Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Pinnu Láti Máa Sin Ẹlẹ́dàá Mi Nìṣó

Mo Pinnu Láti Máa Sin Ẹlẹ́dàá Mi Nìṣó

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Pinnu Láti Máa Sin Ẹlẹ́dàá Mi Nìṣó

GẸ́GẸ́ BÍ CONSTANCE BENANTI ṢE SỌ Ọ́

Ká tó pajú pẹ́ẹ́, gbẹgẹdẹ ti gbiná! Láàárín ọjọ́ mẹ́fà péré, akọ ibà kọ lu Camille, ọmọ wa tó jẹ́ ọmọ ọdún kan àtoṣù mẹ́wàá, ó sì kú. Ọkàn mi gbọgbẹ́ gidigidi. Ó ṣe mí bíi pé kémi náà kú. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láyè? Gbogbo ẹ̀ tojú sú mi.

ÌLÚ Castellammare del Golfo, tó wà ní Sicily, lórílẹ̀-èdè Ítálì làwọn òbí mi ti ṣí wá sílùú New York, níbi tí wọ́n ti bí mi ní ọjọ́ kẹjọ oṣù December, ọdún 1908. Bàbá mi àti ìyá mi àtàwa ọmọ mẹ́jọ, ìyẹn ọmọkùnrin márùn-ún àti ọmọbìnrin mẹ́ta la wà nínú ìdílé wa. a

Lọ́dún 1927, Bàbá mi, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Santo Catanzaro, bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwùjọ kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyẹn ni orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Arákùnrin Giovanni De Cecca tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ítálì tó ń sìn ní orílé-iṣẹ́ (tá a ń pè ní Bẹ́tẹ́lì) ní Brooklyn, New York, sì máa ń wá ṣèpàdé níbi tá à ń gbé nítòsí ìpínlẹ̀ New Jersey. Nígbà tó yá, bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Ó ṣe iṣẹ́ náà títí tó fi kú lọ́dún 1953.

Nígbà tí màmá mi wà lọ́mọdé, ó wù ú láti jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ kò gbà fún un Nítorí pé màmá mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ni kò jẹ́ kí èmi náà kọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ bàbá mi nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, láìpẹ́ mo ṣàkíyèsí pé ìwà bàbá mi ń yí padà. Ara rẹ̀ ń balẹ̀ sí i, ó dẹni tó ń níwà tútù, àlàáfíà sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba nínú ìdílé wa. Ìyẹn sì wù mí.

Lákòókò yìí ni mo bá Charles pàdé, ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju tèmi lọ, Brooklyn ni wọ́n sì bì i sí. Ìlú Sicily ni ìdílé rẹ̀ ti ṣí wá síbẹ̀ bí ìdílé tèmi náà. Láìpẹ́ a ṣèlérí pé a máa fẹ́ ara wa, a sì ṣègbéyàwó lẹ́yìn tí bàbá mi dé láti àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣe ní ìlú Columbus, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lọ́dún 1931. Láàárín ọdún kan la bí ọmọbìnrin wa tó ń jẹ́ Camille. Nígbà tó kú, ọkàn mi bà jẹ́ gidigidi. Lọ́jọ́ kan, Charles ń sunkún ó sì sọ fún mi pé: “Ṣé o mọ̀ pé bí Camille ṣe jẹ́ ọmọ tiẹ̀ náà ló jẹ́ ọmọ tèmi. Kí ló dé tá ò fi máa gbé ìgbésí ayé wa nìṣó ká sì máa tu ara wa nínú?”

Mo Tẹ́wọ́ Gba Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni

Charles rán mi létí pé bàbá mi sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde nígbà tó sọ̀rọ̀ níbi ìsìnkú Camille. Mo bi í pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ gbà gbọ́ pé àjíǹde wà?”

Ó dáhùn pé: “Mo gbà gbọ́ pé ó wà! Kí ló dé tá ò ṣèwádìí láti túbọ̀ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀?”

