Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Di Òjíṣẹ́ Tó Mọṣẹ́ Rẹ̀ Níṣẹ́ Tó Tún Mọwọ́ Yí Padà

Bá A Ṣe Lè Di Òjíṣẹ́ Tó Mọṣẹ́ Rẹ̀ Níṣẹ́ Tó Tún Mọwọ́ Yí Padà

Bá A Ṣe Lè Di Òjíṣẹ́ Tó Mọṣẹ́ Rẹ̀ Níṣẹ́ Tó Tún Mọwọ́ Yí Padà

“Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 9:22.

1, 2. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà jẹ́ òjíṣẹ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ tí Jésù gbé lé e lọ́wọ́?

 Ẹ̀RÙ kì í bà á láti bá àwọn ọ̀mọ̀ràn sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì mọ ọ̀nà tó lè gbà bá àwọn púrúǹtù tó ń ṣiṣẹ́ àgọ́ pípa sọ̀rọ̀. Ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ yí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ilẹ̀ Róòmù àtàwọn mẹ̀kúnù ilẹ̀ Fíríjíà lérò padà. Báwọn ìwé tó kọ ṣe wọ àwọn Gíríìkì lọ́kàn, ìyẹn àwọn tó máa ń gba èrò ẹlòmíràn yẹ̀ wò, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe wọ àwọn Júù tí kò fi àṣà ìbílẹ̀ wọn ṣeré lọ́kàn. Àwọn àlàyé rẹ̀ bọ́gbọ́n mu, kò ṣeé ta kò, bẹ́ẹ̀ sì ni ìtara ọkàn tó fi ń sọ̀rọ̀ kò lẹ́gbẹ́. Ó máa ń sapá láti rí i pé ohun tóun àtàwọn tí òun ń bá sọ̀rọ̀ jọ fara mọ́ lọ̀rọ̀ òun dá lé, kó bàa lè mú díẹ̀ lára wọn wá sọ́dọ̀ Kristi.—Ìṣe 20:21.

2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó dájú pé òjíṣẹ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ tó sì mọwọ́ yí padà ni. (1 Tímótì 1:12) Àtọ̀dọ̀ Jésù ló ti gba àṣẹ pé kó “gbé orúkọ [Kristi] lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣe 9:15) Ọwọ́ wo ló fi mú iṣẹ́ tí Jésù gbé lé e lọ́wọ́ yìí? Ó sọ pé: “Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là. Ṣùgbọ́n mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.” (1 Kọ́ríńtì 9:19-23) Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dẹni tó túbọ̀ gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe?

Ọkùnrin Tá A Yí Lọ́kàn Padà Borí Ìṣòro Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ̀

3. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń ṣe sáwọn Kristẹni kóun fúnra rẹ̀ tó di Kristẹni?

3 Ṣé ẹnì kan tó lámúùmọ́ra tó sì ń gba tàwọn èèyàn rò ni Pọ́ọ̀lù látìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀, tíyẹn sì wá mú kó tóótun fún iṣẹ́ ìsìn tó rí gbà yẹn? Rárá o! Ìtara òdì tí Sọ́ọ̀lù (ìyẹn orúkọ Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ rí) ní fún ẹ̀sìn ti mú kó ṣe inúnibíni rírorò sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi nígbà kan rí. Nígbà tó wà ní ọ̀dọ́kùnrin, ó fara mọ́ pípa tí wọ́n pa Sítéfánù. Ẹ̀yìn ìyẹn ló tún bẹ̀rẹ̀ sí í dọdẹ àwọn Kristẹni kiri kó lè fimú wọn dánrin. (Ìṣe 7:58; 8:1, 3; 1 Tímótì 1:13) Kò yéé ‘halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa ó sì ń wá bóun ṣe máa pa wọ́n.’ Nígbà tí dídọdẹ tó ń dọdẹ àwọn onígbàgbọ́ kiri nílùú Jerúsálẹ́mù kò tó o, ló bá tún tìtorí ìkórìíra tó ní yìí forí lé Dámásíkù tó jìnnà gan-an ní ìhà àríwá.—Ìṣe 9:1, 2.

4. Àtúnṣe wo ni Pọ́ọ̀lù ní láti ṣe kó tó lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́?

