Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èèyàn “Láti Inú Gbogbo Èdè” Ń Gbọ́ Ìhìn Rere Náà

Àwọn Èèyàn “Láti Inú Gbogbo Èdè” Ń Gbọ́ Ìhìn Rere Náà

Àwọn Èèyàn “Láti Inú Gbogbo Èdè” Ń Gbọ́ Ìhìn Rere Náà

“Ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò [wí] pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’”—SEKARÁYÀ 8:23.

1. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣètò àkókò àti ọ̀nà tó dára jù lọ láti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fáwọn èèyàn ní onírúurú èdè?

 ÀKÓKÒ tí ìṣẹ̀lẹ̀ tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí bọ́ sí dára gan-an ni, ibì tó sì ti ṣẹlẹ̀ pàápàá bójú mu. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn làwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù, ìyẹn àwọn tó di ẹlẹ́sìn Júù ti rọ́ wá sí Jerúsálẹ́mù láti ṣàjọ̀dún ìrékọjá. Ó kéré tán, àgbègbè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nílẹ̀ Ọba Róòmù tó tóbi gan-an àtàwọn ibòmíràn ni wọ́n ti wá. Lọ́jọ́ náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn ló gbọ́ báwọn èèyàn tó jẹ́ púrúǹtù tí wọ́n kún fún ẹ̀mí ṣe ń kéde ìhìn rere ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè táwọn èèyàn ń sọ nílẹ̀ ọba náà. Síbẹ̀ kò sí ìdàrúdàpọ̀ bí irú èyí tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn ìlú Bábélì ayé ọjọ́un, gbogbo wọn ló lóye ohun tí wọ́n ń gbọ́. (Ìṣe 2:1-12) Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn jẹ́ àmì pé a ti dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ àti pé iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lónírúurú èdè ní gbogbo orílẹ̀-èdè ti bẹ̀rẹ̀, èyí tó ń tẹ̀ síwájú títí dòní.

2. Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tó jẹ́ “kàyéfì” fún onírúurú èèyàn tó ń tẹ́tí gbọ́ wọn?

2 Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà lè sọ èdè Gíríìkì tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń sọ lákòókò yẹn. Wọ́n tún máa ń sọ èdè Hébérù, ìyẹn èdè tí wọ́n ń lò ní tẹ́ńpìlì. Àmọ́ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yìí, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lédè àbínibí àwọn èèyàn tó wá láti àgbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Èyí sì ṣe àwọn èèyàn tó ń tẹ́tí gbọ́ wọn ní “kàyéfì.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Àwọn òtítọ́ ṣíṣekókó táwọn èèyàn wọ̀nyí gbọ́ lédè àbínibí wọn wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin. Lópin ọjọ́ yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọn ò ju ìwọ̀nba díẹ̀ lọ tẹ́lẹ̀ ti wá pọ̀ gan-an, wọ́n lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́ta!—Ìṣe 2:37-42.

3, 4. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti ń ṣí kúrò ní Jerúsálẹ́mù, Jùdíà, àti Gálílì?

3 Kété lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí ni inúnibíni ńlá bẹ̀rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, “àwọn tí a tú ká [sì] la ilẹ̀ náà já, wọ́n ń polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.” (Ìṣe 8:1-4) Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Ìṣe orí kẹjọ, a kà nípa Fílípì, tó hàn gbangba pé ajíhìnrere tó ń sọ èdè Gíríìkì ni. Fílípì wàásù fáwọn ará Samáríà. Ó tún wàásù fún òṣìṣẹ́ ará Etiópíà kan tó tẹ́wọ́ gba ìhìn rere nípa Kristi.—Ìṣe 6:1-5; 8:5-13, 26-40; 21:8, 9.

4 Bí àwọn Kristẹni náà ti ń ṣí lọ láti lọ wá àwọn àgbègbè mìíràn tí wọ́n á máa gbé, níbi tí kò ti ní sí ìdílọ́wọ́ bíi ti ìlú Jerúsálẹ́mù, Jùdíà, àti Gálílì ni wọ́n ń bá àwọn ìṣòro mìíràn pàdé. Ìyẹn ìṣòro èdè àti ìṣòro bíbá àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn Júù nìkan làwọn kan lára wọn ń bá sọ̀rọ̀. Àmọ́ Lúùkù tòun náà jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn ará Kípírù àti ará Kírénè kan wà, tí wọ́n wá sí Áńtíókù, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Gíríìkì sọ̀rọ̀, tí wọ́n ń polongo ìhìn rere Jésù Olúwa.”—Ìṣe 11:19-21.