Mi ò lè sùn lóru ọjọ́ yẹn. Láago mẹ́fà òwúrọ̀ kí bàbá mi tó lọ síbi iṣẹ́ mo lọ bá a, mo sì sọ fún un pé èmi àti Charles fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì dì mọ́ mi. Màmá mi tí kò tíì dìde lórí ibùsùn gbọ́ ohun tá à ń sọ. Ó béèrè lọ́wọ́ mi pé kí ló ṣẹlẹ̀. Mo fèsì pé: “Kò sí nǹkan kan. Èmi àti Charles ti pinnu pé a óò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ó dáhùn pé: “Gbogbo wa ló yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Bí gbogbo wa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, títí kan àwọn àbúrò mi ọkùnrin àtàwọn àbúrò mi obìnrin. Gbogbo àwa mọ́kànlá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ bí ìdílé kan.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ tù mí nínú, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ìrètí tí mo wá ní sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ́pò ṣìbáṣìbo tó bá mi àti ìdààmú ọkàn tí mo ní. Ọdún kan lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1935, èmi àti Charles bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn. Ní oṣù February ọdún 1937, lórílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn, a gbọ́ àsọyé kan tó ṣàlàyé bí ìrìbọmi tí Ìwé Mímọ́ sọ ti ṣe pàtàkì tó, lẹ́yìn àsọyé yìí làwa àtàwọn ọ̀pọ̀ èèyàn mìíràn ṣèrìbọmi nínú omi kan tó wà ní òtẹ́ẹ̀lì kan nítòsí. Ìrìbọmi tí mo ṣe yìí kì í ṣe nítorí pé ó wù mí kí n rí ọmọ mi lọ́jọ́ kan nìkan ni, àmọ́ nítorí pé mo tún fẹ́ láti sin Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tí mo ti wá mọ̀ nísinsìnyí tí mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò-kíkún

Sísọ ohun tí mo ti kọ́ fáwọn èèyàn ń múnú mi dùn, ó sì lérè gan-an, nítorí pé lákòókò yẹn ọ̀pọ̀ èèyàn ló fetí sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn náà sì dẹni tó ń pòkìkí rẹ̀ fáwọn èèyàn. (Mátíù 9:37) Lọ́dún 1941, èmi àti Charles di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pe àwọn òjíṣẹ́ tí ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kò pẹ́ sígbà náà la ra ọkọ̀ àfiṣelé kan, Charles sì fi ilé iṣẹ́ wa tá ti ń ṣe ṣòkòtò síkàáwọ́ àbúrò mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Frank. Láìpẹ́ sí àkókò yẹn, a gba lẹ́tà kan tí wọ́n fi sọ fún wa pé wọ́n ti sọ wá di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ìyẹn sì múnú wa dùn gan-an. Níbẹ̀rẹ̀, a sìn ní ìlú New Jersey, lẹ́yìn náà ni wọ́n ní ká lọ sí Ìpínlẹ̀ New York.

Nígbà tá a wà ní àpéjọ kan nílùú Baltimore, ní Ìpínlẹ̀ Maryland, lọ́dún 1946, wọ́n sọ fún wa pé ká wá sí ìpàdé kan tí a óò ṣe pẹ̀lú àwọn aṣojú pàtàkì fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A pàdé arákùnrin Nathan H. Knorr àti Milton G. Henschel níbẹ̀. Wọ́n bá wa sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì, àmọ́ ní pàtàkì, ohun tí wọ́n bá wa sọ̀rọ̀ lé lórí ni iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè Ítálì. Wọ́n sọ pé ká lọ ronú bóyá a óò fẹ́ láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead.

