Kí Ló Máa Ń Jẹ Àwọn Èèyàn Lógún Nígbà Ọdún Kérésì?
Kí Ló Máa Ń Jẹ Àwọn Èèyàn Lógún Nígbà Ọdún Kérésì?
Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn gbà pé ìgbà ọdún jẹ́ àsìkò tó yẹ káwọn máa fi ṣe fàájì pẹ̀lú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn, àsìkò tí wọ́n á fi mú kí okùn ìfẹ́ tó wà láàárín wọn lágbára sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn gbà pé ó jẹ́ àsìkò tó yẹ káwọn fi máa ronú lórí ìbí Jésù Kristi àti lórí ohun tí Jésù ṣe láti gba aráyé là. Ọ̀pọ̀ ibi làwọn èèyàn ti lómìnira láti máa ṣọdún Kérésì lọ́dọọdún àmọ́ ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà ò rí bẹ́ẹ̀ torí pé àwọn ìgbà kan wà tí wọn ò fún wọn lómìnira láti ṣe é. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn tó ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti ń ṣọdún Kérésì láìsí pé wọ́n ń yọ́ ọ ṣe, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún ni wọn ò fi fàyè gbà wọ́n láti ṣe é. Kí ló fa àyípadà yìí?
Kété lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ òṣèlú Bolshevik tó jẹ́ Kọ́múníìsì gbàjọba ilẹ̀ Soviet lọ́dún 1917, wọ́n gbé ìlànà lílekoko kan kalẹ̀ tó fi hàn pé wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni gba Ọlọ́run gbọ́ lórílẹ̀-èdè wọn. Bí ọdún Kérésì àti ààtò ìsìn tí wọ́n máa ń ṣe lásìkò ọdún ṣe di ohun tí wọ́n lòdì sí nìyẹn. Ìjọba wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kó ṣòro fáwọn èèyàn láti ṣọdún Kérésìmesì àti Ọdún Tuntun. Wọ́n tiẹ̀ sọ ọ́ gbangba pé ó lòdì láti máa lo àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń lò lásìkò ọdún, irú bí igi Kérésìmesì àti Ded Moroz, ìyẹn Baba Kérésì àwọn ará Rọ́ṣíà.
Àyípadà kan wáyé lọ́dún 1935 tó yí gbogbo bí àwọn ará Rọ́ṣíà ṣe ń ṣayẹyẹ ọdún Kérésì àti Ọdún Tuntun padà. Àwọn ará ilẹ̀ Soviet tún bẹ̀rẹ̀ sí lo Baba Kérésì àti igi Kérésì, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun. Àmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló yí padà nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe é. Wọ́n ní Baba Kérésì kò ní máa fún àwọn èèyàn lẹ́bùn nígbà ọdún Kérésì mọ́, pé Ọjọ́ Ọdún Tuntun ni yóò jẹ́. Bákan náà, wọ́n ní kò ní sí igi Kérésì mọ́, pé igi Ọdún Tuntun ni wọn yóò máa lò! Báyìí ni ìyípadà tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ ṣe dé bá ohun táwọn ará ilẹ̀ Soviet Union máa ń ṣe nígbà ọdún. Bí ayẹyẹ Ọdún Tuntun sì ṣe rọ́pò ọdún Kérésì nìyẹn.
Ọdún Kérésì wá di ayẹyẹ tí kò ní ọ̀rọ̀ ìsìn nínú mọ́ rárá. Dípò tí wọ́n á fi lo àwọn nǹkan ẹlẹ́wà tó jẹ́ ti ìsìn láti fi ṣe igi Ọdún Tuntun lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn nǹkan míì tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí ìtẹ̀síwájú ṣe ń dé bá ilẹ̀ Soviet Union ni wọ́n ń lò. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó ń jẹ́ Vokrug Sveta (Kárí Ayé) sọ pé: “Téèyàn bá wo ohun tí wọ́n fi ń ṣe igi Ọdún Tuntun lọ́ṣọ̀ọ́ ní ọdún kọ̀ọ̀kan, èèyàn lè fìyẹn mọ ìtàn bí ìjọba Kọ́múníìsì ṣe fìdí múlẹ̀ nílẹ̀ Soviet. Yàtọ̀ sáwọn nǹkan tó wọ́pọ̀ bí ehoro àtọwọ́dá, àwọn bébà dídán yanranyanran, àti búrẹ́dì tó rí bìrìkìtì, àwọn ilé iṣẹ́ kan tún máa ń ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí akọ́rọ́, òòlù àti katakata. Nígbà tó yá, wọ́n wá fi ère àwọn awakùsà, ère àwọn tó ń lọ sójú sánmà, ohun èlò tí wọ́n fi ń wa epo rọ̀bì, rọ́kẹ́ẹ̀tì, àti ọkọ̀ tí wọ́n fi ń rìn nínú òṣùpá rọ́pò àwọn nǹkan wọ̀nyẹn.”
Ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe ọdún Kérésì ńkọ́? Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Soviet ò kà á sí ọjọ́ ọdún mọ́, ńṣe ni wọ́n kàn sọ ọ́ dọjọ́ iṣẹ́ lásán. Ó wá di pé káwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ọdún Kérésì máa yọ́ ọ ṣe, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ìjọba á fojú wọn han èèmọ̀ tọ́wọ́ bá tẹ̀ wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni o, ní ọ̀rúndún ogún, ńṣe làwọn ará Rọ́ṣíà sọ ọdún Kérésì di ayẹyẹ tí kò ní ọ̀rọ̀ ìsìn nínú mọ́.
Àyípadà Ẹnu Àìpẹ́ Yìí
Nígbà tó di ọdún 1991, ilẹ̀ Soviet Union pín sórílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí wá mú káwọn èèyàn túbọ̀ lómìnira. Bí ìlànà tí ìjọba gbé kalẹ̀ tó fi hàn pé wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni gba Ọlọ́run
gbọ́ ṣe kásẹ̀ nílẹ̀ nìyẹn. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbòmìnira kò da ìsìn pọ̀ mọ́ ìṣèlú rárá. Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ràn ẹ̀sìn wá rí i pé ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fáwọn láti ṣe ẹ̀sìn àwọn fàlàlà. Wọ́n wò ó pé ọ̀nà kan táwọn lè gbà ṣe ìyẹn ni pé káwọn máa ṣe ọdún Kérésì. Àmọ́, kò pẹ́ tí ìjákulẹ̀ ńlá fi bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Kí ló fa ìjákulẹ̀ yìí?Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ẹ̀mí káràkátà túbọ̀ ń gba àwọn èèyàn lọ́kàn lásìkò ọdún. Bẹ́ẹ̀ ni o, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ayé, ìgbà ọdún Kérésì ni àsìkò táwọn ilé iṣẹ́ ńlá, àwọn oníṣòwò aládàá ńlá àtàwọn ọlọ́jà ń fojú sí láti pa owó gidi. Àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ táwọn èèyàn ń lò nígbà Kérésì wá di ohun tí wọ́n ń ṣàfihàn rẹ̀ níwájú ṣọ́ọ̀bù káàkiri. Àwọn orin Kérésì tí wọ́n máa ń kọ ní ìwọ̀ oòrùn ayé, èyí tí kò sí nílẹ̀ Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀ wá dohun tí wọ́n ń gbé sáfẹ́fẹ́ láwọn ṣọ́ọ̀bù. Àwọn tó ń ta àwọn nǹkan àfiṣeré nígbà Kérésì máa ń kó wọn sínú àpò ńlá, wọ́n á wá máa polówó wọn nínú ọkọ̀ ojú irin àtàwọn ọkọ̀ èrò mìíràn. Ìwọ̀nyí làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí nílẹ̀ Rọ́ṣíà lásìkò ọdún.
Ohun àìdáa mìíràn tó ń wáyé lásìkò ọdún lè máa mú kí ominú kọ àwọn kan tí kò rí ohun tó burú pẹ̀lú báwọn ọlọ́jà ṣe ń ta ọ̀wọ́n gógó ọjà lásìkò ọdún. Ohun náà ni ìmukúmu ọtí àtohun tó máa ń tìdí rẹ̀ yọ. Dókítà kan tó máa ń bójú tó ọ̀ràn pàjáwìrì ní ọsibítù kan nílùú Moscow sọ pé: “Ó ti dájú pé lọ́jọ́ Ọdún Tuntun, onírúurú àwọn èèyàn làwọn dókítà máa tọ́jú, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tí ibì kan wú lára wọn àtàwọn tó ní ọgbẹ́ kékeré títí dórí àwọn tí wọ́n gún lọ́bẹ tàbí tí wọ́n yìnbọn lù. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí ló sì jẹ́ pé ìjà inú ilé ló fà á, nígbà tó jẹ́ pé ọtí àmujù tàbí jàǹbá ọkọ̀ ló fa tàwọn míì.” Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó jẹ́ ọ̀gá ní Ẹ̀ka Ilé Ìwé Sáyẹ́ǹsì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ pé: “Ńṣe ni iye àwọn tó ń kú nítorí ọtí àmujù ń pọ̀ sí i. Tí ọdún 2000 tiẹ̀ wá pàpọ̀jù. Iye àwọn tó para wọn àtàwọn tó pààyàn náà pọ̀ sí i pẹ̀lú.”
Ó dunni pé ohun mìíràn tún wà tó ń mú káwọn èèyàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà máa ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí lọ́nà tó lékenkà lásìkò ọdún. Ìwé ìròyìn Izvestiya gbé àkòrí kan jáde, ìyẹn “Àwọn Ará Rọ́ṣíà Ń Ṣọdún Kérésì Lẹ́ẹ̀mejì.” Lábẹ́ àkòrí náà, ó ròyìn pé: “Nílẹ̀ Rọ́ṣíà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀kan nínú èèyàn mẹ́wàá ló ń ṣọdún Kérésì lẹ́ẹ̀mejì. Ìwádìí tí àjọ kan tó ń ṣèwádìí nílẹ̀ Rọ́ṣíà (Russian Public Opinion and Market Research) ṣe fi hàn pé, ìdá mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu wọn sọ pé àwọn máa ń ṣe ọdún Kérésì ní December 25, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú kàlẹ́ńdà àwọn Kátólíìkì, àwọn á sì tún ṣe é ní January 7 bó ṣe wà nínú kàlẹ́ńdà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì . . . àwọn kan wà lára wọn tó jẹ́ pé kì í ṣe ààtò ìsìn ìgbà ọdún yẹn ló jẹ wọ́n lógún bí kò ṣe pé kí wọ́n ṣáà ti ṣọdún.” a
Ǹjẹ́ Ayẹyẹ Ọdún Ìsinsìnyí Ń Gbé Kristi Ga?
Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìwà tínú Ọlọ́run ò dùn sí làwọn èèyàn máa ń hù lásìkò ọdún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ò bójú mu, síbẹ̀ àwọn kan lè ronú pé ó yẹ káwọn máa ṣọdún Kérésì nítorí ọ̀wọ̀ táwọn ní fún Ọlọ́run àti Kristi. Ohun tó dára ni láti ṣe nǹkan tó máa múnú Ọlọ́run dùn. Àmọ́, ṣé inú Ọlọ́run àti Kristi dùn sí ọdún Kérésìmesì? Ẹ wo ibi tí ayẹyẹ náà ti ṣẹ̀ wá.
Bí àpẹẹrẹ, èrò yòówù téèyàn ì báà ní nípa ojú tàwọn ará ilẹ̀ Soviet fi wo ọdún Kérésìmesì, ṣàṣà lẹni tí kò ní gbà pé òótọ́ lohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Great Soviet Encyclopedia sọ, pé: “Látinú ìjọsìn àwọn òrìṣà ‘tó ń kú tó ń jíǹde’ táwọn kan ń bọ ṣáájú ayé ìgbà Kristẹni ni . . . ayẹyẹ ọdún Kérésì ti ṣẹ̀ wá. Àwọn tó sì sábà máa ń ṣe ìjọsìn yìí láyé ìgbà yẹn làwọn àgbẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ‘ìbí’ Ọlọ́run Olùgbàlà, tó lágbára láti mú nǹkan sọjí. Ìgbà yíyọ oòrùn lásìkò òtútù ni wọ́n sì sábà máa ń ṣe é bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kọkànlélógún sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù December.”
O lè rí i pé ọ̀rọ̀ pàtàkì ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yẹn sọ pé: “Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ò mọ ohun tó ń jẹ́ Kérésìmesì. . . . láti ìdajì ọ̀rúndún kẹrin làwọn Kristẹni ti gba àṣà ṣíṣe ọdún yíyọ oòrùn tó máa ń wáyé nígbà òtútù èyí tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn òrìṣà tó ń jẹ́ Mithra, wọ́n wá sọ ọ́ di ọdún Kérésì. Àwọn ẹlẹ́sìn ilẹ̀ Róòmù ló bẹ̀rẹ̀ ọdún Kérésì. Ní ọ̀rúndún kẹwàá, ọdún Kérésì àti ẹ̀sìn Kristẹni gbilẹ̀ dé ilẹ̀ Rọ́ṣíà, níbi tí wọ́n ti wá da ayẹyẹ náà pọ̀ mọ́ ayẹyẹ ọdún ìgbà òtútù táwọn ọmọ Slav máa ń ṣe láyé àtijọ́ láti fi yẹ́ àwọn baba ńlá wọn tó ti kú sí.”
O lè béèrè pé: ‘Kí ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ lórí ọ̀rọ̀ bóyá December 25 ni wọ́n bí Jésù àbí ọjọ́ yẹn kọ́?’ Lóòótọ́, Bíbélì ò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù ní pàtó, kò sì sí àkọsílẹ̀ kankan pé Jésù alárà sọ ọjọ́ tí wọ́n bí òun ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé ká máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ àwọn ohun kan tó jẹ́ ká mọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù nínú ọdún.
Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìhìn Rere Mátíù orí kẹrìndínlọ́gbọ̀n àti ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n fi hàn pé ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn ni wọ́n pa Jésù, ní alẹ́ ọjọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Júù èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní March 31, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ìhìn rere Lúùkù jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tó ṣèrìbọmi tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Lúùkù 3:21-23) Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ló fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yìí. Nítorí náà, nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àtààbọ̀ ni Jésù nígbà tó kú. Ì bá pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ní nǹkan bí October 1, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Lúùkù ròyìn pé lákòókò tí wọ́n bí Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn “ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.” (Lúùkù 2:8) Ó dájú pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn ò ní jẹ́ kó ẹran wọn lọ síta nínú òtútù ìgbà December, tó jẹ́ pé ńṣe ni yìnyín yóò tiẹ̀ máa já bọ́ lágbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àmọ́, ó ṣeé ṣe káwọn olùṣọ́ àgùntàn kó ẹran wọn lọ síta ní nǹkan bí ọjọ́ kìíní oṣù October, ìyẹn àkókò tí ẹ̀rí fi hàn dájú pé wọ́n bí Jésù.
