Bíbélì Èdè Ítálì Ohun Tójú Àwọn Olùtumọ̀ Rí Kí Wọ́n Tó Ṣe É
Bíbélì Èdè Ítálì Ohun Tójú Àwọn Olùtumọ̀ Rí Kí Wọ́n Tó Ṣe É
“BÍBÉLÌ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jù lórílẹ̀-èdè wa [Ítálì], ṣùgbọ́n àfàìmọ̀ ni ò fi ní wà lára àwọn ìwé tí wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ kà rárá. Kò sí ìṣírí gidi kan fáwọn ọmọ ìjọ láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìrànlọ́wọ́ tààrà kan fún wọn láti máa kà á. Àwọn kan wà tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ wọn kì í rí ẹni tó máa kọ́ wọn.”
Àwọn aṣojú Ẹgbẹ́ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Ilẹ̀ Ítálì ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí lọ́dún 1995. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí lè mú kéèyàn máa ronú nípa àwọn ìbéèrè bíi: Báwo làwọn tó ń ka Bíbélì nílẹ̀ Ítálì ṣe pọ̀ tó láwọn ọ̀rúndún tó kọjá? Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi ní in lọ́wọ́ bíi tàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nígbà náà lọ́hùn-ún? Kí nìdí tó ṣì fi wà lára àwọn ìwé táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ kà rárá nílẹ̀ Ítálì? Tá a bá wo ohun tí ìtàn sọ nípa àwọn Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè Ítálì, a óò rí ìdáhùn.
Ó gba ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún káwọn èdè bí èdè Faransé, èdè Ítálì, èdè Potogí, èdè Spanish, àtàwọn èdè mìíràn tí wọ́n jẹ yọ látinú èdè Látìn tó fìdí múlẹ̀. Díẹ̀díẹ̀ làwọn èdè ìbílẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó para pọ̀ di ilẹ̀ Yúróòpù tó jẹ́ pé inú èdè Látìn ni èdè wọn ti jẹ yọ di ohun táwọn èèyàn ń sọ nílé lóko, tí wọ́n sì di èdè táwọn ọ̀mọ̀wé fi ń ṣèwé pàápàá. Bí èdè ìbílẹ̀ ṣe ń gbèrú yìí mú ìyàtọ̀ dé bá iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì. Lọ́nà wo? Lákòókò kan, ìyàtọ̀ tó wà láàárín èdè Látìn tó jẹ́ èdè tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń lò, àti èdè ìbílẹ̀ táwọn èèyàn ń sọ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀ka èdè àti èdè àdúgbò wọn, pọ̀ débi pé àwọn tí kò bá kàwé ò lè lóye èdè Látìn.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1000, ó ti ṣòro gan-an fún ọ̀pọ̀ lára àwọn olùgbé ilẹ̀ Ítálì láti ka Bíbélì Vulgate tí wọ́n ṣe ní èdè Látìn, ìyẹn bí wọ́n bá tiẹ̀ jàjà rí ẹ̀dà kan gbà. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn olórí ìjọ fi ń nìkan mójú tó ètò ẹ̀kọ́, títí kan ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láwọn yunifásítì kọ̀ọ̀kan tó wà láyé ìgbà yẹn. Kìkì àwọn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n rí jájẹ láwùjọ ló sì láǹfààní láti gba ẹ̀kọ́ yìí. Ìyẹn ni Bíbélì fi wá di “ìwé táwọn èèyàn ò mọ̀.” Síbẹ̀, ó wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́, kí wọ́n sì tún máa kà á lédè wọn.
Àwọn àlùfáà ò tiẹ̀ fẹ́ káwọn èèyàn ṣètumọ̀ Bíbélì rárá torí wọ́n ń bẹ̀rù pé ńṣe ni ìyẹn á jẹ́ káwọn ẹ̀kọ́ tó ta ko ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì máa gbilẹ̀. Òpìtàn Massimo Firpo sọ pé “báwọn èèyàn bá ń lo èdè ìbílẹ̀, [ńṣe nìyẹn máa] fòpin sí gbogbo agbára tí èdè Látìn jẹ́ káwọn àlùfáà nìkan ṣoṣo ní lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.” Nípa bẹ́ẹ̀, àṣà ìbílẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ ni ò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìmọ̀ Bíbélì nílẹ̀ Ítálì títí dòní olónìí.
