Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Ìwọ Ń Ṣègbọràn Sí—Ọlọ́run Ni Tàbí Ènìyàn?

Ta Ni Ìwọ Ń Ṣègbọràn Sí—Ọlọ́run Ni Tàbí Ènìyàn?

Ta Ni Ìwọ Ń Ṣègbọràn Sí—Ọlọ́run Ni Tàbí Ènìyàn?

“Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—ÌṢE 5:29.

1. (a) Kí ni àkòrí àpilẹ̀kọ tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ yìí? (b) Kí nìdí tí wọ́n fi mú àwọn àpọ́sítélì?

 LẸ́YÌN ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti àwọn Júù dájọ́ ikú fún Jésù Kristi tí wọ́n sì pa á, àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ yẹn tún kóra jọ. Wọ́n fẹ́ wá han àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi tó sún mọ́ ọn jù lọ léèmọ̀ wàyí. Àmọ́ nígbà táwọn ẹ̀ṣọ́ tó fẹ́ kó wọn wá sílé ẹjọ́ náà dé àtìmọ́lé tí wọ́n fi wọ́n sí, ńṣe ni ibẹ̀ mọ́ foo bó tilẹ̀ jẹ́ pé títì ni ilẹ̀kùn wà. Inú ti ní láti bí àwọn adájọ́ wọ̀nyí gan-an. Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ẹ̀ṣọ́ náà gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì, wà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jésù Kristi láìbẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ torí ìyẹn gan-an ni wọ́n ṣe mú wọn tẹ́lẹ̀ o! Bí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà ṣe gba tẹ́ńpìlì lọ láti tún mú wọn nìyẹn, tí wọ́n sì kó wọn wá sílé ẹjọ́.—Ìṣe 5:17-27.

2. Kí ni áńgẹ́lì kan ní káwọn àpọ́sítélì ṣe?

2 Áńgẹ́lì ló tú àwọn àpọ́sítélì náà sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n. Ṣé torí kí wọ́n má bàa ṣenúnibíni sí wọn mọ́ ló fi ṣe bẹ́ẹ̀? Rárá o. Torí káwọn ará Jerúsálẹ́mù lè gbọ́ ìhìn rere nípa Jésù Kristi ni. Ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fáwọn àpọ́sítélì ni pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní sísọ gbogbo àsọjáde nípa ìyè yìí fún àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:19, 20) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà táwọn ẹ̀ṣọ́ dé tẹ́ńpìlì, ẹnu iṣẹ́ yẹn ni wọ́n bá àwọn àpọ́sítélì.

3, 4. (a) Nígbà tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí Pétérù àti Jòhánù yéé wàásù, báwo ni wọ́n ṣe fèsì? (b) Báwo làwọn àpọ́sítélì yòókù ṣe fèsì?

3 Pétérù àti Jòhánù wà lára àwọn àpọ́sítélì tí ò yéé wàásù náà, àwọn méjèèjì yìí sì ti fojú ba ilé ẹjọ́ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà Jósẹ́fù Káyáfà ṣe rán wọn létí tìkanra-tìkanra. Ó ní: “A pa àṣẹ fún yín ní pàtó láti má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ [Jésù], síbẹ̀, sì wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 5:28) Kò yẹ kó ya Káyáfà lẹ́nu pé Pétérù àti Jòhánù tún padà délé ẹjọ́. Torí pé, nígbà tí wọ́n pàṣẹ fún wọn lákọ̀ọ́kọ́ yẹn pé kí wọ́n má wàásù mọ́, èsì táwọn àpọ́sítélì méjèèjì fún wọn ni pé: “Bí ó bá jẹ́ òdodo lójú Ọlọ́run láti fetí sí yín dípò Ọlọ́run, ẹ fúnra yín ṣèdájọ́. Ṣùgbọ́n ní tiwa, àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” Bí wòlíì Jeremáyà tó gbé ayé ṣáájú wọn ò ṣe lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà ni Pétérù àti Jòhánù ò ṣe lè dẹ́kun iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe.—Ìṣe 4:18-20; Jeremáyà 20:9.