Wọ́n sọ fún wa pé: “Ẹ ronú nípa rẹ̀ kẹ́ ẹ sì wá fún wa lésì.” Nígbà tá a kúrò níbi ìpàdé yẹn, èmi àti Charles wo ojú ara wa, a sì yí padà, a wá padà sínú ọ́fíìsì náà. A sọ fún wọn pé: “A ti ronú nípa rẹ̀. A ti ṣe tán láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì.” Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, a ti wà ní kíláàsì keje ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì.

A kò lè gbàgbé àwọn oṣù tá a fi gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yẹn. Ohun tó wọ̀ wá lọ́kàn jù lọ ni sùúrù àti ìfẹ́ táwọn olùkọ́ wa fi hàn sí wa, tí wọ́n múra wa sílẹ̀ láti borí oríṣiríṣi ìṣòro tó lè yọjú nílẹ̀ òkèèrè. Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege lóṣù July ọdún 1946, wọ́n yàn wá sílùú New York láti wàásù fúngbà díẹ̀ níbi táwọn ọmọ ilẹ̀ Ítálì pọ̀ sí dáadáa. Lẹ́yìn náà, ọjọ́ ayọ̀ náà dé! Lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù June ọdún 1947, a gbéra látibẹ̀ lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì níbi tí wọ́n yàn wá sí láti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì.

Bí Ara Wa Ṣe Mọlé Níbi Tí Wọ́n Yàn Wá Sí

Ọkọ̀ òkun táwọn ọmọ ogun ti lò tẹ́lẹ̀ la wọ̀ nígbà ìrìn àjò náà. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnlá lórí òkun, a gúnlẹ̀ sí èbúté ìlú Genoa ní orílẹ̀-èdè Ítálì. A rí àwọn nǹkan tí Ogun Àgbáyé Kejì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí lọ́dún méjì sígbà yẹn bà jẹ́ nínú ìlú yẹn. Bí àpẹẹrẹ, kò sí gíláàsì kankan lójú àwọn fèrèsé ilé tó wà ní ibùdókọ̀ rélùwéè, nítorí pé bọ́ǹbù ti ba ibẹ̀ jẹ́. Láti ìlú Genoa, a wọ ọkọ̀ ojú irin akẹ́rù lọ sílùú Milan, níbi tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa àti ilé àwọn míṣọ́nnárì wà.

Ipò nǹkan kò dára rárá ní Ítálì lẹ́yìn ogun yẹn. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtúnṣe ìlú náà lóòótọ́ àmọ́ ipò òṣì táwọn èèyàn ibẹ̀ wà kò ṣeé fẹnu sọ. Láìpẹ́ àìsàn ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mí lẹ́nu. Dókítà kan sọ fún mi pé àìsàn náà ti le débi pé ohun tó dára jù lójú tòun ni pé kí n padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Inú mi dùn pé ohun tó sọ kò rí bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ọdún méjìdínlọ́gọ́ta, mo ṣì wà níbi tí wọ́n yàn mí sí ní Ítálì.

A ò tíì lò ju ọdún mélòó kan níbi ti wọ́n yàn wá sí tí àwọn àbúrò mi ọkùnrin ní Amẹ́ríkà fi sọ pé àwọn fẹ́ gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan fún wa. Ṣùgbọ́n Charles fọgbọ́n sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣèyọnu, inú mi sì dùn sóhun tó sọ yẹn. A mọ̀ pé kò sí Ẹlẹ́rìí kankan ní Ítálì nígbà yẹn tó ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, Charles sì rò pé ohun tó dára jù lọ fún wa ni pé ká má ṣe gbé ìgbésí ayé olówó tó máa mú ká yàtọ̀ sáwọn tá a jo jẹ́ Kristẹni. Ọdún 1961 la tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan.

