Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Máa Ṣọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí o Tẹ́wọ́ Gbà Nínú Olúwa”

“Máa Ṣọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí o Tẹ́wọ́ Gbà Nínú Olúwa”

“Máa Ṣọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí o Tẹ́wọ́ Gbà Nínú Olúwa”

“Máa ṣọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí o tẹ́wọ́ gbà nínú Olúwa, kí o lè mú un ṣẹ.”—KÓL. 4:17.

1, 2. Ojúṣe pàtàkì wo làwọn Kristẹni ní láti máa ṣe fáwọn èèyàn?

 ANÍ ojúṣe pàtàkì kan láti ṣe fáwọn tó ń gbé láyìíká wa. Ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá gbé nísinsìnyí ló máa pinnu bóyá wọ́n máa la “ìpọ́njú ńlá náà” já tàbí wọn ò ní là á já. (Ìṣí. 7:14) Ọlọ́run mí sí ẹni tó kọ ìwé Òwe láti sọ pé: “Dá àwọn tí a ń mú lọ fún ikú nídè; àwọn tí ó sì ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sínú ìfikúpa, kí o fà wọ́n sẹ́yìn.” Ọ̀rọ̀ ńlá lọ̀rọ̀ yìí o! A lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn bá a bá kùnà láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n yan ìyè. Kódà ẹsẹ Bíbélì yẹn tún sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ sọ pé: ‘Wò ó! Àwa kò mọ̀ nípa èyí,’ ẹni tí ń díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà kì yóò ha fi òye mọ̀ ọ́n, ẹni tí ń ṣàkíyèsí ọkàn rẹ kì yóò ha mọ̀ kí ó sì san án padà dájúdájú fún ará ayé ní ìbámu pẹ̀lú ìgbòkègbodò rẹ̀?” Ó dájú pé kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà tó máa sọ pé òun “kò mọ̀ nípa” ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn èèyàn.—Òwe 24:11, 12.

2 Ìwàláàyè ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ìdí nìyí tó fi rọ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ká sa gbogbo ipá wa láti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn là bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Gbogbo òjíṣẹ́ Ọlọ́run ló gbọ́dọ̀ máa polongo ìhìn rere tó ń gbani là tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ńṣe ni iṣẹ́ wa dà bíi ti olùṣọ́ tó máa ń kìlọ̀ fáwọn aráàlú tó bá rí ewu èyíkéyìí tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán. A ò fẹ́ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí wọn. (Ìsík. 33:1-7) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká máa bá a lọ láti “wàásù ọ̀rọ̀ náà”!—Ka 2 Tímótì 4:1, 2, 5.

3. Àwọn kókó wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí àti àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá kọ́ bó o ṣe máa borí àwọn ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là yìí, wàá sì tún mọ bó o ṣe lè ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó sì tẹ̀ lé èyí, a máa ṣàyẹ̀wò bó o ṣe lè di olùkọ́ tó já fáfá nínú kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì. Àpilẹ̀kọ kẹta máa sọ díẹ̀ nínú àwọn àṣeyọrí tó múnú ẹni dùn táwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe jákèjádò ayé. Ṣùgbọ́n ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó mú kí àkókò tá a wà yìí le koko tó bẹ́ẹ̀.

Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ò Fi Nírètí

4, 5. Kí lọmọ aráyé ń fojú winá, kí sì ni púpọ̀ nínú wọn máa ń ṣe?

4 Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé lónìí jẹ́ ká mọ̀ pé “ìparí ètò àwọn nǹkan” là ń gbé, àti pé òpin ti sún mọ́lé gan-an. Aráyé ń fojú winá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìṣòro tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé ó máa fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà. Àwọn nǹkan bí ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn àjálù míì jẹ́ “ìroragógó wàhálà” tó ń dé bá àwa èèyàn. Ìwà ta-ni-yóò-mú-mi, ìmọtara-ẹni-nìkan àtàwọn ìwà mìíràn tínú Ọlọ́run ò dùn sí ló kúnnú ayé. Ìgbà tá a wà yìí jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” kódà fáwọn tó ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì.—Mát. 24:3, 6-8, 12; 2 Tím. 3:1-5.

