Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Mátíù

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Mátíù

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Mátíù

MÁTÍÙ alábàákẹ́gbẹ́ Jésù Kristi, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ agbowó orí, ló kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ tó fani lọ́kàn mọ́ra nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Nǹkan bí ọdún 41 Sànmánì Kristẹni ni Mátíù parí kíkọ ìwé Ìhìn Rere tó ń jẹ́ orúkọ rẹ̀ yìí. Ìwé Ìhìn Rere tí wọ́n tú láti èdè Hébérù sí Gíríìkì yìí ló so Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pọ̀ mọ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn Júù ni Mátíù ní lọ́kàn nígbà tó ń kọ ìwé yìí, Ìhìn Rere tó nítumọ̀ tó sì fani lọ́kàn mọ́ra yìí fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà, Ọmọ Ọlọ́run. Tá a bá fiyè sáwọn ìsọfúnni tó wà nínú ìwé ìhìn rere yìí, á fún ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀, àtàwọn ìlérí Rẹ̀ lókun.—Héb. 4:12.

“ÌJỌBA Ọ̀RUN TI SÚN MỌ́LÉ”

(Mát. 1:1–20:34)

Mátíù tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ò jẹ́ kó lè to àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Bí àpẹẹrẹ, ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè wà lára àwọn ohun tí Mátíù kọ́kọ́ ṣàlàyé nínú ìwé ìhìn rere yìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ti fẹ́rẹ̀ dé ìdajì kí ìwàásù náà tó wáyé.

Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá nítọ̀ọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù, ó fi àwọn Farisí bú, ó sì ṣe onírúurú àkàwé nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó kúrò ní Gálílì ó sì lọ sí “ààlà ilẹ̀ Jùdíà ní òdì-kejì Jọ́dánì.” (Mát. 19:1) Nígbà tí wọ́n wà lójú ọ̀nà, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘A ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, níbí tí wọn yóò ti dá Ọmọ ènìyàn lẹ́bi ikú, àmọ́ a ó gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta.’—Mát. 20:18, 19.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

3:16—Kí ni ṣíṣí tí “ọ̀run ṣí sílẹ̀” nígbà ìrìbọmi Jésù túmọ̀ sí? Ó ṣeé ṣe kéyìí túmọ̀ sí pé Jésù rántí gbogbo ohun tó ti gbé ṣe lọ́run kó tó wá sáyé.

5:21, 22—Ṣé sísọ̀rọ̀ ìṣáátá síni burú ju kéèyàn máa fini sínú lọ? Jésù kìlọ̀ pé ẹni tó bá ń fi arákùnrin rẹ̀ sínú dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kéèyàn máa sọ̀rọ̀ ìṣáátá síni burú jùyẹn lọ, ó lè mú kéèyàn fojú ba ilé ẹjọ́ tó ga ju kóòtù àdúgbò lọ.

5:48—Ṣóòótọ́ la lè jẹ́ ‘pípé gẹ́gẹ́ bí Baba wa ọ̀run ti jẹ́ pípé’? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀ dé ìwọ̀n tí agbára wa mọ. Ọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ni Jésù ń sọ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, ó sì rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti fara wé Ọlọ́run nípa fífi ìfẹ́ pípé tàbí ojúlówó ìfẹ́ hàn. (Mát. 5:43-47) Lọ́nà wo? Nípa nínífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn.

7:16—“Àwọn èso” wo la fi ń dá ìsìn tòótọ́ mọ̀? Kì í ṣe ìwà wa nìkan làwọn èso wọ̀nyí dúró fún o. Wọ́n tún túmọ̀ sáwọn ohun tá a gbà gbọ́, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tá à ń fi sílò.

10:34-38—Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ló ń fa ìpínyà láàárín ìdílé? Ká má ri. Kàkà bẹ́ẹ̀ ohun táwọn mọ̀lẹ́bí wa tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ bá yàn láti ṣe ló máa ń fa ìpínyà. Tí wọn ò bá tẹ́wọ́ gba ìsìn tòótọ́ tí wọ́n sì ń ṣàtakò, kò sí bí ìpínyà ò ṣe ní wáyé láàárín ìdílé.—Lúùkù 12:51-53.

