Máa Rìn Ní Ọ̀nà Jèhófà
Máa Rìn Ní Ọ̀nà Jèhófà
“Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”—SM. 128:1.
1, 2. Kí ló mú kó dá wa lójú pé èèyàn lè ní ayọ̀?
GBOGBO èèyàn ló fẹ́ láti jẹ́ aláyọ̀. Láìsí àní-àní, wàá gbà pé ọ̀tọ̀ ni kéèyàn fẹ́ láti jẹ́ aláyọ̀ kó sì máa wá a lójú méjèèjì; ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn wá ní ayọ̀ ọ̀hún.
2 Síbẹ̀, ayọ̀ kì í ṣohun tọ́wọ́ èèyàn ò lè tẹ̀. Sáàmù 128:1 sọ pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.” Tá a bá ń jọ́sìn Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tá a sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tó fẹ́ ká máa ṣe, a óò láyọ̀. Báwo nìyẹn ṣe máa hàn nínú ìwà àti ànímọ́ wa?
Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Fọkàn Tán
3. Báwo ni yíyà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ṣe fi hàn pé a jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán?
3 Àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà máa ń ṣeé fọkàn tán, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un ló mú ṣẹ. (1 Ọba 8:56) Ìlérí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a tíì ṣe rí ni yíyà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, gbígbàdúrà déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìlérí náà ṣẹ. Àwa náà lè gba irú àdúrà tí Dáfídì gbà nínú sáàmù tó kọ, pé: “Ìwọ fúnra rẹ, Ọlọ́run, ti fetí sí àwọn ẹ̀jẹ́ mi. . . . Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ títí láé, kí n lè san àwọn ẹ̀jẹ́ mi ní ọjọ́ dé ọjọ́.” (Sm. 61:5, 8; Oníw. 5:4-6) Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán.—Sm. 15:1, 4.
4. Ọwọ́ wo ni Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ fi mú ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́ fún Jèhófà?
4 Nígbà ayé àwọn Onídàájọ́ lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, Jẹ́fútà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé tí Jèhófà bá lè ran òun lọ́wọ́ tóun sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì, ẹni tó bá kọ́kọ́ wá pàdé òun nígbà tóun bá ń tójú ogun bọ̀ lòun máa fi fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ ẹbọ sísun.” Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tó kọ́kọ́ wá pàdé rẹ̀ yẹn ni ọmọbìnrin rẹ̀, ìyẹn ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Nítorí ìgbàgbọ́ tí Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ tí kò tíì lọ́kọ ní nínú Jèhófà, wọ́n san ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́ fún Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan pàtàkì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ka ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí sí láyé ìgbà yẹn, ọmọbìnrin Jẹ́fútà fínnúfíndọ̀ gbà láti wà láìlọ́kọ títí ayé rẹ̀, ìyẹn sì fún un láǹfààní àtimáa ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ nínú ibùjọsìn Jèhófà.—Oníd. 11:28-40.
5. Báwo ni Hánà ṣe fi hàn pé ẹni tó ṣeé fọkàn tán lòun?
5 Hánà, obìnrin kan báyìí tó bẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ọ̀ọ̀dẹ̀ ọkọ rẹ̀ Ẹlikénà tó jẹ́ ọmọ Léfì lòun àti orogún rẹ̀ tó ń jẹ́ Pẹ̀nínà wà. Àgbègbè olókè ńlá Éfúráímù ni wọ́n ń gbé. Pẹ̀nínà bímọ púpọ̀, ó sì máa ń pẹ̀gàn Hánà torí pé ó yàgàn, pàápàá nígbà tí gbogbo ìdílé wọn bá lọ sí àgọ́ ìjọsìn. Lọ́jọ́ kan tí ọ̀rọ̀ yìí wáyé bó ṣe máa ń wáyé, Hánà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé tóun bá fi lè rí ọmọkùnrin kan bí, Jèhófà lòun máa fi ọmọ náà fún. Kò pẹ́ sígbà yẹn tó fi lóyún tó sì bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n sọ ní Sámúẹ́lì. Lẹ́yìn tó já Sámúẹ́lì lẹ́nu ọmú, ó mú un lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Ṣílò, ó sì fi í fún Jèhófà “ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.” (1 Sám. 1:11) Bó ṣe san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀ pé òun ṣì máa bí àwọn ọmọ míì.—1 Sám. 2:20, 21.
