Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ

Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ

Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ

“Wàásù ọ̀rọ̀ náà, . . . fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”—2 TÍM. 4:2.

1. Àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àpẹẹrẹ wo ló sì fi lélẹ̀ fún wọn?

 BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu láti fi wo àwọn èèyàn sàn nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ohun táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí ni olùkọ́, kì í ṣe oníwòsàn tàbí oníṣẹ́ ìyanu. (Máàkù 12:19; 13:1) Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù sí Jésù ni kíkéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, bó sì ṣe rí fáwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí náà nìyẹn. Iṣẹ́ tí Jésù gbé lé àwa Kristẹni lọ́wọ́ ni pé ká máa bá iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn nìṣó nípa kíkọ́ àwọn èèyàn láti máa pa gbogbo ohun tó pa láṣẹ mọ́.—Mát. 28:19, 20.

2. Ká tó lè kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ ìwàásù wa kí la ní láti ṣe?

2 Ká bàa lè kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ yìí, ìgbà gbogbo la máa ń wá bá a ṣe máa mú kí ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni sunwọ̀n sí i. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, ó tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kó mú ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni sunwọ̀n sí i. Ó ní: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tím. 4:16) Kì í ṣe pé kéèyàn ṣáà ti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí o. Kristẹni òjíṣẹ́ tó bá mọ̀ọ̀yàn kọ́ máa ń kọ́ni lọ́nà tó ń wọni lọ́kàn ṣinṣin èyí á sì mú kí àwọn tó ń kọ́ ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nígbèésí ayé wọn. Ìyẹn là ń pè ní ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Báwo la ṣe lè lo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” tá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn?—2 Tím. 4:2.

Bó O Ṣe Lè Dẹni Tó Ń Lo “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́”

3, 4. (a) Báwo la ṣe lè dẹni tó ń lo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́”? (b) Báwo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń mú ká jáfáfá nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́?

3 Ìwé atúmọ̀ èdè kan fi hàn pé kéèyàn tó lè mọ bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ “ọnà” onítọ̀hún ní láti kọ́kọ́ “kẹ́kọ̀ọ́, kó ṣe ìdánrawò kó sì lákìíyèsí.” Ká tó lè jáfáfá nínú kíkọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ fiyè sáwọn ohun mẹ́ta tá a mẹ́nu kàn yìí. Ohun tó lè mú ká ní òye kíkún nípa àwọn nǹkan tá à ń kọ́ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ wọn tàdúràtàdúrà. (Ka Sáàmù 119:27, 34.) Tá a bá tún ń kíyè sí báwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá ṣe ń kọ́ni, èyí á mú ká kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, ká sì máa kọ́ni bíi ti wọn. Bákan náà, ká máa sapá gidigidi láti fàwọn ohun tá à ń kọ́ dánra wò, èyí á mú kí ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni máa sunwọ̀n sí i.—Lúùkù 6:40; 1 Tím. 4:13-15.

4 Jèhófà ni Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa. Ó ń lo ètò rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé láti fi tọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù. (Aísá. 30:20, 21) Ìdí rèé tí ètò Ọlọ́run fi ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa ń wáyé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí tá à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ńṣe la ṣètò ilé ẹ̀kọ́ yìí láti ran àwọn tó bá ń kópa nínú rẹ̀ lọ́wọ́ láti di ọ̀jáfáfá akéde Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì ni lájorí ìwé tá à ń lò nílé ẹ̀kọ́ yìí. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí jẹ́ ká mọ ohun tá a máa fi kọ́ àwọn èèyàn. Ó tún jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà tó múná dóko tó sì bójú mu tá a lè gbà kọ́ni. Ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run yìí, ìgbà gbogbo la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tó lè mú ká di olùkọ́ tó jáfáfá ni pé ká máa gbé àwọn ẹ̀kọ́ wa ka orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká máa lo àwọn ìbéèrè lọ́nà tó jáfáfá, ká máa kọ́ni lọ́nà tó rọrùn ká sì máa fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sáwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, a óò wá jíròrò bá a ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa fi wọ ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́kàn.

