Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkókò Yìí Gan-an Ló Yẹ Kó O Gbé Ìgbésẹ̀ Kánkán

Àkókò Yìí Gan-an Ló Yẹ Kó O Gbé Ìgbésẹ̀ Kánkán

Àkókò Yìí Gan-an Ló Yẹ Kó O Gbé Ìgbésẹ̀ Kánkán

“Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra?”—1 ÀWỌN ỌBA 18:21.

1. Kí ló mú kí ìgbà tiwa yìí yàtọ̀ pátápátá sí tàtẹ̀yìnwá?

 ǸJẸ́ o gbà pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́? Ǹjẹ́ o sì tún gbà pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ìgbà tiwa yìí ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan búburú tí Sátánì ń darí? (2 Tímótì 3:1) Tó o bá gbà bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá gbà pé ìgbà tó yẹ kó o gbé ìgbésẹ̀ kánkán la wà yìí. Ìdí ni pé kò sígbà kan tí ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn wà nínú ewu bí àkókò tá a wà yìí.

2. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Áhábù ń ṣàkóso ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì?

2 Ní ọ̀rúndún kẹwàá ṣáájú Sànmánì Kristẹni, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ìpinnu pàtàkì kan láti ṣe, ìyẹn ìpinnu nípa ẹni tó yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn. Ìdí ni pé Jésíbẹ́lì abọ̀rìṣà ti mú kí ọkọ rẹ̀ Áhábù Ọba sọ àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì dẹni tó ń bọ Báálì. Wọ́n ka Báálì yìí sí òrìṣà tó máa ń rọ òjò, tó sì máa ń mú kí irè oko dára. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń bọ òrìṣà Báálì ti forí balẹ̀ fún ère rẹ̀ tàbí kí wọ́n ti fi àtẹ́lẹwọ́ wọn ba ẹnu láti fi júbà rẹ̀. Àwọn tó ń bọ òrìṣà Báálì máa ń bá àwọn kárùwà tàbí aṣẹ́wó inú tẹ́ńpìlì ṣe onírúurú ìṣekúṣe torí kí Báálì lè fìbùkún sí ohun ọ̀gbìn wọn àti ohun ọ̀sìn wọn. Wọ́n tún sábà máa ń fi nǹkan ya ara wọn lára kí ẹ̀jẹ̀ lè jáde lára wọn.—1 Àwọn Ọba 18:28.

3. Àkóbá wo ni ìjọsìn Báálì ṣe fáwọn èèyàn Ọlọ́run?

3 Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kò kópa nínú ìbọ̀rìṣà tó kún fún ìṣekúṣe àti ìwà ipá náà. (1 Àwọn Ọba 19:18) Wọn kò yà kúrò nínú májẹ̀mú tí wọ́n bá Jèhófà Ọlọ́run dá rárá, inúnibíni sì bá wọn nítorí ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì Jèhófà ni Jésíbẹ́lì Ayaba pa. (1 Àwọn Ọba 18:4, 13) Nígbà tó di pé kò rọrùn láti jọ́sìn Jèhófà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àmúlùmálà ìgbàgbọ́. Wọ́n fẹ́ máa ṣe ohun tó wu Jèhófà, wọ́n sì tún ń gbìyànjú láti tẹ́ Báálì lọ́rùn lẹ́sẹ̀ kan náà. Àmọ́ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá fi Jèhófà sílẹ̀ tó lọ ń bọ̀rìṣà, ó ti di apẹ̀yìndà nìyẹn. Jèhófà sọ pé òun yóò bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n bá fẹ́ràn òun tí wọ́n sì ń pa òfin òun mọ́. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé tí wọn ò bá fún òun ní “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe,” òun yóò pa wọ́n run.—Diutarónómì 5:6-10; 28:15, 63.

