Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀rí Tó Fi Ìfẹ́, Ìgbàgbọ́ àti Ìgbọràn Hàn

Ẹ̀rí Tó Fi Ìfẹ́, Ìgbàgbọ́ àti Ìgbọràn Hàn

Ẹ̀rí Tó Fi Ìfẹ́, Ìgbàgbọ́ àti Ìgbọràn Hàn

NÍ ÒWÚRỌ̀ ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù May, ọdún 2005, ní Oko Watchtower tó wà nílùú Wallkill, New York, ojú ọjọ́ dárá gan-an, oòrùn sì rọra yọ. Òjò tó rọ̀ kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó mọ́ mú káwọn koríko tá a fi ẹ̀rọ gé lọ́nà tó gún régé àtàwọn òdòdó tá a gbìn káàkiri ibẹ̀ máa dán gbinrin. Pẹ́pẹ́yẹ kan àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́jọ rọra ń wẹ̀ létí omi pípa rọ́rọ́ kan tó wà níbẹ̀. Ẹwà ibẹ̀ jọ àwọn àlejò tó wá síbẹ̀ lójú gan-an. Ńṣe ni wọ́n rọra ń bára wọn sọ̀rọ̀, bíi pé wọn ò fẹ́ kí ariwo wọn ṣèdíwọ́ ní òwúrọ̀ pípa rọ́rọ́ yẹn.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn àlejò náà. Orílẹ̀-èdè méjìdínláàádọ́ta [48] láti apá ibi gbogbo láyé ni wọ́n sì ti wá. Àmọ́ kì í ṣe ẹwà àyíká náà ni wọ́n wá wò o. Ohun tó ń lọ nínú ilé ńlá tuntun kan tí wọ́n fi bíríkì pupa kọ́ tó sì fẹ̀ gbàràmù-gbaramu ni wọ́n fẹ́ mọ̀. Ilé náà jẹ́ àfikún sí Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ìlú Wallkill. Nígbà tí wọ́n wọnú ilé náà, ẹnu tún yà wọ́n gidigidi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ariwo àwọn ẹ̀rọ kò jẹ́ kí inú ilé náà pa rọ́rọ́.

Látorí ibì kan tó ga téèyàn lè dúró sí nínú ilé náà làwọn èèyàn ti ń wo àwọn ẹ̀rọ kíkàmàmà tó wà nísàlẹ̀. Àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé gìrìwò-giriwo márùn-ún ló wà lórí ilẹ̀ tí wọ́n fi kankéré ṣe tó ń dán gbinrin tó sì fẹ̀ ju pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù ní ìlọ́po mẹ́fà. Ibí yìí ni wọ́n ti ń tẹ Bíbélì, ìwé ńlá, àtàwọn ìwé ìròyìn jáde. Àwọn róòlù bébà ńláńlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wúwo tó àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ń yí bíi táyà ọkọ̀ ńlá tó ń sáré gan-an. Ìṣẹ́jú márùndínlọ́gbọ̀n péré ni róòlù bébà tó gùn tó kìlómítà mẹ́tàlélógún yìí fi ń tú tán bó ṣe ń gba inú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà kọjá. Àárín àkókò yẹn náà ni ẹ̀rọ ìtẹ̀wé yìí ń lo yíǹkì láti tẹ nǹkan sára bébà náà, tá á tún jẹ́ kí yíǹkì náà gbẹ, tá á sì tún jẹ́ kí bébà tó ti gbóná náà tutù kó lè ṣeé ká sí ìwé ìròyìn. Eré làwọn ìwé ìròyìn náà máa ń sá bí wọ́n ti ń kọjá lórí irin tó wà lókè, èyí tó ń gbé wọn lọ síbi tá a ti máa dì wọ́n sínú páálí tá a ó sì kó wọn sínú ọkọ̀ tó máa gbé wọn lọ sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé mìíràn ń tẹ àwọn ìwé ní abala-abala, wọ́n á sì ká wọn. Àwọn ìwé tí wọ́n ti ká yìí á wá ti ìsàlẹ̀ lọ sókè lọ́nà tó yára kánkán títí wọ́n á fi dé ibi tí wọ́n máa kó wọn sí kí wọ́n tó kó wọn lọ síbi tí wọ́n ti ń dì wọ́n pọ̀ sí odindi ìwé kọ̀ọ̀kan. Ètò tó gún régé lọ́nà tó bùáyà tí wọ́n ti ṣe sínú kọ̀ǹpútà ló ń darí ọ̀nà tí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà ń gbà ṣiṣẹ́.