Àjàalẹ̀ ilé kan ni Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àkọ́kọ́ ní Milan, wọn ò sì rẹ́ ilẹ̀ rẹ̀. Kò sómi ẹ̀rọ níbẹ̀ o, àmọ́ ńṣe lomi máa ń ṣàn níbẹ̀ nígbà tójò bá rọ̀. Àwọn eku kéékèèké tún máa ń sáré káàkiri níbẹ̀. Gílóòbù iná méjì tó wà níbẹ̀ la máa ń fi ríran nígbà ìpàdé wa. Láìka gbogbo ìnira wọ̀nyẹn sí, inú wa máa ń dùn bá a ti ń rí àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń wá sáwọn ìpàdé wa tí wọ́n sì tún dẹni tó dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

Àwọn Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Wa

Nígbà kan, a fún ọkùnrin kan ní ìwé kékeré tó ń jẹ́ Peace—Can It Last? Bá a ti ń kúrò níbẹ̀ ni ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Santina dé pẹ̀lú àwọn báàgì tó kó nǹkan tó rà lọ́jà sí. Bẹ́ẹ̀ ló ń kanra, tó ń sọ pé òun ní ọmọbìnrin mẹ́jọ tóun ń tọ́jú, òun kò sì ráyè. Nígbà tí mo tún padà sọ́dọ̀ Santina, ó ń hun súwẹ́tà lọ́wọ́, ọkọ rẹ̀ kò sì sí nílé. Ló bá sọ pé: “Mi ò ráyè láti gbọ́ ohunkóhun. Yàtọ̀ síyẹn, mi ò mọ̀wé kà.”

Mo rọra gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì bi obìnrin náà bóyá mo lè fún un lówó kó bá mi hun súwẹ́tà kan fún ọkọ mi. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn ìyẹn ni mo gba súwẹ́tà náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwé “Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira” kọ́ Santina lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Santina kọ́ bá a ti ń kàwé, ó tẹ̀ síwájú dáadáa, ó sì ṣèrìbọmi láìka àtakò ọkọ rẹ̀ sí. Márùn-ún lára àwọn ọmọbìnrin Santina di Ẹlẹ́rìí, òun alára sì ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ohun tí Bíbélì kọ́ni.

Ní oṣù March ọdún 1951, wọ́n gbé àwa àtàwọn míṣọ́nnárì méjì mìíràn, ìyẹn Ruth Cannon b àti Loyce Callahan, tó wá fẹ́ Bill Wengert nígbà tó yá, lọ sílùú Brescia, níbi tí kò ti sí Ẹlẹ́rìí kankan. A rí ilé kan tó ní gbogbo nǹkan tó yẹ kí ilé ní, àmọ́ oṣù méjì lẹ́yìn náà ni onílé náà sọ pé ká kúrò nínú ilé náà kí wákàtí mẹ́rìnlélógún tó pé. Nítorí pé kò sí Ẹlẹ́rìí kankan lágbègbè náà, kò sí ohun tá a lè ṣe ju pé ká lọ sí òtẹ́ẹ̀lì kan, a sì gbé ibẹ̀ fún nǹkan bí oṣù méjì.

Gbogbo oúnjẹ wa kò ju kọfí, àwọn ìpápánu díẹ̀, wàràkàṣì àti èso. Láìka àwọn ìnira wọ̀nyí sí, a láyọ̀, Jèhófà sì bù kún wa. Nígbà tó yá, a rí ilé kékeré kan. Nígbà Ìrántí ikú Kristi tá a ṣe lọ́dún 1952, àwọn márùn-ún dín lógójì ló pésẹ̀ sínú yàrá kékeré tá a ń lò gẹ́gẹ́ bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba wa.

Bá A Ṣe Borí Àwọn Òkè Ìṣòro

Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣì ń lo agbára gan-an lórí àwọn èèyàn nígbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a ń wàásù nílùú Brescia, àwọn àlùfáà sọ fáwọn ọmọkùnrin kan pé kí wọ́n sọ wá lókùúta. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn èèyàn mẹ́rìndínlógún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wa, kò sì pẹ́ rárá tí wọ́n fi di Ẹlẹ́rìí. Ta sì ni ọ̀kan lára wọn? Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n fẹ́ sọ wá lókùúta yẹn ni! Alàgbà ni nísinsìnyí ní ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà nílùú Brescia. Nígbà tá a fi ìlú Brescia sílẹ̀ lọ́dún 1955, ogójì akéde Ìjọba Ọlọ́run ló ń wàásù níbẹ̀.