Ọlọ́run Tí Kì Í Ṣojúsàájú Ní Ohun Kan Tó Fẹ́ Kí Gbogbo Èèyàn Mọ̀

5. Báwo ni ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀ ṣe fi hàn pé Jèhófà kì í ṣojúsàájú?

5 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu nítorí pé Ọlọ́run kì í ṣojúsàájú. Lẹ́yìn tí Jèhófà ran àpọ́sítélì Pétérù lọ́wọ́ láti yí èrò tó ní tẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè padà, Pétérù sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó mọyì kókó yìí, ó ní: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35; Sáàmù 145:9) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ti ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni nígbà kan rí sọ pé “ìfẹ́ [Ọlọ́run ni] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là,” ńṣe ló túbọ̀ ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run kì í ṣojúsàájú rárá. (1 Tímótì 2:4) Ó ṣe kedere lóòótọ́ pé Ẹlẹ́dàá wa kì í ṣojúsàájú, nítorí pé gbogbo èèyàn ló fún láǹfààní láti mọ̀ nípa ohun tí Ìjọba rẹ̀ fẹ́ ṣe, láìka àwọ̀, orílẹ̀-èdè, tàbí èdè kálukú wọn sí.

6, 7. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo ló fi hàn pé ìhìn rere náà yóò tàn dé gbogbo orílẹ̀-èdè, pé a ó sì fi onírúurú èdè sọ ọ́?

6 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti sàsọtẹ́lẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tó ń tàn kárí ayé yìí. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ti sọ, Ọlọ́run “fún [Jésù] ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dáníẹ́lì 7:14) Títẹ̀ tá à ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí jáde ní èdè mọ́kànléláàádọ́jọ [151] tá a sì tún ń pín in fáwọn èèyàn káàkiri ayé, tó mú kó ṣeé ṣe fún ìwọ náà láti kà nípa Ìjọba Jèhófà, jẹ́ ẹ̀rí pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ń nímùúṣẹ.

7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sàsọtẹ́lẹ̀ pé àkókò kan yóò dé táwọn èèyàn tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yóò gbọ́ nípa ìhìn rere tó ń fúnni ní ìyè látinú Bíbélì. Nígbà tí wòlíì Sekaráyà ń sọ nípa bí ìjọsìn tòótọ́ yóò ṣe fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn mọ́ra, ó sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú [ìyẹn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tó jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”], pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23; Gálátíà 6:16) Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù sì ń sọ ohun tó rí nínú ìran kan, ó sọ pé: “Wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 7:9) À ń rí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tí wọ́n ń nímùúṣẹ!

Wíwàásù fún Onírúurú Èèyàn

8 Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lóde òní tó gba pé ká yíwọ́ padà nínú iṣẹ́ ìwàásù wa?

8 Lóde òní, àwọn èèyàn ń ṣí kiri ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Lílu tí ayé ti lu jára ti mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti máa ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn. Ẹgbàágbèje èèyàn ló ń ṣí kúrò láwọn àgbègbè tógun ti ń jà àtàwọn orílẹ̀-èdè tí ọrọ̀ ajé wọn ti dẹnu kọlẹ̀, tí wọ́n ń lọ sáwọn ibi tí nǹkan á ti ṣẹnuure fún wọn. Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, bí ogunlọ́gọ̀ èèyàn ṣe ń ṣí wá, títí kan àwọn tó sá wá nítorí ogun, ti mú kí wọ́n ní àwọn àgbègbè tó jẹ́ pé kìkì àwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè nìkan ló wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Finland, ó lé lọ́gọ́fà [120] èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Èdè tí wọ́n sì ń sọ nílẹ̀ Ọsirélíà lé ní igba [200]. Àní ní ìlú kan ṣoṣo péré lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn ìlú San Diego, èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ lé lọ́gọ́rùn-ún!