4. Kí ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò wáyé láàárín àwọn Kristẹni, báwo lọ̀rọ̀ wọn sì ṣe ṣẹ?

4 Irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì yìí gan-an ló ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lónìí. Wọ́n máa ń sọ pé Kristẹni làwọn, àmọ́ àwọn àjọ̀dún wọn, ìwà wọn àti ẹ̀kọ́ ìsìn wọn lòdì sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Ìwà àwọn aṣáájú ìsìn wọn kò yàtọ̀ sí ti Jésíbẹ́lì torí pé àwọn ni olórí àwọn tó ń ṣenúnibíni sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀wẹ̀, àtọdúnmọ́dún wá làwọn aṣáájú ìsìn wọn ti ń ṣètìlẹ́yìn fún ogun jíjà, èyí tó fi hàn pé àwọn àti ìjọba ayé ló jọ jẹ̀bi ikú ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ìjọ wọn tó ń kú sógun. Bíbélì fi hàn pé ẹ̀sìn tó bá ń ti àwọn ìjọba ayé lẹ́yìn láti ṣe irú nǹkan báwọ̀nyí jẹ́ alágbèrè nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 18:2, 3) Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sì tún gbà káwọn ọmọ ìjọ máa ṣèṣekúṣe bó ṣe wù wọ́n, àní àwọn olórí ìsìn wọn pàápàá ń ṣe é. Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti sọ tẹ́lẹ̀ ṣá o pé irú ìpẹ̀yìndà ńlá bẹ́ẹ̀ máa wáyé. (Mátíù 13:36-43; Ìṣe 20:29, 30; 2 Pétérù 2:1, 2) Kí ló máa wá jẹ́ àtúbọ̀tán àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí iye wọn lé ní ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́ta? Kí sì ni ojúṣe àwọn olùjọsìn Jèhófà sí wọn àti sí gbogbo àwọn mìíràn tí ẹ̀sìn èké ti ṣì lọ́nà? A óò rí ìdáhùn ìbéèrè wọ̀nyí tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ohun pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ kó tó di pé Jéhù “pa Báálì rẹ́ ráúráú kúrò ní Ísírẹ́lì.”—2 Àwọn Ọba 10:28.

Ìfẹ́ Tí Ọlọ́run Ní Sáwọn Èèyàn Rẹ̀ Tó Yàyàkuyà

5. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn rẹ̀ tó yàyàkuyà?

5 Kì í dùn mọ́ Jèhófà Ọlọ́run láti máa fìyà jẹ àwọn tó bá hùwà àìṣòótọ́ sí i. Baba onífẹ̀ẹ́ ni, nítorí náà ohun tó ń fẹ́ ni pé kí àwọn èèyàn burúkú ronú pìwà dà kí wọ́n padà sọ́dọ̀ òun. (Ìsíkíẹ́lì 18:32; 2 Pétérù 3:9) A rí bí èyí ṣe jẹ́ òótọ́ látinú bí Jèhófà ṣe lo ọ̀pọ̀ wòlíì nígbà ayé Áhábù àti Jésíbẹ́lì láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa ohun tó máa bá wọn bí wọn ò bá jáwọ́ nínú sísin Báálì. Ọ̀kan lára àwọn wòlíì tí Jèhófà lò ni Èlíjà. Ní òpin ọ̀dá ńlá kan tí Èlíjà sọ tẹ́lẹ̀, Èlíjà sọ pé kí Áhábù Ọba kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn wòlíì Báálì jọ sórí Òkè Kámẹ́lì.—1 Àwọn Ọba 18:1, 19.

6, 7. (a) Báwo ni Èlíjà ṣe fi ohun tó mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì di apẹ̀yìndà hàn? (b) Kí làwọn wòlíì Báálì ṣe? (d) Kí ni Èlíjà ṣe?

6 Ibi tí wọ́n pé jọ sí ni ibi pẹpẹ Jèhófà tí wọ́n “ya lulẹ̀,” bóyá láti fi wá ojúure Jésíbẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 18:30) Ó tini lójú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ kò mọ ẹni tí wọn ì bá sọ pé ó lè rọ òjò tí wọ́n ń wá lójú méjèèjì nínú Jèhófà àti Báálì. Àádọ́ta-lé-nírínwó [450] wòlíì ló wá ṣojú fún Báálì níbẹ̀, àmọ́ Èlíjà nìkan ni wòlíì tó ṣojú fún Jèhófà. Èlíjà bi àwọn èèyàn náà ní ìbéèrè kan láti fi sọ ohun tó jẹ́ olórí ìṣòro wọn, ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra?” Lẹ́yìn náà ó wá sọ ojú abẹ níkòó, ó ní: “Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Èlíjà wá dá àbá kan tí wọ́n á fi mọ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ nínú àwọn méjèèjì. Ìdí tó fi dá àbá yẹn ni pé ó fẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì oníyèmejì máa sin Jèhófà nìkan ṣoṣo. Ó ní kí wọ́n pa akọ màlúù méjì láti fi rúbọ, ọ̀kan sí Jèhófà ìkejì sí Báálì. Ó ní kí èyí tó bá jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ lára wọn fúnra rẹ̀ finá sí ẹbọ rẹ̀. Àwọn wòlíì Báálì wá ṣètò ẹbọ tiwọn, ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n sì fi ń ké pe Báálì pé: “Báálì, dá wa lóhùn!” Nígbà tí Èlíjà wá ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi nǹkan ya ara wọn lára títí ẹ̀jẹ̀ fi jáde lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ké lóhùn rara. Ṣùgbọ́n wọn ò rí ìdáhùn kankan gbà.—1 Àwọn Ọba 18:21, 26-29.