6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Tíkíkù jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán?
6 Tíkíkù, Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán àti “olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́.” (Kól. 4:7) Tíkíkù bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò láti Gíríìsì lọ sí Makedóníà títí tí wọ́n fi dé àgbègbè Éṣíà Kékeré, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó bá a dé Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 20:2-4) Ó sì tún lè jẹ́ òun ni “arákùnrin náà” tó ran Títù lọ́wọ́ láti ṣètò pípín ọrẹ fáwọn ará Jùdíà tí wọ́n di aláìní. (2 Kọ́r. 8:18, 19; 12:18) Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ju Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó rán Tíkíkù tó jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán pé kó bá òun kó lẹ́tà lọ sọ́dọ̀ àwọn ará tó wà ní Éfésù àti Kólósè. (Éfé. 6:21, 22; Kól. 4:8, 9) Lákòókò tí wọ́n ju Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì ní Róòmù, ó rán Tíkíkù lọ sí Éfésù. (2 Tím. 4:12) Táwa náà bá jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, a máa ní ọ̀pọ̀ àǹfààní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
7, 8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Dáfídì àti Jónátánì fẹ́ ara wọn dénú?
7 Ọlọ́run fẹ́ ká jẹ́ ẹni táwọn ọ̀rẹ́ wa lè fọkàn tán. (Òwe 17:17) Dáfídì àti Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn ṣọ̀rẹ́. Nígbà tí Jónátánì gbọ́ pé Dáfídì ti pa Gòláyátì, “ọkàn Jónátánì pàápàá wá fà mọ́ ọkàn Dáfídì, Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn òun tìkára rẹ̀.” (1 Sám. 18:1, 3) Kódà Jónátánì ta Dáfídì lólobó nígbà tí Sọ́ọ̀lù fẹ́ pa á. Lẹ́yìn tí Dáfídì sá lọ, Jónátánì lọ bá a, ó sì bá a dá májẹ̀mú. Díẹ̀ ló kù kí Sọ́ọ̀lù pa Jónátánì nítorí ọ̀rọ̀ Dáfídì. Síbẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ méjì yìí tún pàdé, wọ́n sì mú kí okùn ọ̀rẹ́ wọn lágbára sí i. (1 Sám. 20:24-41) Nígbà táwọn méjèèjì fojú kanra gbẹ̀yìn, Jónátánì fún ọwọ́ Dáfídì lókun “nípa ti Ọlọ́run.”—1 Sám. 23:16-18.
8 Jónátánì kú sójú ogun nígbà tí wọ́n ń bá àwọn Filísínì jà. (1 Sám. 31:6) Nínú orin arò kan tí Dáfídì kọ, ó sọ pé: “Wàhálà-ọkàn bá mi nítorí rẹ, Jónátánì arákùnrin mi, ẹni gbígbádùnmọ́ni gidigidi ni ìwọ jẹ́ fún mi. Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ àgbàyanu ju ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn obìnrin.” (2 Sám. 1:26) Ìfẹ́ tí Dáfídì ń sọ yìí kì í ṣerú ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n jẹ́ olólùfẹ́ o. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ọ̀rẹ́ tó fẹ́ ara wọn dénú ni Dáfídì àti Jónátánì.
Máa Hùwà Ìrẹ̀lẹ̀ Nígbà Gbogbo
9. Báwo lohun tó wà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ orí kẹsàn-án ṣe jẹ́ ká rí bí ìrẹ̀lẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó?
9 Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ “jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.” (1 Pét. 3:8; Sm. 138:6) Ohun tó wà ní orí kẹsàn-án ìwé Àwọn Onídàájọ́ fi bí ìrẹ̀lẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó hàn. Jótámù ọmọ Gídíónì sọ pé: “Nígbà kan rí, àwọn igi lọ fòróró yan ọba lórí ara wọn.” Ó mẹ́nu ba igi ólífì, igi ọ̀pọ̀tọ́, àti igi àjàrà. Àwọn igi yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn tí ipò ọba tọ́ sí àmọ́ tí kò wù wọ́n láti máa ṣàkóso lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiwọn. Ṣùgbọ́n igi tó gbà láti jọba ni igi ẹlẹ́gùn-ún tí kò wúlò fún nǹkan míì kọjá kí wọ́n fi dáná. Ohun tí ìyẹn ṣàpẹẹrẹ ni ìjọba Ábímélékì tó jẹ́ agbéraga àti apààyàn tó fẹ́ máa jẹ gàba lórí àwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘ó ṣe bí ọmọ aládé lórí Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́ta,’ ńṣe ló kú ikú àìtọ́jọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Oníd. 9:8-15, 22, 50-54) Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀!
10. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hẹ́rọ́dù tí kò “fi ògo fún Ọlọ́run”?
10 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, wàhálà kan ṣẹlẹ̀ láàárín Hẹ́rọ́dù Àgírípà Ọba Jùdíà àtàwọn ará ìlú Tírè òun Sídónì, àwọn wọ̀nyí sì wá túúbá fún un. Ó wá di ọjọ́ kan tí Hẹ́rọ́dù bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tó wà níwájú ẹ̀ sọ̀rọ̀ ní gbangba, àwọn wọ̀nyẹn hó yèè, wọ́n ní: “Ohùn ọlọ́run kan ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Hẹ́rọ́dù kò kọ irú ìyìn tí wọ́n ń fi fún un yẹn, bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe lù ú nìyẹn, ló bá kú ikú ẹ̀sín “nítorí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run.” (Ìṣe 12:20-23) Tó bá dà bíi pé àwa náà ò kẹ̀rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, tàbí pé a mọ èèyàn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa ńkọ́? Ọlọ́run tó fún wa ní irú ẹ̀bùn yẹn ló yẹ ká máa fìyìn fún.—1 Kọ́r. 4:6, 7; Ják. 4:6.
Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára
11, 12. Báwo ni ìrírí Énọ́kù ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìgboyà àti okun?
11 Tá a bá ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà, ó máa fún wa ní ìgboyà àti agbára. (Diu. 31:6-8, 23) Énọ́kù tó wà ní ìran keje sí ìran ti Ádámù bá Ọlọ́run rìn tìgboyà tìgboyà nípa bó ṣe hùwà tó dáa, láìwo tàwọn èèyàn burúkú tí wọ́n jọ wà láyé nígbà yẹn. (Jẹ́n. 5:21-24) Jèhófà fún Énọ́kù lókun láti jẹ́ iṣẹ́ kan tó lágbára fáwọn èèyàn yẹn nítorí ìwà àti ọ̀rọ̀ burúkú wọn. (Ka Júúdà 14, 15.) Ṣéwọ náà nígboyà tó máa jẹ́ kó o lè polongo ìdájọ́ Ọlọ́run?
12 Jèhófà lo Ìkún-omi ọjọ́ Nóà tó kárí ayé láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ lórí àwọn ẹni ibi wọ̀nyẹn. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù yẹn ṣì jẹ́ ohun ìṣírí fún wa. Ìdí ni pé ẹgbàágbèje ẹgbẹ́ ọmọ ogun mímọ́ ti Ọlọ́run máa tó wá pa àwọn ẹni ibi ọjọ́ tiwa náà run. (Ìṣí. 16:14-16; 19:11-16) Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ìgboyà láti polongo iṣẹ́ tó rán wa, bóyá ti ìdájọ́ rẹ̀ ni o tàbí ti ìbùkún tí Ìjọba rẹ̀ máa mú wá.