9. Irú ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa tí wọ́n ń sọ àwọn èdè tó yàtọ̀ sí tiwa?

9 Ṣé ohun tó ń ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa làwa Kristẹni tá a jẹ́ òjíṣẹ́ ka àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè wọ̀nyí sí? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, nǹkan ìdùnnú ló jẹ́ fún wa nítorí pé ó mú kí ìpínlẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ gbòòrò sí i, èyí tó fi hàn pé ‘àwọn pápá ti funfun fún ìkórè.’ (Jòhánù 4:35) À ń sa gbogbo ipá wa láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí ohun tí wọ́n ṣaláìní nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, láìka orílẹ̀-èdè yòówù tí wọ́n ti wá tàbí irú èdè tí wọ́n ń sọ sí. (Mátíù 5:3) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọdọọdún làwọn èèyàn tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń di ọmọ ẹ̀yìn Kristi túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Ìṣípayá 14:6) Bí àpẹẹrẹ, lóṣù August ọdún 2004 tó kọjá, nǹkan bí ogójì èdè làwọn arákùnrin wa fi ń wàásù nílẹ̀ Jámánì. Lákòókò yẹn kan náà nílẹ̀ Ọsirélíà, èdè tí wọ́n fi ń wàásù ìhìn rere fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n, bẹ́ẹ̀ kẹ̀, èdè méjìdínlógún ni lọ́dún mẹ́wàá péré sẹ́yìn. Onírúurú èdè táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wàásù nílẹ̀ Gíríìsì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún. Jákèjádò ayé, nǹkan bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́jọ nínú mẹ́wàá ló jẹ́ pé èdè tí wọ́n ń sọ kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè tá à ń sọ níbi púpọ̀ láyé.

10. Ipa wo ni akéde kọ̀ọ̀kan ń kó nínú sísọ àwọn èèyàn “gbogbo orílẹ̀-èdè” di ọmọ ẹ̀yìn?

10 Láìsí àní-àní, à ń mú àṣẹ Jésù ṣẹ pé ká “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn”! (Mátíù 28:19) Tọkàntara làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ yìí, à ń wàásù ní igba ilẹ̀ ó lé márùndínlógójì [235], ó sì lé ní irínwó [400] èdè tá a fi ń tẹ àwọn ìwé tí à ń pín fáwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò Jèhófà ló ń pèsè àwọn ohun tá a nílò láti lè wàásù fáwọn èèyàn, ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run ló máa wá ọ̀nà tó máa fi sọ ìhìn rere inú Bíbélì fún “onírúurú ènìyàn” lédè tí wọ́n á lóye dáadáa. (Jòhánù 1:7) Ìsapá tí gbogbo wa ń pawọ́ pọ̀ ṣe yìí ló ń mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí èdè wọn yàtọ̀ síra jàǹfààní nínú ìhìn rere náà. (Róòmù 10:14, 15) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ń kó ipa pàtàkì!

Ọ̀nà Tí À Ń Gbà Kójú Ìṣòro Náà

11, 12. (a) Àwọn ìṣòro wo la ní láti borí, báwo sì ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? (b) Kí nìdí tí wíwàásù fáwọn èèyàn lédè àbínibí wọn fi máa ń ṣèrànwọ́ gan-an?

11 Lónìí, ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba Ọlọ́run ní ì bá fẹ́ láti kọ́ èdè mìíràn, àmọ́ wọn ò lè retí pé kí ẹ̀mí mímọ́ mú wọn sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà ìyanu. (1 Kọ́ríńtì 13:8) Kíkọ́ èdè tuntun kò rọrùn rárá. Kódà, àwọn tó gbọ́ èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè tiwọn lè ní láti yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú padà, kí wọ́n sì tún mọ ọgbọ́n tí wọ́n á fi lè bá àwọn tó ni èdè náà sọ̀rọ̀, káwọn èèyàn náà lè nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì. Ìdí ni pé ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ wọn dàgbà àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí wá sí orílẹ̀-èdè mìíràn máa ń tijú, èèyàn sì gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kó tó lè lóye bí wọ́n ṣe ń ronú.

12 Síbẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ṣì ń ṣiṣẹ́ lọ láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bí wọ́n ti ń sapá láti máa bá àwọn tó ń sọ èdè mìíràn sọ̀rọ̀. (Lúùkù 11:13) Dípò kí ẹ̀mí yìí mú ká máa sọ àwọn èdè mìíràn lọ́nà ìyanu, ó lè mú kí ìfẹ́ tá a ní láti bá àwọn tí kì í sọ èdè wa sọ̀rọ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i. (Sáàmù 143:10) Tá a bá ń fi èdè táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ wàásù tàbí tá a fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè yé wọn díẹ̀. Àmọ́ kí ohun tá à ń sọ tó lè wọ àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn dáadáa, lílò èdè àbínibí wọn ló dára jù, ìyẹn èdè tó máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà nípa lórí èrò ọkàn wọn, kó nípa lórí ohun tó wù wọ́n, àtohun tí wọ́n ń fẹ́ láyé wọn.—Lúùkù 24:32.

13, 14. (a) Kí ló mú káwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fáwọn tó ń sọ èdè mìíràn? (b) Báwo làwọn kan ṣe ń lo ara wọn fáwọn ẹlòmíràn?

13 Ọ̀pọ̀ àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fáwọn èèyàn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Orí àwọn kan sì túbọ̀ yá gágá nígbà tí iṣẹ́ ìsìn wọn wá di èyí tó túbọ̀ gba ìsapá tó sì túbọ̀ gbádùn mọ́ wọn. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lápá gúúsù ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá láti Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Yúróòpù ni òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ.” Ríran irú àwọn èèyàn tó ṣe tán láti tẹ́tí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ jẹ́ ohun tó gbádùn mọ́ni gan-an!— Aísáyà 55:1, 2.

14 Àmọ́ ká tó lè ṣe iṣẹ́ yìí lọ́nà tí yóò méso jáde, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti lo ara wa fáwọn ẹlòmíràn. (Sáàmù 110:3) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìdílé kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Japan ń fi àwọn ilé tó túra tí wọ́n ń gbé láwọn ìlú ńlá sílẹ̀, wọn sì ń ṣí lọ sáwọn àgbègbè jíjìnnà kí wọ́n bàa lè ran àwọn ọmọ ilẹ̀ Ṣáìnà tó ń ṣí wá sórílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Gbogbo ìgbà làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run lágbègbè etíkun ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà máa ń wakọ̀ fún wákàtí kan sí méjì láti lọ kọ́ àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Filipino lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lórílẹ̀-èdè Norway, tọkọtaya kan ń kọ́ ìdílé kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Afghanistan lẹ́kọ̀ọ́. Ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? a lédè Gẹ̀ẹ́sì àti lédè Norwegian ni tọkọtaya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí náà ń lò. Ìdílé yìí yóò ka àwọn ìpínrọ̀ náà lédè Páṣíà tó sún mọ́ èdè Dari tó jẹ́ èdè àbínibí wọn. Àmọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Norwegian ni wọ́n fi ń bára wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà táwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè bá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere, ó fi hàn pé Jèhófà ń bù kún àwọn akéde náà gan-an fún ẹ̀mí ìyọ̀ǹda-ara-ẹni wọn àti ìmọwọ́-yí-padà wọn nìyẹn. b

15. Ọ̀nà wo ni gbogbo wa lè gbà kópa nínú iṣẹ́ wíwàásù lónírúurú èdè?

15 Ǹjẹ́ ìwọ náà lè kópa nínú iṣẹ́ tí à ń ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè yìí? O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ nípa kíkọ́kọ́ mọ àwọn èdè ilẹ̀ òkèèrè táwọn èèyàn sábà ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín? Lẹ́yìn náà, kó o wá kó àwọn ìwé ìléwọ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ dání láwọn èdè yẹn. Ìwé kékeré náà Good News for People of All Nations tá a mú jáde lọ́dún 2004 ń ràn wa lọ́wọ́ láti sọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn, nítorí ó lo onírúurú èdè láti sọ ìhìn rere náà lọ́nà tó rọrùn tó sì máa wọ onírúurú èèyàn lọ́kàn.—Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìhìn Rere Fáwọn Èèyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè,” lójú ìwé 32.

Bá A Ṣe Lè “Nífẹ̀ẹ́ Àtìpó”

16. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan hàn láti lè ran àwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè lọ́wọ́?