7 Ọpọ́n wá sún kan Èlíjà báyìí. Ó kọ́kọ́ tún pẹpẹ Jèhófà tó wà níbẹ̀ ṣe, ó sì kó ègé ọmọ akọ màlúù tirẹ̀ sórí rẹ̀. Ó ní kí wọ́n da omi ìṣà ńlá mẹ́rin sórí ẹbọ náà. Wọ́n dá omi sí i bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta títí yàrà tó yí pẹpẹ náà ká fi kún fómi. Èlíjà wá gbàdúrà pé: “Ìwọ Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì, àti pé èmi jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ, àti pé nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Dá mi lóhùn, Jèhófà, dá mi lóhùn, kí àwọn ènìyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, ni Ọlọ́run tòótọ́, àti pé ìwọ fúnra rẹ ti yí ọkàn-àyà wọn padà.”—1 Àwọn Ọba 18:30-37.

8. Báwo ni Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà Èlíjà, kí ni wòlíì náà sì wá ṣe?

8 Ọlọ́run tòótọ́ dá Èlíjà lóhùn, ó rán iná látọ̀runwá láti fi sun ẹbọ náà àti pẹpẹ rẹ̀ ráúráú. Kódà iná náà lá omi inú yàrà tó yí pẹpẹ náà ká láú! Ẹ̀yin ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn. Ńṣe ni “wọ́n dojú bolẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì wí pé: ‘Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!’” Èlíjà wá ṣe ohun pàtàkì kan láìjáfara. Ó pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ gbá àwọn wòlíì Báálì mú! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹyọ kan lára wọn sá lọ!” Bí wọ́n ṣe pa gbogbo àádọ́ta-lé-nírínwó [450] wòlíì Báálì tó wà níbẹ̀ nísàlẹ̀ Òkè Kámẹ́lì nìyẹn.—1 Àwọn Ọba 18:38-40.

9. Kí ló tún jẹ́ ìdánwò fún àwọn olùjọsìn tòótọ́?

9 Ọjọ́ mánigbàgbé yìí kan náà ni Jèhófà mú kí òjò rọ̀ fúngbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àtààbọ̀! (Jákọ́bù 5:17, 18) Ẹ fojú inú wo ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa bá ara wọn sọ lójú ọ̀nà bí wọ́n ṣe ń lọ sílé; láìsí àní-àní Jèhófà ti fi hàn kedere pé òun ni Ọlọ́run tòótọ́. Àmọ́ àwọn tó ń bọ Báálì ò jáwọ́ o. Jésíbẹ́lì náà ò sì dáwọ́ inúnibíni tó ń ṣe sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dúró. (1 Àwọn Ọba 19:1, 2; 21:11-16) Gbogbo èyí tún dán ìdúróṣinṣin àwọn èèyàn Ọlọ́run wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣé wọ́n á ṣì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn lọ́nà tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe nígbà tọ́jọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run bá dé sórí àwọn tó ń bọ Báálì?

Gbé Ìgbésẹ̀ Kankan Nísinsìnyí

10. (a) Kí làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe lóde òní? (b) Kí lẹni tó bá fẹ́ tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Ìṣípayá 18:4 gbọ́dọ̀ ṣe?

