Ǹjẹ́ O Gbà Pé Èṣù Wà?
Ǹjẹ́ O Gbà Pé Èṣù Wà?
ÌWÉ MÍMỌ́ fi yé wa pé Èṣù wà lóòótọ́. Ẹ̀dá ẹ̀mí téèyàn ò lè fojú rí ni, bá ò ṣe lè fojú rí Ọlọ́run. Ìdí ni pé Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Àmọ́ Èṣù ò bá Ẹlẹ́dàá dọ́gba o, torí Èṣù ní ìbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dàá kò ní ìbẹ̀rẹ̀.
Jèhófà Ọlọ́run ti kọ́kọ́ dá ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá ẹ̀mí tipẹ́tipẹ́ kó tó dá ọmọ èèyàn. (Jóòbù 38:4, 7) Áńgẹ́lì ni Bíbélì pe àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí. (Hébérù 1:13, 14) Gbogbo wọn pátá ni Ọlọ́run dá ní pípé, kò sí ìkankan nínú wọn tó jẹ́ èṣù, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run kò dá ìwà ibi mọ́ èyíkéyìí lára wọn. Ibo wá ni Èṣù ti wá? Nínú àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ náà “èṣù” túmọ̀ sí “abanijẹ́,” ìyẹn, ẹnì kan tó ń parọ́ mọ́ni láti fi ba tẹni jẹ́. “Sátánì” túmọ̀ sí “Alátakò.” Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tẹ́lẹ̀ ṣe lè sọ ara rẹ̀ di olè tó bá lọ jí nǹkan, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí pípé tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ṣe ro èròkérò lọ́kàn, tó sì lọ ṣe ohun tó fi sọ ara rẹ̀ di Sátánì Èṣù. Bíbélì sọ bí ẹnì kan ṣe lè ba ìwà ara rẹ̀ jẹ́, ó ní: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.”—Jákọ́bù 1:14, 15.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, tọkọtaya àkọ́kọ́, áńgẹ́lì tó padà wá di ọlọ̀tẹ̀ yìí ń wo gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń ṣe. Ó mọ̀ pé Jèhófà pàṣẹ pé kí Ádámù àti Éfà bímọ káwọn ọmọ olóòótọ́ tí yóò máa sin Ẹlẹ́dàá lè kún inú ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Áńgẹ́lì yìí wò ó pé òun lè dá ọgbọ́n tóun á fi di ẹni pàtàkì táwọn ẹ̀dá á máa júbà. Ẹ̀mí ìwọra mú kí ojú rẹ̀ wọ ohun tó jẹ́ ti Ẹlẹ́dàá nìkan ṣoṣo, ìyẹn ni pé òun náà fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun. Dípò kó mú èrò burúkú yìí kúrò lọ́kàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí rẹ̀ títí tó fi purọ́ tó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ìwọ wo ohun tó ṣe.
Áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí lo ejò láti fi bá Éfà obìnrin Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ẹ̀sùn tó fi kan Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ tó sọ yìí ni pé Ọlọ́run kò sòótọ́ fún Ádámù àti Éfà. Ó fi yé Éfà pé tó bá jẹ èso igi náà yóò dà bí Ọlọ́run, yóò sì lè máa dá pinnu ohun tó jẹ́ rere àti ohun tó jẹ́ búburú. Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí ni irọ́ àkọ́kọ́ láyé àtọ̀run. Irọ́ tó pa yẹn ló sọ ọ́ di abanijẹ́. Ó sì tún jẹ́ kó di alátakò Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé ọ̀tá Ọlọ́run yìí ni “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì.”—Ìṣípayá 12:9.
àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Ejò náà bi Éfà pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Nígbà tí Éfà sọ àṣẹ tí Ọlọ́run pa àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tí kò bá pa á mọ́, ejò yẹn sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú [èso igi tí ó wà ní àárín ọgbà] ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (“Ẹ Máa Kíyè Sára”
Éfà gba irọ́ Èṣù gbọ́. Bíbélì sọ pé: “Nítorí náà, obìnrin náà rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni, bẹ́ẹ̀ ni, igi náà fani lọ́kàn mọ́ra láti wò. Nítorí náà, ó mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Éfà gba Èṣù gbọ́, ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì tún mú kí Ádámù rú òfin Ọlọ́run. Bí Èṣù ṣe gbin ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ sọ́kàn tọkọtaya àkọ́kọ́ nìyẹn kí wọ́n lè máa ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Látìgbà náà ni Sátánì ti fara pa mọ́ tó ń dá sí ọ̀ràn ẹ̀dá èèyàn. Kí nìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó fẹ́ yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà kí wọ́n má sin Ọlọ́run tòótọ́ mọ́ kí wọ́n lè máa sin òun. (Mátíù 4:8, 9) Abájọ tí Ìwé Mímọ́ fi kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—1 Pétérù 5:8.