Lẹ́yìn náà, a fi ọdún mẹ́ta ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ìlú Leghorn (tó tún ń jẹ́ Livorno), níbi tó jẹ́ pé obìnrin ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé àwa obìnrin ló ń bójú tó àwọn iṣẹ́ ìjọ tó jẹ́ ti àwọn ọkùnrin. Lẹ́yìn ìyẹn, a ṣí lọ sí ìlú Genoa, níbi tá a ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dún mọ́kànlá sẹ́yìn. Nísinsìnyí ìjọ kan ti wà níbẹ̀. Àjà kejì ilé tá à ń gbé ni Gbọ̀ngàn Ìjọba wa wà.

Nígbà tá a dé ìlú Genoa, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá obìnrin kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ni iṣẹ́ ọkọ obìnrin náà tẹ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ máníjà ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn. Obìnrin náà tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ó sì di Kristẹni arábìnrin wa. Àmọ́ ṣá o, ọkọ rẹ̀ ta kò ó, ó sì ń ṣe àtakò náà nìṣó fúngbà pípẹ́. Lẹ́yìn náà ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé aya rẹ̀ wá sí ìpàdé. Àmọ́ kàkà kó wọlé, ńṣe ló máa jókòó síta tá á sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tá a ti kúrò nílùú Genoa la wá gbọ́ pé ó ti ní kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ó ṣèrìbọmi, ó sì di alábòójútó onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Ó ṣolóòótọ́ títí tó fi kú.

Mo tún bá obìnrin kan tó fẹ́ fẹ́ ọlọ́pàá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níbẹ̀rẹ̀, ọlọ́pàá náà nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó ṣègbéyàwó tán, ìwà rẹ̀ yí padà. Ó gbógun ti obìnrin náà, ìyẹn ò sì kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Nígbà tí obìnrin náà tún bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì padà, ọkọ rẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọn pé tóun bá rí wa tá a jọ ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ńṣe lòun á yìnbọn lù wá. Àmọ́, obìnrin náà tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ó sì di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní pé à ń sọ pé kò yìnbọn lù wá. Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tá a wà ní àpéjọ kan nílùú Genoa, ẹnì kan wá sẹ́yìn mi, ó fọwọ́ bò mí lójú, ó sì bi mí bóyá mo mọ ẹni tó fọwọ́ bò mí lójú. Mi ò lè pa omijé ayọ̀ náà mọ́ra nígbà tí mo rí i pé ọkọ obìnrin náà ni. Lẹ́yìn tá a dì mọ́ra wa tán, ó sọ fún mi pé ọjọ́ yẹn gan-gan lòun ṣèrìbọmi láti fi hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà!

Láàárín ọdún 1964 sí ọdún 1972, mo láǹfààní láti máa tẹ̀lé Charles nígbà tó bá ń bẹ àwọn ìjọ wò láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìlú tó wà lápá àríwá orílẹ̀-èdè Ítálì la ti sìn, ìyẹn ní Piedmont, Lombardy, àti ní Liguria. Lẹ́yìn ìyẹn la wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà nítòsí ìlú Florence tá a sì tún lọ sílùú Vercelli lẹ́yìn náà. Ìjọ kan ṣoṣo ló wà nílùú Vercelli lọ́dún 1977, àmọ́ nígbà tá a máa fi kúrò níbẹ̀ lọ́dún 1999, ìjọ mẹ́ta ti wà níbẹ̀. Ọdún yẹn ni mo di ẹni ọdún mọ́kànlé-láàádọ́rùn-ún, wọ́n sì sọ pé ká lọ máa gbé nílé àwọn míṣọ́nnárì tó wà nílùú Róòmù, èyí tó jẹ́ ilé kékeré kan tó sì lẹ́wà lágbègbè kan tó tòrò minimini.