5 Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ọmọ aráyé ni kò mọ ohun tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé túmọ̀ sí. Ìdí nìyẹn tí púpọ̀ nínú wọn fi ń ṣàníyàn nípa ààbò tara wọn àti ti ìdílé wọn. Ikú èèyàn ẹni àti oríṣiríṣi ìṣòro ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn èèyàn wọ̀nyí máa wà láìnírètí tí wọn ò bá ní ìmọ̀ pípéye nípa ìdí táwọn nǹkan wọ̀nyẹn fi ń ṣẹlẹ̀, kí wọ́n sì mọ ibi tí wọ́n ti lè rí ojútùú sí wọn.—Éfé. 2:12.

6. Kí nìdí tí “Bábílónì Ńlá” kò fi lè ran àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́?

6 “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn gbogbo ìsìn èké ayé lápapọ̀, kò ṣe ohun tó máa tu àwọn èèyàn nínú rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi “wáìnì àgbèrè rẹ̀” kó ọ̀pọ̀ èèyàn ṣìnà, tí wọn ò sì mọ báwọn ṣe lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìsìn èké ń ṣe bí aṣẹ́wó, ó forí “gbogbo ọba ilẹ̀ ayé” sábẹ́, ó sì ń darí wọn, ó sì tún ń fi ẹ̀kọ́ èké àti ìbẹ́mìílò lóríṣiríṣi sọ ẹgbàágbèje ọmọ aráyé di dọ̀bọ̀sìyẹsà sáwọn tó ń ṣàkóso wọn. Ìsìn èké wá tipa báyìí jẹgàba lé àwọn èèyàn lórí, ó ń darí wọn síbi tó bá wù ú, ó sì tún wá pa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tì pátápátá.—Ìṣí. 17:1, 2, 5; 18:23.

7. Kí ló ń dúró dé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ọmọ aráyé, ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè ran àwọn kan lọ́wọ́?

7 Jésù sọ pé púpọ̀ nínú ọmọ aráyé ló ń gba ojú ọ̀nà aláyè gbígbòòrò tó jẹ́ ọ̀nà ìparun. (Mát. 7:13, 14) Àwọn kan wà ní ojú ọ̀nà aláyè gbígbòòrò yẹn torí pé wọ́n dìídì kọ̀ láti má ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àmọ́, ohun tó mú káwọn míì wà níbẹ̀ ni pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ṣì wọ́n lọ́nà, wọn ò sì kọ́ wọn ní ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí wọ́n ṣe gan-an. Ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú wọn yí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbé ìgbésí ayé wọn padà tí wọ́n bá rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́. Ṣùgbọ́n àwọn tó bá ṣì wà nínú Bábílónì Ńlá, tí wọ́n sì kẹ̀yìn sáwọn ìlànà Bíbélì kò ní la “ìpọ́njú ńlá náà” já.—Ìṣí. 7:14.

Máa Bá A Lọ Láti Wàásù “Láìdábọ̀”

8, 9. Kí làwọn Kristẹni ayé àtijọ́ ṣe nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wọn, kí sì nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀?

8 Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yóò wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, wọn yóò sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni tòótọ́ fi ka iṣẹ́ ìwàásù sí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àti ohun pàtàkì kan tó lè fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́. Èyí ló mú káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní pẹrẹu láyé àtijọ́, kódà nígbà táwọn èèyàn ń ṣe inúnibíni sí wọn. Wọ́n gbọ́kàn lé Jèhófà pé ó máa fún wọn lókun, wọ́n sì ń gbàdúrà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ káwọn lè máa bá a lọ ní “fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ [rẹ̀].” Jèhófà gbọ́ àdúrà wọn, ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, wọ́n sì ń fìgboyà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Ìṣe 4:18, 29, 31.