16 Yálà a kọ́ èdè tuntun tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa la lè kópa nínú iṣẹ́ ríran àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wà lágbègbè wa lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ tẹ̀mí. Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ àtìpó.” (Diutarónómì 10:18, 19) Bí àpẹẹrẹ, ní ìlú ńlá kan lórílẹ̀-èdè kan ní Àríwá Amẹ́ríkà, àwọn ìjọ márùn-ún ló jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí lọ́pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ọdọọdún làwọn ìjọ yìí máa ń yí àkókò tí wọ́n ń ṣèpàdé padà láàárín ara wọn, èyí á sì mú kí àkókò ìpàdé àwọn tó ń sọ èdè Ṣáìnà níbẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ alẹ́ lọ́jọ́ Sunday. Àmọ́, èyí kò ní jẹ́ kí ọ̀pọ̀ lára àwọn àjèjì tó wà níjọ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láwọn ilé oúnjẹ lè wá sípàdé. Tìfẹ́tìfẹ́ làwọn alàgbà tó wà láwọn ìjọ yòókù fi gbà láti máa ṣèpàdé wọn ní àkókò mìíràn kí ìpàdé àwọn tó ń sọ èdè Ṣáìnà yìí lè bọ́ sí àárọ̀ ọjọ́ Sunday.

17. Kí ló yẹ kó jẹ́ èrò wa nígbà táwọn kan bá fẹ́ ṣí lọ láti lọ ran àwùjọ tó ń sọ èdè mìíràn lọ́wọ́?

17 Àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ máa ń gbóríyìn fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó jáfáfá tí wọ́n sì tóótun, tí wọ́n fẹ́ ṣí lọ sáwọn agbègbè mìíràn láti lọ ran àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè mìíràn níbẹ̀ lọ́wọ́. Lóòótọ́, ó lè dun àwọn tó wà nínú ìjọ kan náà pẹ̀lú àwọn olùkọ́ tó jáfáfá nínú fífi Bíbélì kọ́ni yìí pé wọ́n fẹ́ fi àwọn sílẹ̀, àmọ́ bọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn alàgbà ìjọ Lísírà àti Íkóníónì ló ṣe rí lára àwọn alábòójútó wọ̀nyí. Àwọn alàgbà wọ̀nyẹn kò dá Tímótì dúró pé kó máà bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì jẹ́ ẹnì kan tó wúlò gan-an nínú ìjọ wọn. (Ìṣe 16:1-4) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù kì í jẹ́ kí èrò, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tàbí ìwà àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó máa ń yàtọ̀ sí tiwọn ṣèdíwọ́ fáwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fara mọ́ àwọn ìyàtọ̀ náà wọ́n sì máa ń wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n á fi lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kí wọ́n bàa lè sọ ìhìn rere náà fún wọn.—1 Kọ́ríńtì 9:22, 23.

18. Ilẹ̀kùn ńlá tó ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò wo ló ṣí sílẹ̀ fún gbogbo wa?

18 Níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, à ń wàásù ìhìn rere náà báyìí ní “gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè.” Ẹ̀rí wà pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ṣì máa jáde wá sin Jèhófà láti àárín àwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akéde tó jáfáfá ti ń gba ẹnu “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” wọlé. (1 Kọ́ríńtì 16:9) Àmọ́ o, àwọn nǹkan kan wà tá a ṣì gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ran àwọn èèyàn tó wà ní irú àwọn ìpínlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan náà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

b Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ nípa àwọn àpẹẹrẹ mìíràn, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Nǹkan Díẹ̀ Tá A Yááfì Jẹ́ Ká Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún,” nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2004, ojú ìwé 24 sí 28.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà táwa náà ò ní ṣojúsàájú sí ẹnikẹ́ni?

• Irú ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa àmọ́ tí wọn kò sọ èdè wa?

• Kí nìdí tí wíwàásù fáwọn èèyàn lédè àbínibí wọn fi máa ń ṣèrànwọ́ gan-an?

• Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wà láàárín wa?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Róòmù

ÉṢÍÀ

KÍRÉTÈ

LÍBÍÀ

FÍRÍJÍÀ

PANFÍLÍÀ

Jerúsálẹ́mù

JÙDÍÀ

ÍJÍBÍTÌ

PỌ́ŃTÙ

KAPADÓKÍÀ

MESOPOTÁMÍÀ

MÍDÍÀ

ÉLÁMÙ

ARÉBÍÀ

PÁTÍÀ

[Àwn omi ńlá]

Òkun Mẹditaréníà

Òkun Dúdú

Òkun Pupa

Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà

[Àwòrán]

Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn èèyàn láti àgbègbè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nílẹ̀ Ọba Róòmù àtàwọn ibòmíràn gbọ́ ìhìn rere náà lédè àbínibí wọn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Pátákó ìsọfúnni kan tí wọ́n fi èdè márùn-ún kọ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí lára