10 Irú iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe lóde òní. Wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu àti ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ ṣèkìlọ̀ ewu tí ń bẹ nínú ìsìn èké fáwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo, àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn tí kì í ṣe oníṣọ́ọ̀ṣì. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tètè jáwọ́ nínú ìsìn èké, kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Ohun tí Ọlọ́run sì ní káwọn èèyàn ṣe nípa ẹ̀sìn èké láìjáfara náà nìyẹn, ó ni: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣípayá 18:4.

11. Kí lẹni tó bá fẹ́ rójú rere Jèhófà ní láti ṣe?

11 Àmọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn míì ṣì wà tí wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ṣiyèméjì nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Àwọn míì lára wọn máa ń wá sáwọn ìpàdé ìjọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bóyá nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tàbí kí wọ́n wá gbádùn díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ ìpàdé àgbègbè. A gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ronú lórí ọ̀rọ̀ Èlíjà yìí dáadáa, ó ní: “Yoo ti pẹ́ to ti ẹyin yoo fi maa ṣiyemeji?” (1 Àwọn Ọba 18:21, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Dípò bí wọ́n ṣe ń fọ̀rọ̀ falẹ̀ ńṣe ló yẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ kánkán nísinsìnyí láti ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì di olùjọsìn Jèhófà tó ṣèrìbọmi. Ohun tó máa fi hàn bóyá wọ́n á níyè àìnípẹ̀kun tàbí wọn ò ní ní nìyẹn o!—2 Tẹsalóníkà 1:6-9.

12. Ọ̀fìn wo làwọn Kristẹni kan tó ti ṣèrìbọmi jìn sí, kí ló sì yẹ kí wọ́n ṣe?

12 Ó ṣeni láàánú pé àwọn Kristẹni kan tó ti ṣèrìbọmi kò ṣe ìjọsìn wọn déédéé mọ́, kódà àwọn míì tiẹ̀ ti pa á tì. (Hébérù 10:23-25; 13:15, 16) Ìbẹ̀rù inúnibíni, àníyàn gbígbọ́ bùkátà, ìlépa ọrọ̀ àti fàájì jíjẹ ò jẹ́ káwọn mìíràn nítara mọ́. Bẹ́ẹ̀ Jésù ti kìlọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí ṣáájú o, pé wọ́n á mú àwọn míì nínú ọmọ ẹ̀yìn òun kọsẹ̀ tàbí káwọn nǹkan wọ̀nyí fún ìgbàgbọ́ wọn pa tàbí kí wọ́n di ìdẹkùn fún wọn. (Mátíù 10:28-33; 13:20-22; Lúùkù 12:22-31; 21:34-36) Dípò tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á fi máa “ṣiyèméjì,” ńṣe ni kí wọ́n di ‘onítara, kí wọ́n ronú pìwà dà,’ kí wọ́n tún tara ṣàṣà máa ṣe ojúṣe wọn bí wọ́n ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ nígbà tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.—Ìṣípayá 3:15-19.

Bí Ìsìn Èké Yóò Ṣe Dópin Lójijì

13. Ṣàlàyé ipò tí Ísírẹ́lì wà nígbà tí a fòróró yan Jéhù láti di ọba.

13 Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì ní nǹkan bí ọdún méjìdínlógún lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ yanjú lórí Òkè Kámẹ́lì jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn tètè jáde kúrò nínú ẹ̀sìn èké nísinsìnyí. Òjijì ni ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà dé sórí àwọn tó ń bọ Báálì nígbà ayé wòlíì Èlíṣà tó gbaṣẹ́ lọ́wọ́ Èlíjà. Jèhórámù ọmọ Áhábù Ọba ló ń ṣàkóso Ísírẹ́lì nígbà náà, Jésíbẹ́lì ìyá ọba náà sì wà láàyè lákòókò yẹn. Èlíṣà rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́ pé kó lọ fòróró yan Jéhù ọ̀gágun Ísírẹ́lì láti di ọba tó máa rọ́pò Jèhórámù. Rámótì-gílíádì ní ìlà oòrùn Jọ́dánì ni Jéhù wà nígbà náà, tó ń darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń bá àwọn ọ̀tá wọn jagun. Jèhórámù Ọba sì wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jésíréélì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Mẹ́gídò, ó ń tọ́jú ibi tó fi gbọgbẹ́ lójú ogun.—2 Àwọn Ọba 8:29–9:4.