4 Àmọ́ Pétérù àti Jòhánù nìkan kọ́ ló wá ṣàlàyé ara wọn nílé ẹjọ́ lọ́tẹ̀ yìí, gbogbo àwọn àpọ́sítélì ni, títí kan Mátíásì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di àpọ́sítélì. (Ìṣe 1:21-26) Nígbà tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n yéé wàásù, ńṣe làwọn náà fìgboyà fèsì pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

Àṣẹ Ọlọ́run Ni Kí Wọ́n Pa Mọ́ Ni Tàbí Ti Èèyàn?

5, 6. Kí nìdí táwọn àpọ́sítélì ò fi lè pa àṣẹ ilé ẹjọ́ yẹn mọ́?

5 Ọmọlúwàbí èèyàn tí kò ní ṣàdédé kọ ohun tí ilé ẹjọ́ bá sọ làwọn àpọ́sítélì wọ̀nyẹn. Àmọ́ kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan, bó ti wù kónítọ̀hún lágbára tó, tí Ọlọ́run yọ̀ǹda fún pé ó lè pàṣẹ fún ọmọnìkejì rẹ̀ láti rú èyíkéyìí nínú òfin Ọlọ́run. Jèhófà ni “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Yàtọ̀ sí pé òun ni “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé,” òun tún ni Afúnnilófin tó ga jù lọ láyé àti lọ́run, òun sì tún ni Ọba ayérayé. Òfin èyíkéyìí tí ilé ẹjọ́ bá ṣe tó bá forí gbárí pẹ̀lú èyíkéyìí nínú àṣẹ Ọlọ́run kò lẹ́sẹ̀-ń-lẹ̀ lójú Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 18:25; Aísáyà 33:22.

6 Àwọn kan lára àwọn ògbóǹkangí amòfin pàápàá sọ pé òfin èèyàn kò gbọ́dọ̀ ta ko ti Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ògbóǹkangí amòfin ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ William Blackstone tó gbé láyé ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún sẹ́yìn kọ̀wé pé ọmọ èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èyíkéyìí nínú òfin rẹ̀ ta ko “òfin tí a ṣí payá,” tó wà nínú Bíbélì. Nítorí náà, àjọ Sànhẹ́dírìn ṣàṣejù nígbà tí wọ́n pàṣẹ pé káwọn àpọ́sítélì má wàásù mọ́. Àwọn àpọ́sítélì ò sì lè pa àṣẹ yẹn mọ́ rárá.

7. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù àwọn àpọ́sítélì fi ń bí àwọn olórí àlùfáà nínú?

7 Inú bí àwọn olórí àlùfáà gan-an bí àwọn àpọ́sítélì ṣe láwọn ò ní yéé wàásù. Sadusí làwọn kan lára àwọn àlùfáà yẹn, títí kan Káyáfà alára, àwọn Sadusí ò sì gbà pé àjíǹde wà. (Ìṣe 4:1, 2; 5:17) Síbẹ̀, ohun táwọn àpọ́sítélì ṣáà ń tẹnu mọ́ ni pé Jésù ti jíǹde. Yàtọ̀ síyẹn, ńṣe làwọn kan lára àwọn olórí àlùfáà ń pá kúbẹ́kúbẹ́ lábẹ́ àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Róòmù láti wá ojúure wọn. Àní nígbà tí wọ́n ń ṣẹjọ́ Jésù, tí Pílátù bi wọ́n bóyá wọ́n á gba Jésù lọ́ba wọn, ńṣe làwọn olórí àlùfáà kígbe pé: “Àwa kò ní ọba kankan bí kò ṣe Késárì.” (Jòhánù 19:15) a Ṣùgbọ́n àwọn àpọ́sítélì ò tiẹ̀ wá fi ìwàásù wọn mọ sí pé Jésù ti jíǹde, wọ́n tún ń kọ́ni pé yàtọ̀ sí orúkọ Jésù “kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.” (Ìṣe 2:36; 4:12) Ìbẹ̀rù àwọn àlùfáà sì ni pé táwọn èèyàn bá lọ gbà pé Jésù tó jíǹde ni Aṣáájú wọn, àwọn ará Róòmù lè wá sí orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn sì lè mú káwọn aṣáájú àwọn Júù pàdánù ‘àyè wọn àti orílẹ̀-èdè wọn.’—Jòhánù 11:48.

8. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wo ni Gàmálíẹ́lì fún àjọ Sànhẹ́dírìn?

8 Ó wá dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ kankan fáwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi. Ìdí ni pé àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ Sànhẹ́dírìn ti pinnu láti dájọ́ ikú fún wọn. (Ìṣe 5:33) Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà ṣàdédé yí bírí. Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ Òfin dìde ó sì kìlọ̀ fáwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù pé kí wọ́n má fìkánjú ṣèdájọ́ wọn. Ó wá sọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n yìí fún wọn pé: “Bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìpètepèrò tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú.” Ó sì fọ̀rọ̀ pàtàkì yìí kún un pé: “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.”—Ìṣe 5:34, 38, 39.

9. Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run ló gbé iṣẹ́ ìwàásù lé àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́?

9 Èèyàn ò tiẹ̀ lè rò pé wọ́n á gba ìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì yìí, àmọ́ wọ́n gbà á. Àjọ Sànhẹ́dírìn wá “fi ọlá àṣẹ pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pa àṣẹ fún wọn pé kí wọ́n dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.” Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì ò mikàn rárá o, torí inú iṣẹ́ ìwàásù tí áńgẹ́lì pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe lọkàn wọn wà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n fi wọ́n sílẹ̀, “ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni [àwọn àpọ́sítélì náà] ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:40, 42) Jèhófà sì bù kún ìsapá wọn. Báwo ni ìbùkún yẹn ṣe tó? Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù.” Kódà “ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà . . . bẹ̀rẹ̀ sí di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà.” (Ìṣe 6:7) Ìyẹn á dun àwọn olórí àlùfáà yẹn gan-an ni! Torí ńṣe lèyí túbọ̀ fi hàn gbangba pé Ọlọ́run ló gbé iṣẹ́ ìwàásù lé àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́!

Àwọn Tí Ń Bá Ọlọ́run Jà Ò Lè Borí

10. Kí ni Káyáfà lè rò pé ó jẹ́ kóun pẹ́ lórí oyè, àmọ́ kí nìdí tíyẹn fi jẹ́ àṣìṣe?

10 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Róòmù ló ń yan àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù. Gómìnà Valerius Gratus ló fi Jósẹ́fù Káyáfà tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ jẹ olórí àlùfáà, ó sì pẹ́ lórí oyè yẹn ju ọ̀pọ̀ àwọn olórí àlùfáà tó ṣáájú rẹ̀. Dípò kí Káyáfà gbé ògo pípẹ́ tó pẹ́ lórí oyè fún Ọlọ́run, ó jọ pé ńṣe ló gbà pé bí òun ṣe jẹ́ ògbóǹkangí olóṣèlú àti ọ̀rẹ́ Pílátù ló jẹ́ kí òun pẹ́ lórí òye. Àmọ́, àṣìṣe gbáà ló ṣe bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọmọ èèyàn. Ọdún mẹ́ta péré lẹ́yìn tí wọ́n gbé àwọn àpọ́sítélì wá sílé ẹjọ́ Sànhẹ́dírìn ló di pé ọ̀rọ̀ ò wọ̀ mọ́ láàárín Káyáfà àtàwọn aláṣẹ ilẹ̀ Róòmù, wọ́n sì yọ ọ́ kúrò nípò àlùfáà àgbà.

