“Wàásù Ìtúsílẹ̀ fún Àwọn Òǹdè”
“Wàásù Ìtúsílẹ̀ fún Àwọn Òǹdè”
NÍGBÀ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ní ara iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun ni pé kóun “wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè.” (Lúùkù 4:18) Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọ̀gá wọn yìí, wọ́n ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún “gbogbo onírúurú ènìyàn,” wọ́n sì ń tipa báyìí tú wọn sílẹ̀ nínú ìgbèkùn tẹ̀mí, wọ́n sì tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ìgbésí ayé wọn ṣe.—1 Tímótì 2:4.
Lóde òní, àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà wà lára àwọn tá à ń wàásù fún, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀ràn kan tàbí òmíràn tí wọ́n dá àmọ́ tí wọ́n mọyì ìtúsílẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ẹ ka ìròyìn tó ń wúni lórí yìí nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà lórílẹ̀-èdè Ukraine àti láwọn ibòmíràn nílẹ̀ Yúróòpù.
Àwọn Kan Tó Ń Lo Oògùn Olóró Di Kristẹni
Ogún ọdún ni Serhii a ti fi ṣẹ̀wọ̀n lára ọdún méjìdínlógójì tó tíì gbé láyé. Ẹ̀wọ̀n ló tiẹ̀ ti parí ilé ìwé rẹ̀. Ó sọ pé: “Torí pé mo pààyàn ni mo ṣe dèrò ẹ̀wọ̀n láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, mi ò sì tíì lo ọdún mi pé. Mo ya òǹrorò kalẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ló máa ń bẹ̀rù mi.” Ǹjẹ́ ìwà tí Serhii ń hù yìí mú kó wà lómìnira bó ṣe fẹ́? Rárá o. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló fi wà lábẹ́ àjàgà oògùn olóró, ọtí àmujù àti sìgá mímu.
Ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ rẹ̀ kan wá sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì fún un. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ náà dà bí ìgbà tẹ́nì kan tanná síbi tó ṣókùnkùn. Kò ju bí oṣù mélòó kan tó fi jáwọ́ nínú gbogbo ìwàkiwà tó ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù tẹ́lẹ̀, tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere, tó sì ṣèrìbọmi. Ní báyìí, Serhii ń bá iṣẹ́ Jèhófà lọ ní pẹrẹu lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó ti di òjíṣẹ́ Jèhófà tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù báyìí. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n méje ló ti ràn lọ́wọ́ láti yí ìwà wọn padà, wọ́n sì ti di arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Wọ́n ti dá mẹ́fà lára wọn sílẹ̀, àmọ́ Serhii ṣì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Kò bínú rárá pé wọn ò tíì dá òun sílẹ̀ torí pé inú rẹ̀ dùn pé òun lè máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kúrò nígbèkùn tẹ̀mí.—Ìṣe 20:35.
Victor jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Serhii kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Oògùn olóró ni Victor ń tà tẹ́lẹ̀, ó sì tún máa ń lo oògùn olóró. Lẹ́yìn tí ìjọba dá a sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí, nígbà tó sì yá ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Ukraine. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni lórílẹ̀-èdè Moldova báyìí. Victor sọ pé: “Ìgbà tí mo wà Hébérù 4:12.