Orí Bíbélì Ni Kó O Gbé Ẹ̀kọ́ Rẹ Kà

5. Orí kí ló yẹ ká gbé ẹ̀kọ́ wa kà, kí sì nìdí?

5 Orí Ìwé Mímọ́ ni Jésù, olùkọ́ tó ju gbogbo olùkọ́ lọ láyé gbé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kà. (Mát. 21:13; Jòh. 6:45; 8:17) Jésù ò fi ẹ̀kọ́ ara rẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn, ohun tó gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ ló fi kọ́ni. (Jòh. 7:16-18) Àpẹẹrẹ Jésù làwa náà ń tẹ̀ lé. Nítorí náà, yálà à ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí à ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ wa gbọ́dọ̀ dá lé. (2 Tím. 3:16, 17) Kò sí bá a ṣe lè gbọ́n ká sì mọ̀rọ̀ sọ tó tọ́rọ̀ wa á fi múná dóko, táá sì lágbára bíi ti Ìwé Mímọ́. A ò gbọ́dọ̀ kóyán ohun tó wà nínú Bíbélì kéré rárá. Ohun yòówù tá a bá fẹ́ kí òye rẹ̀ yé ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tó dáa jù ni pé ká jẹ́ kóun fúnra rẹ̀ ka ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀.—Ka Hébérù 4:12.

6. Báwo ni olùkọ́ kan ṣe lè rí i dájú pé akẹ́kọ̀ọ́ òun lóye ẹ̀kọ́ tó ń kọ́?

6 Èyí ò wá túmọ̀ sí pé kí Kristẹni tó jẹ́ olùkọ́ má ṣe múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fẹ́ ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn sílẹ̀ rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó fara balẹ̀ ronú ṣáájú, kó sì pinnu àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí òun tàbí ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa kà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ohun tó sábà máa ń dáa jù ni pé kí á ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti àwọn ohun tá a gbà gbọ́ lẹ́yìn. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí olùkọ́ náà rí i pé akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lóye gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá kà.—1 Kọ́r. 14:8, 9.

Lo Àwọn Ìbéèrè Tó Múná Dóko

7. Kí nìdí tí lílo àwọn ìbéèrè fi jẹ́ ọ̀nà tó múná dóko láti gbà kọ́ni?

7 Bí olùkọ́ kan bá ń lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko, á mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ronú jinlẹ̀ á sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ olùkọ́ náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Nítorí náà, dípò tí wàá fi máa ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, sọ pé kó ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹ. Nígbà míì kẹ̀, ó tún lè pọn dandan pé kó o béèrè àfikún ìbéèrè kan tàbí àwọn ìbéèrè mélòó kan kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè ní òye tó tọ̀nà nípa ohun tó ń kọ́. Tó o bá ń lo ìbéèrè lọ́nà yìí, ńṣe lò ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lóye àwọn ìdí táwọn ohun tó ń kọ́ fi rí bẹ́ẹ̀, èyí á sì tún mú kóun fúnra rẹ̀ gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé ni wọ́n.—Mát. 17:24-26; Lúùkù 10:36, 37.

8. Báwo la ṣe lè fòye mọ ohun tó jẹ́ èrò akẹ́kọ̀ọ́ kan?

8 Ìbéèrè àti ìdáhùn la ṣe àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Kò sí àní-àní pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n máa ń tètè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tá a bá béèrè nínú àwọn ìpínrọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Síbẹ̀, olùkọ́ tó mòye kò ní fi mọ sórí pé kí ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣáà ti dáhùn lọ́nà tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, akẹ́kọ̀ọ́ kan lè ṣàlàyé tó tọ̀nà lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa àgbèrè. (1 Kọ́r. 6:18) Àmọ́, tí olùkọ́ náà bá fọgbọ́n béèrè ìbéèrè láti fi mọ èrò akẹ́kọ̀ọ́ náà, èyí lè mú kí olùkọ́ náà mọ èrò akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nípa ohun tó ń kọ́. Olùkọ́ náà lè bi akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láwọn ìbéèrè bíi: “Kí nìdí tí Bíbélì fi lòdì sí ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni? Kí ni èrò rẹ nípa ohun tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ yìí? Ǹjẹ́ o rò pé àǹfààní kankan wà nínú títẹ̀lé àwọn ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run fún wa?” Ìdáhùn akẹ́kọ̀ọ́ náà sáwọn ìbéèrè yìí lè jẹ́ kó o mọ ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀ gan-an.—Ka Mátíù 16:13-17.

Kọ́ni Lọ́nà Tó Máa Tètè Yéni

9. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́?

9 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló rọrùn láti lóye. Ó lè jẹ́ pé wọ́n ti ṣi àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n ti kọ́ wọn láwọn ilé ìjọsìn wọn. Ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ni pé ká kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó máa fi tètè yé wọn. Olùkọ́ tó mòye máa ń kọ́ni lọ́nà tó lè tètè yéni, tó ṣe kedere, tó sì péye. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí, kò ní jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣòro láti lóye fáwọn èèyàn. Má ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí kò pọn dandan. Kì í ṣe dandan pé ká ṣàlàyé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a bá kà. Kìkì ohun tó máa jẹ́ kí kókó tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò ṣe kedere nìkan ni kó o sọ̀rọ̀ lé lórí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́ náà á máa lóye àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ tó túbọ̀ jinlẹ̀.—Héb. 5:13, 14.