11. Kí ló wá gbẹ̀yìn Pọ́ńtù Pílátù àti ètò àwọn nǹkan àwọn Júù, ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa?

11 Ọ̀gá Pílátù, ìyẹn Lucius Vitellius, tó jẹ́ gómìnà Síríà ló ní kí wọ́n yọ Káyáfà lóyè, kò sì sóhun tí Pílátù ọ̀rẹ́ Káyáfà tímọ́tímọ́ lè ṣe sí i. Ọdún kan lẹ́yìn tí wọ́n rọ Káyáfà lóyè ni wọ́n yọ Pílátù pàápàá lóyè tí wọ́n sì ní kó wá sí Róòmù láti jẹ́jọ́ àwọn ẹ̀sùn ńláńlá tí wọ́n fi kàn án. Ní tàwọn aṣáájú àwọn Júù tó gbẹ́kẹ̀ lé Késárì, àwọn ará Róòmù gba ‘àyè wọn àti orílẹ̀-èdè wọn’ gbẹ̀yìn náà ni. Èyí ṣẹlẹ̀ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa ìlú Jerúsálẹ́mù run, títí kan tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ àti gbọ̀ngàn ilé ẹjọ́ Sànhẹ́dírìn. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ onísáàmù ṣẹ sí wọn lára, èyí tó sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀”!—Jòhánù 11:48; Sáàmù 146:3.

12. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ṣe jẹ́ kó hàn pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn ṣègbọràn sí Ọlọ́run?

12 Àmọ́ ní ti Jésù Kristi, ńṣe ni Ọlọ́run fi jẹ Àlùfáà Àgbà nínú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí lẹ́yìn tó jíǹde. Kò sì séèyàn tó lè yọ ọ́ lóyè rárá. Kódà ńṣe ní Jésù “ní iṣẹ́ àlùfáà rẹ̀ láìsí àwọn arọ́pò kankan.” (Hébérù 2:9; 7:17, 24; 9:11) Ọlọ́run sì tún fi Jésù ṣe Onídàájọ́ àwọn tó wà láàyè àtàwọn tó ti kú. (1 Pétérù 4:5) Ipò yìí ni Jésù náà yóò ti wá pinnu bóyá Jósẹ́fù Káyáfà àti Pọ́ńtù Pílátù yóò jíǹde tàbí wọn ò ní jíǹde.—Mátíù 23:33; Ìṣe 24:15.

Àwọn Oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run Tí Kì Í Bẹ̀rù Lóde Òní

13. Lóde òní, iṣẹ́ wo ló jẹ́ iṣẹ́ èèyàn, èwo sì ni iṣẹ́ Ọlọ́run? Báwo lo ṣe mọ̀?

13 Bí ‘àwọn tó ń bá Ọlọ́run jà’ ṣe pọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní náà ni wọ́n ṣe pọ̀ lóde òní. (Ìṣe 5:39) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Jámánì ò gbà láti máa polongo Adolf Hitler pé òun ni Aṣáájú wọn, Hitler lérí pé òun máa tẹ̀ wọ́n rẹ́ pátápátá. (Mátíù 23:10) Bí ẹní ń fàkàrà jẹ̀kọ nìyẹn sì jẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ Násì tó ń lò. Ẹgbẹ́ òṣìkà yẹn kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lóòótọ́. Kódà wọ́n tiẹ̀ pa àwọn Ẹlẹ́rìí kan. Àmọ́ àbá ni ikán ń dá lọ̀rọ̀ wọn o, torí pé ẹgbẹ́ Násì ò lè yí ìpinnu táwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣe pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo làwọn yóò máa jọ́sìn padà láé, kò sì ṣeé ṣe fún wọn láti pa ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. Ọlọ́run ló gbé iṣẹ́ lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn lọ́wọ́ kì í ṣe ènìyàn, ẹnikẹ́ni ò sì lè bi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú. Àní ní báyìí tó ti tó ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, àwọn olóòótọ́ tí kò kú sínú ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ṣì ń bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú wọn.’ Àmọ́ Hitler àti ẹgbẹ́ Násì rẹ̀ ti pa rẹ́ ráúráú, ìwà ìkà wọn nìkan làwọn èèyàn fi ń rántí wọn.—Mátíù 22:37.