lọ́mọ ọdún mẹ́jọ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí fa sìgá, ọmọ ọdún méjìlá ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mutí, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sì ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró. Mo gbìyànjú láti jáwọ́ nínú gbogbo ìwà játijàti yẹn, àmọ́ pàbó ni akitiyan mi já sí. Lọ́dún 1995, lákòókò tí èmi àti ìyàwó mi pinnu láti ṣí kúrò lágbègbè ibi táwọn ọ̀rẹ́ búburú tí mò ń bá kẹ́gbẹ́ tẹ́lẹ̀ ń gbé lẹnì kan tó kàn fẹ́ràn àtimáa gbẹ̀mí èèyàn fi ọ̀bẹ gún ìyàwó mi pa. Ayé mi wá dojú rú pátápátá. ‘Ibo ni ìyàwó mi wà báyìí? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?’ Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni mo máa ń béèrè, àmọ́ n kì í rí ìdáhùn. Ni mo bá túbọ̀ ń lo oògùn olóró láti fi pàrònú rẹ́. Ọwọ́ ìjọba tẹ̀ mí fún oògùn olóró tí mò ń tà, wọ́n sì ní kí n lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún gbára. Ibẹ̀ ni Serhii ti bá mi rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Ó ti pẹ́ tí mo ti fẹ́ fi oògùn olóró sílẹ̀ tí kò ṣeé ṣe, àmọ́ Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti fi í sílẹ̀ pátápátá báyìí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà lágbára o!”—Àwọn Ọ̀daràn Paraku Yí Padà
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Vasyl kì í lo oògùn olóró ní tiẹ̀, àmọ́ òun náà ṣẹ̀wọ̀n. Ó ní: “Fífi ìpá àti ìkúùkù báni jà ti wọ̀ mí lẹ́jẹ̀. Mo mọ bí mo ṣe lè lu èèyàn tí kò sì ní sí àpá kankan lára onítọ̀hún.” Vasyl tún máa ń lo ìwà jàgídíjàgan yìí láti ja àwọn èèyàn lólè. “Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo lọ ṣẹ̀wọ̀n, ìdí nìyẹn tí ìyàwó mi fi kọ̀ mí. Lákòókò tí mò ń ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún tí wọ́n sọ mí sí kẹ́yìn, mo ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí mo kà nínú ìwé wọn ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì, àmọ́ mo ṣì ń ṣe ohun tí mo fẹ́ràn jù lọ, ìyẹn ni fífi ìpá àti ìkúùkù báni jà.
“Àmọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí mo ti ń ka Bíbélì, èrò ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí yí padà. Ayọ̀ tí mo máa ń ní tẹ́lẹ̀ nígbà tí mo bá lu èèyàn bolẹ̀ kì í sí mọ́. Torí náà, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 2:4 yẹ ìgbésí ayé mi wò, mo sì rí i pé tí mi ò bá ṣe nǹkan kan nípa ìwà tí mò ń hù, ẹ̀wọ̀n ni màá ti lo ìyókù ìgbésí ayé mi. Ni mo bá sọ gbogbo ohun ìjà mi nù, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí tún ìwà mi ṣe. Kò rọrùn o, àmọ́ àṣàrò lórí àwọn nǹkan tí mo kọ́ àti àdúrà ràn mí lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò bójú mu wọ̀nyẹn. Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé pẹ̀lú omijé lójú ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà búburú tó ti di bárakú fún mi. Níkẹyìn, mo jáwọ́.
“Lẹ́yìn tí mo tẹ̀wọ̀n dé, èmi àti ìyàwó mi àtọmọ mi tún padà wà pa pọ̀. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ìwakùsà. Èyí jẹ́ kí èmi àti ìyàwó mi máa ráyè lọ wàásù, ó sì tún fún mi láyè láti bójú tó àwọn iṣẹ́ mi nínú ìjọ.”
Ní orílẹ̀-èdè Ukraine, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mykola àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ fọ́ báńkì bíi mélòó kan. Ìyẹn ló mú kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá gbáko. Kó tó di pé ó dèrò ẹ̀wọ̀n, ẹ̀ẹ̀kan ló tíì tẹ ṣọ́ọ̀ṣì rí láyé ẹ̀. Ohun tó sì gbé e lọ ni pé ó fẹ́ lọ wojú ilẹ̀ kó lè lọ jalè níbẹ̀. Ohun tí Mykola pète yìí kò bọ́ sí i, àmọ́ lílọ tó lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ náà mú kó rò pé ìtàn àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àbẹ́là àti ọdún táwọn ẹlẹ́sìn máa ń ṣe ló kúnnú Bíbélì, wọ́n sì jẹ́ ìtàn tó máa ń súni. Ó ní: “Mi ò tiẹ̀ lè sọ pé nǹkan báyìí ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì, mo kàn ṣáà ri pé mò ń kà á ni. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi pé bí mo ṣe rò kọ́ lọ́rọ̀ rí!” Mykola ní kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1999. Téèyàn bá ń wo Mykola lónìí, èèyàn ò lè gbà gbọ́ pé jàgùdà páálí tó lọ ń fọ́ báńkì lọ́jọ́sí náà ló di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ yìí!