Nígbà táwọn àlejò náà kúrò níbi táwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wọ̀nyí wà, wọ́n forí lé ibi táwọn ẹ̀rọ tó ń di ìwé pọ̀ wà. Ibí yìí ni wọ́n ti rí àwọn ẹ̀rọ tó máa ń ṣe àwọn ìwé ẹlẹ́yìn páálí àtàwọn Bíbélì elétí omi góòlù. Wọ́n sì máa ń ṣe tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ẹ̀dà lóòjọ́. Ibẹ̀ làwọn ẹ̀rọ náà ti ń to àwọn abala ìwé tí wọ́n ti ká yìí jọ, tí wọ́n á wá dì wọ́n pọ̀ sí odindi ìwé kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀rọ tó ń gé etí ìwé á wá gé eteetí wọn lọ́nà tó gún régé. Ẹ̀rọ mìíràn á sì fi páálí sí ẹ̀yìn wọn. Lẹ́yìn náà yóò wá kó wọn sínú páálí ìkẹ́rùsí, yóò lẹ̀ ẹ́ fúnra rẹ̀, á sì tún lẹ orúkọ ìwé ọ̀hún mọ́ ara páálí ìkẹ́rùsí náà, á sì tò wọ́n sórí pátákó ìkẹ́rùlé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹ̀rọ mìíràn tún wà láyè tiwọn, tí wọ́n máa ń ṣe àwọn ìwé ẹlẹ́yìn bébà tí wọ́n sì ń kó àwọn ìwé náà sínú páálí, ó sì tó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] irú ìwé bẹ́ẹ̀ táwọn ẹ̀rọ náà máa ń ṣe lóòjọ́ tí wọ́n á sì tò wọ́n sínú páálí ìkẹ́rùsí. Àwọn ẹ̀rọ tá à ń wí yìí náà ò ṣeé fẹnu sọ o. Àwọn ẹ́ńjìnnì tó ń fún wọn lágbára pọ̀ rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ń gbé ẹrù kiri tó wà níbẹ̀ ò lóǹkà, wọ́n tún ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun tó ń darí bí wọ́n ṣe máa sáré tó, àwọn àgbá àtàwọn bẹ́líìtì ara wọn kò sì níye. Ọ̀nà tí gbogbo wọn sì fi ń yára ṣiṣẹ́ láti mú àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde kàmàmà gan-an.

Àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tó péye gan-an gẹ́gẹ́ bí ojúlówó aago ṣe máa ń ṣiṣẹ́. Báwọn àgbà ẹ̀rọ yìí ṣe ń yára ṣiṣẹ́ fi hàn pé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti di nǹkan ìyanu lóde òní. Bá a ṣe máa rí i tó bá yá, ó tún jẹ́ ẹ̀rí tó fi ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn àwọn èèyàn Ọlọ́run hàn. Àmọ́, kí nìdí tá a fi gbé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwé títẹ̀ kúrò ní Brooklyn, New York, tá a sì gbé e lọ sí Wallkill?

Olórí ìdí tá a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo ọ̀rọ̀ ìwé títẹ̀ àti kíkó ìwé lọ síbi gbogbo lè wà lójú kan kí nǹkan lè túbọ̀ rọrùn sí i. Ọ̀pọ̀ ọdún la fi tẹ ìwé ńlá ní Brooklyn tá a sì tibẹ̀ ń kó wọn lọ síbi gbogbo, tá a tún ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn ní Wallkill tá a sì ń tibẹ̀ kó àwọn náà lọ sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Jíjẹ́ kí iṣẹ́ ìtẹ̀wé yìí wà lójú kan yóò mú kí iye àwọn tó máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ dín kù, yóò sì tún jẹ́ ká lè lo owó tó wà fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i. Àti pé, níwọ̀n bí àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó wà ní Brooklyn ti ń gbó, a wá ṣètò fún àgbà ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun méjì tó ń jẹ́ MAN Roland Lithoman láti Jámánì. Àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé yìí tóbi ju ohun tá a lè gbé sí ibi ìtẹ̀wé wa ní Brooklyn.