10. Àwọn nǹkan wo ló máa pinnu bí ibi tá a máa kà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣe máa pọ̀ tó?

10 Báwo ni ibi tẹ́ ẹ máa kà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe yẹ kó pọ̀ tó? Ó gba ìfòyemọ̀ ká tó lè mọ èyí. Ohun kan ni pé, ó níbi tágbára olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ mọ, ipò kálukú wọn sì yàtọ̀ síra. Ṣùgbọ́n, ó yẹ ká máa rántí pé ohun tó jẹ wá lógún gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ni pé ká ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ ká fún akẹ́kọ̀ọ́ kan ní àkókò tó pọ̀ tó láti ka àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó lóye rẹ̀, kó sì fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ náà. Kò yẹ kí á kà ju ohun tí òye akẹ́kọ̀ọ́ náà lè gbé. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ká máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà falẹ̀ o. Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti lóye kókó kan, ńṣe ni ká máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.—Kól. 2:6, 7.

11. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa ọ̀nà tá a lè gbà kọ́ni?

11 Ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi wàásù ìhìn rere fáwọn ẹni tuntun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀mọ̀wé ni, kò lo àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà nígbà tó ń wàásù fáwọn èèyàn. (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:1, 2.) Bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ṣe rọrùn láti lóye ń fa àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ mọ́ra, ó sì ń tù wọ́n lára. Kò dìgbà téèyàn bá jẹ́ ọ̀mọ̀wé kó tó lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́.—Mát. 11:25; Ìṣe 4:13; 1 Kọ́r. 1:26, 27.

Mú Káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Mọyì Ohun Tí Wọ́n Ń Kọ́

12, 13. Kí ló lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ kan máa fohun tó ń kọ́ ṣèwà hù? Ṣàpèjúwe.

12 Kí ẹ̀kọ́ wa tó lè múná dóko, ó ní láti wọ akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́kàn. A ní láti jẹ́ kó rí bọ́rọ̀ náà ṣe kàn án, bó ṣe máa ṣe é láǹfààní àti bí ìgbé ayé rẹ̀ ṣe máa dèyí tó sunwọ̀n sí i tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́.—Aísá. 48:17, 18.

13 Bí àpẹẹrẹ, bóyá Hébérù 10:24, 25 lẹ̀ ń gbé yẹ̀ wò, èyí tó gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká máa pé jọ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ká lè gba ìṣírí látinú Ìwé Mímọ́, ká sì lè gbádùn ìfararora onífẹ̀ẹ́. Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ò bá tíì máa wá sáwọn ìpàdé ìjọ, a lè ṣàlàyé ní ṣókí lórí bá a ṣe ṣètò àwọn ìpàdé wa àtohun tá a máa jíròrò ní ọ̀kan lára irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀. A lè tún ṣàlàyé pé àwọn ìpàdé ìjọ yìí jẹ́ ara àwọn ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn ìpàdé náà máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an. Tá a bá ti ṣe àwọn àlàyé wọ̀nyí, a lè wá fi ìpàdé lọ akẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó yẹ kó hàn gbangba pé torí pé ó wù ú látọkànwá láti ṣègbọràn sí Jèhófà ló ṣe ń tẹ̀ lé àwọn àṣẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́, kì í ṣe torí kó lè tẹ́ ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́rùn.—Gál. 6:4, 5

14, 15. (a) Kí làwọn nǹkan tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè mọ̀ nípa Jèhófà? (b) Báwo ni mímọ̀ tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣe lè ṣe é láǹfààní?

14 Olórí àǹfààní táwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa máa jẹ tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú rẹ̀ ni pé, wọ́n á dẹni tó mọ Jèhófà dáadáa wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. (Aísá. 42:8) Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́ àti Ẹlẹ́dàá ayé òun ìsálú ọ̀run, ó tún jẹ́ káwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń sìn ín mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tó lè ṣe. (Ka Ẹ́kísódù 34:6, 7.) Nígbà tí Mósè fẹ́ kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lóko ẹrú ní Íjíbítì, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tóun jẹ́, ó ní: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kís. 3:13-15) Èyí fi hàn pé Jèhófà yóò di ohunkóhun tó bá yẹ láti lè ṣe àwọn ohun tó pinnu láti ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀. Nípa báyìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá rí i pé Jèhófà di Olùgbàlà, Jagunjagun, Olùpèsè, Ẹni tó ń mú ìlérí ṣẹ tó sì tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì.—Ẹ́kís. 15:2, 3; 16:2-5; Jóṣ. 23:14.