9 Ǹjẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dá iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe dúró torí inúnibíni? Rárá o. Inú bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù báwọn àpọ́sítélì ṣe ń wàásù, ni wọ́n bá mú wọn, wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì nà wọ́n. Síbẹ̀, àwọn àpọ́sítélì “ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” Kedere ló yé wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:28, 29, 40-42.

10. Àwọn ìṣòro wo làwọn Kristẹni ń dojú kọ lónìí, síbẹ̀ kí ló lè jẹ́ àbájáde ìwà rere wọn?

10 Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ni wọn ò tíì lù tàbí kí wọ́n jù sẹ́wọ̀n rí torí pé wọ́n ń wàásù. Ṣùgbọ́n, gbogbo Kristẹni tòótọ́ ló ń dojú kọ ìdánwò àti ìṣòro lónírúurú. Bí àpẹẹrẹ, torí pé o ti fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ, o lè máa ṣe àwọn nǹkan kan táwọn èèyàn á fi máa wò ẹ́ bí ọ̀dẹ̀ tàbí ẹni tí ò rọ́ọ̀ọ́kán. Nítorí pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ọmọ ilé ìwé rẹ tàbí àwọn aládùúgbò lè máa wò ẹ́ bí ẹni tí nǹkan tiẹ̀ kì í bá tayé mu. Síbẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà hùwà sí ọ mú kó o rẹ̀wẹ̀sì. Tó bá dọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run, inú òkùnkùn biribiri ni aráyé wà, àmọ́ àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa “tàn bí atànmọ́lẹ̀.” (Fílí. 2:15) Ó ṣeé ṣe káwọn aláìlábòsí tó ń kíyè sí àwọn iṣẹ́ àtàtà tá à ń ṣe mọyì rẹ̀, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fògo fún Jèhófà.—Ka Mátíù 5:16.

11. (a) Kí ló lè jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn kan sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe? (b) Irú àtakò wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dojú kọ, kí ló sì ṣe?

11 Ó ń béèrè ìgboyà ká tó lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. Àwọn kan, títí kan àwọn ẹbí rẹ pàápàá, lè máa fi ọ́ ṣẹlẹ́yà tàbí kí wọ́n máa ṣé àwọn nǹkan míì tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. (Mát. 10:36) Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ táwọn èèyàn lu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nítorí pé ó ń wàásù. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn àtakò bẹ́ẹ̀, ó ní: “Lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ jìyà, tí a sì hùwà sí wa lọ́nà àfojúdi,” a “máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.” (1 Tẹs. 2:2) Ó gba ìgboyà kí Pọ́ọ̀lù tó lè má bá iṣẹ́ ìwàásù lọ lẹ́yìn tí wọ́n gbá a mú, tí wọ́n bọ́ aṣọ rẹ̀, tí wọ́n fi ọ̀pá nà án, tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. (Ìṣe 16:19-24) Kí ló jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù ní ìgboyà láti máa bá a lọ? Ohun tó fún un nígboyà ni bó ṣe ń wù ú gan-an láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.—1 Kọ́r. 9:16.

12, 13. Àwọn ìṣòro wo ló ń bá àwọn kan nínú wa fínra, kí sì ni wọ́n ti ṣe láti borí àwọn ìṣòro náà?

12 Ó tún lè ṣòro fún wa láti máa fi ìtara wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ pé agbára káká la fi ń bá àwọn èèyàn nílè tàbí níbi táwọn èèyàn ò ti kọbi ara sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Kí la lè ṣe tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀? Ó lè gba pé ká lo ìgboyà gidi láti wàásù fáwọn èèyàn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Ó tún lè gba pé ká ṣètò àkókò wa láti máa wàásù láwọn àkókò míì tó yàtọ̀ sí ìgbà tá a ti máa ń wàásù tẹ́lẹ̀ tàbí láwọn ọjọ́ tó yàtọ̀. A sì tún lè máa lọ wàásù láwọn ibi tá a bá ti lè rí ọ̀pọ̀ èèyàn.—Fi wé Jòhánù 4:7-15; Ìṣe 16:13; 17:17.