14. (a) Àwọn ìsapá wo làwọn alátakò ti ṣe láti ba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, kí sì nìyẹn ti yọrí sí? (b) Ǹjẹ́ wọ́n á lè rẹ́yìn àwọn èèyàn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ìsapá wọn yẹn? (Hébérù 13:5, 6)

14 Lẹ́yìn ìjọba Násì, àwọn èèyàn míì náà tún ti dìde ìjà sí Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀, wọn ò sì lè borí ìjà ọ̀hún láéláé. Láwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan nílẹ̀ Yúróòpù, àwọn èèyànkéèyàn kan láàárín àwọn onísìn àti olóṣèlú ti gbìyànjú láti pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ tí kì í ṣe tiwa. Wọ́n ń pè wá ní ‘ẹ̀ya ìsìn eléwu.’ Ẹ̀sùn kan náà tí wọ́n fi kan àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní sì nìyẹn. (Ìṣe 28:22) Ṣùgbọ́n ní tòdodo, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù mọ̀, wọ́n sì ti sọ pé ojúlówó ẹ̀sìn ni ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé kì í ṣe ẹ̀ya ìsìn rárá. Àwọn alátakò wọ̀nyí sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n ṣáà fẹ́ ba orúkọ àwa Ẹlẹ́rìí jẹ́ ṣáá ni. Ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ wọn yìí ti mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pàdánù iṣẹ́ wọn. Àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí míì ò rímú mí nílé ìwé nítorí ẹ̀. Àwọn onílé kan tí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ wọn yìí bà lẹ́rù fagi lé àdéhùn tí wọ́n ti bá àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe tẹ́lẹ̀ lórí àwọn ilé tí wọ́n ti ń lò fún ìpàdé wọn látọdún pípẹ́. Kódà a ti ríbi táwọn ilé iṣẹ́ ìjọba kan ti kọ̀ láti fún àwọn kan níwèé àṣẹ pé kí wọ́n máa gbé orílẹ̀-èdè lọ bí ọmọ onílẹ̀ kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Ṣùgbọ́n ṣá, àwa Ẹlẹ́rìí kò mikàn o.

15, 16. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Faransé ṣe nípa àtakò táwọn kan ń ṣe sí iṣẹ́ ìwàásù wọn, kí sì nìdí tí wọn ò fi dáwọ́ iṣẹ́ wàásù dúró?

15 Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn nílẹ̀ Faransé ni kì í ṣe oníwàhálà tàbí ẹlẹ́tanú. Ṣùgbọ́n àwọn alátakò mélòó kan níbẹ̀ di rìkíṣí kí ìjọba lè ṣòfin tó máa ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Faransé wá ṣe? Ńṣe ni wọ́n tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wọn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, wọ́n sì ṣàṣeyọrí tó wúni lórí. (Jákọ́bù 4:7) Kódà nígbà kan, láàárín oṣù mẹ́fà péré, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè yẹn fi ìdámẹ́ta lé sí ti tẹ́lẹ̀! Láìsí àní-àní, ńṣe ni inú Èṣù á máa ru gùdù pé àwọn olùfẹ́ òdodo ń kọbi ara sí ìhìn rere nílẹ̀ Faransé. (Ìṣípayá 12:17) Ó dá àwọn Kristẹni ẹlẹ́gbẹ́ wa nílẹ̀ Faransé lójú pé ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà máa ṣẹ sí wọn lára, èyí tó sọ pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi.”—Aísáyà 54:17.

16 Kò wu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n máa ṣenúnibíni sí wọn. Ṣùgbọ́n torí kí wọ́n lè pa àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún gbogbo Kristẹni mọ́ ni wọn ò ṣe ní dákẹ́, tí wọn ò sì ní yéé sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ohun tí wọ́n ti gbọ́. Wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti rí i dájú pé àwọn jẹ́ ọmọlúwàbí. Ṣùgbọ́n tí òfin èèyàn bá fi lè forí gbárí pẹ̀lú òfin Ọlọ́run, ó dájú gbangba pé Ọlọ́run ni wọ́n á ṣègbọràn sí gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.

Ẹ Má Ṣe Bẹ̀rù Wọn

17. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù àwọn ọ̀tá wa? (b) Irú ìwà wo ló yẹ ká máa hù sí àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa?