Jèhófà Ti Iṣẹ́ Náà Lẹ́yìn

Ìdí tá a fi ń tẹ àwọn ìwé yìí ni kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú. Àtìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwé títẹ̀ la ti rí ẹ̀rí pé ìbùkún Jèhófà wà lórí iṣẹ́ náà. Láti ọdún 1879 sí ọdún 1922, àwọn ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé ló máa ń bá wa tẹ̀wé, tá a sì máa ń sanwó fún wọn. Nígbà tó di ọdún 1922, a háyà ilé alájà mẹ́fà kan ní Nọnba 18, Concord Street ní Brooklyn, a sì ra àwọn ẹ̀rọ tá a ó fi máa tẹ àwọn ìwé wa. Lákòókò yẹn, àwọn kan ń ṣiyèméjì pé bóyá lapá wa máa ká iṣẹ́ náà.

Ọ̀kan lára àwọn tó ṣiyèméjì bẹ́ẹ̀ ni ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ tó ti bá wa tẹ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé ńlá wa. Nígbà tó wá sílé tá a háyà náà, ó sọ pé: “Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó gbayì jù lọ lẹ ní sígbà yìí, bẹ́ẹ̀ kò sẹ́nì kankan nínú yín tó mọ bá a ṣe ń lò ó. Tó bá fi máa di oṣù mẹ́fà síbi tá a wà yìí, gbogbo wọn á ti dẹnu kọlẹ̀; ẹ ó wá rí i pé àwọn tó ń bá yín tẹ̀wé tẹ́lẹ̀ ló yẹ kó máa bá a yín tẹ̀ ẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn ni.”

Arákùnrin Robert J. Martin, tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka ìtẹ̀wé lákòókò yẹn sọ pé: “Ohun tó sọ yẹn mọ́gbọ́n dání lóòótọ́, àmọ́ ó ti gbàgbé Olúwa. Olúwa ò sì fi wá sílẹ̀ rí. . . . Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn la bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ńlá jáde.” Ní ọgọ́rin ọdún lẹ́yìn náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ọ̀kẹ́ àìmọye ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde látinú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tiwa fúnra wa.

Nígbà tó wá di October 5, 2002, níbi ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, a gbọ́ ìkéde kan níbẹ̀ pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti fọwọ́ sí i pé ká gbé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwé títẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sílùú Wallkill. Wọ́n ní a ti kọ̀wé fún àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun méjì, wọ́n sì máa dé lóṣù February ọdún 2004. Àwọn arákùnrin ní láti ṣètò ibi ìtẹ̀wé náà kó gbòòrò gan-an, kí gbogbo ètò náà sì parí láàárín oṣù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ká lè ríbi kó àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun náà sí. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ẹ̀rọ tuntun tó wà fún ìdìwépọ̀ àtàwọn ohun èlò ìkówèéránṣẹ́ ti gbọ́dọ̀ wà ní sẹpẹ́ láàárín oṣù mẹ́sàn-án sí àkókò yẹn. Ó ṣeé ṣe káwọn kan máa ṣiyèméjì nígbà tí wọ́n gbọ́ báwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ nípa ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà ṣe máa rí, kí wọ́n rò pé ohun tí kò lè ṣeé ṣe ni. Àmọ́, àwọn ará mọ̀ pé pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, yóò ṣeé ṣe.

“Ẹ̀mí Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Tó Fúnni Láyọ̀”

Báwọn ará ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ní pẹrẹu nìyẹn o, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn Jèhófà yóò yọ̀ǹda ara wọn tinútinú. (Sáàmù 110:3) Iṣẹ́ ibẹ̀ nílò àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ ju iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìkọ́lé ní Bẹ́tẹ́lì. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà lé ní ẹgbẹ̀rún. Àwọn tó wá yìí ní ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé, wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fúngbà díẹ̀, ìyẹn fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan sí oṣù mẹ́ta. Wọ́n pe àwọn kan lára àwọn òṣìṣẹ́ káyé, ìyẹn àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé kárí ayé àtàwọn tó máa ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé, láti wá kópa nínú iṣẹ́ náà. Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn náà ṣe gudugudu méje níbi iṣẹ́ náà.

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ Wallkill náà ló náwó nára gan-an láti rìnrìn àjò wá, wọ́n sì tún kúrò nídìí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn fúngbà díẹ̀. Síbẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi yọ̀ǹda ara wọn. Pípèsè ilé àti oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí fún àwọn tó jẹ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì láǹfààní láti lo gbogbo okun wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti márùndínlógójì [535] èèyàn látinú ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, Patterson, àti Wallkill tó yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láwọn ọjọ́ Sátidé. Wọ́n wá ṣiṣẹ́ yìí láfikún sí iṣẹ́ wọn tí wọ́n máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀. Ohun tó mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti ṣe ìtìlẹ́yìn àrà ọ̀tọ̀ fún iṣẹ́ kíkàmàmà yìí ni pé Jèhófà ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn.