13 Àwọn ìṣòro míì tí ọ̀pọ̀ tún máa ń ní tí kì í jẹ́ kí wọ́n lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ni àìlera ara àti ara tó ti ń dara àgbà. Bó bá jẹ́ pé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn, má bọkàn jẹ́. Jèhófà mọyì bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, torí ó mọ ibi tágbára rẹ mọ. (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:12.) Ìpọ́njú yòówù kó máa bá ọ fínra, ì báà jẹ́ inúnibíni, ẹ̀tanú tàbí àìlera, ṣáà máa ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ gbé nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà.—Òwe 3:27; fi wé Máàkù 12:41-44.

‘Máa Ṣọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ’

14. Àpẹẹrẹ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ fáwa Kristẹni, ìmọ̀ràn wo ló sì gbà wá?

14 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá, ohun tó sì ní káwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ ṣe náà nìyẹn. (Ìṣe 20:20, 21; 1 Kọ́r. 11:1) Ọ̀kan lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí Pọ́ọ̀lù gbà níyànjú gidigidi ni ẹnì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ákípọ́sì. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó ní: “Ẹ sọ fún Ákípọ́sì pé: ‘Máa ṣọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí o tẹ́wọ́ gbà nínú Olúwa, kí o lè mú un ṣẹ.’” (Kól. 4:17) A ò mọ irú ẹni tí Ákípọ́sì jẹ́, a ò sì mọ bí ipò rẹ̀ ṣe rí, ṣùgbọ́n ó hàn gbangba pé ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìwàásù. Bó o bá jẹ́ Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ìwọ náà ti gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ nìyẹn. Ǹjẹ́ ò ń kíyè sí bó o ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, kó o bàa lè ṣe é débi tó yẹ kó o ṣe é dé?

15. Kí ni ìyàsímímọ́ tí Kristẹni kan ṣe túmọ̀ sí, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

15 Kó tó di pé a ṣèrìbọmi, a ya ara wa sí mímọ́ pẹ̀lú àdúrà àtọkànwá tá a gbà sí Jèhófà. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé a ti pinnu láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Á dáa ká bi ara wa nísinsìnyí pé, ‘Ṣé ó dá mi lójú pé mo fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ohun pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé mi?’ Lóòótọ́, a ní onírúurú ojúṣe tí Jèhófà retí pé ká bójú tó, irú bíi ká pèsè àtijẹ àtimu fáwọn ìdílé wa. (1 Tím. 5:8) Àmọ́, kí là ń fi àkókò àti agbára wa tó kù ṣe? Kí la fi ṣe nǹkan àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa?—Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.

16, 17. Àwọn àǹfààní wo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tàbí àwọn tí bùkátà wọn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lè gbé yẹ̀ wò?

16 Ṣé ọ̀dọ́ tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ni ọ́? Ṣó o ti parí ẹ̀kọ́ ìwé rẹ, àbí ó ku díẹ̀ kó o parí rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó o máà tíì ní ìdílé tó ò ń bójú tó báyìí. Nítorí náà, báwo lo ṣe fẹ́ lo ìgbésí ayé rẹ? Níwọ̀n bó o ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé wàá ṣe ìfẹ́ Jèhófà, àwọn ìpinnu tó dára jù lọ wo lo lè ṣe tó máa jẹ́ kó o lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ? Ọ̀pọ̀ ti ṣètò àkókò wọn kí wọ́n bàa lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, èyí sì ti mú kí wọ́n ní ayọ̀ tó pọ̀ gan-an, ọkàn wọn sì tún balẹ̀.—Sm. 110:3; Oníw. 12:1.

