Ilé Ìṣọ́ Ẹ̀dà Tuntun Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
Ilé Ìṣọ́ Ẹ̀dà Tuntun Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
ÌWÉ ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó ò ń kà yìí ni àkọ́kọ́ lára ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. A óò fẹ́ láti ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ohun tuntun tó máa máa jáde nínú ìwé ìròyìn yìí tá à ń tẹ̀ jáde lákọ̀tun báyìí.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọn là ń tẹ ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí fún. Ẹ̀ẹ̀kan lóṣù la ó máa tẹ̀ ẹ́ jáde, àpilẹ̀kọ mẹ́rin tàbí márùn-ún tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ni yóò sì máa wà nínú rẹ̀. Ara èèpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn náà la ó máa kọ àkòrí àwọn àpilẹ̀kọ tá ó máa kẹ́kọ̀ọ́ àti ọjọ́ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ wọn sí. Nítorí pé a ò ní máa lo ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lóde ẹ̀rí, a ò ní máa ya oríṣiríṣi àwòrán sára èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ bíi ti ẹ̀dà tá ó máa fi sóde.
A ó máa kọ àlàyé ṣókí tí ń lani lọ́yẹ̀ sójú ìwé kejì ìwé ìròyìn náà. Àlàyé náà á máa sọ ohun tí àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan tàbí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ máa dá lé. Àkòrí àwọn àpilẹ̀kọ míì tó wà nínú ìwé ìròyìn náà á tún máa wà lójú ìwé yìí pẹ̀lú. Èyí á máa ran àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́wọ́ gan-an bí wọ́n ṣe ń múra sílẹ̀ láti jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú ìjọ lọ́nà tó máa gbà yé wọn yékéyéké.
Wàá kíyè sí i pé àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ò gùn tó ti tẹ́lẹ̀. Nítorí èyí, àkókò á túbọ̀ wà fún ṣíṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kín kókó pàtàkì inú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá à ń jíròrò lẹ́yìn. A fìfẹ́ gbà yín níyànjú pé tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kẹ́ ẹ máa ka gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá ò bá fa ọ̀rọ̀ inú wọn yọ. A tiẹ̀ kọ “kà á” ṣáájú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá ò fa ọ̀rọ̀ inú wọn yọ, ẹ kà wọ́n, kí ẹ sì tún jíròrò wọn nígbà tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Ẹ tún lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì bí àkókò bá ṣe wà sí. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ kan, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wà tá a kọ “fèrò yìí wé” ṣáájú wọn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé irú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bẹ́ẹ̀ ò kín kókó pàtàkì èyíkéyìí lẹ́yìn nínú ìpínrọ̀ náà, gbogbo ìgbà kọ́ la ó máa kà wọ́n nípàdé ìjọ. Síbẹ̀, irú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a bá kọ “fèrò yìí wé” ṣáájú wọn bẹ́ẹ̀ máa ń ní àfikún ìṣọfúnni tó lárinrin, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n tan mọ́ kókó tá à ń jíròrò lọ́nà kan tàbí òmíràn. A gbà yín níyànjú pé kẹ́ ẹ máa kà wọ́n bẹ́ ẹ bá ń múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀. Èyí á jẹ́ kẹ́ ẹ lè máa mú wọn wọnú ọ̀rọ̀ yín nígbà tẹ́ ẹ bá ń dáhùn nípàdé.
Ìròyìn ọdọọdún ò ní máa jáde nínú Ilé Ìṣọ́ mọ́. Láti ọdún 2008, inú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti ìwé ọdọọdún, ìyẹn Yearbook, lá á ti máa jáde. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, àwọn àpilẹ̀kọ míì á tún máa wà nínú ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní máa jíròrò ọ̀pọ̀ lára irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ nípàdé ìjọ, a gbà ẹ́ níyànjú pé kó o máa fara balẹ̀ kà wọ́n. Oúnjẹ tẹ̀mí látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ló wà nínú wọn.—Mát. 24:45-47.
Lákòótán, ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àtèyí tá ó máa fi sóde kì í ṣe ìwé ìròyìn méjì tó yàtọ̀ síra o. Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà ṣì làwọn méjèèjì. Wọ́n ní ìpínrọ̀ kan tó bára mu lójú ìwé kejì tó ṣàlàyé ìdí tá a fi ń tẹ Ilé Ìṣọ́. Àwọn méjèèjì la ó máa pa pọ̀ sínú ìdìpọ̀ ìwé ìròyìn ọdọọdún. Orí ẹ̀dà méjèèjì la ó máa gbé àwọn ìbéèrè táá máa wà lábẹ́ àkọlé náà, “Ǹjẹ́ O Rántí?” kà. Inú ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ la ó sì máa tẹ àkọlé yìí sí.
Látọdún 1879, títí jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí iná ogun ń rú tútú, tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀, tí inúnibíni sì ń lọ, Ilé Ìṣọ́ ò dẹ́kun láti máa polongo òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àdúrà wa ni pé kí ìbùkún Jèhófà wà lórí rẹ̀, kó lè máa bá a nìṣó láti ṣe bẹ́ẹ̀ bó ṣe ń jáde lákọ̀tun yìí. A sì gbà á ládùúrà pé kí Jèhófà rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí ìwọ náà tó ò ń ka ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tuntun tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, bó o ṣe ń fàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ sílò.