4 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù kórìíra ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ́ẹ̀ ni pé, ó gbà pé ẹ̀sìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí yóò da ìgbàgbọ́ àwọn Kèfèrí àtàwọn èrò tí kò bójú mu pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn àwọn Júù. Ó ṣe tán, “Farisí ni” Pọ́ọ̀lù, ìtumọ̀ Farisí sì ni “ẹni tá a yà sọ́tọ̀.” (Ìṣe 23:6) Fojú inú wo bẹ́nu á ṣe ya Pọ́ọ̀lù tó nígbà tó gbọ́ pé, òun, láàárín gbogbo èèyàn, ni Ọlọ́run wá yàn láti lọ máa wàásù nípa Kristi fáwọn Kèfèrí! (Ìṣe 22:14, 15; 26:16-18) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, àwọn Farisí kì í bá àwọn tí wọ́n kà sí ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun! (Lúùkù 7:36-39) Kò sí àní-àní pé ó ní láti sapá gidigidi kó tó lè yí èrò rẹ̀ padà kó sì mú un bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, pé kí onírúurú èèyàn rí ìgbàlà.—Gálátíà 1:13-17.

5. Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

5 Àwa náà lè ní láti ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù. Bá a ti túbọ̀ ń bá onírúurú èèyàn pàdé ní ìpínlẹ̀ wa tó kún fún àwọn èèyàn láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè pẹ̀lú èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó yẹ ká sapá gidigidi láti yẹ ìṣesí wa wò ká sì mú ẹ̀tanú èyíkéyìí tó lè wà lọ́kàn wa kúrò. (Éfésù 4:22-24) Yálà a mọ̀ tàbí a ò mọ̀, àwọn èèyàn tó yí wa ká àtohun tí wọ́n fi kọ́ wa láti kékeré ló mú ká jẹ́ irú ẹni tá a jẹ́. Èyí lè mú ká ní àwọn èrò àtàwọn ìwà tó mú ẹ̀tanú lọ́wọ́, ká sì tún jẹ́ ẹni tí kì í fẹ́ yí èrò rẹ̀ padà. Ká tó lè wá àwọn ẹni bí àgùntàn rí ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́, ó di dandan ká mú irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ọkàn wa pátápátá. (Róòmù 15:7) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó mú gbogbo èrò òdì tó ní lọ́kàn kúrò kó lè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Nítorí ìfẹ́ tó ní, ó dẹni tó mọ àwọn ọ̀nà tó lè gbà kọ́ àwọn èèyàn dáadáa, èyí táwa náà lè ṣàmúlò wọn. Àní, bá a bá gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” yìí yẹ̀ wò dáadáa, a óò rí i pé ẹnì kan tó lákìíyèsí ni, tó mọ bá a ti ń yíwọ́ padà, tó sì já fáfá gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. aRóòmù 11:13.

Òjíṣẹ́ Kan Tó Mọwọ́ Yí Padà Ṣe Bẹbẹ

6. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà kíyè sí irú ẹni táwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ jẹ́, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

6 Pọ́ọ̀lù máa ń kíyè sí ohun táwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ gbà gbọ́ àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Nígbà tó ń bá Ọba Àgírípà Kejì sọ̀rọ̀, ó sọ fún un pé òun mọ̀ pé “ògbógi [ni] nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn láàárín àwọn Júù.” Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù wá fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ karí àwọn ohun tó mọ̀ pé Àgírípà gbà gbọ́, ó sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó mọ̀ pé ọba náà lóye dáadáa. Àlàyé Pọ́ọ̀lù yé Àgírípà yékéyéké, ó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé Àgírípà ò mọ̀gbà tó sọ pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.”—Ìṣe 26:2, 3, 27, 28.

7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀nà mìíràn láti wàásù nígbà tó ń bá àwọn èrò kan sọ̀rọ̀ nílùú Lísírà?

