Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Lẹ́mìí Ìfara-Ẹni-Rúbọ

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Lẹ́mìí Ìfara-Ẹni-Rúbọ

“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Lẹ́mìí Ìfara-Ẹni-Rúbọ

ỌKÙNRIN kan máa ń gun kẹ̀kẹ́ gba àárín igbó kìjikìji kan lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ló fi ń gun kẹ̀kẹ́ lójú ọ̀nà inú igbó náà tó lómi àti ẹrọ̀fọ̀ láìfi ewu ibẹ̀ pè, nítorí pé ó fẹ́ lọ gbé àwọn ẹlòmíràn ró. Lórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè, àwọn arákùnrin méjì kan tó fẹ́ lọ kọ́ àwọn ará tó wà ní àdádó lẹ́kọ̀ọ́ máa ń rin ìrìn kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lójú ọ̀nà tó láwọn odò tó kún àkúnya. Ńṣe ni wọ́n máa ń kó aṣọ àti bàtà wọn lé orí nítorí omi. Nílùú mìíràn, obìnrin kan máa ń jí lọ sílé nọ́ọ̀sì kan láago mẹ́rin ìdájí láti lọ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ torí pé àárọ̀ kùtù lobìnrin nọ́ọ̀sì náà máa ń ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wákàtí kan péré.

Kí làwọn tá a mẹ́nu kàn nínú àpẹẹrẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́? Gbogbo wọn jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò láti máa fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Irú àwọn òjíṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, míṣọ́nnárì, alábòójútó arìnrìn-àjò àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì káàkiri ayé. Gbogbo àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún wọ̀nyí ló ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. a

Irú Ẹ̀mí Tó Tọ́ Láti Ní

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì, ìyẹn: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Kí ló wá ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà di òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún?

Tá a bá bi àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún léèrè ìdí tí wọ́n fi ń ṣakitiyan tó pọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, lára ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ni pé, ìfẹ́ táwọn ní sí Ọlọ́run àti ọmọnìkejì àwọn ló mú káwọn máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 22:37-39) Ìyẹn ló sì dára jù, torí pé tí kì í bá ṣe ìfẹ́ ló ń mú wọn ṣakitiyan bẹ́ẹ̀, asán pátápátá ni wàhálà wọn máa já sí.—1 Kọ́ríńtì 13:1-3.

Iṣẹ́ Ìsìn Tó Gba Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ

Gbogbo Kristẹni tó bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run ló ti gbà láti ṣe ohun tí Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Tá a bá sọ pé èèyàn sẹ́ níní ara rẹ̀, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún finú-fíndọ̀ gbà pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ló ni òun àti pé àwọn ni yóò máa darí òun. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tó gba ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ.

Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ń sapá gidigidi láti mú kí iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà túbọ̀ tẹ̀ síwájú. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ti Júlia ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nílùú São Paulo, ni ilẹ̀ Brazil. Ó sọ pé: “Arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà tẹ̀ mí láago, ó sì béèrè bóyá màá fẹ́ láti kọ́ èdè àwọn ará Ṣáínà. Àmọ́ mi ò rò pé èdè kíkọ́ ló kàn níbi tí mo dàgbà dé yìí. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan ṣá, mo gbà láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè kíkọ́ kò rọrùn. Lónìí báyìí, mo ti lè fi èdè àwọn ará Ṣáínà wàásù.”

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Peru ròyìn pé: “Lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni wọ́n ti ṣí lọ sáwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni, tí wọ́n sì ń fi ìgboyà àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n ṣí lọ sáwọn ìlú tó jìnnà réré, níbi tí kò ti sí àwọn ohun amáyédẹrùn, tí kò sì rọrùn láti ríṣẹ́. Àwọn ará wọ̀nyí sì ń ṣe gbogbo ohun tó bá gbà kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ níbẹ̀. Ní pàtàkì, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ń mú kí ìtẹ̀síwájú wáyé láwọn ibi tí wọ́n lọ. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò sọ pé ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé wọ̀nyí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àwọn àwùjọ kéékèèké tuntun.”

Àwọn Kristẹni kan tiẹ̀ fẹ̀mí wọn wewu láti lè ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn. (Róòmù 16:3, 4) Alábòójútó àyíká kan tó wà ní àgbègbè kan tí wọ́n ti ń jagun nílẹ̀ Áfíríkà sọ pé: “Ká tó dé ibi ìkẹyìn táwọn ẹ̀ṣọ́ ojú ọ̀nà wà láàárín ibi táwọn ọmọ ogun àwọn ọlọ̀tẹ̀ ń ṣàkóso àti ibi tí ìjọba ń ṣàkóso, mẹ́rin lára ọ̀gágun àwọn ọlọ̀tẹ̀ àtàwọn ẹ̀ṣọ́ wọn yí èmi àti aya mi ká, wọ́n sì béèrè ẹni tá a jẹ́. Bí wọ́n ṣe ń yẹ ìwé ìdánimọ̀ wa wò, wọ́n rí i pé ibi tí ìjọba ń ṣàkóso la ti ń bọ̀, ara wọn ò sì balẹ̀ mọ́. Wọ́n ní amí ni mí. Wọ́n wá pinnu láti sọ mí sínú kòtò kan. Mo ṣàlàyé ẹni tá a jẹ́ fún wọn, wọ́n sì fi wá sílẹ̀ nígbà tó yá.” Inú àwọn ìjọ tí wọ́n lọ dùn gan-an pé tọkọtaya tó lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ yìí wá bẹ àwọn wò!

Ńṣe ni àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún wọ̀nyí ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé láìfi gbogbo ìnira tí wọ́n ń rí pè. (Aísáyà 6:8) Àwọn òjíṣẹ́ aláápọn yìí mọyì àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní láti sin Jèhófà lọ́nà yìí gan-an. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ kan náà yìí ló ń mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn máa yin Jèhófà lógo lóde òní. Jèhófà sì ń bù kún wọn jìngbìnnì. (Òwe 10:22) Àwọn òjíṣẹ́ aláápọn yìí mọ̀ dájú pé Jèhófà yóò máa bù kún àwọn nìṣó àti pé kò ní kúrò lẹ́yìn àwọn, ìyẹn ni wọ́n fi ní irú ẹ̀mí tí onísáàmù ní, ẹni tó kọrin pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo oṣù November àti December nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2005.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ.”—SÁÀMÙ 110:3.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

JÈHÓFÀ FẸ́RÀN ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ RẸ̀ TÓ JẸ́ OLÙFỌKÀNSÌN GAN-AN NI

“Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.

“Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Hébérù 6:10.