Ìjọba dájọ́ ikú fún Vladimir. Lákòókò tó fi ń dúró dìgbà tí wọ́n máa pa á, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sì ṣèlérí pé òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọ́run tí wọ́n bá lè dá ẹ̀mí òun sí. Láàárín àkókò yìí ni òfin yí padà, wọ́n wá sọ ọ́ sẹ́wọ̀n gbére dípò kí wọ́n pa á. Kí Vladimir lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ìsìn tòótọ́. Nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ló ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ẹ̀kọ́ ìjọ Adventist nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́, ó sì gboyè jáde àmọ́ gbogbo ìyẹn ò tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí Vladimir ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní yàrá ìkówèésí tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ukraine pé kí wọ́n rán Ẹlẹ́rìí kan wá sọ́dọ̀ òun láti máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Kí àwọn arákùnrin tó wà lágbègbè náà tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ló tiẹ̀ ti ka ara rẹ̀ sí Ẹlẹ́rìí tó sì ti ń wàásù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Àwọn arákùnrin yìí ràn án lọ́wọ́ láti di akéde Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń kọ̀wé yìí, Vladimir àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n méje mìíràn ò ní pẹ́ ṣèrìbọmi. Àmọ́ wọ́n ní ìṣòro kan o. Ìṣòro náà ni pé yàrá kan náà ni wọ́n máa ń fi àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà sí, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ ẹ̀sìn kan náà ni Vladimir àtàwọn tó wà nínú yàrá kan náà jọ ń ṣe. Ta ni wọ́n wá ń wàásù fún? Wọ́n máa ń wàásù fáwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n wọ́n sì máa ń kọ lẹ́tà láti fi wàásù fáwọn mìíràn.
Nazar kúrò ní orílẹ̀-èdè Ukraine lọ sí orílẹ̀-èdè Czech Republic, níbi tó ti wẹgbẹ́ olè. Ìyẹn ló mú kó dèrò ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta àtààbọ̀. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń wá láti ìlú Karlovy Vary, ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì dẹni tí ìwà rẹ̀ yí padà pátápátá. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n rí ìyípadà yìí, ó sọ fún àwọn tó wà nínú yàrá kan náà pẹ̀lú Nazar pé: “Tí gbogbo yín bá lè dà bí ọkùnrin ará Ukraine yìí, ńṣe ni ǹ bá lọ wáṣẹ́ mìíràn ṣe.” Òmíràn sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyí mà ń gbìyànjú o. Ìjọba á sọ ẹnì kan tó bá dáràn sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, nígbà tó bá sì fi máa jáde á ti di ọmọlúwàbí èèyàn.” Nazar ti kúrò lẹ́wọ̀n báyìí. Ó kọ́ iṣẹ́ káfíńtà, ó fẹ́yàwó, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún báyìí. Ó dájú pé inú rẹ̀ dùn gan-an fún wíwá táwọn Ẹlẹ́rìí wá sọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n!
Àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba Náà Mọyì Iṣẹ́ Wa
Àwọn ẹlẹ́wọ̀n nìkan kọ́ ló mọrírì ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe o. Miroslaw Kowalski tó jẹ́ agbẹnusọ fún ọ̀kan lára àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n orílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “A mọrírì wíwá táwọn Ẹlẹ́rìí máa ń wá sọ́gbà ẹ̀wọ̀n gan-an. Ìgbésí ayé àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan ò dára látilẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń hùwà ìkà sí wọn tẹ́lẹ̀. . . . Ìrànlọ́wọ́ [táwọn Ẹlẹ́rìí] ń ṣe wúlò gan-an torí pé a ò ní àwọn òṣìṣẹ́ àtàwọn olùkọ́ tó pọ̀ tó.”
Wọ́dà kan ní ọgbà ẹ̀wọ̀n míì lórílẹ̀-èdè Poland kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé káwọn Ẹlẹ́rìí túbọ̀ máa wá ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tóun ti ń ṣiṣẹ́. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣàlàyé pé: “Táwọn aṣojú Watchtower bá túbọ̀ ń wá, ó lè ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ láti ní ìwà tó dára láwùjọ, á sì mú kí wọ́n máa ṣe jẹ́jẹ́.”
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ukraine kan ròyìn nípa ẹlẹ́wọ̀n kan tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tó sì gbìyànjú láti para rẹ̀ àmọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn lọ́wọ́. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ara ọkùnrin náà ti ń balẹ̀ báyìí. Gbogbo ohun tí wọ́n là kalẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn ló ń tẹ̀ lé, ó sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù.”
Àǹfààní Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Ò Mọ sí Ìgbà Táwọn Ẹlẹ́wọ̀n Wà Lẹ́wọ̀n
Kì í ṣe ìgbà táwọn ẹlẹ́wọ̀n wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nìkan ni iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe wọ́n láǹfààní.
Iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ṣì tún máa ń ṣe wọ́n láǹfààní àní lẹ́yìn tí ìjọba bá ti dá wọn sílẹ̀ pàápàá. Àwọn obìnrin Ẹlẹ́rìí méjì kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Brigitte àti Renate ti máa ń ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún lọ́nà yìí. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì tó ń jẹ́ Main-Echo Aschaffenburg ròyìn nípa àwọn obìnrin náà pé: “Wọ́n máa ń mójú tó àwọn ẹlẹ́wọ̀n fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta sí márùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dá wọn sílẹ̀, wọ́n á máa gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n lè ní ohun kan tó ṣe gúnmọ́ tí wọ́n fẹ́ fi ayé wọn ṣe. . . . Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n kà wọ́n sí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa mójú tó àwọn ẹlẹ́wọ̀n obìnrin tí wọ́n fún lómìnira ráńpẹ́ láti fi wo ìwà wọn. . . . Àwọn àtàwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n mọwọ́ ara wọn gan-an.” Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀ ló ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà látàrí ìrànlọ́wọ́ bí irú èyí tí wọ́n rí gbà.Kódà àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n pàápàá ń jàǹfààní ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, Roman jẹ́ ọ̀gá sójà, ó sì tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan lórílẹ̀-èdè Ukraine. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí wá sílé rẹ̀, ó gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ó gbọ́ pé wọn ò gbà káwọn Ẹlẹ́rìí máa wá wàásù fáwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó ti ń ṣiṣẹ́. Ló bá ní kí wọ́dà tó wà níbẹ̀ gba òun láyé láti máa lo Bíbélì nínú iṣẹ́ tóun máa ń ṣe fáwọn ẹlẹ́wọ̀n. Wọ́n gbà á láyè, ó sì tó nǹkan bí ẹlẹ́wọ̀n mẹ́wàá tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ń bá wọn sọ. Gbogbo ìgbà ni Roman máa ń sọ ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí, ìwàásù rẹ̀ sì so èso rere. Àwọn kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n dá sílẹ̀ tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n sì di Kristẹni tó ṣèrìbọmi. Nígbà tí Roman rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó, ó túbọ̀ tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, ó sì ń bá iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń ṣe nìṣó. Ní báyìí, òun àti ẹnì kan tó ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n rí ló jọ ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù.
Ẹlẹ́wọ̀n kan kọ̀wé pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ nínú Bíbélì lára wa.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí jẹ́ ká mọ bí àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n míì ṣe nílò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó. Ìjọ kan tó wà lórílẹ̀-èdè Ukraine ròyìn nípa bí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń lọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan, ó ní: “Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ wa gan-an fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń kó wá síbẹ̀. A máa ń kó ọgọ́ta ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kọ̀ọ̀kan lọ fún wọn lóṣooṣù.” Ìjọ mìíràn kọ̀wé pé: “A máa ń kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó ní ogún yàrá ìkówèésí. A máa ń fi àwọn ìwé wa pàtàkì-pàtàkì sí yàrá ìkówèésí kọ̀ọ̀kan. Gbogbo ìwé wa tá a ti kó fún wọn báyìí kún ogún páálí.” Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan, àwọn ẹ̀ṣọ́ ibẹ̀ máa ń to àwọn ìwé ìròyìn wa sójú kan káwọn ẹlẹ́wọ̀n bàa lè jàǹfààní látinú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
Lọ́dún 2002, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Ukraine dá ẹ̀ka kan sílẹ̀ tí yóò máa bójú tó ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nǹkan bí ọgọ́fà ọgbà ẹ̀wọ̀n ni ẹ̀ka náà ti kàn sí báyìí, wọ́n sì ti yan àwọn ìjọ tí yóò lọ máa wàásù níbẹ̀. Nǹkan bí àádọ́ta lẹ́tà ni ẹ̀ka yìí ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lóṣooṣù, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń béèrè fún. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń fi ìwé ńlá, ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé pẹlẹbẹ ránṣẹ́ sí wọn títí dìgbà táwọn ará tó wà lágbègbè ibẹ̀ yóò lọ sọ́dọ̀ wọn.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé: “Ẹ máa fi àwọn tí ń bẹ nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n sọ́kàn.” (Hébérù 13:3) Àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gbàgbé àwọn tó wà lẹ́wọ̀n, wọ́n lọ ń wàásù láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì ń “wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè.”—Lúùkù 4:18.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú L’viv, lórílẹ̀-èdè Ukraine
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Mykola rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Vasyl àti Iryna ìyàwó rẹ̀ rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Victor nìyí