Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Tó “Ní Ìtẹ̀sí-ọkàn Títọ́” Ń kọbi Ara Sí Ìwàásù Wa

Àwọn Tó “Ní Ìtẹ̀sí-ọkàn Títọ́” Ń kọbi Ara Sí Ìwàásù Wa

Àwọn Tó “Ní Ìtẹ̀sí-ọkàn Títọ́” Ń kọbi Ara Sí Ìwàásù Wa

“Gbogbo àwọn tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun di onígbàgbọ́.”—ÌṢE 13:48.

1, 2. Irú ọwọ́ wo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù pé a ó wàásù ìhìn rere ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé?

 NÍNÚ ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì, a rí ìtàn nípa báwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe ṣe ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀, pé a ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. (Mát. 24:14) Àwọn Kristẹni tó ń fi ìtara wàásù nígbà yẹn fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn tó ń bọ̀ wá di ọmọ ẹ̀yìn. Ìtara táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi wàásù ní Jerúsálẹ́mù mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, títí kan “ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà,” di ara ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 2:41; 4:4; 6:7.

2 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó lọ wàásù nílẹ̀ òkèèrè náà tún sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn di Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, Fílípì lọ sí Samáríà, ogunlọ́gọ̀ èèyàn sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Ìṣe 8:5-8) Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ rìnrìn àjò lọ wàásù ìhìn rere láwọn ibi púpọ̀, irú àwọn ìlú bíi Kípírọ́sì, àwọn ibì kan ní Éṣíà Kékeré, Makedóníà, ilẹ̀ Gíríìsì àti Ítálì. Ẹgbàágbèje àwọn Júù àtàwọn Gíríìkì ló di onígbàgbọ́ láwọn ìlú tí Pọ́ọ̀lù ti wàásù. (Ìṣe 14:1; 16:5; 17:4) Títù náà ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní pẹrẹu nílùú Kírétè. (Títù 1:5) Pétérù pẹ̀lú ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní Bábílónì. Ìgbà tó sì máa fi kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ọdún 62 sí 64 Sànmánì Kristẹni, iṣẹ́ ìwàásù ti gbilẹ̀ ní Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà, Éṣíà àti Bítíníà. (1 Pét. 1:1; 5:13) Bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń lọ nígbà náà wúni lórí gan-an ni! Àní ìtara táwọn Kristẹni ayé ọjọ́un fi ń wàásù pọ̀ gan-an débi táwọn ọ̀tá wọn fi sọ pé wọ́n ti “sojú ilẹ̀ ayé tí a ń gbé dé.”—Ìṣe 17:6; 28:22.

3. Àṣeyọrí wo làwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn lóde òní, báwo nìyẹn sì ṣe rí lára rẹ?

3 Lóde òní pẹ̀lú, ìjọ Kristẹni ti gbèrú gan-an ni. Ǹjẹ́ orí rẹ kì í wú tó o bá ka ìròyìn ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o sì rí báwọn èèyàn ṣe ń ya wá sínú òtítọ́ jákèjádò ayé? Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn láti mọ̀ pé lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2007, àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó tó ọ̀ọ́dúnrún ọ̀kẹ́, ẹgbàá mẹ́tàlélógóje àti okòó lé lẹ́gbẹ̀ta ó dín méjì [6,286,618]? Ìyẹn nìkan kọ́ o, nínú iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi léṣìí, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọ̀kẹ́ làwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn wọ̀nyí wá síbẹ̀ nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere. Èyí tó fi hàn pé iṣẹ́ ṣì ń bẹ fún wa láti ṣe.

4. Àwọn wo ló ń kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run?

4 “Gbogbo àwọn tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” ń kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run lóde òní gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 13:48) Jèhófà ló ń fa irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wá sínú ètò rẹ̀. (Ka Hágáì 2:7.) Kí ló wá yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Kristẹni, ká bàa lè ṣe iṣẹ́ ìkórè yìí bó ṣe yẹ?

Wàásù Láìṣojúsàájú

5. Irú àwọn èèyàn wo ló ń rí ojú rere Jèhófà?

5 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní mọ̀ pé, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Àmọ́, kéèyàn tó lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jòh. 3:16, 36) Ìfẹ́ Jèhófà sì ni pé kí a “gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:3, 4.

6. Kí ni kò ní bójú mu káwọn oníwàásù ìhìn rere ṣe, kí sì nìdí rẹ̀?

6 Nítorí náà, kò ní bójú mu rárá pé kí oníwàásù ìhìn rere fi ẹ̀yà àwọn èèyàn, ipò wọn, ìrísí wọn, ẹ̀sìn wọn tàbí àwọn nǹkan míì tó mú wọn yàtọ̀ láwùjọ pinnu ìhà tí wọ́n máa kọ sí ìhìn rere. Rò ó wò ná: Ǹjẹ́ inú rẹ kò máa dùn pé ẹni tó kọ́kọ́ wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọ kò gbójú fò ọ́? Lọ́nà kan náà, kò yẹ ká fi ìhìn rere tó ń gbani là du ẹnikẹ́ni tó bá yẹ kó gbọ́.—Ka Mátíù 7:12.

7. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣèdájọ́ àwọn tá à ń wàásù fún?

7 Jèhófà ti gbé ìdájọ́ lé Jésù lọ́wọ́, nítorí náà a ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni. Bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn, níwọ̀n bí a kò ti dà bí Jésù tó lè mọ èrò ọkàn èèyàn. ‘Ohun tó hàn lásán sí ojú wa,’ tàbí “ohun tí etí [wa] wulẹ̀ gbọ́” nìkan la fi ń dáni lẹ́jọ́.—Aísá. 11:1-5; 2 Tím. 4:1.

8, 9. (a) Irú èèyàn wo ni Sọ́ọ̀lù kó tó di Kristẹni? (b) Ẹ̀kọ́ wo ló yẹ ká kọ́ látinú bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe di Kristẹni?

8 Onírúurú èèyàn ló ti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Àpẹẹrẹ pàtàkì kan ni ti Sọ́ọ̀lù ará Tásù tó dẹni tá a wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Alátakò àwọn Kristẹni paraku ni Sọ́ọ̀lù yìí nígbà tó ṣì jẹ́ Farisí. Èrò rẹ̀ ni pé kì í ṣe Jèhófà ni ìjọ Kristẹni ń sìn, ìyẹn ló mú kó máa ṣenúnibíni sí wọn. (Gál. 1:13) Kò sẹ́ni tó máa rò pé Sọ́ọ̀lù lè di Kristẹni láéláé. Àmọ́ Jésù rí i pé, kì í ṣe pé Sọ́ọ̀lù kúkú jẹ́ èèyàn burúkú, ó sì wá gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé e lọ́wọ́. Bí Sọ́ọ̀lù ṣe wá di ọ̀kan nínú ọmọ ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó jẹ́ akíkanjú àti onítara jù lọ nìyẹn.

9 Kí la rí kọ́ látinú bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe di Kristẹni? Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn kan wà ní ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù tí wọn kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé wọn kò ní lè di Kristẹni tòótọ́, àmọ́, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú wa láti máa wá bá a ṣe máa bá wọn sọ̀rọ̀. Nígbà míì, ẹni téèyàn ò tiẹ̀ rokàn sí rárá pé ó lè gbọ́ ìwàásù máa ń tẹ́tí gbọ́ wa. Iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ ni pé ká máa wàásù fún gbogbo èèyàn “láìdábọ̀.”—Ka Ìṣe 5:42.

Ìbùkún Ń Bẹ Fáwọn Tó Bá Ń Wàásù “Láìdábọ̀”

10. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí ìrísí àwọn tó dà bí òǹrorò èèyàn mú ká má ṣe wàásù fún wọn? Sọ ìrírí kan tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè yín.

10 Ìrísí èèyàn lè tàn wá jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni ọ̀gbẹ́ni Ignacio a wà lórílẹ̀-èdè kan ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òǹrorò ẹ̀dá táwọn èèyàn ń bẹ̀rù gan-an ló jẹ́ nígbà náà. Àní òun lagbowó-ipá táwọn ẹlẹ́wọ̀n tó bá ta nǹkan fáwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi tiwọn máa ń lò láti gbowó lọ́wọ́ àwọn tí ò bá tètè sanwó wọn. Àmọ́ bí Ignacio tó jẹ́ òǹrorò àti jàǹdùkú yìí ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tó sì ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, ó dèèyàn jẹ́jẹ́. Lóòótọ́, kò sẹ́ni tó ń lò ó láti gbowó ipá mọ́, ṣùgbọ́n ó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ àtẹ̀mí Ọlọ́run ṣe sọ ọ́ di ọmọlúwàbí. Inú rẹ̀ sì tún ń dùn pé àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n sapá láti kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ kò wo ti ìwà òun mọ́ òun lára.

11. Kí nìdí tá a fi máa ń padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a ti wàásù fún?

11 Ọ̀kan lára àwọn ìdí tá a fi ń padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a ti wàásù fún tẹ́lẹ̀ ni pé ipò wọn àti ìwà wọn lè ti yí padà, a sì ti rí tàwọn tó yí padà lóòótọ́. Àìsàn lè ti ṣe àwọn kan, iṣẹ́ lè ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn míì tàbí kéèyàn wọn kan ti kú lẹ́yìn ìgbà tá a dé ọ̀dọ̀ wọn. (Ka Oníwàásù 9:11.) Àwọn ìṣòro inú ayé lè mú káwọn èèyàn máa ronú nípa bí ọjọ́ ọ̀la wọn ṣe máa rí. Ìyẹn sì lè mú kẹ́ni tí kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa tàbí tó máa ń ta kò wá tẹ́lẹ̀ fara balẹ̀ gbọ́ wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ní gbogbo ìgbà tá a bá rí àǹfààní rẹ̀.

12. Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tá à ń wàásù fún, kí sì nìdí?

12 Ó jẹ́ àṣà àwa èèyàn láti kàn gbà pé irú ìwà kan lẹ́nì kan máa ní, wọ́n a sì ṣèdájọ́ onítọ̀hún láìjẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n dáadáa. Àmọ́ ní ti Jèhófà, ohun tí kálukú wa jẹ́ ló ń rí. Ó rí àwọn ànímọ́ rere ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Ka 1 Sámúẹ́lì 16:7.) Ohun tó yẹ káwa náà rí i pé à ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nìyẹn. Ọ̀pọ̀ ìrírí ló ti fi hàn pé tá a bá ní èrò tó dáa sí gbogbo àwọn tá à ń wàásù fún, ó máa ń yọrí sí rere.

13, 14. (a) Kí nìdí tí aṣáájú-ọ̀nà kan ò fi wá obìnrin kan tó bá pàdé lóde ẹ̀rí lọ mọ́? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa?

13 Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Sandra ń wàásù látilé-délé ní erékùṣù kan ní ilẹ̀ Caribbean nígbà tó pàdé Ruth tó ti kira bọ ṣíṣe àríyá aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti fi Ruth jẹ ọbabìnrin àríyá aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ ti orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó fara balẹ̀ gbọ́ ìwàásù Sandra gan-an ni, wọ́n sì jọ ṣàdéhùn bí wọ́n ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sandra sọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Bí mo ṣe wọnú pálọ̀ Ruth, mo rí fọ́tò rẹ̀ ńlá kan tòun ti aṣọ aláràbarà tó fi ṣe àríyá aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀, mo sì tún rí àwọn ife ẹ̀yẹ tó ti gbà. Mo gbà lọ́kàn mi pé ẹni tó gbajúmọ̀ tó báyìí, tó sì ti kira bọ àríyá tó bẹ́ẹ̀ kò lè nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́. Bí mi ò ṣe wá a lọ mọ́ nìyẹn.”

14 Nígbà díẹ̀ lẹ́yìn náà, Ruth wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí ìpàdé sì parí ó bi Sandra pé, “Kí ló dé tó ò wá bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ mọ́?” Sandra bẹ̀ ẹ́ pé kó máà bínú, ó sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà padà. Òye òtítọ́ tètè yé Ruth gan-an, ó sì kó àwọn fọ́tò ibi tó ti ń ṣàríyà kúrò nílẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kópa nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìjọ, ó sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Sandra pàápàá wá rí i pé èrò tó mú kóun má ṣe wá Ruth lọ mọ́ lákọ̀ọ́kọ́ yẹn kò tọ̀nà.

15, 16. (a) Àṣeyọrí wo ni akéde kan ṣe nígbà tó wàásù fún àna rẹ̀? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí irú èèyàn tí ìbátan wa kan jẹ́ dí wa lọ́wọ́ láti wàásù fún un?

15 Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wàásù fáwọn èèyàn wọn tó dà bíi pé wọn ò lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti rí i pé ó yọrí sí rere. Àpẹẹrẹ kan ni ti arábìnrin wa kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Joyce. Látìgbà tí ọkọ àbúrò rẹ̀ tẹlẹ̀ ti wà ní ọ̀dọ́mọdé ló ti ń jáde lẹ́wọ̀n tó tún ń wẹ̀wọ̀n padà. Joyce ní: “Àwọn èèyàn tiẹ̀ sọ pé ayé ẹ̀ ti bà jẹ́ pátápátá, nítorí pé ìwà bíi ká kó oògùn jẹ, olè jíjà àti ọ̀pọ̀ ìwàkiwà míì ló kún ọwọ́ ẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ọdún mẹ́tàdínlógójì ni mo fi wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún un láìjẹ́ kó sú mi.” Bí Joyce ṣe fi sùúrù ran àna rẹ̀ tẹ́lẹ̀ yìí lọ́wọ́ yọrí sí rere, torí pé nígbà tó yá, ó gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì yíwà padà pátápátá. Láìpẹ́ yìí, nígbà tí àna Joyce yẹn ti di ẹni àádọ́ta ọdún, ó ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè kan ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Joyce sọ pé: “Omijé ayọ̀ bọ́ lójú mi. Inú mi dùn pé mi ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sú mi!”