7 Bákan náà, ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù máa ń gbà bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Wo bí ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ ṣe yàtọ̀ nígbà tó ń gbìyànjú láti dá àwọn èrò kan lẹ́kun nílùú Lísírà kí wọ́n má bàa jọ́sìn òun àti Bánábà bí òrìṣà. Àwọn kan sọ pé àwọn èèyàn tí ń sọ èdè Likaóníà yìí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé, wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán ju gbogbo èèyàn tó kù lọ. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣe 14:14-18 ti fi hàn, Pọ́ọ̀lù tọ́ka sáwọn ìṣẹ̀dá àtàwọn irè oko bọ̀kùàbọ̀kùa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé Ọlọ́run tòótọ́ ló ga jù. Àlàyé náà rọrùn láti lóye, ó sì hàn gbangba pé ó “ṣèdíwọ́ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà láti má ṣe rúbọ” sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà.

8. Àwọn ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà fi hàn pé òun kì í rinkinkin mọ́ èrò òun bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú máa ń bí i nígbà mìíràn?

8 Lóòótọ́ Pọ́ọ̀lù kì í ṣe ẹni pípé, ìgbà mìíràn sì wà táwọn nǹkan kan máa ń múnú bí i. Bí àpẹẹrẹ nígbà kan, àwọn kan gbéjà kò ó lọ́nà tí kò bójú mu tó sì kó ìtìjú bá a, ló bá sọ̀rọ̀ burúkú sí Júù kan tó ń jẹ́ Ananíà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ fún Pọ́ọ̀lù pé olórí àlùfáà ló sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí láìmọ̀, kíá ló bẹ̀bẹ̀. (Ìṣe 23:1-5) Nílùú Áténì, inú kọ́kọ́ bí i nígbà tó rí i pé “ìlú ńlá náà kún fún òrìṣà.” Síbẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí Òkè Máàsì, Pọ́ọ̀lù kò fi ìbínú náà hàn rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bá àwọn ará Áténì sọ̀rọ̀ níbi tí wọ́n máa ń pé jọ sí, ó sì gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka ohun tí wọ́n jọ fara mọ́ nípa títọ́ka sí pẹpẹ wọn tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan sí lára pé, “Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.” Ó sì tún fa ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára àwọn akéwì wọn yọ.—Ìṣe 17:16-28.

9. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun lè bójú tó ipòkípò tó bá yọjú nígbà tó bá ń bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀?

9 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bá ń bá onírúurú àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ó mọ ọ̀nà tó lè gbà bójú tó ipòkípò tó bá yọjú. Ó máa ń gba ti àṣà ìbílẹ̀ àti ipò àwọn tó ń tẹ́tí sí i rò, ìyẹn àwọn ohun tó mú kí wọ́n máa ronú lọ́nà tí wọ́n gbà ń ronú. Nígbà tó kọ̀wé sáwọn Kristẹni nílùú Róòmù, ó mọ̀ dájú pé olú ìlú ìjọba tó lágbára jù láyé nígbà yẹn ni wọ́n ń gbé. Kókó tó ṣe pàtàkì jù nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni ìlú Róòmù ni pé agbára Kristi tó ń rani padà ló ń ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù tó ń sọni dìdàkudà. Ó bá àwọn Kristẹni ìlú Róòmù àtàwọn tó wà láyìíká wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ọ̀rọ̀ náà á fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn.—Róòmù 1:4; 5:14, 15.

10, 11. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe mú àpèjúwe rẹ̀ bá àwọn olùgbọ́ rẹ̀ mu? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

10 Kí ni Pọ́ọ̀lù máa ń ṣe nígbà tó bá fẹ́ ṣàlàyé àwọn kókó tó ṣòro láti lóye nínú Bíbélì fáwọn tó ń tẹ́tí sí i? Àpọ́sítélì náà jáfáfá gan-an tó bá dọ̀rọ̀ lílo àwọn àpèjúwe táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó tó sì rọrùn láti lóye láti mú kí àwọn kókó tẹ̀mí túbọ̀ ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn èèyàn ìlú Róòmù mọ̀ nípa ètò ìfiniṣẹrú tó wà jákèjádò gbogbo àgbègbè tí Róòmù ti ń ṣàkóso. Kódà, ó ṣeé ṣé kó jẹ́ pé ẹrú ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ̀wé sí. Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi àpèjúwe jíjẹ́ ẹrú ti àlàyé rẹ̀ tó fakíki lẹ́yìn pé ẹnì kan lè yan ohun tó wù ú, bóyá kó di ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ tàbí fún òdodo.—Róòmù 6:16-20.

