Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Amágẹ́dọ́nì Ṣé Ogun Tó Máa Pa Ayé Run Yán-ányán-án Ni?

Amágẹ́dọ́nì Ṣé Ogun Tó Máa Pa Ayé Run Yán-ányán-án Ni?

Amágẹ́dọ́nì Ṣé Ogun Tó Máa Pa Ayé Run Yán-ányán-án Ni?

AMÁGẸ́DỌ́NÌ! Èrò wo ni ọ̀rọ̀ yìí gbé wá sí ọ lọ́kàn? Ṣé èrò pé gbogbo èèyàn máa pa run ni àbí pé gbogbo ayé máa jóná? Lápá ibi púpọ̀ láyé, ṣàṣà làwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì táwọn èèyàn máa ń sọ tó bí wọ́n ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nípa “Amágẹ́dọ́nì.” Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà láti sọ nípa ohun búburú tó dojú kọ ọmọ aráyé. Ohun táwọn fíìmù, fídíò àti tẹlifíṣọ̀n máa ń gbé jáde nípa “Amágẹ́dọ́nì” tó ń bọ̀ máa ń dẹ́rù bani, ó sì máa ń da àwọn èèyàn lọ́kàn rú. Àwọn nǹkan àràmàǹdà táwọn èèyàn máa ń sọ nípa rẹ̀ àtàwọn èrò òdì tí wọ́n máa ń fi síni lọ́kàn ti jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ mù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ń sọ nípa ohun tí Amágẹ́dọ́nì túmọ̀ sí, síbẹ̀ èyí tó pọ̀ jù lára ohun tí wọ́n ń wí ta ko ohun tí Bíbélì tó jẹ́ orísun ọ̀rọ̀ náà sọ nípa Amágẹ́dọ́nì.

Níwọ̀n bí Bíbélì ti sọ pé Amágẹ́dọ́nì ní í ṣe pẹ̀lú “opin aye,” ǹjẹ́ o ò gbà pé ó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn ní òye tó ṣe kedere nípa ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ní ti gidi? (Mátíù 24:3 Bibeli Mimọ) Ǹjẹ́ kò sì ní bọ́gbọ́n mu ká yíjú sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ orísun òtítọ́ láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa ohun tí Amágẹ́dọ́nì jẹ́ àti bó ṣe máa kan ìwọ àti ìdílé rẹ?

Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ yóò fi hàn pé dípò kí Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ogun tó máa pa ayé run yán-ányán-án, ńṣe ló máa jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé aláyọ̀ fáwọn tó fẹ́ gbé nínú ayé tuntun òdodo tí wọ́n á sì máa gbádùn níbẹ̀. Wàá túbọ̀ ní òye tó ṣe kedere nípa ọ̀rọ̀ yìí látinú Ìwé Mímọ́ bó o ṣe ń kà nípa ìtumọ̀ Amágẹ́dọ́nì nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

KÍ LO RÒ PÉ AMÁGẸ́DỌ́NÌ JẸ́?

• Ogun runlérùnnà

• Àjálù lọ́tùn-ún lósì

• Àwọn ìràwọ̀ àtàwọn ohun mìíràn tó wà lọ́run á já lu ayé

• Pípa tí Ọlọ́run yóò pa àwọn ẹni ibi run