Àsìkò Ọdún Ṣó Máa Rí Bó O Ṣe Fẹ́ Kó Rí?
Àsìkò Ọdún Ṣó Máa Rí Bó O Ṣe Fẹ́ Kó Rí?
“Peter [Ńlá] pàṣẹ pé kí gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ààtò ìsìn àkànṣe Ọdún Tuntun lọ́jọ́ kìíní oṣù January. Yàtọ̀ síyẹn, ó ní kí wọ́n fi ẹ̀ka igi tó tútù yọ̀yọ̀ tí wọ́n máa ń lò nígbà ọdún ṣe ọ̀ṣọ́ sí gbogbo ẹnu ọ̀nà tó wà nínú ilé, ó sì ní káwọn ọmọ bíbí ìlú Moscow máa ‘fi ìdùnnú wọn hàn nípa kíkí ara wọn kú ọdún’ lọ́jọ́ Ọdún Tuntun.”—Ìwé Peter the Great—His Life and World.
KÍ LO máa ń ronú àtiṣe lásìkò ọdún Kérésì àti Ọdún Tuntun? Àkókò ọdún méjèèjì yìí gùn díẹ̀. Àwọn òbí lè ti gbàyè níbi iṣẹ́ káwọn ọmọ sì ti gba ọlidé nílé ìwé lásìkò yìí. Èyí á wá mú kó dà bíi pé àsìkò yẹn gan-an ló dára jù lọ fún àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn láti jọ gbádùn ara wọn. Tipẹ́tipẹ́ làwọn èèyàn ti gbà pé ọjọ́ ọdún Kérésìmesì ni wọ́n bí Kristi. Ìdí nìyí táwọn kan fi máa ń fẹ́ láti gbé Kristi ga lákòókò yẹn, torí wọ́n gbà pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ téèyàn lè fi àsìkò yẹn ṣe nìyẹn. Bóyá ohun tí ìwọ náà rò nìyẹn.
Àìmọye ọkọ, aya, àtàwọn ọmọ lara wọn máa ń wà lọ́nà fún àsìkò ọdún. Èyí lè jẹ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ gbé Kristi ga tàbí wọ́n kàn fẹ́ jẹ̀gbádùn pẹ̀lú ìdílé wọn, ó sì lè jẹ́ nítorí ìdí méjèèjì. Ọdún Kérésì àti Ọdún Tuntun tó ń bọ̀ yìí ńkọ́? Ǹjẹ́ ó máa jẹ́ àsìkò tó mìrìngìndìn fún ìdílé rẹ? Ṣé Ọlọ́run lẹ sì máa fi àsìkò yẹn gbé ga? Tí ìdílé rẹ yóò bá kóra jọ láti ṣe fàájì lásìkò náà, ṣé àsìkò náà máa rí bó o ṣe fẹ́ kó rí tàbí kò ní rí bẹ́ẹ̀?
Púpọ̀ nínú àwọn tó jẹ́ pé ìjọsìn tó máa ń wáyé nígbà ọdún Kérésì àti Ọdún Tuntun ni wọ́n ń wọ̀nà fún ti rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi ti Kristi ṣe lásìkò náà. Dípò ìyẹn, ẹ̀bùn làwọn èèyàn máa ń há fún ara wọn, tàbí kí wọ́n fi àsìkò yẹn kẹ́wọ́ láti ṣe àríyá tí wọ́n ti máa hu àwọn ìwà tí kò buyì kún Kristi, tàbí kí àwọn mọ̀lẹ́bí kàn fi àsìkò yẹn pàdé pọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó wà níbi fàájì bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ àjẹkì tàbí kí wọ́n mu ọtí ní àmuyíràá, èyí sì máa ń fa àríyànjiyàn láàárín wọn débi tí wọ́n á fi máa bára wọn jà nínú ilé. Ó ṣeé ṣe kó o ti rí irú nǹkan tá à ń sọ yìí rí tàbí kó tiẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ alára.
Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè wò ó pé nǹkan ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yí padà sí bó ṣe rí nígbà ayé Peter Ńlá ọba Rọ́ṣíà tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú. Ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe ayẹyẹ yìí láyé ìsinsìnyí kò dùn mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn nínú, wọ́n ní ì bá dára kó jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn ń fi àsìkò yìí ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tó bójú mú bí wọ́n ṣe ń gbádùn pẹ̀lú ìdílé wọn. Láwọn ibì kan, àwọn kan tiẹ̀ ń sapá lójú méjèèjì kí ìyípadà lè wà, wọ́n wá ń kéde ọ̀rọ̀ bíi, tìtorí Jésù la ṣe ń ṣọdún. Àmọ́, ṣé ìyípadà lè wà? Ṣé èyí á sì gbé Kristi ga lóòótọ́? Ǹjẹ́ ìdí kan wà tó fi yẹ ká tún ọ̀rọ̀ ọdún Kérésì àti Ọdún Tuntun gbé yẹ̀ wò?
Láti lè rí ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn, ẹ jẹ́ ká gbé èrò táwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kan ní nípa ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, ìyẹn àwọn tó rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí wọ́n máa gbé ayẹyẹ yìí lárugẹ.