11 Ìwé kan sọ pé: “Láàárín àwọn ará Róòmù, ẹnì kan tó ní ẹrú lè yọ̀ǹda rẹ̀ pátápátá tàbí kẹ̀, ẹrú náà lè sanwó fún ọ̀gá rẹ̀ kó lè dòmìnira. Wọ́n sì lè ṣètò fún ẹrú kan láti dòmìnira bí ẹrú náà bá di ti òrìṣà kan.” Ẹrú tó ti dòmìnira lè máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀gá rẹ̀ nìṣó kó sì máa gbowó. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àṣà kí ẹrú ṣì máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀gá rẹ̀ lẹ́yìn tó ti dòmìnira yìí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé nípa irú ọ̀gá tẹ́nì kan yàn láti máa ṣègbọràn sí, yálà ẹ̀ṣẹ̀ ni tàbí òdodo. Àwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n sì ti di ti Ọlọ́run. Wọ́n lómìnira láti máa ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run, tó bá sì wù wọ́n, wọ́n lè yàn láti máa ṣiṣẹ́ sin ẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn ọ̀gá wọn tẹ́lẹ̀. Àpèjúwe tó rọrùn láti lóye táwọn Kristẹni ìlú Róòmù sì mọ̀ dáadáa yìí yóò sún wọn láti béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, ‘Ọ̀gá wo ni mò ń sìn?’ b

Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

12, 13. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe lóde òní kí ọ̀rọ̀ wa lè wọ onírúurú èèyàn tó ń tẹ́tí sí wa lọ́kàn? (b) Ọ̀nà wo lo ti lò tó o sì rí i pé ó gbéṣẹ́ gan-an láti bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀?

12 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a gbọ́dọ̀ lákìíyèsí, ká mọwọ́ yí padà, ká sì já fáfá ká bàa lè bá onírúurú àwọn èèyàn tá à ń bá pàdé sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tó lè lóye ìhìn rere náà dáadáa, a ò kàn fẹ́ máa tọ̀ wọ́n lọ lásán, ká sọ ọ̀rọ̀ tá a ti múra rẹ̀ sílẹ̀ tàbí ká kàn fún wọn láwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. A ó sapá láti mọ ohun tí wọ́n nílò, ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àtohun tí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí, ká tún mọ àwọn ohun tó ń bà wọ́n lẹ̀rù àtàwọn ohun tó ń bí wọn nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí gba kéèyàn máa ronú jinlẹ̀ dáadáa kó sì máa sapá, síbẹ̀ ohun táwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe lójú méjèèjì jákèjádò ayé nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Hungary sọ pé: “Àwọn arákùnrin máa ń gba ti àṣà ìbílẹ̀ àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn rò àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn, wọn ò sì retí pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ tàwọn.” Àwọn Ẹlẹ́rìí níbòmíràn náà máa ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀.

13 Lórílẹ̀-èdè kan ní Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé, ohun tó jẹ àwọn èèyàn lógún jù níbẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ìlera, ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, àti ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́. Àwọn kókó wọ̀nyí làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà níbẹ̀ sì máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn dá lé lórí dípò kí wọ́n máa bá wọn sọ̀rọ̀ lórí bí ipò nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé tàbí lórí àwọn ìṣòro kàǹkà kàǹkà mìíràn tó wà láwùjọ. Bákan náà, àwọn akéde ní ìlú ńlá kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣàkíyèsí pé ní àdúgbò kan ní ìpínlẹ̀ wọn, àwọn ọ̀ràn bí ìkówójẹ, sún-kẹẹrẹ fà-kẹẹrẹ ọkọ̀, àti ìwà ipá ló jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn àwọn èèyàn ibẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí wá ń lo àwọn kókó ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn, wọ́n sì ń tẹ́tí sí wọn dáadáa. Àwọn tó mọ bá a ṣe ń fi Bíbélì kọ́ni dáadáa máa ń múra sílẹ̀ lọ́nà tó jẹ́ pé kò sí kókó yòówù táwọn yàn láti fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ò ní fetí sílẹ̀, wọ́n sì tún máa ń sọ̀rọ̀ wọn lọ́nà tí yóò gbádùn mọ́ àwọn èèyàn. Ohun tí wọ́n tún máa ń tẹnu mọ́ ni àwọn àǹfààní táwọn èèyàn á rí lákòókò yìí bí wọ́n bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, wọ́n sì tún máa ń tẹnu mọ́ àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run sọ pé òun ń mú bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Aísáyà 48:17, 18; 52:7.

