníṣekúṣe á jẹ̀ka àbámọ̀ gbẹ̀yìn ni. Ìgbẹ̀yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà ò ní dára rárá.
21. Báwo la ṣe lè kórè ohun tó dára?
21 Báwo la ṣe wá lè kórè ohun tó dára? A lè fi àpèjúwe ṣókí kan dáhùn ìbéèrè yìí. Ká ní àgbẹ̀ kan fẹ́ kórè ìrẹsì, kí ló máa gbìn? Ṣé àgbàdo ni? Rárá o! Ohun tó bá fẹ́ kórè ló gbọ́dọ̀ gbìn. Lọ́nà kan náà, bá a bá fẹ́ kórè ohun tó dára, ohun tó dára la gbọ́dọ̀ gbìn. Ṣé ohun tó dára ni wàá fẹ́ kórè, ìyẹn ni pé ṣé ó wù ọ́ kí ìgbésí ayé rẹ dùn kó sì lárinrin nísinsìnyí, kó o sì tún máa wọ̀nà fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun Ọlọ́run? Bó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, o ní láti máa fúnrúgbìn ohun tó dára nìṣó nípa bíbá Ọlọ́run rìn àti nípa fífi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ ṣèwà hù.
22. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú orí kẹfà sí ìkẹsàn-án ìwé Hóséà?
22 Nínú orí kẹfà sí ìkẹsàn-án ìwé Hóséà, a ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́rin tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti bá Ọlọ́run rìn. Àwọn ẹ̀kọ náà ni pé: (1) Ìwà ẹni ló máa fi hàn bóyá èèyàn ronú pìwà dà tọkàntọkàn; (2) ẹbọ rírú nìkan ò lè múnú Ọlọ́run dùn; (3) ó máa ń dun Jèhófà báwọn olùjọsìn rẹ̀ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀; àti (4) ká tó lè kórè ohun tó dára, a gbọ́dọ̀ fúnrúgbìn ohun tó dára. Báwo ni orí márùn-ún tó gbẹ̀yìn ìwé Hóséà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti bá Ọlọ́run rìn?
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló máa fi hàn pé èèyàn ronú pìwà dà tọkàntọkàn?
• Kí nìdí tí ẹbọ rírú nìkan ò fi lè múnú Baba wa ọ̀run dùn?
• Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run báwọn olùjọsìn rẹ̀ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀?
• Kí la gbọ́dọ̀ fúnrúgbìn tá a bá fẹ́ kórè ohun tó dára?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Inú rere onífẹ̀ẹ́ Ísírẹ́lì pòórá gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà òwúrọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ńṣe ni ìfẹ́ àtiṣe ohun búburú ń jó fòfò lọ́kàn Ísírẹ́lì bí iná ìléru
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kí nìdí tí Jèhófà ò fi gba ẹbọ táwọn èèyàn rẹ̀ ń rú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ká tó lè kórè ohun tó dára, a ní láti fúnrúgbìn ohun tó dára