Owó làwọn mìíràn fi ṣèrànwọ́. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́tà kan wá látọ̀dọ̀ Abby tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Ohun tí ọmọbìnrin náà kọ sínú lẹ́tà náà nìyí: “Mo mọyì gbogbo iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe, tí ẹ̀ ń tẹ gbogbo àwọn àgbàyanu ìwé wọ̀nyẹn. Ó ṣeé ṣe kí èmi náà wá wò yín láìpẹ́. Dádì mi ti sọ pé ọdún tó ń bọ̀ la máa wá o! Màá fi báàjì kan sáyà kẹ́ ẹ lè dá mi mọ̀. Ogun dọ́là rèé fún àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun wọ̀nyẹn! Owó táwọn òbí mi máa ń fún mi ni, àmọ́ ó wù mí láti fún ẹ̀yin arákùnrin mi lówó náà.”

Arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gba àwọn fìlà tí mo fi ọwọ́ ara mi hun yìí bẹ́ẹ̀. Inú mi yóò dùn tẹ́ ẹ bá lè kó àwọn fìlà wọ̀nyí fáwọn ará tó ń ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ ní Wallkill. Ìwé ìròyìn kan tó sọ̀rọ̀ nípa ojú ọjọ́ sọ pé òtútù máa mú gan-an. Bóyá ó máa rí bẹ́ẹ̀ tàbí kò ní rí bẹ́ẹ̀, mi ò lè sọ. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ ní Wallkill ni wọ́n á máa ṣe níta gbangba, mo sì fẹ́ rí i dájú pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi rí nǹkan fi borí nítorí òtútù. Mi ò mọ èyíkéyìí nínú àwọn iṣẹ́ tí wọ́n sọ pé kéèyàn mọ̀ kó tó lè wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, àmọ́ mo mọ nǹkan hun, ìdí nìyẹn tí mo fi pinnu láti lo òye tí mo ní yìí láti ṣe ipa tèmi nínú iṣẹ́ náà.” Fìlà àfọwọ́hun ọgọ́rùn-ún ó lé mẹ́fà ló wà nínú àpò yìí!

Àkókò tá a fọkàn sí gẹ́lẹ́ ni iṣẹ́ ibi ìtẹ̀wé náà parí. Arákùnrin John Larson tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka ìtẹ̀wé sọ pé: “A rí ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó fúnni láyọ̀ gidi níbi iṣẹ́ náà. Ta ló lè sọ pé Jèhófà kò bù kún iṣẹ́ náà? Iṣẹ́ náà yára kankan. Mo rántí ìgbà tí mo dúró sínú ẹrẹ̀ ní oṣù May, ọdún 2003 tí mò ń wo àwọn ará bí wọ́n ṣe ń fi ìpìlẹ̀ ilé náà lélẹ̀. Kò tíì pé ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn tí mo tún dúró sí ibì kan náà yẹn tí mo sì ń wo àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu.”

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìyàsímímọ́

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ ibi ìtẹ̀wé tuntun náà àtàwọn ilé gbígbé mẹ́ta tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ wáyé ní Wallkill lọ́jọ́ Monday, May 16, 2005. Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ń lọ lọ́wọ́, orí fídíò làwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ní Patterson àti Brooklyn ti ń wò ó, títí kan àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ti Kánádà. Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé mọ́kàndínláàádọ́ta [6,049] làwọn tó gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lápapọ̀. Arákùnrin Theodore Jaracz tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó sì sọ̀rọ̀ ṣókí lórí ìtàn iṣẹ́ ìtẹ̀wé wa. Arákùnrin John Larson àti John Kikot tí wọ́n wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka fi ọ̀rọ̀ wá àwọn kan lẹ́nu wò, wọ́n sì tún fi àwọn àwòrán inú fídíò bíi mélòó kan hàn láti sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò tí iṣẹ́ náà ń lọ lọ́wọ́ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìwé títẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Arákùnrin John Barr tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn, ó ya ibi ìtẹ̀wé tuntun náà àtàwọn ilé gbígbé mẹ́ta tó wà níbẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run.

Láàárín ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ìyàsímímọ́ náà, wọ́n fún àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Patterson àti Brooklyn láǹfààní láti lọ wo àwọn ilé tuntun náà kí wọ́n sì rìn yí ká ibẹ̀. Gbogbo àwọn tó wá síbẹ̀ láàárín àkókò yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti ogun [5,920] èèyàn lápapọ̀.