14. Sọ àwọn ọ̀nà tá a lè gbà mú kí ọ̀rọ̀ wa bá ohun táwọn èèyàn nílò mu àti ipò wọn tó yàtọ̀ síra.

14 Lílo ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tún máa ń ṣèrànwọ́ nítorí pé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn èèyàn, ìmọ̀ wọn, àti ìsìn wọn yàtọ̀ síra gan-an. Ọ̀nà tá a máa gbà bá àwọn tó gbà pé Ẹlẹ́dàá wà àmọ́ tí wọn ò gba Bíbélì gbọ́ sọ̀rọ̀ yóò yàtọ̀ sí ọ̀nà tá à ń gbà bá àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà sọ̀rọ̀. Bá a bá bá ẹnì kan pàdé tó lérò pé mímú káwọn mìíràn tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn ẹni ni gbogbo ìwé ìsìn wà fún, bá a ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ á yàtọ̀ sí ọ̀nà tá à ń gbà bá ẹni tó fara mọ́ ohun tí Bíbélì kọ́ni sọ̀rọ̀. Ọ̀nà tá a máa gbà gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ tún gbọ́dọ̀ yàtọ̀ síra tá a bá ń bá àwọn èèyàn tí iye ìwé tí wọ́n kà yàtọ̀ síra sọ̀rọ̀. Àwọn olùkọ́ tó já fáfá yóò lo àlàyé àtàwọn àpèjúwe tó bá ipò tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lé lórí mu.—1 Jòhánù 5:20.

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Òjíṣẹ́ Lọ́wọ́

15, 16. Kí nídìí tó fi pọn dandan pé ká dá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di òjíṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́?

15 Kì í ṣe bí Pọ́ọ̀lù á ṣe mú kí ọ̀nà tó ń gbà kọ́ àwọn èèyàn túbọ̀ dára sí i nìkan ló jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ó tún rí i pé ó ṣe pàtàkì láti dá àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́ kóun sì múra wọn sílẹ̀, ìyẹn àwọn bíi Tímótì àti Títù, káwọn náà lè di òjíṣẹ́ tó pegedé. (2 Tímótì 2:2; 3:10, 14 Títù 1:4) Lákòókò tiwa yìí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fúnni ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ká sì gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láìfi falẹ̀.

16 Lọ́dún 1914, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún akéde Ìjọba ló wà ní gbogbo ayé. Lónìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn ẹni tuntun ló ń ṣèrìbọmi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! (Aísáyà 54:2, 3; Ìṣe 11:21) Nígbà táwọn ẹni tuntun bá bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni tí wọ́n sì fẹ́ láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọ́n nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìtọ́sọ́nà. (Gálátíà 6:6) Ó ṣe pàtàkì ká lo àwọn ọ̀nà tí Jésù Ọ̀gá wa lò nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tá a sì ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. c

17, 18. Ọ̀nà wo la lè gbà ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?

17 Jésù ò ṣàdédé lọ síbi táwọn èrò wà kó sì sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ó kọ́kọ́ jẹ́ kí wọ́n mọ bí iṣẹ́ ìwàásù náà ti ṣe pàtàkì tó, ó sì ní kí wọ́n máa gbàdúrà gan-an nípa rẹ̀. Lẹ́yìn náà ló wá pèsè àwọn nǹkan mẹ́ta tó ṣe kókó, ìyẹn ni: alábàáṣiṣẹ́, ìpínlẹ̀ tí wọ́n á ti ṣiṣẹ́, àti ohun tí wọn yóò sọ. (Mátíù 9:35-38; 10:5-7; Máàkù 6:7; Lúùkù 9:2, 6) Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ì báà jẹ́ ọmọ tiwa fúnra wa là ń ràn lọ́wọ́, bó sì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tuntun ni, tàbí ẹnì kan tó ti pẹ́ díẹ̀ tó ti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù gbẹ̀yìn, ó dára ká sapá láti máa lo ọ̀nà tí Jésù lò láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́.