Bíbélì jẹ́ kó yé wa kedere pé Èṣù jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí kan tàbí áńgẹ́lì tó ti ya ìyàkuyà tó sì léwu! Ohun àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì tó yẹ ká ṣe láti lè máa kíyè sára ni pé ká gbà pé Èṣù wà lóòótọ́. Àmọ́ o, ìyẹn nìkan kọ́ lohun tó yẹ ká ṣe ká lè máa pa agbára ìmòye wa mọ́ ká sì lè máa kíyè sára. Ó tún ṣe pàtàkì pẹ̀lú pé ká mọ “àwọn ète-ọkàn rẹ̀,” àtàwọn ọ̀nà tó gbà ń tanni jẹ. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Kí làwọn ọ̀nà àrékérekè tó ń lò? Kí la sì lè ṣe kí àrékérekè rẹ̀ má bàa mú wa?
Èṣù Máa Ń Lo Ìjọsìn Tọmọ Èèyàn Ò Lè Ṣàìṣe
Àtìgbà tí Ẹlẹ́dàá ti dá ọmọ èèyàn ni Èṣù ti ń kíyè sí wọn. Ó mọ ọmọ èèyàn látòkèdélẹ̀, ohun tí wọ́n nílò àti ohun tó ń wù wọ́n. Sátánì mọ̀ dáadáa pé Ọlọ́run dá ìjọsìn ṣíṣe mọ́ ọmọ èèyàn, pé èèyàn ò lè ṣàìṣe ìjọsìn, ó sì máa ń lò ó láti fi mú wọn. Ọ̀nà wo ló gbà ń ṣe èyí? Ó ń kọ́ ọmọ aráyé láwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tó jẹ́ irọ́. (Jòhánù 8:44) Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ táwọn onísìn ń kọ́ni nípa Ọlọ́run ló ta kora tó sì lọ́jú pọ̀. Ta lo rò pé ó fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀? Táwọn ẹ̀kọ́ kan bá sì ti ta kora, kò sí bí gbogbo rẹ̀ ṣe lè jóòótọ́. Nígbà náà, ṣé kì í ṣe pé Sátánì ló dá ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ìsìn sílẹ̀ tó sì ń lò ó láti fi ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? Àní Bíbélì pè é ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” tó ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.—2 Kọ́ríńtì 4:4.
Òtítọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa ń múni bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìtànjẹ ìsìn. Bíbélì fi òótọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé àmùrè tí ọmọ ogun máa ń dì láyé àtijọ́ láti fi dáàbò bo abẹ́nú rẹ̀. (Éfésù 6:14) Bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó o sì ń tẹ̀ lé ohun tó o kọ́ nínú rẹ̀ bí ẹni pé o fi di ara rẹ lámùrè, ẹ̀kọ́ irọ́ àti ẹ̀kọ́ ìṣìnà táwọn onísìn fi ń kọ́ni kò ní lè ṣì ọ́ lọ́nà.
Ìfẹ́ tí ọmọ èèyàn ní láti jọ́sìn máa ń mú kí wọ́n fẹ́ wádìí ohun tí wọn kò bá mọ̀. Sátánì mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sì máa ń lo èyí láti fi mú kí wọ́n kó sínú páńpẹ́ mìíràn. Ó ń lo ìbẹ́mìílò láti fi kó ọ̀pọ̀ èèyàn nígbèkùn torí ó ti mọ̀ pé ohun kàyéfì àti nǹkan abàmì máa ń jọ ọmọ èèyàn lójú. Bí ọlọ́dẹ ṣe máa ń fi ìjẹ dẹ ẹran kó lè kó sí tàkúté ni Sátánì ṣe ń fi àwọn nǹkan bí iṣẹ́ wíwò, ìwòràwọ̀, ìmúnimúyè, iṣẹ́ àjẹ́, wíwo-àtẹ́lẹwọ́-sọtẹ́lẹ̀, àti idán pípa dẹ páńpẹ́ mú àwọn èèyàn káàkiri ayé.—Léfítíkù 19:31; Sáàmù 119:110.
Kí lo lè ṣe kó o má bàa jìn sọ́fìn ìbẹ́mìílò? Diutarónómì 18:10-12 sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni tí ń mú ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ la iná kọjá, ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ní tìtorí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí sì ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi lé wọn lọ kúrò níwájú rẹ.”
Láìfọ̀rọ̀ gùn, ìmọ̀ràn tí Bíbélì ń fún wa ni pé ká má ṣe lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Bó o bá ti wá ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò lọ́nà kan tàbí òmíràn tó o sì fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀ kí lo lè ṣe? Ńṣe ni kó o ṣe bíi tàwọn Kristẹni tó wà nílùú Éfésù láyé àtijọ́. Bíbélì fiyé wa pé nígbà tí wọ́n tẹ́wọ́ gba “ọ̀rọ̀ Jèhófà,” ńṣe ni “ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.” Owó ńlá ni wọ́n fi ra àwọn ìwé yẹn. Àròpọ̀ iye owó wọn tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50, 000] ẹyọ fàdákà. (Ìṣe 19:19, 20) Síbẹ̀ àwọn Kristẹni ìlú Éfésù kò fọkàn dá méjì kí wọ́n tó dáná sun wọ́n.
Sátánì Máa Ń Lo Àìpé Ẹ̀dá
Ìgbéraga ló sọ áńgẹ́lì kan tó jẹ́ ẹni pípé di Sátánì Èṣù. Ẹ̀mí ìgbéraga yìí ló gbìn sọ́kàn Éfà tó mú kóun náà fẹ́ dà bí Ọlọ́run. Ẹ̀mí ìgbéraga kan náà ni Sátánì ń gbìn sọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí láti fi mú wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan gbà pé ìran, ẹ̀yà, tàbí orílẹ̀-èdè tiwọn ló dáa jù. Èyí lòdì sóhun tí Bíbélì fi kọ́ni pátápátá! (Ìṣe 10:34, 35) Bíbélì sọ ọ́ kedere pé: ‘Láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.’—Ìṣe 17:26.
Ohun téèyàn lè ṣe tí Sátánì ò fi ní lè gbin ẹ̀mí ìgbéraga síni lọ́kàn ni pé kéèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká “má ṣe ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” (Róòmù ) Ó ní: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” ( 12:3Jákọ́bù 4:6) Ohun tó dájú pé a lè ṣe tí Sátánì ò fi ní rí wa mú ni pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì rí i pé a ní àwọn ànímọ́ mìíràn tí Ọlọ́run fẹ́.
Èṣù tún máa ń fẹ́ lo àìpé ẹ̀dá láti fi múni hu ìwàkiwà. Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ káwa ọmọ èèyàn gbádùn ayé wa. Ẹni tó bá sì gbádùn ayé ẹ̀ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu yóò ní ojúlówó ayọ̀. Ṣùgbọ́n Sátánì máa ń ti àwọn èèyàn ṣe ìṣekúṣe láti fi tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́run. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ohun tó ti dáa ni pé kó o máa ronú nípa àwọn ohun mímọ́ àtohun tó jẹ mọ́ ìwà funfun. (Fílípì 4:8) Èyí á jẹ́ kó o lè káwọ́ èrò ọkàn rẹ àti ìṣe rẹ.
Má Gbà fún Èṣù
Ǹjẹ́ o lè ṣe é kí Èṣù má rí ọ tàn jẹ? Bẹ́ẹ̀ ni o. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) Àmọ́ kì í ṣe pé tó o bá ti kọjú ìjà sí Sátánì yóò kàn fi ọ́ sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láìní yọ ọ́ lẹ́nu mọ́ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó tì o. Èṣù tún máa gbìyànjú wò ní “àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Ṣùgbọ́n ìyẹn kò ní kó o wá máa bẹ̀rù Èṣù o. Bí o kò bá ti gbà fún un, ó dájú pé kò ní lè yí ọ padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.
Tí o kò bá fẹ́ kí Èṣù rí ọ tàn jẹ, o ní láti mọ irú ẹni tó jẹ́, bó ṣe ń tanni jẹ àti ohun tó o lè ṣe kí àrékérekè rẹ̀ má bàa mú ọ. Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo lo sì ti lè rí òótọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí. Nítorí náà máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má sì jẹ́ kí ohunkóhun mú ọ dáwọ́ dúró, kó o sì rí i pé ò ń fi ohun tó ò ń kọ́ ṣèwà hù. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ yóò dùn láti máa kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì yẹn lọ́fẹ̀ẹ́ lásìkò tó wọ̀ fún ẹ. Jọ̀wọ́ kàn sí wọn láìjáfara tàbí kó o kọ lẹ́tà sáwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.
Bó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á dára kó o mọ̀ pé Sátánì lè fẹ́ lo àtakò tàbí inúnibíni láti fi mú ọ jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn mìíràn lára àwọn èèyàn rẹ lè bínú sí ọ torí pé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọn kò mọ àgbàyanu òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Àwọn míì tiẹ̀ lè máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Ṣùgbọ́n ṣé inú Ọlọ́run máa dùn sí ọ tó o bá wá torí nǹkan wọ̀nyẹn dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ dúró? Èṣù á fẹ́ fi nǹkan wọ̀nyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ kó o má bàa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tóòtọ́ mọ́. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kó o gbà kí Èṣù borí rẹ? (Mátíù 10:34-39) O kò jẹ Èṣù lóhunkóhun rárá. Ṣùgbọ́n Jèhófà lẹni tó ni ẹ̀mí rẹ. Nítorí náà, má ṣe gbà fún Èṣù rárá àti rárá, kó o sì máa ‘mú ọkàn Jèhófà yọ̀.’—Òwe 27:11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn tó di Kristẹni dáná sun àwọn ìwé wọn tó dá lórí ìbẹ́mìílò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má sì jẹ́ kí ohunkóhun mú ọ dáwọ́ dúró