Ọdún Tuntun wá ńkọ́ o? Gẹ́gẹ́ bí ohun tá à
ń sọ bọ̀ ṣe fi hàn, onírúurú ìwàkiwà làwọn èèyàn máa ń hù lásìkò yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbìyànjú láti yọ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kúrò nínú ayẹyẹ Ọdún Tuntun, ibi tí òun náà ti ṣẹ̀ wà kò bá òfin Ọlọ́run mu.Tá a bá fojú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò ọdún wò ọ̀rọ̀ náà, ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ láwọn ibì kan pé tìtorí Jésù la ṣe ń ṣọdún kò já mọ́ nǹkan kan. Bí inú rẹ kò bá dùn sí bí àwọn èèyàn ṣe ń wá owó lójú méjèèjì lásìkò ọdún Kérésì, tí ìwàkiwà sì tún gbòde, àti bó ṣe jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ni ọdún náà ti ṣẹ̀ wá, má ṣe bọkàn
jẹ́. Ọ̀nà dídára kan wà tó o lè gbà fi ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run, kó o gbé Kristi ga, kó o sì tún mú kí okùn ìfẹ́ tó wà láàárín ìdílé rẹ̀ túbọ̀ lágbára.Ọ̀nà Tó Dára Jù Lọ Láti Gbà Gbé Ọlọ́run àti Kristi Ga
Bíbélì sọ fún wa pé Jésù Kristi wá sáyé “kí ó [lè] fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Jésù gbà kí wọ́n pa òun, ó fi tinútinú kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Àwọn kan lè fẹ́ yẹ́ Kristi sí, bóyá kí wọ́n máa rò ó pé àsìkò ọdún Kérésì làwọn lè ṣe èyí. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò ṣe fi hàn, ọdún Kérésìmesì àti Ọdún Tuntun kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Kristi, ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà làwọn ayẹyẹ náà sì ti bẹ̀rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, bó ti wù kí àwọn kan fẹ́ràn ọdún Kérésìmesì tó, káràkátà ló máa ń gba àwọn èèyàn lọ́kàn lásìkò yẹn. Àti pé àwọn ìwà tó ń tini lójú tínú Ọlọ́run àti Kristi ò dùn sí làwọn èèyàn máa ń hù lásìkò ọdún Kérésì.
Kí ló wá yẹ kí ẹni tó bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí? Dípò tí yóò fi rọ̀ mọ́ àwọn àṣà tó wu àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn àmọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ńṣe ló yẹ kí ẹni tó bá jẹ́ olóòótọ́ ọkàn wá ọ̀nà tó tọ́ láti gbà gbé Ọlọ́run àti Kristi ga. Kí ni ọ̀nà tó tọ́ náà, kí ló sì yẹ ká ṣe?
Kristi fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bẹ́ẹ̀ ni o, ńṣe lẹni tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn gidi máa wá bóun ṣe máa ní ìmọ̀ pípéye nípa bó ṣe lè gbé Ọlọ́run àti Kristi ga. Yóò sì máa fi àwọn ohun tó kọ́ yìí sílò lójoojúmọ́ ayé rẹ̀, kì í kàn án ṣe ní àsìkò kan lọ́dún. Inú Ọlọ́run máa ń dùn sí irú akitiyan téèyàn bá fòótọ́ inú ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì lè yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun fónítọ̀hún.