18 Àwọn ẹni tuntun nílò ìrànwọ́ gan-an kí wọ́n lè ní ìgboyà láti sọ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà fáwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan sílẹ̀, èyí tó rọrùn tó sì máa fa àwọn èèyàn mọ́ra? Tẹ́ ẹ bá wà lóde ẹ̀rí, jẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ bó o ti ń wàásù láwọn ilé tẹ́ ẹ ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́. O lè ṣe bíi ti Gídíónì tó sọ fáwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ fẹ́ lọ jà pé: “Kí ẹ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wíwò mí, bẹ́ẹ̀ sì ni kí ẹ ṣe.” (Àwọn Onídàájọ́ 7:17) Lẹ́yìn náà kó o wá fún ẹni tuntun náà láǹfààní láti wàásù. Máa yin àwọn ẹni tuntun dáadáa fún ìsapá wọn, sì fún wọn láwọn àbá tó ṣe ṣókí tí yóò jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ṣe dáadáa nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.

19. Kí ni ìpinnu rẹ bó o ti ń sapá láti “ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún”?

19 Ká lè ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún,’ ìpinnu wa ni pé a óò túbọ̀ máa lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, a sì tún fẹ́ máa dá àwọn ẹni tuntun lẹ́kọ̀ọ́ láti lè máa ṣe ohun kan náà. Nígbà tá a bá ronú nípa bí ohun tó jẹ wá lógún ti ṣe pàtàkì tó, ìyẹn fífún àwọn èèyàn ní ìmọ̀ Ọlọ́run tó máa jẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà, ó dá wa lójú pé kò sóhun tá a ṣe tó pọ̀ jù láti di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí [a] lè rí i dájú pé [a] gba àwọn kan là.”—2 Tímótì 4:5; 1 Kọ́ríńtì 9:22.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bákan náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé àjọṣe tuntun tó wà láàárín Ọlọ́run àtàwọn “ọmọ” rẹ̀ tó fi ẹ̀mí yàn, ó lo ọ̀rọ̀ tó bá òfin mu táwọn tó ń kàwé rẹ̀ mọ̀ dáadáa ní gbogbo àgbègbè tí Ilẹ̀ Róòmù ti ń ṣàkóso. (Róòmù 8:14-17) Ìwé tó ń jẹ́ St. Paul at Rome sọ pé: “Ìsọdọmọ jẹ́ ọ̀rọ̀ táwọn ará Róòmù sábà máa ń lò, ó sì jẹ́ ohun tí kò ṣàjèjì rárá nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìdílé.”

b Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ètò “Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́” ti wà ní gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ètò yìí ń jẹ́ káwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún lo ìrírí wọn àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti gbà láti ran àwọn akéde tí wọn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí lọ́wọ́.

c Bó o bá fẹ́ mọ àpẹẹrẹ irú àwọn ànímọ́ tí Pọ́ọ̀lù ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, wo Ìṣe 13:9, 16-42; 17:2-4; 18:1-4; 19:11-20; 20:34; Róòmù 10:11-15; 2 Kọ́ríńtì 6:11-13.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fara wé Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ ìwàásù wa?

• Àwọn ìyípadà wo ló lè pọn dandan pé ká ṣe nínú bá a ṣe ń ronú?

• Kí la lè ṣe táwọn èèyàn á fi nífẹ̀ẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?

• Kí làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di òjíṣẹ́ nílò kí wọ́n lè dẹni tó nígboyà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹnì kan tó lákìíyèsí, tó mọ bá a ti ń yíwọ́ padà, tó sì já fáfá gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]

Jésù pèsè àwọn nǹkan mẹ́ta tó ṣe kókó fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn ni: alábàáṣiṣẹ́, ìpínlẹ̀ tí wọ́n á ti ṣiṣẹ́, àti ohun tí wọn yóò sọ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti wàásù fún onírúurú èèyàn nítorí pé ó mọ bá a ti ń yíwọ́ padà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn òjíṣẹ́ tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń gba ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn tí wọ́n ń wàásù fún rò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn òjíṣẹ́ tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù