Igi Ọdún Tuntun Ṣé Àṣà Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ni Àbí Tàwọn Kristẹni?
Igi Ọdún Tuntun Ṣé Àṣà Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ni Àbí Tàwọn Kristẹni?
“NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ àwọn ọdún 1830, àwọn èèyàn ṣì gbà pé àwọn ará Jámánì ló máa ń fi irú igi kan tó máa ń léwé tó tutù yọ̀yọ̀ ṣe ilé wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Nígbà tó fi máa di ọdún 1840, ó ti ‘di àṣà’ àwọn èèyàn pàtàkì nílùú St. Petersburg [nílẹ̀ Rọ́ṣíà] láti máa gbé igi yìí sílé. . . . Àwọn àlùfáà àtàwọn tálákà nìkan ni kò bá wọn dá àṣà ká máa gbé igi náà sínú ilé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún. . . .
“Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn . . . kò fi bẹ́ẹ̀ ka igi yìí kún rárá. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ará Rọ́ṣíà ti gbà pé téèyàn bá ti rí igi yìí, ó túmọ̀ sí pé ẹnì kan ti kú nìyẹn àti pé ó máa ń jẹ́ kéèyàn ronú nípa ibi táwọn òkú wà. Wọ́n tún máa ń fojú burúkú wo igi yìí torí pé wọ́n máa ń gbé e sórí ilé ọtí. Ṣùgbọ́n irú ojú tí wọ́n fi ń wo igi yìí yàtọ̀ pátápátá sí ojú táwọn èèyàn fi wá ń wò ó láàárín ọ̀rúndún kọkàndínlógún. . . . Ó ṣe kedere pé títẹ̀lé àṣà fífi igi yìí ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́ tó jẹ́ àṣà ilẹ̀ òkèèrè ti wá nítumọ̀ kan náà bíi ti igi Kérésì táwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń lò, ìyẹn ni pé ọ̀rọ̀ Kérésìmesì ló jẹ mọ́. . . .
“Àmọ́ o, kò rọrùn rárá láti gbé àṣà lílo igi yìí wọnú ẹ̀sìn Kristẹni nílẹ̀ Rọ́ṣíà. Ńṣe ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì gbógun ti àṣà yìí. Àwọn àlùfáà sọ pé wọ́n ti mú ‘ọ̀rọ̀ ẹ̀mí èṣù’ wọnú ayẹyẹ yìí, wọ́n ní ó ti di àṣà abọ̀rìṣà, èyí tó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìbí Olùgbàlà. Kódà, wọ́n ní àṣà Ìwọ Oòrùn ayé ni.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Yelena V. Dushechkina tó jẹ́ onímọ̀ èdè ní Yunifásítì St. Petersburg ló sọ̀rọ̀ yìí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Fọ́tò: Nikolai Rakhmanov