13. Kí ló mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run á fún wa ní ìgboyà àti okun tá a nílò láti fara da àwọn ìṣòro tó lè kó ìdààmú ọkàn bá wa?
13 A nílò ìgboyà àti okun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti lè máa fara da àwọn ìṣòro tó ń kó ìdààmú ọkàn bá èèyàn. Nígbà tí Ísọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin Hétì méjì ṣe ìyàwó, “wọ́n jẹ́ orísun ìkorò ẹ̀mí fún Ísákì àti Rèbékà [tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀].” Rèbékà tiẹ̀ sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì. Bí Jékọ́bù [ọmọ wa] bá lọ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì bí ìwọ̀nyí nínú àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ yìí, ire wo ni ìgbésí ayé jẹ́ fún mi?” (Jẹ́n. 26:34, 35; 27:46) Ísáákì yáa wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, ó ní kí Jékọ́bù lọ wá ìyàwó tó máa fẹ́ láàárín àwọn olùjọsìn Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ísáákì àti Rèbékà ò lè yí ohun tí Ísọ̀ ti ṣe padà, Ọlọ́run fún wọn ní ọgbọ́n, ìgboyà àti okun tí wọ́n á fi lè máa jẹ́ olóòótọ́ sí Òun nìṣó. Báwa náà bá gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́, Jèhófà á ràn wá lọ́wọ́.—Sm. 118:5.
14. Báwo ni ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan ṣe lo ìgboyà?
14 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn èyí, àwọn ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí mú ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan lẹ́rù, ọmọ yìí sì wá di ọmọ ọ̀dọ̀ nílé Náámánì, ọ̀gágun ilẹ̀ Síríà, ẹni tó jẹ́ adẹ́tẹ̀. Ọmọdébìnrin yìí ti gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ń tọwọ́ wòlíì Èlíṣà ṣe, ló bá lo ìgboyà, ó sọ fún ìyàwó Náámánì pé: ‘Ká sì ní ọ̀gá mi lè lọ sí Ísírẹ́lì ni, wòlíì Jèhófà ì bá wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn.’ Náámánì kúkú lọ sí Ísírẹ́lì, ó sì rí ìwòsàn gbà. (2 Ọba 5:1-3) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àtàtà tí ọmọdébìnrin yìí jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n gbára lé Jèhófà pé kó fáwọn lókun tí wọ́n á fi wàásù fáwọn olùkọ́ wọn, àwọn ọmọ iléèwé wọn, àwọn ọ̀gá wọn tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n jọ wà níbi iṣẹ́ àtàwọn ẹlòmíì!
15. Kí ni Ọbadáyà, alámòójútó ilé Áhábù ṣe tó fi hàn pé ó nígboyà?
15 Ìgboyà tí Ọlọ́run bá fún wa máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da inúnibíni. Ẹ wo àpẹẹrẹ ti alámòójútó ilé Áhábù Ọba, ìyẹn Ọbadáyà, ẹni tó gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú wòlíì Èlíjà. Nígbà tí Jésíbẹ́lì Ayaba pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa àwọn wòlíì Ọlọ́run, Ọbadáyà lọ fi ọgọ́rùn-ún wòlíì pa mọ́ “ní àádọ́ta-àádọ́ta nínú hòrò kan.” (1 Ọba 18:13; 19:18) Ṣéwọ náà lè lo ìgboyà láti ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn Kristẹni bíi tìẹ tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí, bí Ọbadáyà ṣe ran àwọn wòlíì Jèhófà lọ́wọ́?
16, 17. Kí ni Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì ṣe nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn?