11:2-6—Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jòhánù ti mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà náà nítorí ohùn Ọlọ́run tó gbọ́, kí nìdí tó tún fi bi Jésù pé ṣé òun ni “Ẹni Tí Ń Bọ̀”? Ó ṣeé ṣe kí Jòhánù fẹ́ kí Jésù fẹnu ara ẹ̀ sọ ọ́. Yàtọ̀ síyẹn Jòhánù fẹ́ mọ̀ bóyá “ẹnì kan tí ó yàtọ̀” ṣì ń bọ̀ pẹ̀lú agbára Ìjọba láti ṣe gbogbo ohun táwọn Júù ń fẹ́ fún wọn. Ìdáhùn Jésù sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí fi hàn pé kò sẹ́lòmíì tó ń bọ̀ lẹ́yìn òun.

19:28—Àwọn wo ni “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” tó máa gba ìdájọ́? Wọn kì í ṣe ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Gál. 6:16; Ìṣí. 7:4-8) Ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí làwọn àpọ́sítélì tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ wà, wọn kì í ṣe onídàájọ́ àwọn arákùnrin wọn. Jésù bá wọn “dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan,” ó sì tún mú kí wọ́n jẹ́ “ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 22:28-30; Ìṣí. 5:10) Àwọn tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí yìí ló máa “ṣèdájọ́ ayé.” (1 Kọ́r. 6:2) Nítorí náà, “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” táwọn tó wà lórí ìtẹ́ lókè ọ̀run máa ṣèdájọ́ lé lórí ní láti jẹ́ àwọn èèyàn tí kì í ṣe apá kan ẹgbẹ́ àlùfáà aládé táwọn ẹ̀yà méjìlá máa ń ṣàpẹẹrẹ ní Ọjọ́ Ètùtù.—Léf., orí 16.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

4:1-10. Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì wà lóòótọ́, kì í ṣe èrò burúkú táwọn èèyàn ń hù níwà. Ó máa ń fi “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” dán wa wò. Síbẹ̀, tá a bá ń fàwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò, a ó lè máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.—1 Jòh. 2:16.

5:1-7:29. Má ṣe gbàgbé pé níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì. Jẹ́ ẹni àlàáfíà. Máa yẹra fáwọn èrò tó lè mú kó o hùwà pálapàla. Máa pa àdéhùn mọ́. Tó o bá ń gbàdúrà, máa fohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣáájú àwọn nǹkan tó o nílò. Jẹ́ káwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run jẹ ọ́ lógún. Kọ́kọ́ máa wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀. Má máa ṣe lámèyítọ́. Máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lèèyàn mà lè rí kọ́ nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè yìí o!

9:37, 38. Ẹ jẹ́ ká máa ṣe ohun gbogbo ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà tá à ń gbà pé kí Ọ̀gá ìkórè “rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀,” ká sì máa fìtara ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19, 20.

10:32, 33. Ká má ṣe bẹ̀rù láti sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì.

13:51, 52. Tá a bá ti mọ òkodoro òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó ti di ojúṣe wa láti kọ́ àwọn ẹlòmíì ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ wọ̀nyí.

14:12, 13, 23. Ó yẹ ká máa wà níbi tó dákẹ́ rọ́rọ́ tá a bá fẹ́ ṣàṣàrò, torí irú àwọn àṣàrò bẹ́ẹ̀ ló máa ń nítumọ̀.—Máàkù 6:46; Lúùkù 6:12.

17:20. Ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ kí gbogbo ìṣòro tó dà bí òkè, tó fẹ́ ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, di pẹ̀tẹ́lẹ̀, á sì tún jẹ́ ká lè fara da àdánwò. Kò yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú fífún ìgbàgbọ́ tá a ni nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ lókun.—Máàkù 11:23; Lúùkù 17:6.

18:1-4; 20:20-28. Inú ẹ̀sìn tí wọ́n ti ń ka ipò sí nǹkan ńlá tí wọ́n ti tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dàgbà àti àìpé ẹ̀dá ló jẹ́ kí wọ́n máa ka ipò sí nǹkan bàbàrà. A ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bá a ṣe ń dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè mú wa dẹ́sẹ̀ tá a sì ń fojú tó tọ́ wo àwọn àǹfààní àti ojúṣe wa nínú ìjọ.