Ǹjẹ́ wàá fẹ́ kí ìdílé rẹ̀ wà lára àwọn tó ń gbé Ọlọ́run àti Kristi ga níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye ìdílé lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì. A fẹ́ kí o kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí èyíkéyìí lára àdírẹ́sì tó wà lójú ewé kejì ìwé ìròyìn yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ṣáájú kí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú Bolshevik tó gbàjọba ní October 1917, kàlẹ́ńdà Júlíọ́sì tó ti wà tipẹ́ làwọn ará Rọ́ṣíà máa ń lò, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè ló ti yí sí kàlẹ́ńdà Gregory. Lọ́dún 1917, ọjọ́ mẹ́tàlá ni kàlẹ́ńdà Gregory fi yá ju kàlẹ́ńdà Júlíọ́sì lọ. Láti ìgbà ìjọba ẹgbẹ́ Bolshevik ni ilẹ̀ Soviet ti bẹ̀rẹ̀ sí lo kàlẹ́ńdà Gregory. Bí Rọ́ṣíà ṣe wá ń lo kàlẹ́ńdà kan náà pẹ̀lú gbogbo ayé nìyẹn. Àmọ́ ṣá o, Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ṣì ń lo kàlẹ́ńdà Júlíọ́sì fún àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún, wọ́n pè é ní kàlẹ́ńdà “Ayé Àtijọ́.” Ẹ lè máa gbọ́ pé àwọn ará Rọ́ṣíà ń ṣọdún Kérésì ní January 7. Ṣùgbọ́n, ẹ fi sọ́kàn pé January 7 nínú kàlẹ́ńdà Gregory jẹ́ ìkan náà pẹ̀lú December 25 nínú kàlẹ́ńdà Júlíọ́sì. Abájọ tí púpọ̀ lára àwọn ará Rọ́ṣíà fi to ayẹyẹ ọdún wọn báyìí: December 25, ọdún Kérésì tàwọn ará ìwọ̀ oòrùn ayé; January 1, Ọdún Tuntun tí kò ní ètò ẹ̀sìn nínú; January 7, ọdún Kérésì ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì; January 14, Ọdún Tuntun ti kàlẹ́ńdà Ayé Àtijọ́.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ibi Tí Ayẹyẹ Ọdún Tuntun Ti Ṣẹ̀ Wá
Ẹ Gbọ́ Ohun Tí Ọmọ Ilẹ̀ Georgia Kan Tó Jẹ́ Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé Nínú Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Sọ
“Ilẹ̀ Róòmù ìgbàanì ni ayẹyẹ Ọdún Tuntun àtàwọn ọdún òrìṣà mìíràn bẹ́ẹ̀ ti ṣẹ̀ wá. Wọ́n dìídì ya ọjọ́ kìíní oṣù January sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń jẹ́ Janus, látinú orúkọ òrìṣà yìí sì ni wọ́n ti mú orúkọ oṣù January. Ère òrìṣà Janus ní ojú méjì, ọ̀kan kọjú síwájú, èkejì kọjú sẹ́yìn, tó túmọ̀ sí pé ó ń wo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn àtèyí tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí. Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé ńṣe lẹni tó bá fi fàájì, ẹ̀rín àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ àtohun mímú wọ Ọdún Tuntun yóò ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn jálẹ̀ ọdún yẹn. Ìgbàgbọ́ táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wa ní nìyí tí wọ́n fi ń ṣe ayẹyẹ Ọdún Tuntun . . . àwọn èèyàn máa ń gbé ẹbọ wá fún òrìṣà nígbà tí wọ́n bá ń ṣayẹyẹ ọdún òrìṣà kan. Ìṣekúṣe, panṣágà àti àgbèrè máa ń gbilẹ̀ nírú àsìkò yẹn. Láwọn ìgbà míì, irú bí àkókò ọdún Janus, àwọn èèyàn máa ń jẹ àjẹkì, wọ́n máa ń mutí ní àmuyíràá, wọ́n sì tún máa ń hu oríṣiríṣi ìwà àìmọ́ mìíràn bẹ́ẹ̀. Tá a bá rántí bí àwa fúnra wa ṣe ń ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, gbogbo wa la máa gbà pé a ti ṣe ọdún àwọn abọ̀rìṣà yìí rí.”—Látinú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Georgia kan.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mú ìjọsìn òrìṣà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mithra wọnú ẹ̀sìn wọn
[Credit Line]
Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí nílùú Wiesbaden
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn olùṣọ́ àgùntàn kì í kó ẹran wọn jẹ̀ ní oṣù December tó jẹ́ ìgbà tí òtútù máa ń mú gan-an