Àwọn Bíbélì Tí Kì Í Ṣe Odindi Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Ṣe
Nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] ọdún sẹ́yìn ni wọ́n kọ́kọ́ tú àwọn ìwé Bíbélì sí èdè Ítálì látinú èdè Látìn. Ọwọ́ ni wọ́n fi ṣàdàkọ àwọn Bíbélì tí kì í ṣe odindi wọ̀nyí, owó gegere ni wọ́n sì ń tà wọ́n. Nígbà táwọn ìtumọ̀ Bíbélì wá ń pọ̀ sí i ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo Bíbélì lódindi ni wọ́n tú sí èdè Ítálì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tó tú u, àsìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ti tú u. Àwọn olùtumọ̀ tó ṣe wọ́n kì í fi orúkọ wọn sára rẹ̀, àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tó mọ̀wé ló sì ń ra ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyí torí pé àwọn nìkan lagbára wọn ká a. Òpìtàn Gigliola Fragnito jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí wọ́n tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀rọ tẹ̀wé tí owó ìwé sì lọ sílẹ̀ pàápàá, “ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn tó ní [Bíbélì] lọ́wọ́.”
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn Ítálì fi jẹ́ púrúǹtù, tí wọn ò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Àní, lọ́dún 1861 tí gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ kéékèèké tó wà nílẹ̀ Ítálì para pọ̀ di orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo, tá a bá rí èèyàn mẹ́wàá, mẹ́jọ nínú wọn ni kò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, nígbà tí ìjọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso nílẹ̀ Ítálì ń ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tó jẹ́ kàn-ń-pá fáwọn aráàlú, ńṣe ni Póòpù Pius Kẹsàn-án kọ̀wé sí ọba lọ́dún 1870 pé kó má fara mọ́ òfin náà. Ìdí tí póòpù fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ka òfin náà sí “àjàkálẹ̀ àrùn” kan tó máa “run gbogbo ilé ẹ̀kọ́ àwọn Kátólíìkì pátá.”
Odindi Bíbélì Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Ṣe Lédè Ítálì
Ọdún 1471 ni wọ́n tẹ odindi Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe lédè Ítálì, èyí sì jẹ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlógún tí wọ́n kọ́kọ́ fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò tẹ̀wé nílẹ̀ Yúróòpù. Nicolò Malerbi, ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan ní àgbègbè Camaldol lórílẹ̀-èdè Ítálì, fi oṣù mẹ́jọ ṣe ìtumọ̀ Bíbélì tirẹ̀. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó ti wà tẹ́lẹ̀ ló dìídì gbé iṣẹ́ rẹ̀ kà, ó fi Bíbélì Vulgate tó wà lédè Latin ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ, ó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn àdúgbò rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Venetia máa ń lò rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ kan. Bíbélì tó ṣe yìí ni Bíbélì àkọ́kọ́ lédè Ítálì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lọ́wọ́.
Ẹlòmíì tó ṣe ìtumọ̀ Bíbélì nílùú Venice ni Antonio Brucioli. Ọ̀kan lára àwọn tí kò fẹ́ kí àṣà ilẹ̀ Gíríìkì àti Róòmù ayé àtijọ́ pa run ni. Ó fẹ́ràn ẹ̀kọ́ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sílẹ̀. Lọ́dún 1532, Brucioli tú Bíbélì sí èdè Ítálì látinú èdè Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Èyí ni Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n tú látinú àwọn ìwé Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Brucioli ò túmọ̀ Bíbélì yìí bíi tàwọn ọ̀mọ̀wé, síbẹ̀ bí a bá fojú báwọn èèyàn ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ láyé ìgbà yẹn wò ó, ìtumọ̀ Bíbélì náà dára gan-an torí pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sún mọ́ ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Láwọn ibì kan nínú Bíbélì náà àti nínú àwọn kan lára ẹ̀dà Bíbélì yìí tó ṣe, ó dá orúkọ Ọlọ́run padà síbi tó yẹ kó wà; ó lo “Ieova,” ìyẹn orúkọ Ọlọ́run lédè Ítálì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ọdún táwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ilẹ̀ Ítálì àtàwọn tí kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn fi ń gbé Bíbélì rẹ̀ gẹ̀gẹ̀.