Ohun Ìbànújẹ́ Mìíràn Tún Ṣẹlẹ̀ sí Mi

Ọkọ mi, Charles, tí kì í ṣàìsàn kàn dédé bẹ̀rẹ̀ àìsàn lóṣù March ọdún 2002. Àìsàn náà le débi pé ó kú lọ́jọ́ kọkànlá oṣù May ọdún 2002. Ọdún mọ́kànléláàádọ́rin la fi bára wa gbé, tá a jọ máa ń sunkún nígbà ìbànújẹ́ tá a sì jọ máa ń yọ̀ nígbà tá a bá rí ìbùkún. Àdánù ńláǹlà tó ń bà mí lọ́kàn jẹ́ ni ikú rẹ̀ jẹ́ fún mi.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń rántí bí Charles ṣe máa ń rí nínú aṣọ kóòtù rẹ̀ àti fìlà kan báyìí tó máa ń dé, èyí tó gbayì láwọn ọdún 1930. Mò máa ń fojú inú wò ó bó ṣe máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì tún máa ń dà bíi pé mò ń gbọ́ ohùn rẹ̀ bó ṣe ń rẹ́rìn-ín. Ọpẹ́lọpẹ́ ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti ìfẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọ̀wọ́n ń fi hàn sí mi. Ìwọ̀nyí ló ń mú kó ṣeé ṣe fún mi láti fara da àkókò ìbànújẹ́ yìí. Mò ń fojú sọ́nà de ìgbà tí màá padà rí Charles.

Mò Ń Bá Iṣẹ́ Ìsìn Mi Nìṣó

Sísin Ẹlẹ́dàá mi ti jẹ́ ohun àgbàyanu nínú ìgbésí ayé mi. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ‘mo ti tọ́ Jèhófà wò, mo sì ti rí i pé ó jẹ́ ẹni rere.’ (Sáàmù 34:8) Mo ti ri pé ó nífẹ̀ẹ́ mi ó sì ń tọ́jú mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pàdánù ọmọ mi, Jèhófà ti fún mi ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà káàkiri ilẹ̀ Ítálì, tí wọ́n ń múnú mi dùn, tí wọ́n si ń múnú Ọlọ́run dùn pẹ̀lú.

Bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá mi lohun tí mo fẹ́ràn jù láti máa ṣe. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń bá a lọ láti máa wàásù kí n sì máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà mìíràn, ó máa ń dùn mí pé mi ò lè ṣe ju ìwọ̀nba tí mò ń ṣe nítorí àìlera mi. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé Jèhófà mọ ibi tí agbára mi mọ, ó sì nífẹ̀ẹ́ mi bẹ́ẹ̀ ló sì mọyì ìwọ̀nba ohun tí agbára mi gbé. (Máàkù 12:42) Mò ń sapá láti máa ṣe ohun tí Sáàmù 146:2 sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa yin Jèhófà ní ìgbà ayé mi. Ṣe ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà.” c

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ nípa Angelo Catanzaro, àbúrò mi ọkùnrin jáde nínú Ile-Iṣọ Na October, 1975, ojú ìwé 584 sí 586.

b Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa ìtàn ìgbésí ayé Ruth Cannon, wo Ile Iṣọ Na, December 1, 1971, ojú ìwé 728 sí 731.

c Arábìnrin Benanti kú lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù July ọdún 2005, nígbà tí à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́. Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Camille

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1931

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Màmá mi kò nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákọ̀ọ́kọ́, àmọ́ ó wá gbà pé kí gbogbo wa máa kẹ́kọ̀ọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwa àti Arákùnrin Knorr nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1946

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Èmi àti Charles kété ṣáájú ikú rẹ̀