Ojú Wo La Fi Ń Wo Ibi Ìtẹ̀wé Náà?

Nínú ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ náà, Arákùnrin Barr rán àwọn tó wà níbẹ̀ létí pé bó ti wù kí ibi ìtẹ̀wé náà jọni lójú tó, kì í ṣe àwọn ẹ̀rọ kíkàmàmà tó wà níbẹ̀ ló mú kó ṣe pàtàkì. Ohun tó mú kó ṣe pàtàkì gan-an làwọn èèyàn. Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń tẹ̀ jáde máa ń ní ipa tó lágbára lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun náà lè tẹ̀ tó mílíọ̀nù kan ìwé àṣàrò kúkúrú ní wákàtí kan ó lé ìṣẹ́jú díẹ̀ péré! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìwé àṣàrò kúkúrú kan ṣoṣo lè ní ipa tó lágbára lórí ìgbésí ayé ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1921, àwọn ọkùnrin bíi mélòó kan tó ń ṣiṣẹ́ lójú ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin ní Gúúsù Áfíríkà wà lẹ́nu iṣẹ́ wọn lọ́jọ́ kan. Ọ̀kan lára wọn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Christiaan rí bébà kékeré kan tó há sábẹ́ irin lójú ọ̀nà tí ọkọ̀ ń gbà. Ọ̀kan lára ìwé àṣàrò kúkúrú wa ni bébà náà. Christiaan kà á, ohun tó kà níbẹ̀ sì dùn mọ́ ọn nínú gan-an. Bó ṣe sáré lọ sọ́dọ̀ ọkọ ọmọ rẹ̀ nìyẹn, tó sì sọ fún un tayọ̀tayọ̀ pé: “Wò ó, mo ti rí òtítọ́ lónìí!” Láìpẹ́ sí àkókò yẹn, àwọn méjèèjì kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ pé àwọn túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Gúúsù Áfíríkà sì fi àwọn ìwé mìíràn tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ sí wọn. Àwọn ọkùnrin méjèèjì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n ṣèrìbọmi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì tipasẹ̀ wọn rí òtítọ́. Kódà, nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ti di Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ti lé ní ọgọ́rùn-ún. Ohun tó sì mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe kò ju ìwé àṣàrò kúkúrú kan ṣoṣo tẹ́nì kan rí lọ́nà ọkọ̀ ojú ìrìn!

Arákùnrin Barr sọ pé, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń tẹ̀ jáde ń mú àwọn èèyàn wá sínú òtítọ́, ó ń jẹ́ kí wọ́n dúró nínú òtítọ́, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ jẹ́ onítara, ó tún ń jẹ́ kí ẹgbẹ́ àwọn ará wà níṣọ̀kan. Lékè gbogbo rẹ̀, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí gbogbo wa ń pín kiri ń fi ògo fún Jèhófà, Ọlọ́run wa!

Ojú Wo Ni Jèhófà Fi Ń Wo Ibi Ìtẹ̀wé Náà?

Arákùnrin Barr tún sọ pé káwọn tó wà níbẹ̀ ronú lórí ojú tí Jèhófà fi ń wo ibi ìtẹ̀wé náà. Ó dájú pé òun kọ́ ni Jèhófà gbára lé. Ó lè mú káwọn òkúta wàásù ìhìn rere náà! (Lúùkù 19:40) Síwájú sí i, ohun tó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà kì í ṣe bí àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ṣe kàmàmà tó, bí wọ́n ṣe tóbi tó, àti bí wọ́n ṣe lágbára tó. Ó ṣe tán, Òun ló dá ọ̀run òun ayé! (Sáàmù 147:10, 11) Jèhófà mọ bá a ṣe lè tẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde lọ́nà tó dáa ju tiwa lọ fíìfíì. Ó mọ àwọn ọ̀nà tẹ́nikẹ́ni ò tíì mọ̀, kódà ó mọ èyí tẹ́nikẹ́ni ò tiẹ̀ tíì ronú kàn rí pàápàá. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ni Jèhófà ń wò tó sì ṣe pàtàkì lójú rẹ̀? Láìsí àní-àní, ohun tó rí níbi ìtẹ̀wé yìí ni ànímọ́ ṣíṣeyebíye àwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn ìfẹ́ tí wọ́n ní, ìgbàgbọ́ wọn, àti bí wọ́n ṣe jẹ́ onígbọràn.