Àwọn olùtumọ̀ ṣe àwọn Bíbélì mìíràn, àmọ́ ká ṣáà sọ pé àtúntẹ̀ Bíbélì Brucioli ni wọ́n, àwọn Kátólíìkì sì tẹ̀ lára àwọn Bíbélì wọ̀nyí. Àmọ́ àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ní wọn lọ́wọ́. Lọ́dún 1607, Giovanni Diodati tó jẹ́ pásítọ̀ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Calvin ṣe ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn sí èdè Ítálì látinú àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ nílùú Geneva lórílẹ̀-èdè Switzerland, níbi táwọn òbí rẹ̀ sá lọ kí wọ́n má bàa ṣenúnibíni sí wọn nítorí ẹ̀sìn wọn. Ìtumọ̀ Bíbélì tí Diodati ṣe yìí ló wá di Bíbélì táwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ilẹ̀ Ítálì ń lò fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Lásìkò tí wọ́n ṣe é, àwọn èèyàn gbà pé gbogbo ọ̀nà ni Bíbélì ọ̀hún fi dára gan-an. Bíbélì tí Diodati ṣe ran àwọn ará Ítálì lọ́wọ́ láti mọ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Àmọ́ lámèyítọ́ táwọn àlùfáà ń ṣe kò jẹ́ kí Bíbélì Diodati àtàwọn Bíbélì mìíràn dé ọwọ́ àwọn èèyàn bó ṣe yẹ.
Bíbélì—“Ìwé Táwọn Èèyàn Ò Mọ̀”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Enciclopedia Cattolica sọ pé: “Ó ti pẹ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì ti ń rí sí i pé ìwé tí wọn ò bá fara mọ́ kò ní tẹ àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àmọ́ kó tó di pé ìwé títẹ̀ mú kí ìwé pọ̀ rẹpẹtẹ nílé lóko, àwọn olórí ìjọ wò ó pé kò pọn dandan láti to gbogbo ìwé tí wọ́n fòfin dè lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé kan pàtó, nítorí pé báwọn ìwé tí wọ́n gbà pé kò dára ṣe ń jáde ni wọ́n ń dáná sun wọ́n.” Kódà lẹ́yìn táwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí ta ko àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì pàápàá,
àwọn àlùfáà àwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù sapá lójú méjèèjì láti rí i pé àwọn ìwé tí wọ́n kà sí ìwé àwọn tó ta ko ẹ̀kọ́ Kátólíìkì kò fi bẹ́ẹ̀ dọ́wọ́ àwọn èèyàn. Àmọ́ nǹkan yí padà bìrí lẹ́yìn àpérò táwọn olórí ìjọ ṣe nílùú Trent lọ́dún 1546, nígbà tí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ títú Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀ yẹ̀ wò. Èrò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tó wà nípàdé yẹn ní. Àwọn tí kò fẹ́ kí wọ́n tú Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀ sọ pé títú tí wọ́n ń tú Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀ ló jẹ́ káwọn èèyàn máa ta ko àwọn ẹ̀kọ́ ìjọ Kátólíìkì. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n tú u sọ pé àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n jẹ́ alátakò yóò máa sọ pé torí káwọn èèyàn má bàa mọ gbogbo “jìbìtì àti ẹ̀tàn” inú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ni wọ́n ṣe ṣòfin pé kí wọ́n má ṣe tú Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀.Bí àwọn tó ṣèpàdé yìí kò ṣe fohùn ṣọ̀kan túmọ̀ sí pé wọn ò dórí ìpinnu kan tó ṣe gbòógì lórí ọ̀rọ̀ náà, àyàfi pé wọ́n fàṣẹ sí i pé Bíbélì Vulgate tó wá di Bíbélì tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń lò ni ìtumọ̀ Bíbélì tó péye. Àmọ́ ṣá o, Carlo Buzzetti, olùkọ́ kan ní yunifásítì Pontifical University Salesianum tó wà nílùú Róòmù sọ pé, pípè tí wọ́n ń pe Bíbélì Vulgate ní “ojúlówó” “fi hàn pé kò sí àní-àní pé òun ló máa jẹ́ Bíbélì kan ṣoṣo tí [Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì] fi àṣẹ tì lẹ́yìn.” Àwọn ohun tó tún ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí fi hàn pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn.
