Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nígbà Tí Èṣù Bá Ku Àwọn Kristẹni bí Àlìkámà

Nígbà Tí Èṣù Bá Ku Àwọn Kristẹni bí Àlìkámà

Nígbà Tí Èṣù Bá Ku Àwọn Kristẹni bí Àlìkámà

KÉTÉ kí Jésù tó kú, ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wò ó! Sátánì ti fi dandan béèrè láti gbà yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà.” (Lúùkù 22:31) Kí lọ̀rọ̀ Jésù yẹn túmọ̀ sí?

Nígbà tí Jésù wà láyé, kíkórè àlìkámà máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá. Àwọn olùkórè á kọ́kọ́ kó pòròpórò àlìkámà tí ṣírí ọkà tò sí lára jọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í jan àwọn pòròpórò náà mọ́ ibi tó le. Wọ́n tiẹ̀ lè so ẹranko mọ́ ohun èèlò ìpakà, bí ẹranko náà bá sì ti ń wọ́ ohun èlò ìpakà gba orí pòròpórò tó wà nílẹ̀yílẹ̀ kọjá, kóró àlìkámà tó wà nínú rẹ̀ á máa yọ jáde. Wàyí o, ó ku kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣa pòròpórò tó ti dà pọ̀ mọ́ kóró àlìkámà yìí kúrò. Wọ́n lè máa fi igbá fẹ́ ẹ, bí wọ́n bá sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, afẹ́fẹ́ á máa fẹ́ ìyàngbò tàbí èèpo ara kóró àlìkámà náà dà nù, kóró àlìkámà á sì máa já bọ́ sórí ilẹ̀ ìpakà. Lẹ́yìn èyí, wọ́n lè lo pàkátà, ìyẹn àtẹ pẹrẹsẹ tàbí ohun mìíràn láti fi fẹ́ ìdọ̀tí tó bá kù lára kóró àlìkámà náà.

Bí Jésù ṣe sọ, Sátánì ò fìgbà kan dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yé gbéjà ko àwa náà lónìí. (Éfé. 6:11) Òótọ́ ni pé Sátánì kọ́ ló ń fa gbogbo ìṣòro yòówù kó máa bá wa. (Oníw. 9:11) Síbẹ̀, ó ti ṣe tán láti pa gbogbo itú ọ̀wọ́ ẹ̀ kó lè mú wa ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè fi kíkó ọrọ̀ jọ, eré ìnàjú tí kò bójú mu tàbí ìṣekúṣe dán wa wò. Ó tún lè lo àwọn tá a jọ jẹ́ ọmọléèwé tàbí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ìbátan wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa fúngun mọ́ wa pé ká jayé òní nípa kíka jẹ̀jẹ̀rẹ̀ ìwé tàbí ká fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ ká bàa lè jéèyàn. Kò mọ síbẹ̀, Sátánì tún lè dojú inúnibíni kọ wá ká bàa lè ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́. Mélòó la tiẹ̀ fẹ́ kà nínú onírúurú ọ̀nà tí Sátánì ń gbà kó bàa lè fì wá lògbòlògbò bí ẹni ń ku àlìkámà.

Báwo gan-an la ṣe lè gbara wa lọ́wọ́ ọ̀tá tá ò lè dá mú yìí? Àfi ká yáa fà á lé Ọlọ́run lọ́wọ́. A ò lè bá Sátánì figẹ̀ wọngẹ̀, àmọ́ ó yé wa pé Jèhófà lágbára jù ú lọ fíìfíì. Bá a bá gbà pé Jèhófà ni aláàbò wa, tá à ń gbàdúrà tọkàntọkàn pé kó fún wa ní ọgbọ́n àti ìgboyà ká lè fara dà á, tá a sì mọ̀ pé ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ ò ní já sófo, ó dájú pé ó máa sọ agbára wa láti gbéjà ko Sátánì dọ̀tun.—Sm. 25:4, 5.

Bí ìdánwò bá dé, a gbọ́dọ̀ lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́” kọ́wọ́ ṣìnkún Sátánì má bàa tẹ̀ wá. (Héb. 5:13, 14) Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní irú agbára bẹ́ẹ̀. Ohun tó kàn máa gbà ni pé, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ká ṣáà máa ṣe ohun tó tọ́. Bá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, tá ò sì yé fìgboyà ṣe ohun tó tọ́, ó dájú pé Jèhófà ò ní padà lẹ́yìn wa.—Éfé. 6:10.

Sátánì lè gbìyànjú láti kù wá bí àlìkámà. Àmọ́, Jèhófà á fún wa lágbára tá ò fi ní gbà á láyè, tí a sì máa dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (1 Pét. 5:9) Kò sírọ́ ńbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Jèhófà mú-un dá wa lójú pé tá a bá “kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò . . . sá kúrò lọ́dọ̀” wa.—Ják. 4:7.