16 O lè lọ́ tìkọ̀ láti wàásù ìhìn rere fáwọn ìbátan rẹ kan nítorí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́. Àmọ́ Joyce ò lọ́ tìkọ̀ láti wàásù fún àna rẹ̀ yìí. Kò ṣáà séèyàn tó mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kejì. Ó lè jẹ́ pé onítọ̀hún ń fi tọkàntọkàn wá ẹ̀kọ́ òtítọ́. Nítorí náà, má ṣaláì jẹ́ kó mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà.—Ka Òwe 3:27.

Ohun Èlò Tó Wúlò Gan-an Láti Fi Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

17, 18. (a) Kí ni ìròyìn láti onírúurú orílẹ̀-èdè kárí ayé fi hàn nípa bí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ṣe wúlò tó? (b) Ìrírí tó dùn mọ́ni wo lo ti ní bó o ṣe ń fìwé yìí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?

17 Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti onírúurú orílẹ̀-èdè kárí ayé fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n ní ọkàn rere ló fẹ́ràn ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tá a fi ń bá àwọn èèyàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Penni bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé yìí ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Méjì lára àwọn tó ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ àgbàlagbà tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì lójú méjèèjì. Penni ò mọ ohun tó máa jẹ́ ìṣarasíhùwà wọn sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Ṣùgbọ́n ohun tó wá padà sọ rèé: “Ọ̀nà tó yéni, tó mọ́gbọ́n dání, tó sì ṣe ṣókí tí wọ́n gbà ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú ìwé náà mú kó rọrùn fún wọn láti gbà pé òtítọ́ lohun tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láìsí àríyànjiyàn tàbí ìdààmú kankan.”

18 Akéde kan lórílẹ̀-èdè Britain tó ń jẹ́ Pat bẹ̀rẹ̀ sí í bá obìnrin kan tí ogun lé kúrò lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Obìnrin náà sá kúrò lórílẹ̀-èdè rẹ̀ lẹ́yìn táwọn sójà ọlọ̀tẹ̀ ti kó àwọn ọmọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ lọ tí ò sì rí wọn mọ́. Àwọn èèyàn fòòró ẹ̀mí rẹ̀, wọ́n jólé ẹ̀, àwọn ọkùnrin kan sì tún para pọ̀ wá fipá bá a lò pọ̀. Gbogbo èyí mú kí ayé sú u, ó sì gbìyànjú láti pa ara rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú kó dẹni tó nírètí. Pat sọ pé: “Àlàyé àti àpèjúwe tó yéni yékéyéké tí wọ́n lò nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ràn án lọ́wọ́ gan-an.” Òye òtítọ́ tètè yé obìnrin náà, ó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ó sì lóun fẹ́ ṣèrìbọmi ní àpéjọ tí wọ́n máa ṣe lẹ́yìn náà. Ẹ ò rí i pé ayọ̀ téèyàn máa ń ní pọ̀ gan-an ni téèyàn bá ran àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ lọ́wọ́ tí wọ́n sì dẹni tó mọyì ìrètí tó wà nínú Ìwé Mímọ́!

“Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí A Juwọ́ Sílẹ̀ ní Ṣíṣe Ohun Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀”

19. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù wa fi jẹ́ kánjúkánjú?

19 Bílẹ̀ ṣe ń ṣú tílẹ̀ ń mọ́ ni iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ túbọ̀ ń di kánjúkánjú sí i. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ ló ń kọbi ara sí ìwàásù wa lọ́dọọdún. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé,” tó fi hàn pé ńṣe làwọn tí kò tíì mọ Ọlọ́run àtohun tó pinnu láti ṣe “ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sínú ìfikúpa.”—Sef. 1:14; Òwe 24:11.

20. Kí ni kálukú wa gbọ́dọ̀ pinnu láti ṣe?

20 A ṣì lè ṣèrànlọ́wọ́ fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ká tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, a ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó “ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:42) Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn nípa títẹramọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa láìfi ìṣòro pè, nípa kíkọbi ara sí “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” wa, àti nípa wíwàásù fún gbogbo èèyàn láìṣojúsàájú. “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” torí pé tá a bá tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa, a ó rí ojú rere Ọlọ́run lọ́nà àgbàyanu.—2 Tím. 4:2; ka Gálátíà 6:9.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Àwọn wo ló ń kọbi ara sí ìhìn rere?

• Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dédé máa pinnu ìhà tẹ́nì kan máa kọ sí ìhìn rere láìtíì wàásù fún ẹni náà?

• Àwọn àṣeyọrí wo la ti ń ṣe nínú lílo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ ló ń kọbi ara sí ìwàásù wa

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe dẹni tó yí padà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn oníwàásù ìhìn rere kì í dédé pinnu ìhà tẹ́nì kan máa kọ sí ìhìn rere láìwàásù fún ẹni náà