17 Ipò tó léwu làwọn ọ̀tá wa wà. Ìdí ni pé Ọlọ́run ni wọ́n ń bá jà. Nítorí náà, ohun tí Jésù pa láṣẹ la óò máa ṣe, ìyẹn ni pé, dípò ká bẹ̀rù àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wa, ńṣe la óò máa gbàdúrà fún wọn. (Mátíù 5:44) Àdúrà wa sì ni pé tó bá jẹ́ àìmọ̀kan ni èyíkéyìí lára wọn fi ń ṣàtakò sí Ọlọ́run bíi ti Sọ́ọ̀lù ará Tásù, kí Jèhófà jọ̀wọ́ la ojú onítọ̀hún sí òtítọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Sọ́ọ̀lù padà di Kristẹni, ó dẹni tá a mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwọn aláṣẹ ayé ìgbà yẹn sì jẹ ẹ́ níyà gan-an. Síbẹ̀, ó rán àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ létí pé wọ́n ní láti “wà ní ìtẹríba àti láti jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, láti gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo, láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́ [àní títí kan èyíkéyìí nínú àwọn tó ń ṣenúnibíni tó le jù lọ sí wọn], láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.” (Títù 3:1, 2) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Faransé àtàwọn tó wà láwọn ibi yòókù máa ń rí i dájú pé àwọn tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí.

18. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè? (b) Kí ló máa jẹ́ àbáyọrí ohun tí Ọlọ́run bá gbà láyè?

18 Ọlọ́run sọ fún wòlíì Jeremáyà pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè.” (Jeremáyà 1:8) Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dá wa nídè nígbà inúnibíni lóde òní? Ó lè lo adájọ́ tí kò lẹ́tanú bó ṣe lo Gàmálíẹ́lì. Ó sì tún lè rí sí i pé wọ́n yọ òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ tàbí alátakò nípò láìròtẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì fi òmíràn tó jẹ́ ọmọlúwàbí rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ nígbà míì, Jèhófà lè máà dá inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn èèyàn rẹ̀ dúró. (2 Tímótì 3:12) Bí Ọlọ́run bá gba inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa láyè, kò ní ṣàì fún wa lókun tá a ó fi lè fara dà á. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ohunkóhun tí Ọlọ́run bá sì ti gbà láyè, a mọ ohun tó máa yọrí sí dájúdájú, òun sì ni pé: Gbogbo àwọn tó ń bá àwọn èèyàn Ọlọ́run jà ń bá Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jà, àwọn tó bá sì ń bá Ọlọ́run jà kò ní borí láéláé.

19. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2006, kí sì nìdí tó fi bá a mu?

19 Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa retí ìpọ́njú. (Jòhánù 16:33) Nítorí náà, ìsinsìnyí gan-an ni ọ̀rọ̀ Ìṣe 5:29 bọ́ sákòókò jù, ìyẹn ni: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” Ìdí nìyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi fi ọ̀rọ̀ tó wúni lórí yìí ṣe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún wa fún ọdún 2006. Á dára kó jẹ́ ìpinnu wa lọ́dún tó ń bọ̀ àti títí láé pé bí iná ń jó, bí ìjì ń jà, Ọlọ́run la óò máa ṣègbọràn sí gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tìbéríù olú ọba Róòmù tó jẹ́ alágàbàgebè ẹ̀dá àti apààyàn táwọn èèyàn tẹ́ńbẹ́lú ni “Késárì” táwọn olórí àlùfáà yẹn ń sọ ní gbangba pé àwọn fara mọ́ yìí o. Tìbéríù yìí tún jẹ́ ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí oníṣekúṣe ẹ̀dá.—Dáníẹ́lì 11:15, 21.

Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?

• Báwo lohun tí àwọn àpọ́sítélì ṣe nígbà inúnibíni ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa?

• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn?

• Ta ni àwọn alátakò wa ń bá jà gan-an?

• Kí lọ̀rọ̀ àwọn tó bá fara da inúnibíni máa ń yọrí sí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2006 ni: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

“Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èèyàn ni Káyáfà gbẹ́kẹ̀ lé dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run