15 Lóòótọ́, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè má rí i kí Jèhófà darí ìgbésí ayé wọn lọ́nà àrà bó ṣe ṣe fún Mósè. Àmọ́, bí ìgbàgbọ́ wọn bá ṣe ń lágbára sí i, tí wọ́n túbọ̀ ń mọyì àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́, tí wọ́n sì ń fi wọ́n ṣèwà hù, ó dájú pé wọ́n á rídìí tó fi yẹ káwọn gbára lé Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà, ọgbọ́n àti ìgboyà. Bí wọ́n ti ń ṣe èyí, àwọn náà á wá rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́gbọ́n Agbaninímọ̀ràn tó ṣeé fọkàn tán, Olùdáàbòbò àti Olùpèsè tó ń fẹ̀mí ọ̀làwọ́ fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò.—Sm. 55:22; 63:7; Òwe 3:5, 6.

Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn Sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ

16. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kò dìgbà téèyàn bá láwọn ẹ̀bùn àbímọ́ni kan kó tó lè máa kọ́ni lọ́nà tó múná dóko?

16 Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ọ̀nà tó o gbà ń kọ́ni kò fi bẹ́ẹ̀ múná dóko, má mikàn. Jèhófà àti Jésù ló ń bójú tó ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe kárí ayé lóde òní. (Ìṣe 1:7, 8; Ìṣí. 14:6) Wọ́n lè bù kún ìsapá wa débi pé ọ̀rọ̀ tá a bá sọ yóò ta gbòǹgbò lọ́kàn àwọn ọlọ́kàn rere. (Jòh. 6:44) Tí olùkọ́ kan bá nífẹ̀ẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ látọkànwá, ìyẹn lè mú kó má hàn rárá pé olùkọ́ náà ò láwọn ẹ̀bùn àbímọ́ni kan tó bá dọ̀rọ̀ ká kọ́ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣe ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀.—Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.

17. Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa?

17 Àwa náà lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan látọkànwá tá a bá rí i dájú pé a mọ̀ ọ́n dáadáa. Bá a ṣe ń ṣàlàyé àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ fún un, a lè tipa bẹ́ẹ̀ mọ irú ìgbésí ayé tó ń gbé. A lè rí i pé ó ti ń fàwọn nǹkan kan tó ti kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù. Ó sì lè jẹ́ pé ó yẹ kó ṣì ṣàtúnṣe láwọn apá ibòmíì. Tá a bá jẹ́ kó rí bí ohun tá à ń kọ́ ọ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe kàn án, a lè tipa bẹ́ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́ láti dọmọ ẹ̀yìn Kristi tòótọ́.

18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbàdúrà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ wa, ká sì fọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú àdúrà?

18 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a lè gbàdúrà pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ká sì máa fọ̀rọ̀ wọn sínú àdúrà. Ó yẹ kó hàn gbangba sí akẹ́kọ̀ọ́ náà pé ohun tó jẹ wá lógún ni pé a fẹ́ ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ dáadáa, kó sún mọ́ ọn, kó sì jàǹfààní ìtọ́sọ́nà Rẹ̀. (Ka Sáàmù 25:4, 5.) Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ bó ṣe ń sapá láti fàwọn ohun tó ń kọ́ sílò, èyí á mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà.” (Ják. 1:22) Bó sì ṣe ń gbọ́ tá à ń gbàdúrà àtọkànwá bẹ́ẹ̀, òun náà á dẹni tó mọ bá a ṣe ń gbàdúrà. Ẹ ò rí i pé nǹkan ayọ̀ gbáà ló jẹ́ tá a bá ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ tí wọ́n dẹni tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà!

19. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

19 Ó wú wa lórí gan-an bá a ṣe mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ kárí ayé túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú nínú lílo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” yìí. Ìdí tá a sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ ran àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tó ń pa gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ mọ́. Kí ni àbájáde iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe? A óò rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni dẹni tó ń lo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́”?

• Báwo la ṣe lè mú kí ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni túbọ̀ múná dóko?

• Kí ló lè mú kó má hàn pé a ò láwọn ẹ̀bùn àbímọ́ni kan tó bá dọ̀rọ̀ ká kọ́ni?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣé o máa ń kópa nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ní kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ka Bíbélì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Máa gbàdúrà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ kó o sì máa fọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú àdúrà