Lọ́dún 1559, Póòpù Paul Kẹrin tẹ ìwé kan tí wọ́n to àwọn ìwé tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fòfin dè sí lẹ́sẹẹsẹ, ìwé yìí sì ni àkọ́kọ́ lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lò láti fi gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé kan tí wọ́n ní ọmọ ìjọ kankan ò gbọ́dọ̀ kà, tàbí kó rà á, kó tú u tàbí kó ní in lọ́wọ́. Wọ́n ní ìwé burúkú tó lè ṣàkóbá fún ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin àwọn ọmọ ìjọ nirú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ jẹ́. Ìwé náà fòfin de kíka gbogbo àwọn Bíbélì tó wà ní èdè ìbílẹ̀, kódà kò yọ Bíbélì Brucioli sílẹ̀. Ńṣe ni wọ́n máa ń lé àwọn tó bá tàpá sí òfin yìí kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì. Irú ìwé yìí tí wọ́n ṣe lọ́dún 1596 ló tiẹ̀ wá le jù. Ìwé náà sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì ò ní máa fún àwọn èèyàn láṣẹ mọ́ láti tú Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀ tàbí láti tẹ̀ ẹ́ jáde. Wọ́n ní àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ run gbogbo irú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì bẹ́ẹ̀.
Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé nígbà tó fi máa di ìparí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, dídáná sun Bíbélì lójúde ṣọ́ọ̀ṣì wọ́pọ̀ gan-an. Èrò tí èyí gbìn sọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ìwé àwọn tó ti yapa ní Ìwé Mímọ́, èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ilẹ̀ Ítálì sì ní nípa Bíbélì nìyẹn títí dòní olónìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tó wà láwọn ibi ìkówèésí ìlú àti ibi ìkówèésí àdáni ni wọ́n run, kò sì sí ọmọ ìjọ Kátólíìkì kankan tó lè tú Bíbélì sí èdè Ítálì fún igba ọdún lẹ́yìn àkókò yẹn. Àwọn Bíbélì táwọn ọ̀mọ̀wé inú àwọn ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tú nìkan làwọn èèyàn ní lọ́wọ́ nílẹ̀ Ítálì, bòókẹ́lẹ́ sì ni wọ́n ń rà á nítorí pé wọ́n lè gbà á lọ́wọ́ wọn. Abájọ tí òpìtàn Mario Cignoni fi sọ pé: “Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn ọmọ ìjọ ò fi ka Bíbélì rárá. Bíbélì wá di ìwé
táwọn èèyàn ò mọ̀ rárá, ẹgbàágbèje èèyàn nílẹ̀ Ítálì ni ò sì ka Bíbélì rí láyé wọn.”Wọ́n Rọ Òfin Tó De Ṣíṣètumọ̀ Bíbélì Lójú
Nígbà tó yá, Póòpù Benedict Kẹrìnlá ṣe àtúnṣe sí òfin ìṣáájú nínú òfin kan tó gbé jáde ní June 13, 1757 lórí ìwé tí wọ́n fi ń ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè. Òfin tuntun náà “fàyè gba àwọn èèyàn láti máa ka àwọn Bíbélì tó wà lédè ìbílẹ̀, èyí tí ìgbìmọ̀ tó ń mójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì kárí ayé ti fàṣẹ sí, táwọn bíṣọ́ọ̀bù sì ti mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́.” Èyí ló mú kí Antonio Martini tó wá di bíṣọ́ọ̀bù àgbà nílùú Florence bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò láti tú Bíbélì Vulgate. Ọdún 1769 ló tẹ apá àkọ́kọ́ jáde, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ náà lọ́dún 1781. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ṣe ti sọ, Bíbélì Martini “ni Bíbélì èdè Ítálì àkọ́kọ́ tá a lè pè ní ìtumọ̀ tó jẹ́ ògidì.” Kó tó di pé wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde, àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tí kò bá lóye èdè Látìn kì í lè ka Bíbélì tí ṣọ́ọ̀ṣì bá fàṣẹ sí. Ìtumọ̀ Bíbélì tí Martini ṣe ni Bíbélì kan ṣoṣo tí wọ́n gba àwọn Kátólíìkì ilẹ̀ Ítálì láyè láti lò ní gbogbo àádọ́jọ ọdún lẹ́yìn àkókò yẹn.