16 Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sáwa náà, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀. (Róòmù 8:35-39) Bí àpẹẹrẹ, èrò tó pọ̀ bí omi gbéjà ko Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì tí wọ́n jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ní gbàgede ìwòran kan ní ìlú Éfésù. Dímẹ́tíríù alágbẹ̀dẹ fàdákà ló dáná wàhálà yẹn. Òun àtàwọn alágbẹ̀dẹ yòókù máa ń fi fàdákà ṣe ojúbọ abo ọlọ́run kan tí wọ́n ń pè ní Átẹ́mísì. Àmọ́ nígbà tí ìwàásù Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú yẹn jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, wọ́n rí i pé iṣẹ́ ajé tó ti ń mú èrè gọbọi wá fáwọn ti fẹ́ dojú dé. Àwọn jàǹdùkú yẹn wọ́ Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì lọ sí gbàgede ìwòran, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì ti àwọn ará Éfésù!” Ó ṣeé ṣe kí Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì ti gbà lọ́jọ́ yẹn pé ikú ti dé nìyẹn, ṣùgbọ́n akọ̀wé ìlú yẹn pẹ̀tù sáwọn jàǹdùkú yẹn lọ́kàn.—Ìṣe 19:23-41.
17 Ká ní ìwọ lojú ẹ ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ṣó ò ní rò pé á dáa kó o wá nǹkan míì tí kò ní wu ẹ̀mí ẹ léwu tó bẹ́ẹ̀ láti máa ṣe? Àmọ́ ní ti Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì, kò sóhun tó jọ pé wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Àrísítákọ́sì mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé wíwàásù ìhìn rere lè mú inúnibíni wá torí pé Tẹsalóníkà ló ti wá. Rògbòdìyàn ti bẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ nígbà kan rí lákòókò tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù níbẹ̀. (Ìṣe 17:5; 20:4) Nítorí pé Àrísítákọ́sì àti Gáyọ́sì ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ó fún wọn lókun àti ìgboyà láti fara da inúnibíni.
Máa Mójú Tó Ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlòmíì
18. Ọ̀nà wo ni Pírísíkà àti Ákúílà gbà ń “mójú tó” ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì?
18 Yálà wọ́n ń ṣenúnibíni sí wa báyìí àbí wọn ò ṣe é sí wa, ó yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ àwọn ará wa sọ́kàn. Pírísíkà àti Ákúílà máa ń “mójú tó” ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì. (Ka Fílípì 2:4.) Ó ṣeé ṣe káwọn tọkọtaya yìí ti bá Pọ́ọ̀lù wá ibi tó máa dé sí ní Éfésù níbi tí Dímẹ́tíríù alágbẹ̀dẹ fàdákà ti dá wàhálà sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó lè jẹ́ wàhálà ọjọ́ yẹn gan-an ló mú kí Ákúílà àti Pírísíkà ‘fi ọrùn wọn wewu’ nítorí Pọ́ọ̀lù. (Róòmù 16:3, 4; 2 Kọ́r. 1:8) Lónìí pẹ̀lú, a máa ń “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò” nítorí pé ọ̀rọ̀ àwọn ará wa tí wọ́n ń dojú kọ inúnibíni jẹ wá lógún. (Mát. 10:16-18) À ń ṣe iṣẹ́ wa tìṣọ́ratìṣọ́ra, a kì í ṣàkóbá fáwọn ará wa táwọn tó ń ṣenúnibíni sí wọn bá ní ká sọ orúkọ wọn àti nǹkan míì tá a mọ̀ nípa wọn.
19. Àwọn nǹkan rere wo ni Dọ́káàsì ṣe fáwọn èèyàn?