14, 15. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé lé Jéhù lọ́wọ́, ọwọ́ wo ni Jéhù sì fi mú iṣẹ́ náà?

14 Ohun tí Jèhófà sọ pé kí Jéhù ṣe nìyí: “Kí ìwọ . . . ṣá ilé olúwa rẹ Áhábù balẹ̀, èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti ẹ̀jẹ̀ gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́wọ́ Jésíbẹ́lì. Gbogbo ilé Áhábù yóò sì ṣègbé; . . . Jésíbẹ́lì sì ni àwọn ajá yóò jẹ ní abá ilẹ̀ tí ó wà ní Jésíréélì, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò sin ín.”—2 Àwọn Ọba 9:7-10.

15 Jéhù kì í fọ̀rọ̀ falẹ̀ rárá. Kíá ó ti gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì sáré lọ sí Jésíréélì. Nígbà tí olùṣọ́ kan ní Jésíréélì rí bí kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ṣe ń sáré bọ̀, ó ti mọ̀ pé Jéhù ni, ó sì sọ fún Jèhórámù Ọba. Ni Jèhórámù bá gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ lọ pàdé Jéhù olórí ogun rẹ̀. Bí wọ́n ṣe pàdé, Jèhórámù bi Jéhù pé: “Ṣé àlàáfíà ni, Jéhù?” Jéhù fèsì pé: “Àlàáfíà báwo, níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè Jésíbẹ́lì ìyá rẹ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀ bá ń bẹ?” Bí Jèhórámù ṣe ni kóun sá lọ ni Jéhù ta á lọ́fà, ọfà náà sì gún ọkàn rẹ̀, ó sì kú.—2 Àwọn Ọba 9:20-24.

16. (a) Ìpinnu wo làwọn òṣìṣẹ́ ààfin tó wà lọ́dọ̀ Jésíbẹ́lì ní láti ṣe láìròtẹ́lẹ̀? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Jésíbẹ́lì ṣe ṣẹ?

16 Jéhù tún tara ṣàṣà gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ lọ sínú ìlú. Jésíbẹ́lì tó ti tọ́jú tọ́tè wá yọjú lójú fèrèsé, ó sì kí Jéhù ní ìkíni akọ láti fi hàn pé Jéhù ti kẹ́ran. Àmọ́ Jéhù ò ṣe bíi pé òun gbọ́, ó ní, “Ta ní wà pẹ̀lú mi? Ta ni?” kí àwọn yẹn lè yọjú sí i. Ó wá di dandan káwọn ìránṣẹ́ Jésíbẹ́lì ṣèpinnu kíá. Àwọn òṣìṣẹ́ ààfin méjì tàbí mẹ́ta yọjú sí i láti ojú fèrèsé. Jéhù wá pàṣẹ pé: “Ẹ ré e bọ́!” Ọ̀ràn dójú ẹ̀ wàyí. Ti ta ni wọ́n máa ṣe nínú àwọn méjèèjì? Bí àwọn òṣìṣẹ́ ààfin náà ṣe ré Jésíbẹ́lì bọ́ sójú ọ̀nà nísàlẹ̀ nìyẹn, tí àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jéhù sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Báyìí ni Jésíbẹ́lì tó ń ṣagbátẹrù ìjọsìn Báálì nílẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe jèrè iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀. Kí wọ́n tó lọ gbé òkú rẹ̀ láti sin ín, àwọn ajá ti jẹ ẹran ara rẹ̀ bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe wí.—2 Àwọn Ọba 9:30-37.

17. Kí ló yẹ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ bá a ṣe rí i pé Jésíbẹ́lì gba ìdájọ́ Ọlọ́run?

17 Irú ikú ẹ̀sín tí aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ tó ń jẹ́ “Bábílónì Ńlá” ń bọ̀ wá kú nìyẹn. Gbogbo ẹ̀sìn èké tó wà nínú ayé Sátánì, tí wọ́n pilẹ̀ látinú ìlú Bábílónì ìgbàanì, ló para pọ̀ jẹ́ aṣẹ́wó yẹn. Tí ẹ̀sìn èké bá sì ti wá dópin, Jèhófà Ọlọ́run yóò yíjú sí gbogbo èèyàn yòókù tí ń bẹ lábẹ́ àkóso Sátánì. Yóò pa gbogbo wọn run kí ayé tuntun òdodo lè gbilẹ̀.—Ìṣípayá 17:3-6; 19:19-21; 21:1-4.

18. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń sin Báálì ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn ikú Jésíbẹ́lì?

18 Lẹ́yìn ikú Jésíbẹ́lì, kíá ni Jéhù Ọba run gbogbo ọmọ Áhábù àti gbogbo àwọn sàràkí-sàràkí nínú àwọn alátìlẹyìn rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 10:11) Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń bọ Báálì ṣì kù lórílẹ̀-èdè náà. Jéhù wá wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ wọn láti fi hàn pé òun ‘kò fàyè gba bíbá Jèhófà díje.’ (2 Àwọn Ọba 10:16) Jéhù dọ́gbọ́n ṣe bíi pé òun náà ń sin Báálì, ó wá ṣètò àjọyọ̀ ńlá kan tí wọ́n máa ṣe ní tẹ́ńpìlì Báálì tí Áhábù kọ́ sí Samáríà. Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó ń sin Báálì ló wá síbi àjọyọ̀ náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo wọn rọ́ kún inú tẹ́ńpìlì náà tán, ńṣe làwọn ìránṣẹ́ Jéhù pa gbogbo wọn pátápátá. Bíbélì parí ìtàn náà báyìí pé: “Bí Jéhù ṣe pa Báálì rẹ́ ráúráú kúrò ní Ísírẹ́lì nìyẹn.”—2 Àwọn Ọba 10:18-28.

19. Ohun àgbàyanu wo ló wà lọ́jọ́ iwájú fáwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀?

19 Ìjọsìn Báálì dópin nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dájú pé àwọn ẹ̀sìn èké ayé máa dópin lójijì, lọ́nà tó burú jáì. Ìhà ọ̀dọ̀ ta lo máa wà ní ọjọ́ ìdájọ́ ńlá náà? Gbé ìgbésẹ̀ kánkán nísinsìnyí, kó lè ṣeé ṣe fún ọ láti wà lára “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí yóò la “ìpọ́njú ńlá náà” já. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè wẹ̀yìn wò tìdùnnú-tìdùnnú kó o sì yin Ọlọ́run lógo pé ó ṣèdájọ́ lórí “aṣẹ́wó ńlá tí ó fi àgbèrè rẹ̀ sọ ilẹ̀ ayé di ìbàjẹ́.” Wàá sì lè fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn olùjọsìn tòótọ́ yòókù tí wọ́n fara mọ́ ọ̀rọ̀ orin táwọn ẹ̀dá ọ̀run ń kọ pé: “Ẹ yin Jáà, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa, Olódùmarè, ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.”—Ìṣípayá 7:9, 10, 14; 19:1, 2, 6.

Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò

• Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe dẹni tó ń bọ Báálì?

• Ìpẹ̀yìndà ńlá wo ni Bíbélì sọ pé ó máa wáyé, báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ṣe ṣẹ?

• Báwo ni Jéhù ṣe fòpin sí ìjọsìn Báálì?

• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dá wa sí lọ́jọ́ ìdájọ́ rẹ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Sókóhì

Áfékì

Hélíkátì

Jókínéámù

Mẹ́gídò

Táánákì

Dótánì

SAMÁRÍÀ

Ẹ́ń-dórì

Ṣúnémù

Ọ́fírà

Jésíréélì

Íbíléámù (Gati-rímónì)

Tírísà

Bẹti-ṣémẹ́ṣì

Bẹti-ṣéánì (Bẹti-ṣánì)

Jabẹṣi-gílíádì?

Ebẹli-méhólà

Ilé Áríbélì

Ramoti-gílíádì

[Àwọn òkè]

Òkè Kámẹ́lì

Òkè Tábórì

Mórè

Òkè Gíbóà

[Àwn omi ńlá]

Òkun Mẹditaréníà

Òkun Gálílì

[Odò]

Odò Jọ́dánì

[Kànga]

Kànga Háródù

[Credit Line]

A gba àwòrán ilẹ̀ yìí látọ̀dọ̀ Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. and Survey of Israel

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run déédéé àti lílọ sí ìpàdé ìjọ déédéé jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ kí Jèhófà dá òun sí lọ́jọ́ ìdájọ́ rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ kánkán bíi ti Jéhù