Àyípadà dé bá gbogbo èyí níbi àpérò àjọ kejì táwọn olórí ìjọ Kátólíìkì ṣe nílùú Vatican. Lọ́dún 1965, ìwé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Dei Verbum (Ìṣípayá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run) gba àwọn èèyàn níyànjú fún ìgbà àkọ́kọ́ pé kí wọ́n máa túmọ̀ “Bíbélì lọ́nà tó péye tó sì dára . . . sí onírúurú èdè, pàápàá káwọn olùtumọ̀ rí i pé àwọn ń ṣètumọ̀ látinú àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì.” Ṣáájú àkókò yẹn, ìyẹn lọ́dún 1958, Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tí Póòpù Dá Sílẹ̀ (Pontificio istituto biblico) ṣe “ìtumọ̀ Bíbélì ìjọ Kátólíìkì àkọ́kọ́ tó jẹ́ odindi, èyí tí wọ́n tú látinú àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Bíbélì yìí dá orúkọ Ọlọ́run padà síbi tó yẹ kó wà láwọn ibì kọ̀ọ̀kan nípa lílo orúkọ náà “Jahve.”
Ọṣẹ́ kékeré kọ́ ni àtakò tí wọ́n gbé dìde sí títú Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀ ṣe, àwọn ohun tí èyí yọrí sí ṣì ń jà rànyìn títí dòní olónìí. Gigliola Fragnito sọ pé, “[àtakò yìí ló fà á] táwọn onígbàgbọ́ ò fi lè dá ronú fúnra wọn tí wọn ò sì lè gbára lé ẹ̀rí ọkàn wọn.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn olórí ẹ̀sìn Kátólíìkì sọ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ di kàn-ń-pá nínú ẹ̀sìn wọn, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì ló sì máa ń ka èyí sí pàtàkì ju Bíbélì lọ. Ńṣe ni gbogbo èyí sọ Ìwé Mímọ́ dàjèjì sáwọn èèyàn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn aráàlú ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tán.
Àmọ́ o, iṣẹ́ ìjíhìnrere táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ti jẹ́ kí ìfẹ́ táwọn èèyàn ní sí Bíbélì èdè Ítálì bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i. Lọ́dún 1963, àwọn Ẹlẹ́rìí tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Ítálì. Nígbà tó di ọdún 1967, wọ́n ṣe odindi Bíbélì yìí. Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin ẹ̀dà Bíbélì yìí táwọn èèyàn ilẹ̀ Ítálì nìkan ti gbà. Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Titun dá Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, padà síbi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì, ó sì dára gan-an torí pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bá ohun tó wà nínú àwọn ìwé Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu gan-an.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ láti ilé dé ilé láti ka ọ̀rọ̀ ìrètí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ fáwọn tó bá fẹ́ gbọ́ àti láti ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. (Ìṣe 20:20) Bó o bá tún bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, o ò ṣe sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣàlàyé fún ọ látinú Bíbélì rẹ nípa ìlérí amọ́kànyọ̀ tí Ọlọ́run ṣe pé láìpẹ́ òun yóò ṣe “ayé tuntun” kan níbi tí ‘òdodo yóò máa gbé’?—2 Pétérù 3:13.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Venice
RÓÒMÙ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Nínú Bíbélì tí Brucioli ṣe, ó lo “Ieova,” ìyẹn orúkọ Ọlọ́run lédè Ítálì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìwé tí wọ́n fi ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè ka àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè Ítálì mọ́ ara àwọn ìwé tí kò dára
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]
Ojú ìwé tí orúkọ Bíbélì wà: Biblioteca Nazionale Centrale di Roma
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Bíbélì Brucioli: Biblioteca Nazionale Centrale di Roma; Ìwé Index: Su concessione del Ministero per i Beni e le Attività Culturali