Arákùnrin Barr ṣàpèjúwe apá tó fi ìfẹ́ hàn nínú iṣẹ́ náà. Nínú àpèjúwe rẹ̀, ó ní ọmọdébìnrin kan ṣe kéèkì fáwọn òbí rẹ̀. Ó dájú pé inú àwọn òbí náà á dùn gan-an. Bó ti wù kí kéèkì náà rí, ohun tó múnú àwọn òbí náà dùn ni ìfẹ́ tí ọmọ wọn ní sí wọn, tó mú kó fi irú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Bákan náà, nígbà tí Jèhófà bá wo ibi ìtẹ̀wé tuntun yìí, kí i ṣe ilé náà àtàwọn ẹ̀rọ ibẹ̀ nìkan ló ń rí. Ní pàtàkì jù lọ, ó ń wò ó gẹ́gẹ́ bí ohun tó fi ìfẹ́ táwọn èèyàn rẹ̀ ní sí orúkọ rẹ̀ hàn.—Hébérù 6:10.

Láfikún sí i, bí Jèhófà ṣe wo ọkọ̀ áàkì bí ohun tó fi ìgbàgbọ́ Nóà hàn, bákan náà ló ṣe ń wo ibi ìtẹ̀wé yìí bí ẹ̀rí tó fi hàn kedere pé a nígbàgbọ́. Ìgbàgbọ́ nínú kí ni? Nóà gbà gbọ́ pé ohun tí Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yóò nímùúṣẹ. Àwa náà gbà gbọ́ pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, pé ìhìn rere náà lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tá à ń sọ fáyé gbọ́, àti pé ó ṣe pàtàkì fáwọn èèyàn láti gbọ́ ọ. A mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Bíbélì lè gba ẹ̀mí là.—Róòmù 10:13, 14.

Ó dájú pé Jèhófà tún ń wo ibi ìtẹ̀wé yìí bí ẹ̀rí tó fi hàn pé a jẹ́ onígbọràn. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe mọ̀, ìfẹ́ rẹ̀ ni pé ká wàásù ìhìn rere yìí jákèjádò ayé kí òpin tó dé. (Mátíù 24:14) Ibi ìtẹ̀wé yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ibi ìtẹ̀wé yòókù káàkiri ayé, yóò kó ipa tó lágbára nínú iṣẹ́ náà.

Dájúdájú, ìfẹ́, ìgbàgbọ́, àti ìgbọràn tó hàn nínú bá a ṣe kó owó tá a ná jọ, bá a ṣe kọ́ àwọn ilé náà, àti bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ níbí yìí tún ń hàn gbangba nínú iṣẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà ń fìtara ṣe níbi gbogbo, bí wọ́n ti ń kéde òtítọ́ náà nìṣó fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ gbọ́.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

A MÚ Ẹ̀KA ÌTẸ̀WÉ GBÒÒRÒ SÍ I NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

1920: Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo àkọ́kọ́ la fi ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn jáde ní Nọnba 35 Myrtle Avenue, Brooklyn.

1922: A gbé ẹ̀ka ìtẹ̀wé lọ sí ilé alájà-mẹ́fà kan tó wà ní Nọnba 18 Concord Street. A bẹ̀rẹ̀ sí tẹ àwọn ìwé ńlá níbẹ̀ pẹ̀lú.

1927: A kó ẹ̀ka ìtẹ̀wé lọ sílé tuntun kan tá a kọ́ sí Nọnba 117 Adams Street.

1949: A tún kọ́ ilé alájà-mẹ́sàn-án tó mú kí ẹ̀ka ìtẹ̀wé fẹ̀ sí i ní ìlọ́po méjì.

1956: Ẹ̀ka ìtẹ̀wé tó wà ní Adams Street tún fẹ́ sí i ní ìlọ́po méjì nígbà tá a kọ́ ilé tuntun mìíràn sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní Nọnba 77 Sands Street.

1967: A kọ́ ilé alájà-mẹ́wàá, tó jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ní ẹ̀ka ìtẹ̀wé tó so kọ́ra, ilé náà sì tóbi ju ilé ti àkọ́kọ́ yẹn lọ ní ìlọ́po mẹ́wàá.

1973: A kọ́ ẹ̀ka ìtẹ̀wé kékeré kan sí Wallkill, èyí tó wà fún kìkì ìwé ìròyìn.

2004: Ìlú Wallkill ni gbogbo ohun tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ ìwé títẹ̀, dídi ìwé pọ̀, àti kíkó wọn ránṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ń wáyé báyìí.