‘WỌ́N Á FA ỌMỌ ÈNÌYÀN LÉNI LỌ́WỌ́’

(Mát. 21:1–28:20)

Jésù “gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́” wọ Jerúsálẹ́mù ní Nísàn ọjọ́ kẹsàn-án ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Mát. 21:5) Nígbà tó di ọjọ́ kejì, ó lọ sínú tẹ́ńpìlì láti lé àwọn tó ń tajà jáde. Nígbà tó di Nísàn ọjọ́ kọkànlá, ó kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú tẹ́ńpìlì, ó fàwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí bú, lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé àwọn “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan” fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 24:3) Nísàn ọjọ́ kejìlá ló wá sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ̀ pé ọjọ́ méjì sí i, ìrékọjá yóò wáyé, a ó sì fa Ọmọ ènìyàn léni lọ́wọ́ láti kàn án mọ́gi.”—Mát. 26:1, 2.

Nígbà tó wá di Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, lẹ́yìn tí Jésù dá Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀, èyí tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé nígbà yẹn, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dà á, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n dán an wò, wọ́n sì kàn án mọ́gi; ìgbà tó sì di ọjọ́ kẹta Ọlọ́run jí i dìde. Kí Jésù tó lọ sọ́run lẹ́yìn tó jíǹde, ó pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mát 28:19.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

22:3, 4, 9—Ìgbà wo ni ìkésíni mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti wá síbi àsè ìgbéyàwó náà jáde? Ìkésíni àkọ́kọ́ láti kó ẹgbẹ́ ìyàwó jọ jáde nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wàásù lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, ìkésíni yẹn sì ń bá a lọ títí di ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ìkésíni kejì jáde nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gba ẹ̀mí mímọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìkésíni yẹn sì ń bá a lọ títí di ọdún 36 Sànmánì Kristẹni. Àwọn Júù, àwọn aláwọ̀ṣe Júù àtàwọn ará Samáríà làwọn ìkésíni méjèèjì yìí wà fún. Àmọ́ nígbà tó di ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, ìkésíni kẹta lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wà lójú ọ̀nà tó jáde láti inú ìlú ńlá náà, ìyẹn àwọn Kèfèrí. Balógun ìlú Róòmù kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Kọ̀nílíù ló kọ́kọ́ dáhùn sí ìkésíni tó ṣì ń bá a lọ títí di báyìí.

23:15—Kí nìdí tẹ́ni táwọn Farisí bá sọ di aláwọ̀ṣe fi wà nínú “ewu Gẹ̀hẹ́nà ní ìlọ́po méjì ju” àwọn Farisí fúnra wọn lọ? Àwọn kan táwọn Farisí sọ di aláwọ̀ṣe ti lè jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku. Nígbà tí wọ́n bá tún wá di aláwọ̀ṣe àwọn Farisí wọ̀nyí, ẹ ò rí i pé kàkà kéwé àgbọn wọn dẹ̀ líle lá máa le sí i. Àfàìmọ̀ kí tiwọn máà tún wá le ju tàwọn olùkọ́ wọn tí Ọlọ́run ti kọ̀ sílẹ̀ lọ. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ‘dojú kọ ewu Gẹ̀hẹ́nà’ ní ìlọ́po méjì ju tàwọn Farisí tí wọ́n jẹ́ Júù wọ̀nyí lọ.

27:3-5—Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Júdásì tìtorí rẹ̀ kábàámọ̀? Kò sí ẹ̀rí pé Júdásì ronúpìwàdà látọkànwá. Kàkà kó tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbà ọkùnrin ló lọ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún. Lẹ́yìn tí Júdásì ti dẹ́ṣẹ̀ “tí ń fa ikú wá báni,” ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú, ó sì sọ̀rètí nù. (1 Jòh. 5:16) Àìnírètí ló fa ẹ̀dùn ọkàn fún un, kì í ṣe pé ó ronú pìwà dà látọkànwá.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

21:28-31. Ohun tó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà ni pé ká ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa sọni dọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 24:14; 28:19, 20.

22:37-39. Ẹ ò rí i pé ńṣe làwọn òfin méjì tó tóbi jù lọ wọ̀nyí ṣàkópọ̀ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ káwọn ìránsẹ́ rẹ̀ máa ṣe!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ṣé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú iṣẹ́ ìkórè náà?

[Credit Line]

© 2003 BiblePlaces.com

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Mátíù tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run