Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ṣé o gbádùn wọn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn àìgbọràn Ádámù, ṣe dà bí àrùn ìdílé?
Bó ṣe dà bí àrùn ni pé Ádámù kó ẹ̀ṣẹ̀ ran àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ kan ṣe máa ń jogún àìsàn látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn.—8/15, ojú ìwé 5.
• Kí làwọn ohun tó ń dìídì jẹ́ kí ìwà ipá peléke sí i lóde òní?
Sátánì ń sapá láti sọ àwọn èèyàn di ọ̀tá Jèhófà nípa gbíngbin èrò ìwà ipá sí wọn lọ́kàn. Ó máa ń lo àwọn nǹkan bíi fíìmù, orin àtàwọn eré orí kọ̀ǹpútà tó máa ń dà bíi pé ẹni tó ń lò ó ló ń hùwà ìkà àti ìpakúpa tó wà nínú rẹ̀. Ńṣe ni ìwà ipá tí wọ́n ń gbé jáde nínú fíìmù túbọ̀ ń jẹ́ kí ìwà ipá pọ̀ sí i.—9/1, ojú ìwé 29.
• Ta ni Pọ́ńtíù Pílátù?
Ọmọ ilẹ̀ Róòmù ni, ìdílé àwọn bọ̀rọ̀kìnní ilẹ̀ Róòmù ni wọ́n sì bí i sí. Àfàìmọ̀ ni kò ti wà nínú iṣẹ́ ológun tipẹ́. Tìbéríù olú ọba Róòmù ló fi Pílátù jẹ gómìnà ẹkùn Jùdíà lọ́dún 26 Sànmánì Kristẹni. Nígbà ìgbẹ́jọ́ Jésù, Pílátù gbọ́ ẹ̀sùn táwọn aṣáájú àwọn Júù fi kan Jésù. Àmọ́, torí kí Pílátù lè ṣe ohun tó dùn mọ́ àwọn èèyàn nínú, ó fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa Jésù.—9/15, ojú ìwé 10 sí 12.
• Kí ni “àmì” tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Mátíù 24:3?
Àmì yìí ní onírúurú ẹ̀ka. Lára àwọn ohun tó para pọ̀ di àmì yìí ni ogun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìṣẹ̀lẹ̀, àmì náà ni yóò sì jẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ ìgbà “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ àti “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—10/1, ojú ìwé 4 àti 5.
• Àwọn wo làwọn Júù tó wà lájò, àgbègbè wo ni wọ́n sì ń gbé nígbà náà?
Àwọn Júù tó wà lájò ni àwọn tí kò gbé nílẹ̀ Palẹ́sìnì. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn ilẹ̀ bíi Síríà, Éṣíà Kékeré, Bábílónì àti Íjíbítì làwọn Júù pọ̀ sí jù, àwọn Júù tó sì wà láwọn ilẹ̀ wọ̀nyí pọ̀ ju àwọn tó wà ní àgbègbè ilẹ̀ Yúróòpù tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù lọ.—10/15, ojú ìwé 12.
• Ǹjẹ́ Kristẹni kan lè ní ẹ̀rí ọkàn rere bó bá ń ṣe iṣẹ́ tó gba pé kó máa gbé ìbọn?
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni yóò pinnu bóyá ó yẹ kóun ṣe iṣẹ́ tó gba kóun máa gbé ìbọn tàbí ohun ìjà mìíràn. Àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ tó gba pé kéèyàn máa gbé ohun ìjà lè múni jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ béèyàn bá lò ó. Bákan náà, ó lè mú kéèyàn fara pa tàbí kéèyàn tiẹ̀ kú pàápàá báwọn kan bá dojú ìjà kọni tàbí tí wọ́n bá fẹ́ gbẹ̀san. Kristẹni tó bá ń gbé ohun ìjà bẹ́ẹ̀ kò lè ní àwọn àkànṣe àǹfààní nínú ìjọ. (1 Tímótì 3:3, 10)—11/1, ojú ìwé 31.
• Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ọ̀rọ̀ náà “Òkè Ńlá Mẹ́gídò” la ti mú “Amágẹ́dọ́nì,” ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé orí òkè ńlá kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ni wọ́n ti máa ja ogun Amágẹ́dọ́nì?
Rárá o. Kò síbi tó ń jẹ́ Òkè Ńlá Mẹ́gídò, kìkì òkìtì kan tó ga sókè díẹ̀ nítòsí àfonífojì kan tó tẹ́ pẹrẹsẹ ló wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Àgbègbè náà kéré gan-an ju ibi tó lè gba gbogbo “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.” Ogun ńlá Ọlọ́run yìí yóò kárí ayé, yóò sì fòpin sí gbogbo ogun. (Ìṣípayá 16:14, 16; 19:19; Sáàmù 46:8, 9)—12/1, ojú ìwé 4 sí 7.