17 Ṣé ọ̀dọ́langba ni ẹ́? Bóyá ò ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀, o ò sì ní bùkátà tó ò ń gbọ́ ju ti ara rẹ nìkan lọ. O tiẹ̀ lè máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ dé ibi tí ipò rẹ yọ̀ǹda dé, tó o sì ń láyọ̀ bó o ṣe ń ṣe èyí. Ǹjẹ́ o lè túbọ̀ ní ayọ̀ tó pọ̀ sí i? Ǹjẹ́ o ti rò ó wò bóyá o lè túbọ̀ fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? (Sm. 34:8; Òwe 10:22) Iṣẹ́ ṣì wà láti ṣe láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan, kí gbogbo àwọn èèyàn lè gbọ́ nípa ìhìn rere òtítọ́ tó ń gbani la náà. Ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn àyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ, bóyá kó o lọ sìn ní ìpínlẹ̀ táwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run ò ti pọ̀ tó?—Ka 1 Tímótì 6:6-8.

18. Àwọn àtúnṣe wo ni tọkọtaya kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ṣe, kí sì ni àbájáde àwọn àtúnṣe náà?

18 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Kevin àti Elena, tọkọtaya kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó yẹ̀ wò. a Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ń gbé. Wọ́n wò ó pé ó yẹ káwọn ra ilé kan, gẹ́gẹ́ báwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ṣe máa ń ṣe ní àgbègbè wọn. Àwọn méjèèjì ló ń ṣiṣẹ́, èyí sì jẹ́ kí wọ́n lè gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. Síbẹ̀, iṣẹ́ wọn, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ilé míì ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn débi pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ni wọ́n fi ń wàásù. Wọ́n ṣàkíyèsí pé ó fẹ̀rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé orí dúkìá táwọn kó jọ làwọn ń lo gbogbo àkókò àti okun àwọn lé. Àmọ́, nígbà tí Kevin àti Elena wo báwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ò ṣe lépa kíkó ọrọ̀ jọ, síbẹ̀ tí wọ́n láyọ̀, wọ́n wá rí i pé ó yẹ káwọn yí ohun táwọn fi sípò kìíní nígbèésí ayé àwọn padà. Wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ káwọn lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wọ́n wá ta ilé tí wọ́n rà yẹn, wọ́n sì lọ háyà ilé kan. Elena dín àkókò tó fi ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn ìrírí tí Elena ní nínú iṣẹ́ ìwàásù wú Kevin lórí, ni Kevin bá fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè kan ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù láti lọ sìn níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Kevin sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sígbà témi àti ìyàwó mi ò láyọ̀, àmọ́ ayọ̀ wa túbọ̀ kún sí i nígbà tá a sapá láti fi kún iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run.”—Ka Mátíù 6:19-22.

19, 20. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ lónìí?

19 Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tá à ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé lónìí. (Ìṣí. 14:6, 7) Iṣẹ́ ìwàásù yìí sì ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Mát. 6:9) Lọ́dọọdún ni ẹ̀kọ́ Bíbélì ń tún ìgbésí ayé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ṣe, èyí tó lè mú kí wọ́n jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Báwo . . . ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” (Róòmù 10:14, 15) Báwo ni wọ́n ṣe máa gbọ́ lóòótọ́? O ò ṣe pinnu pé wàá ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.

20 Ọ̀nà mìíràn tó o tún lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí àkókò wa yìí ti ṣe pàtàkì tó, kí wọ́n sì lè mọ ohun tí ìpinnu èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe máa yọrí sí ni pé kó o túbọ̀ jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò jíròrò bó o ṣe lè di olùkọ́ tó túbọ̀ já fáfá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Ojúṣe pàtàkì wo làwọn Kristẹni ní láti ṣe fáwọn èèyàn?

• Báwo la ṣe lè máa wàásù nìṣó láìka àwọn ohun kan tó lè jẹ́ ìṣòro sí?

• Báwo la ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa débi tó yẹ ká ṣe é dé?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè wàásù nígbà téèyàn bá dojú kọ àtakò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kí lo lè ṣe bó o bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ tó jẹ́ pé agbára káká lo fi máa ń bá àwọn èèyàn nílé?