19 Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà máa mójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì. Àwọn ará wa kan lè nílò ohun kan táwa sì ní agbára láti ṣe é fún wọn. (Éfé. 4:28; Ják. 2:14-17) Obìnrin ọlọ́làwọ́ kan tó ń jẹ́ Dọ́káàsì wà nínú ìjọ Jópà ti ọ̀rúndún kìíní. (Ka Ìṣe 9:36-42.) Dọ́káàsì “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.” Ẹ̀rí wà pé àwọn aṣọ tó máa ń ṣe fáwọn opó tó jẹ́ aláìní wà lára àwọn iṣẹ́ àti ẹ̀bùn yìí. Nígbà tó kú ní ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, ìbànújẹ́ ńláǹlà ló jẹ́ fáwọn opó yẹn. Ọlọ́run lo àpọ́sítélì Pétérù láti jí Dọ́káàsì dìde, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló lo gbogbo ọdún yòókù tó gbé lórí ilẹ̀ ayé láti máa fayọ̀ wàásù ìhìn rere tó sì tún ń ṣe iṣẹ́ rere fáwọn èèyàn. Inú wa mà dùn pé a ní irú àwọn arábìnrin ọlọ́làwọ́ bẹ́ẹ̀ láàárín wa lónìí o!
20, 21. (a) Báwo ni fífún àwọn èèyàn ní ìṣírí ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún? (b) Kí lo lè ṣe láti lè máa fún àwọn èèyàn níṣìírí?
20 A máa ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíràn jẹ wá lógún nípa fífún wọn níṣìírí. (Róòmù 1:11, 12) Sílà tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tó máa ń fún àwọn èèyàn níṣìírí. Nígbà tí ìgbìmọ̀ olùdarí ní Jerúsálẹ́mù ṣèpinnu lórí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, wọ́n fi lẹ́tà rán àwọn aṣojú sí àwọn Kristẹni láwọn ibòmíì. Sílà, Júdásì, Bánábà àti Pọ́ọ̀lù mú un lọ sí Áńtíókù. Níbẹ̀ Sílà àti Júdásì “fi ọ̀pọ̀ àwíyé fún àwọn ará ní ìṣírí wọ́n sì fún wọn lókun.”—Ìṣe 15:32.
21 Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n fi Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n ní Fílípì, àmọ́ ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé mú kí wọ́n dòmìnira. Ẹ sì wá wo bí inú wọn á ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n láǹfààní láti wàásù tí wọ́n sì rí i tí onítúbú náà àtàwọn aráalé rẹ̀ di onígbàgbọ́! Kí Pọ́ọ̀lù àti Sílà tó fi ìlú yẹn sílẹ̀, wọ́n fún àwọn ará níṣìírí. (Ìṣe 16:12, 40) Ìwọ náà ní láti máa ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Sílà, kó o máa wá bí wàá ṣe máa fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí nípa ìdáhùn rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ àti ìtara rẹ lóde ẹ̀rí. Tíwọ náà bá sì ní “ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí,” jọ̀wọ́ má ṣe bò ó mọ́ra, ńṣe ni kó o “sọ ọ́.”—Ìṣe 13:15.
Máa Rìn ní Ọ̀nà Jèhófà Nìṣó
22, 23. Ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ káwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì ṣe wá láǹfààní?
22 Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa dúpẹ́ pé ìtàn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà, tó jẹ́ “Ọlọ́run ìṣírí gbogbo”! (2 Kọ́r. 1:3, ìtumọ̀ Byington) Tá a bá fẹ́ káwọn ìtàn yìí ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ máa fi ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ nínú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa ká sì gbà kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí wa.—Gál. 5:22-25.
23 Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì, àwọn ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí á máa hàn nínú ìṣe wa. Ó máa mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ẹni tó ń fún wa ní “ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ayọ̀ yíyọ̀.” (Oníw. 2:26) Èyí á sì jẹ́ ká máa mú ọkàn Ọlọ́run ìfẹ́ yọ̀. (Òwe 27:11) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa rírìn ní ọ̀nà Jèhófà nìṣó.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ẹni tó ṣeé fọkàn tán ni ọ́?
• Kí nìdí tá a fi ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
• Báwo làwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onígboyà?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè máa gbà mójú tó ọ̀ràn àwọn ẹlòmíì?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ẹni tó ṣeé fọkàn tán ni Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀, ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún un
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹ̀yin èwe, kí lẹ rí kọ́ lára ọmọdébìnrin ọmọ Ísírẹ́lì yẹn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Kí ni Dọ́káàsì fi ń ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́?